ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 7/22 ojú ìwé 24-27
  • Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Eléwu—Báwo Ni Ohun Tí Ń Náni Ṣe Pọ̀ Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Eléwu—Báwo Ni Ohun Tí Ń Náni Ṣe Pọ̀ Tó?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìyípadà Ọ̀nà Ìgbésí Ayé
  • Àmujù Ọtí Àkóbá Tó Ń Ṣe Fún Àwùjọ
    Jí!—2005
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Bóo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
    Jí!—1999
  • Àwọn Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Gan-an!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 7/22 ojú ìwé 24-27

Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Eléwu—Báwo Ni Ohun Tí Ń Náni Ṣe Pọ̀ Tó?

ÒWE ilẹ̀ Denmark kan sọ pé: “Àìsàn lọ̀gá gbogbo ènìyàn.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àrùn bárakú kan yóò gbà láìjanpata pé òǹrorò gbáà ni “ọ̀gá” yìí! Síbẹ̀, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé àìsàn sábà máa ń dà bí àlejò tí a ránṣẹ́ pè ju bí ọ̀gá kan lọ. Ibùdó Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn ní United States so ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún lára ọjọ́ tí àwọn olùgbàtọ́jú ń lò nílé ìwòsàn pọ̀ mọ́ àwọn àrùn tí a ti lè yẹ̀ sílẹ̀. Kí ni èrèdí rẹ̀? Ọ̀nà ìgbésí ayé búburú, tí ó sì jẹ́ eléwu. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

SÌGÁ MÍMU. Ira, ẹni ọdún 53, ní àrùn ẹran ara wíwú—àbájáde sìgá mímu fún nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀wádún mẹ́rin. Láti ṣètọ́jú àrùn yí, ó nílò ìpèsè afẹ́fẹ́ oxygen tí a dé mọ́ inú ìgò, tí ń náni ní nǹkan bí 400 dọ́là lóṣooṣù. Ní 1994, ọjọ́ mẹ́sàn-án tí ó lò nílé ìwòsàn ná an ní 18,000 dọ́là, tí ó sọ àpapọ̀ owó ìgbàtọ́jú tí Ira ná lọ́dún yẹn di ohun tí ó lé ní 20,000 dọ́là. Síbẹ̀, Ira rò pé ṣíṣíwọ́ sìgá mímu kì í ṣe ọ̀ràn kánjúkánjú. Ó wí pé: “Mo wulẹ̀ ní ìyánhànhàn tí kò ṣeé gbà gbọ́ yìí ni.”

Kì í ṣe Ira nìkan ni ọ̀ràn rẹ̀ rí báyìí. Láìka àwọn ewu tí a mọ̀ pé ó wà nínú sìgá mímu sí, àwọn ènìyàn jákèjádò ayé ń mu nǹkan bíi bílíọ̀nù 15 sìgá lójoojúmọ́. Ní United States, a fojú bù ú pé owó tí a ń ná sórí títọ́jú àwọn àrùn tí ó tan mọ́ sìgá mímu jẹ́ 50 bílíọ̀nù dọ́là. Èyí túmọ̀ sí pé ní 1993, ní ìpíndọ́gba, lórí páálí sìgá kọ̀ọ̀kan tí àwọn ènìyàn rà, nǹkan bíi dọ́là 2.06 ni wọ́n ná sórí títọ́jú àwọn àrùn tí ó tan mọ́ sìgá mímu.

