Omi—Ohun Tí Ń Gbẹ́mìí Pílánẹ́ẹ̀tì Yí Ró
KÒ LÁWỌ̀, kò lóòórùn, kò ní ìtọ́wò, kò sì ní èròjà afáralókun nínú, omi ṣe pàtàkì fún gbogbo ohun abẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹ̀dá ènìyàn, ẹranko, tàbí irúgbìn tí ó lè wà láìsí i. Láti orí erin sí kòkòrò tín-tìn-tín, omi ṣe pàtàkì; kò sì ní àfidípò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ènìyàn tí iye wọn lé ní bílíọ̀nù márùn-ún tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ní láti máa gba nǹkan bíi lítà 2.5 omi sára ní mímu ú bí omi àti nínú oúnjẹ lójoojúmọ́ kí wọ́n lè máa ta kébékébé. Láìsí omi, kò lè sí ìwàláàyè.
Láìsí omi, kò lè ṣeé ṣe láti mú irè jáde lóko tàbí láti sin ohun ọ̀sìn. Láìsí omi, kò lè sí oúnjẹ—láìsí oúnjẹ, kò lè sí ìwàláàyè.
Ó dùn mọ́ni nínú pé omi wà gan-an. Nígbà tí wọ́n ya fọ́tò pílánẹ́ẹ̀tì wa rírẹwà aláwọ̀ búlúù láti gbalasa òfuurufú, ń ṣe ló jọ pé Omi là bá máa pè é, kì í ṣe Ilẹ̀ Ayé. Ní tòótọ́, bí gbogbo omi tó wà lágbàáyé bá bo ojú pílánẹ́ẹ̀tì wa ní dọ́gbandọ́gba, gbogbo àgbáyé yóò di òkun kan tí ó fi kìlómítà 2.5 jìn. Òkun Pacific lè gbé gbogbo ojú ilẹ̀ ayé mì, tí àyè yóò sì ṣẹ́ kù.
Dájúdájú, inú àwọn òkun ni ọ̀pọ̀ jù lọ nínú omi tó wà lórí ilẹ̀ ayé wà, omi oníyọ̀ sì ni omi òkun. Bí ẹnì kan bá ń mu omi òkun nìkan, òògbẹ àti àìsí omi lára kò ní pẹ́ pa á nígbà tí ara bá ń gbìyànjú láti mú àpọ̀jù iyọ̀ kúrò lára. Omi òkun kò dára fún iṣẹ́ àgbẹ̀ tàbí ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ—ó máa ń pa ọ̀pọ̀ jù lọ irúgbìn, ó sì ń tètè mú kí àwọn ẹ̀rọ dógùn-ún. Nítorí náà, fún apá tí ó pọ̀ jù lọ, àwọn ènìyàn lè lo omi òkun kìkì bí wọ́n bá yọ iyọ̀ inú rẹ̀ kúrò, ìyẹn sì jẹ́ iṣẹ́ tó gba ìnáwó gọbọi.
Ìpín 3 nínú ọgọ́rùn-ún péré nínú omi tó wà lágbàáyé ni kò níyọ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo omi tí kò níyọ̀ yẹn—nǹkan bí ìpín 99 nínú ọgọ́rùn-ún nínú rẹ̀—ni ó dúró pa sókè ìṣàn òkìtì yìnyín àti omi dídì tàbí ló wà nísàlẹ̀ ilẹ̀. Ìpín 1 nínú ọgọ́rùn-ún péré ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó ìran aráyé.
Kò jọ pé ìpín 1 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀. A ha lè lo omi tí kò níyọ̀ náà tán pátápátá bí? Ó jọ pé a kò lè lò ó tán. Ìwé ìròyìn náà, People & the Planet, sọ pé: “Kódà bí a bá pín [ìpín 1 nínú ọgọ́rùn-ún] yìí ní dọ́gbandọ́gba ní gbogbo ayé, tí a sì ṣọ́ ọ lò, yóò tó láti pèsè fún ìlọ́po méjì tàbí mẹ́ta iye àwọn tí ń gbé ayé ní lọ́ọ́lọ́ọ́.”
Ní pàtàkì, àpapọ̀ omi tó wà lórí ilẹ̀ ayé kì í pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni kì í dín kù. Ìwé ìròyìn Science World sọ pé: “Ẹranko dinosaur kan lè ti fi omi tí o ń lò lónìí pòùngbẹ nígbà kan rí. Ìyẹn jẹ́ nítorí pé gbogbo omi tó wà lórí Ilẹ̀ Ayé nísinsìnyí ni ó tí ì wà rí—tàbí ni yóò wà nígbàkigbà.”
Èyí jẹ́ nítorí pé omi tó wà lágbàáyé àti àyíká rẹ̀ ń yí po láìlópin—láti inú òkun sínú afẹ́fẹ́ àyíká, sí ilẹ̀, sínú odò, pa dà sínú òkun. Bí ọkùnrin ọlọgbọ́n náà ṣe kọ ọ́ nígbà pípẹ́ sẹ́yìn ló rí pé: “Gbogbo odò ló ń ṣàn lọ sínú òkun lẹ́ẹ̀kan sí i, síbẹ̀ òkun kò kún ya rí; ibi tí àwọn odò tí ń ṣàn bọ̀ ni wọ́n tún ń pa dà sí.”—Oníwàásù 1:7, New English Bible.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé omi tí kò níyọ̀ pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹkùn ilẹ̀ ló wà nínú ìṣòro. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e gbé àwọn ìṣòro àti ìfojúsọ́nà fún yíyanjú wọn yẹ̀ wò.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò NASA