Ọ̀rọ̀ Líle, Ọkàn Tí A Ni Lára
“Ìwọ òpònú afàdìẹ̀dìẹ̀ yí!”a Obìnrin kan ní Japan ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn dáradára—ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń sọ ọ́ sí i nígbà tí ó wà lọ́mọdé. Ta ní ń sọ ọ́ sí i? Ṣé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ni? Ṣé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ ni? Rárá. Àwọn òbí rẹ̀ ni. Ó rántí pé: “Mo máa ń sorí kọ́ nítorí pé ìpeni-lórúkọ-kórúkọ náà máa ń wọ̀ mí ní akínyẹmí ara.”
Ọkùnrin kan ní United States rántí pé nígbà tí òun wà lọ́mọdé, ẹ̀rù máa ń ba òun, tí òun sì máa ń dààmú nígbàkigbà tí bàbá òun bá darí wá sílé. Ó sọ pé: “Títí di òní olónìí, mo ṣì lè rántí ìró táyà rẹ̀ bó ti ń bọ̀ lọ́nà, ó sì ń dá òótù pa mí. Àbúrò mi obìnrin yóò fara pa mọ́. Bàbá mi kì í fẹ́ tẹ́wọ́ gba ohun kan tí ó dín kù sí pípé, ó sì máa ń bú mọ́ wa nígbà gbogbo nítorí pé kò sí iṣẹ́ ilé tí a lè ṣe kí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn.”
Ẹ̀gbọ́nbìnrin ọkùnrin yìí fi kún un pé: “N kò lè rántí ìgbà kankan tí ọ̀kan nínú àwọn òbí wa gbá wa mọ́ra, tí ó fẹnu kò wá lẹ́nu, tàbí tí ó sọ ohun kan bíi ‘Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ’ tàbí ‘O ṣeé mú yangàn.’ Ní ti ọmọdé kan, àìkìígbọ́ ‘Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ’ nígbà kankan dọ́gba pẹ̀lú gbígbọ́ ‘Mo kórìíra rẹ’—lójoojúmọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀.”
ÀWỌN kan lè sọ pé ìrora ọkàn tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jìyà rẹ̀ nígbà ọmọdé kò tó nǹkan. Dájúdájú, kò ṣàjèjì pé kí a máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ líle, aláìnínú-rere sí àwọn ọmọdé, kí a sì máa hùwà ìmúnibínú sí wọn. Àwọn àkọlé ìròyìn àkàtagìrì nínú ìwé agbéròyìnjáde àti àwọn àfihàn ṣókí arùmọ̀lára-sókè lórí tẹlifíṣọ̀n kì í tẹnu mọ́ irú èyí. Ìbàjẹ́ náà kò ṣeé fojú rí. Ṣùgbọ́n bí àwọn òbí bá ń fìyà jẹ àwọn ọmọ wọn bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, àwọn àbájáde rẹ̀ lè máa múni banú jẹ́ bí ó ti wù kí ó rí—kí ó sì wà bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé.
Ṣàgbéyẹ̀wò ìwádìí kan tí a ṣe ní 1990 láti fi tọpa èyí tí a kọ́kọ́ ṣe ní 1951 tí ó ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí àwọn òbí ń gbà tọ́mọ tí a lò fún àwùjọ àwọn ọmọ ọlọ́dún márùn-ún kan. Ó ṣeé ṣe fún àwọn olùwádìí láti ṣàwárí àwọn ọmọ wọ̀nyí, tí ọjọ́ orí wọn ti wà ní ìpín ìdajì ìgbésí ayé ní báyìí, láti lóye ipa ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí ọ̀nà tí a gbà tọ́ wọn dàgbà ní. Ìwádìí tuntun náà parí èrò sí pé àwọn ọmọ náà tí wọ́n wá ní ìṣòro lílekoko jù lọ nínú ìgbésí ayé níkẹyìn, tí wọn kò ní ìgbádùn ní ti ìmọ̀lára, tí ìgbésí ayé wọn nínú ìgbéyàwó, nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́, àti níbi iṣẹ́ pàápàá, kún fún ìṣòro gidigidi, kò fi dandan jẹ́ àwọn ọmọ àwọn òbí tó tálákà tàbí ti àwọn òbí tó lówó tàbí ti àwọn òbí tó ní ìṣòro. Wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ àwọn òbí tí wọ́n ya àṣo, tí wọn kò sì lọ́yàyà, tí wọn kò sì fi ìfẹ́ni hàn tó tàbí tí wọn kò fi hàn rárá.