Nígbà tí a bá bí ọmọ kan, ìnáwó lórí títọ́jú àwọn àrùn tí ó tan mọ́ sìgá mímu lè bẹ̀rẹ̀ sí í kóra jọ. Pé kí a wulẹ̀ mẹ́nu ba àpẹẹrẹ kan, ìwádìí kan ní United States rí i pé àwọn ọmọ tí ìyá wọn ń mu sìgá ní ìlọ́po méjì ewu níní àrùn ètè lílà tàbí òkè ẹnu lílà, àrùn kan tí ó lè gbà tó iṣẹ́ abẹ mẹ́rin nígbà tí wọ́n bá fi tó ọmọ ọdún méjì. Ìpíndọ́gba owó ìgbàtọ́jú àrùn yí jálẹ̀ ìgbésí ayé àti àwọn ìnáwó tó jẹ mọ́ ọn jẹ́ 100,000 dọ́là fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Dájúdájú, a kò lè fi dọ́là ṣírò iye tí níní ààbọ̀ ara nígbà ìbí ń náni ní ti ìmọ̀lára.

Àwọn kan sọ pé a ń rí àfirọ́pò iye owó ìgbàtọ́jú gíga tí mímu sìgá ń náni nínú kókó náà pé ọ̀pọ̀ amusìgá kì í pẹ́ láyé tó pé kí wọ́n gba owó àjẹmọ́nú Ààbò Ìmáyédẹrùn. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine ṣe sọ, “àríyànjiyàn wà lórí òpin èrò yí; jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn yóò gbà pé kíkú láìtọ́jọ́ nítorí sìgá mímu kì í ṣe ọ̀nà ìgbatẹnirò láti bójú tó ìnáwó ìgbàtọ́jú.”

ÀMUJÙ ỌTÍ LÍLE. Wọ́n ti so àmujù ọtí líle pọ̀ mọ́ àwọn àìlera mélòó kan, títí kan ìsúnkì ẹ̀dọ̀ki, àrùn ọkàn àyà, àrùn awọfẹ́lẹ́ inú àpòlúkù wíwú, ọgbẹ́ inú, àti àrùn pancreatitis. Ó tún lè sọ ẹnì kan di ẹni tí ó túbọ̀ lè tètè kó àwọn àrùn tí ń rànnìyàn bí òtútù àyà. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Stanton Peele ṣe sọ, ní United States, “bílíọ̀nù 10 dọ́là ni a ń ná láti ṣètọ́jú àwọn ènìyàn tí kò lè kóra wọn níjàánu nídìí ọtí mímu” lọ́dọọdún.

Ọtí líle sábà máa ń nípa lórí ọmọ inú ọlẹ̀. Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọmọdé tí ó ní àbùkù ara nítorí pé àwọn ìyá wọn ń mutí nígbà tí wọ́n lóyún wọn ni a ń bí ní United States nìkan. Àwọn kan lára àwọn ọmọ ọwọ́ wọ̀nyí ń ní àrùn àbùkù ara láti inú oyún (FAS), lọ́pọ̀ ìgbà sì ni àwọn wọ̀nyí ń ní ìpalára ti ara àti ti ọpọlọ. Wọn ti fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìpíndọ́gba ìnáwó ìgbàtọ́jú jálẹ̀ ìgbésí ayé lórí ọmọ kọ̀ọ̀kan tí ó ní àrùn FAS jẹ́ mílíọ̀nù 1.4 dọ́là.

Níwọ̀n bí ọtí líle ti ń dín agbára láti ṣàkóso ìsúnniṣe òjijì kù, àmujù sábà ń kópa kan nínú ìbújáde ìwà ipá, tí ó lè yọrí sí ìpalára tí ń gba àfiyèsí ìṣègùn. Ìpalára tí kò ṣeé ṣàtúnṣe tí àwọn tí ń wakọ̀ nígbà tí wọ́n ti mutí yó ń fà tún wà níbẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí ó ní lórí Lindsey, ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́jọ kan, tí ó já bọ́ láti orí ìjókòó ẹ̀yìn ọkọ̀ ìyá rẹ̀ nígbà tí ọ̀mùtí awakọ̀ kan forí sọ ọkọ̀ wọn. Lindsey lo ọ̀sẹ̀ méje nílé ìwòsàn, ó sì nílò iṣẹ́ abẹ mélòó kan. Ìnáwó ìgbàtọ́jú rẹ̀ lé ní 300,000 dọ́là. Ó tilẹ̀ rìnnà kore ni láti là á já pàápàá.

