Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwè Wa
Èébú Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Láti Ọ̀rọ̀ Dídunni sí Ọ̀rọ̀ Atunilára” (October 22, 1996) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onírúurú àpilẹ̀kọ tí ó ti fi bí Jèhófà ṣe bìkítà fún wa tó hàn. Àwọn àpilẹ̀kọ lórí “Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀mùtí àti Àwọn Ìdílé Wọn” (May 22, 1992 [Gẹ̀ẹ́sì]), “Awọn Obinrin Yẹ Lati Bọ̀wọ̀ Fún” (July 8, 1992), “Iranlọwọ fun Awọn Ọmọ Òbí Akọrasílẹ̀” (April 22, 1991), àti “Iwa-Ipa Inu Ilé Yoo Ha Dopin Lae Bi?” (February 8, 1993) ni gbogbo wọn ti gbé mi ró láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá nínú fífi ìyà èrò ìmọ̀lára jẹni láti ọwọ́ ọkọ tí ó jẹ́ ọ̀mùtí kan. Mo ti ka àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí pẹ̀lú omijé ayọ̀ àti ìbànújẹ́ lójú. Ọkàn mi kún fún ọpẹ́ sí Ọlọ́run kan tí ó mọ ẹ̀rù, ìrora, àti hílàhílo tí ó wà nínú wa lọ́hùn-ún.
J. C., Kánádà
Àwọn àpilẹ̀kọ náà ru mí sókè gan-an ni. Wọ́n ṣàlàyé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ láàárín èmi àti ọkọ mi. Mo lè gbà pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. Ẹ ń bá àwọn obìnrin lò tìfẹ́tìfẹ́ gan-an, èyí sì fi dá mi lójú pé Jèhófà ń lo ètò àjọ yìí.
P. S., Germany
Àwọn àpilẹ̀kọ náà fún mi níṣìírí láti máa bá àìlera mi jà nípa ṣíṣàkóso ahọ́n mi. Ní báyìí, mo ti mọ bí ó ṣe yẹ kí ń máa bá ọkọ mi lò. Omijé ń bọ́ lójú mi bí mo ṣe ń ka àwọn àpilẹ̀kọ náà.
G. I., Austria
Ọkọ mi ti máa ń bú mi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Mo ti gbìyànjú láti yẹra fún dídi aláìnírètí nípa mímú àwọn èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run dàgbà àti nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ mi dí nínú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún. Àwọn àpilẹ̀kọ yín kì í jẹ́ kí n nímọ̀lára ìdánìkanwà—pé ẹnì kan lóye àwọn ìṣòro mi.
M. N., Ítálì
Mo ti ka púpọ̀ lára àwọn àpilẹ̀kọ yín tẹ́lẹ̀ rí, àmọ́ àwọn wọ̀nyí kàn mí gbọ̀ngbọ̀n. Wíwo àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 9 dà bí wíwo ìyá mi tàbí arábìnrin mi, tí àwọn ọkọ wọn ti fìyà jẹ wọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Mo ṣe ẹ̀dà àwọn àpilẹ̀kọ yìí, mo sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn tí mo mọ̀ tí wọ́n ń jìyà lọ́nà yí. A ń fojú sọ́nà fún ayé tuntun Ọlọ́run, níbi tí kò ní sí oríṣiríṣi èébú mọ́.
B. P., Kenya
Nígbà tí mo mú ìwé ìròyìn náà fún ẹ̀gbọ́n ìyá mi, tí ó máa ń bú ìyàwó rẹ̀, ó kà á lọ́pọ̀ ìgbà. Lẹ́yìn náà, a ṣàkíyèsí pé kì í bú ìyàwó rẹ̀ mọ́ àti pé kò tún sí làásìgbò nílé wọn mọ́. Òun àti ìyàwó rẹ̀ ń dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ara wọn. Mo fẹ́ láti fi ọpẹ́ náà ṣọwọ́ sí Jí!
F. F., Nàìjíríà
Ajoògùnyó Tẹ́lẹ̀ Rí Mo dúpẹ́ fún àpilẹ̀kọ náà, “Òtítọ́ Fún Mi Ní Ìwàláàyè Mi Padà.” (October 22, 1996) Ọmọ ọdún 19 ni mí, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé aṣáájú ọ̀nà déédéé, tàbí ajíhìnrere alákòókò kíkún, ni mí, mo máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé mo ń pàdánù àwọn ohun kan. Ìrírí Dolly Horry ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé ẹ̀tàn lásán ni àwọn ohun tí ń fani mọ́ra nínú ayé.
R. M. A., Bolivia
Mo fẹ́ láti sọ bí àpilẹ̀kọ yìí ti ru mí sókè tó. Bí mo ti ń ka ìtàn ìgbésí ayé Dolly Horry, omijé ń bọ́ lójú mi. Mo gbàdúrà pé kí àpilẹ̀kọ yìí sún àwọn mìíràn tí wọ́n ń tọ ọ̀nà tí Dolly ń tọ̀ tẹ́lẹ̀ rí láti yí pa dà sọ́nà ìgbésí ayé tí ó nítumọ̀ nísinsìnyí.
O. S. O., Nàìjíríà
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo kà á sí àǹfààní láti ní Dolly Horry gẹ́gẹ́ bí arábìnrin Kristẹni. Nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba, ipò kejì ni mo fi Jèhófà sí nínú ìgbésí ayé mi. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀rọ̀ mi kò sú ìyá mi, ó sì láyọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí mo ṣèrìbọmi lọ́dún tó kọjá.
B. B., Australia