Àwárí yìí wulẹ̀ jẹ́ ìkófìrí àfihàn òtítọ́ kan tí a kọ sílẹ̀ ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà sorí kodò.” (Kólósè 3:21) Ó dájú pé ìfìyàjẹni ọlọ́rọ̀ ẹnu tàbí ti ìmọ̀lára láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí máa ń sún àwọn ọmọ bínú, ó sì lè yọrí sí mímú kí wọ́n sorí kọ́ ní gidi.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Growing Up Sad, ṣe sọ, láìpẹ́ sẹ́yìn, àwọn dókítà rò pé kò sí ohun kan tí ń jẹ́ ìsoríkọ́ ìgbà ọmọdé. Ṣùgbọ́n àkókò àti àwọn ìrírí ti fi hàn pé òdì kejì rẹ̀ ni òtítọ́. Lónìí, àwọn òǹkọ̀wé fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ìsoríkọ́ ìgbà ọmọdé wà, ó sì wọ́pọ̀. Lára àwọn ohun tí ń fà á ni kí àwọn òbí ṣá ọmọ tì tàbí kí wọ́n fìyà jẹ ẹ́. Àwọn òǹkọ̀wé náà ṣàlàyé pé: “Nínú àwọn ọ̀ràn kan, òbí náà ti fi ọmọ náà sábẹ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àríwísí àti ìtẹ́nilógo. Nínú àwọn ọ̀ràn míràn, àlàfo kan wulẹ̀ ti wà nínú ipò ìbátan òbí sí ọmọ: òbí náà kò ṣàfihàn ìfẹ́ tí ó ní fún ọmọ náà. . . . Àbájáde rẹ̀ ní pàtàkì jẹ́ ọ̀ràn ìbànújẹ́ fún àwọn ọmọ irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ nítorí pé lójú ọmọdé kan—tàbí lójú àgbàlagbà kan, nínú ọ̀ràn yí—ìfẹ́ ṣe kókó bí ìtànṣán oòrùn àti omi ti ṣe kókó fún ohun ọ̀gbìn kan.”
Nípasẹ̀ ìfẹ́ tí òbí ní, bí a bá fi hàn kedere, ní gbangba, àwọn ọmọ ń kẹ́kọ̀ọ́ kókó kan pé: Wọ́n ṣeé fẹ́ràn; wọ́n níye lórí. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń ṣi èrò yí mú fún oríṣi ẹ̀mí ìjọra ẹni lójú kan, fífẹ́ ara ẹni ju àwọn mìíràn lọ. Àmọ́ nínú ọ̀ràn yí, ohun tí ó túmọ̀ sí kọ́ nìyẹn. Òǹkọ̀wé kan sọ nínú ìwé rẹ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ náà pé: “Èrò tí ọmọ rẹ ní nípa ara rẹ̀ ń nípa lórí irú àwọn ọ̀rẹ́ tí ó ń yàn, bí ó ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ sí, irú ẹni tí ó fẹ́, àti bí yóò ṣe ṣàṣeyọrí tó nínú ìgbésí ayé.” Bíbélì jẹ́wọ́ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti ní ojú ìwòye wíwà déédéé, aláìjọra-ẹni-lójú, nípa ara ẹni, nígbà tí ó sọ pé èkejì tí ó tóbi jù lọ nínú gbogbo àṣẹ ni: “Ìwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Mátíù 22:38, 39.
Ó ṣòro láti ronú kan òbí kan tí orí rẹ̀ pé, tí yóò fẹ́ láti fọ́ ohun kan tí ó ṣe pàtàkì, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́ bí èrò ìníyelórí ara ẹni ọmọdé kan yángá. Nígbà náà, èé ṣe tí ó fi sábà máa ń ṣẹlẹ̀? Báwo ni a sì ṣe lè dá a dúró?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní èdè Japanese, noroma baka!