ÌJOÒGÙNYÓ. Olùwádìí kan fojú bù ú pé iye tí ìjoògùnyó ń náni lọ́dọọdún ní America jẹ́ bílíọ̀nù 67 dọ́là. Joseph A. Califano, Kékeré, ààrẹ Ibùdó Iṣẹ́ Lórí Ìsọdibárakú àti Àwọn Ohun Tí Ń Di Bárakú ní Yunifásítì Columbia ní New York, tọ́ka sí apá anánilówó mìíràn nínú ìṣòro náà pé: “Àwọn ọmọ tí ìyá wọn ń lo oògùn crack nígbà tí wọ́n wà nínú oyún, tí kò wọ́pọ̀ ní ẹ̀wádún kan sẹ́yìn, ń kún iyàrá ilé ìwòsàn àwọn ìkókó tí ń náni ní 2,000 dọ́là lóòjọ́. . . . Ó lè náni ní mílíọ̀nù 1 dọ́là kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó bá là á já tó di àgbàlagbà.” Láfikún sí i, Califano sọ pé, “ìkùnà àwọn aboyún láti wá ìtọ́jú ṣáájú ìbímọ, kí wọ́n sì ṣíwọ́ jíjoògùnyó ló fa ọ̀pọ̀ jú lọ lára bílíọ̀nù 3 dọ́là tí a ná sórí Ìṣètò Ìpèsè Ìrànwọ́ Ìṣègùn ní 1994 lórí àwọn olùgbàtọ́jú tí a fún ní ibùgbé, oúnjẹ àti ìtọ́jú nílé ìwòsàn, tí ọ̀ràn wọn jẹ mọ́ ìjoògùnyó.”

Bí ipò ná ṣe bani nínú jẹ́ tó túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà tí a bá ṣàgbéyẹ̀wò iye púpọ̀ jọjọ tí ipa tí ìwà abèṣe yìí ń ní lórí ẹ̀dá ènìyàn ń náni. Gbọ́nmisi-omi-òto nínú ìgbéyàwó, àwọn ọmọdé tí a pa tì, àti orísun ìṣúnná tí a gbọ́n gbẹ wà lára àwọn ìṣòro wíwọ́pọ̀ tí ń kan àwọn ìdílé tí ìjoògùnyó ti wó palẹ̀.

ÌṢEKÚṢE. Ó lé ní mílíọ̀nù 12 ènìyàn ní United States tí ń kó àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré (STDs) lọ́dọọdún, tí ó mú kí United States ní iye àrùn STD púpọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdè èyíkéyìí tó ti gòkè àgbà. David Celentano, ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìtọ́jú Ara àti Ìlera Ará Ìlú ní Yunifásítì Johns Hopkins, pe èyí ní “ìmójútìbáni orílẹ̀-èdè.” Iye tí àwọn àrùn wọ̀nyí ń náni ní tààrà, láìka ti àrùn AIDS mọ́ ọn, jẹ́ nǹkan bíi bílíọ̀nù 10 dọ́là lọ́dún. Àwọn ọ̀dọ́langba ló wà nínú ewu àrà ọ̀tọ̀. Kò sì yani lẹ́nu! Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ṣe wí, nígbà tí wọ́n bá fi dé ọdún kejìlá nílé ẹ̀kọ́, nǹkan bí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ti ní ìbálòpọ̀, èyí tí ó sì sún mọ́ ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ti bá ẹni mẹ́rin lò pọ̀, ó kéré tán.

Àrùn AIDS jẹ́ àjálù kan fúnra rẹ̀ nínú ọ̀ràn ìlera. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1996, ìtọ́jú gbígbéṣẹ́ jù lọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó—àwọn egbòogi tí ń dí ìṣiṣẹ́ èròjà protease lọ́wọ́ ní àpapọ̀ pẹ̀lú àwọn ojúlówó egbòogi àtijọ́—ń ná ẹnì kọ̀ọ̀kan ní 12,000 dọ́là sí 18,000 dọ́là lọ́dún. Ṣùgbọ́n ńṣe ni èyí wulẹ̀ jẹ́ ìpín kan nínú ohun tí àrùn AIDS ń náni, tí ó fara sin, tí ó kan àdánù lórí ohun tí alárùn náà ì bá ṣe àti àdánù ti àwọn tí ń fi àkókò sílẹ̀ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tàbí kúrò nílé ẹ̀kọ́ láti bójú tó o. A ṣírò rẹ̀ pé nígbà tí ó bá fi di ọdún 2000, fáírọ́ọ̀sì HIV àti àrùn AIDS yóò ti gba iye tí ó wà láàárín 356 bílíọ̀nù dọ́là sí 514 bílíọ̀nù dọ́là kárí ayé—tí ó dọ́gba pẹ̀lú pípa gbogbo ètò ọrọ̀ ajé yálà Australia tàbí Íńdíà run.

ÌWÀ IPÁ. Nígbà tí Joyceline Elders ṣì jẹ́ ọ̀gá àgbà oníṣẹ́ abẹ United States, ó sọ pé iye tí ìwà ipá náni ní ti ìgbàtọ́jú ní 1992 jẹ́ bílíọ̀nù 13.5 dọ́là. Ààrẹ Bill Clinton ti United States sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí ìgbàtọ́jú fi gbówó lórí ní America ni pé àwọn ènìyàn tí a ṣá lọ́gbẹ́ àti àwọn tí a yìnbọn fún ló kún àwọn ilé ìwòsàn wa àti àwọn iyàrá tí a ṣètò fún ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn.” Pẹ̀lú ìdí rere, ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association pe ìwà ipá ní United States ní “ọ̀ràn ìṣòro ìlera ará ìlú.” Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ipá kì í ṣe àrùn kan ní ìtumọ̀ ‘àfiṣàpẹẹrẹ,’ ipa tí ó ń ní lórí ìlera ara ẹni àti ti ará ìlú jinlẹ̀ gan-an bíi ti ọ̀pọ̀ àìlera ara gidi—bóyá kí ó tilẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ìròyìn kan tí 40 ilé ìwòsàn ní Colorado ṣe sọ pé ìpíndọ́gba iye tí ìwà ipá ń ná ẹnì kọ̀ọ̀kan láàárín oṣù mẹ́sàn-án àkọ́kọ́ ní 1993 jẹ́ 9,600 dọ́là. Iye tí ó lé ní ìdajì àwọn tí a gbà sílé ìwòsàn ni kò ní ìṣètò ìbánigbófò ìlera, ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí kò sì lágbára láti san owó ìtọ́jú tàbí wọn kò fẹ́ láti san án. Irú ipò bẹ́ẹ̀ mú kí owó orí, owó ìbánigbófò, àti owó ìgbàtọ́jú nílé ìwòsàn ga sí i. Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ Ilé Ìwòsàn Colorado sọ pé: “Gbogbo wa la jọ ń san án.”

Ìyípadà Ọ̀nà Ìgbésí Ayé

Ní ojú ìwòye ẹ̀dá ènìyàn, ìfojúsọ́nà yíyí ìtẹ̀sí ọ̀nà ìgbésí ayé eléwu pa dà kò dán mọ́rán. Ìròyìn kan tí Yunifásítì Columbia ṣe sọ pé: “America kì í ṣe Ọgbà Édẹ́nì, a kì yóò sì lè gba ara wa lọ́wọ́ lílo gbogbo èròjà tí ń di bárakú nílòkulò. Àmọ́ dé àyè tí a bá dín irú ìlòkulò bẹ́ẹ̀ kù, a óò kórè rere ti àwọn ọmọ tí ara wọn túbọ̀ dá ṣáṣá, ìwà ipá àti ìwà ọ̀daràn tí ó dín kù, owó orí tí ó túbọ̀ kéré, ìnáwó ìgbàtọ́jú tí ó dín kù, èrè tí ó túbọ̀ pọ̀ sí i, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó túbọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ sí i àti ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn AIDS tí ó túbọ̀ dín kù.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé Bíbélì jẹ́ ìrànwọ́ tí ó tóbi jù lọ láti ṣàṣeparí góńgó yẹn. Bíbélì kì í ṣe ìwé lásán kan. Ẹlẹ́dàá ènìyàn, Jèhófà Ọlọ́run, ló mí sí i. (Tímótì Kejì 3:16, 17) Òun ni “Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Àwọn ìlànà tí a là sílẹ̀ nínú Bíbélì gbámúṣé, àwọn tí ó sì ń rìn nínú ìmọ̀ràn rẹ̀ ń jàǹfààní rẹpẹtẹ.

Bí àpẹẹrẹ, Esther ti fìgbà kan jẹ́ afìkanrànkan.a Lẹ́yìn tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì, ẹni tí ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ké sí i láti ṣèbẹ̀wò ọjọ́ kan fún ìfinimọlẹ̀ yí ká orílé iṣẹ́ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní Brooklyn, New York. Lákọ̀ọ́kọ́, Esther lọ́ra. Ní mímọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mu sìgá, ó ṣe kàyéfì lórí bí òun ṣe lè wà pẹ̀lú wọn lódindi ọjọ́ kan. Nítorí náà, Esther fi sìgá kan sínú àpamọ́wọ́ rẹ̀, ní ríronú pé, bí òun bá nímọ̀lára ìsúnni láti mu sìgá, òun yóò wulẹ̀ yọ́ kọ́rọ́ lọ sínú ilé ìtura kan ni. Bí ó ti wéwèé rẹ̀ gẹ́lẹ́, lẹ́yìn ọ̀kan lára àwọn ìrìn ìfinimọlẹ̀ náà, Esther wọ ilé ìtura àwọn obìnrin kan, ó sì mú sìgá rẹ̀ jáde. Ṣùgbọ́n nígbà náà ni ó kíyè sí ohun kan. Iyàrá náà mọ́ tónítóní láìsí àbààwọ́n kankan, afẹ́fẹ́ inú rẹ̀ sì tura. Esther rántí pé: “N kò wulẹ̀ lè dọ̀tí ibẹ̀ nípa mímu sìgá náà, nítorí náà, mo jù ú sínú àwo ìyàgbẹ́, mo sì ṣàn án dà nù. Ìyẹn sì ni sìgá tí mo fọwọ́ kan kẹ́yìn!”

Jákèjádò ayé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn bí Esther ń kọ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Wọ́n ń ṣe ara wọn láǹfààní, wọ́n sì ń di ẹni tí ó wúlò gidi fún àwùjọ tí wọ́n ń gbé. Ní pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n ń mú ọlá wá fún Ẹlẹ́dàá wọn, Jèhófà Ọlọ́run.—Fi wé Òwe 27:11.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsapá dídára jù lọ tí ẹ̀dá ènìyàn ṣe kò lè ṣe àtúnmúwá “Ọgbà Édẹ́nì,” Bíbélì sọ pé Ọlọ́run yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Pétérù Kejì 3:13 sọ pé: “Àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun kan wà tí àwa ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀ [Ọlọ́run], nínú àwọn wọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (Fi wé Aísáyà 51:3.) Nínú ilẹ̀ ayé tuntun yẹn, a kì yóò dààmú nípa ìgbàtọ́jú mọ́, nítorí pé aráyé yóò gbádùn ìwàláàyè nínú ìlera pípe—lọ́nà tí Ọlọ́run pète rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. (Aísáyà 33:24) Ìwọ yóò ha fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gidi.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

© 1985 P. F. Bentley/Black Star

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́