Kí Ni Ojútùú Rẹ̀?
ÀWỌN ògbóǹkangí jiyàn gan-an lórí àwọn ojútùú sí ìṣòro dídíjú tí ìran aráyé ní nípa omi. Báǹkì Àgbáyé fẹ́ kí a ná 600 bílíọ̀nù dọ́là sórí ètò ìmọ́tótó àti omi láàárín ọdún mẹ́wàá tí ń bọ̀. Iye tí kíkùnà láti ná an yóò náni tilẹ̀ lè pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Fún àpẹẹrẹ, ní Peru, láìpẹ́ yìí ni àjàkálẹ̀ àrùn onígbáméjì tó jà fún ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá, tí omi tí a sọ di eléèérí ṣokùnfà, ná wọn ní nǹkan bíi bílíọ̀nù kan dọ́là—ìlọ́po mẹ́ta owó tí wọ́n ná sórí ìpèsè omi orílẹ̀-èdè náà láàárín gbogbo àwọn ọdún 1980.
Síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ṣonígbọ̀wọ́ wọn ní èrò rere lọ́kàn, àwọn ìdáwọ́lé lórí omi kì í sábà fi bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn aláìní láǹfààní. Pípọ̀ tí àwọn ènìyàn ń pọ̀ sí i ní àwọn ìlú ńlá ní àwọn àgbègbè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ti ré kọjá àlà, ó sì kún fún rúdurùdu. Àwọn aláìní ń gbé inú àwọn ahẹrẹpẹ ahéré tí ó kún àkúnya tí kò ní omi ẹ̀rọ, tí kò sì mọ́. Nítorí pé wọn kò ní àǹfààní ìpèsè omi tí ìjọba ṣètò, wọ́n gbọ́dọ̀ sanwó gọbọi fún àwọn tí ń ta omi kí wọ́n tó lè rí omi, tí ó sábà máa ń jẹ́ omi dídọ̀tí.
Ní kedere, ìṣòro omi tí ó wà kárí ayé jẹ́ ohun dídíjú, ó sì kan àwọn kókó abájọ tó bára tan: àìtó omi, bíba omi jẹ́, ipò àìní, àrùn, àti ìwọ̀n púpọ̀ sí i tí àwọn ènìyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i nílò. Bákan náà, ó ṣe kedere pé àwọn ènìyàn kò lè yanjú àwọn ìṣòro wọ̀nyí.
Ìdí fún Níní Ẹ̀mí Nǹkan-Yóò-Dára
Bí ó ti wù kí ó rí, ọjọ́ iwájú kò kún fún àìnírètí tó bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti sọ tẹ́lẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé ojútùú sí ìṣòro omi lágbàáyé kò sí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn; ọwọ́ Ọlọ́run ló wà. Òun nìkan ló ní agbára àti ìfẹ́ inú láti yanjú gbogbo ìṣòro omi.
Kò sí iyàn jíjà nínú pé Jèhófà Ọlọ́run lè yanjú àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Òun ni Olùṣàgbékalẹ̀ àti Ẹlẹ́dàá, kì í ṣe tí ilẹ̀ ayé nìkan ṣùgbọ́n ti omi tó wà nínú rẹ̀ pẹ̀lú. Òun ló mú kí omi máa yí àyípoyípo àgbàyanu tó ń yí pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn àyípoyípo àdánidá mìíràn tí ń mú kí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé ṣeé ṣe. Ìṣípayá 14:7 tọ́ka sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.”
Jèhófà ní agbára láti darí omi tó wà lágbàáyé. Òun ni “Ẹni tí ń rọ òjò sórí ilẹ̀ ayé, tí ó sì ń rán omi sórí àwọn pápá gbayawu.” (Jóòbù 5:10, NW) Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ó ń yí aginjù pa dà di adágún omi tí ó kún fún esùsú, àti ilẹ̀ tí ó jẹ́ ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi di ibi tí omi ti ń ṣàn jáde.”—Orin Dáfídì 107:35, NW.
Léraléra ni ó ti fi agbára rẹ̀ láti pèsè omi hàn. Fún àpẹẹrẹ, ó pèsè omi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù fún 40 ọdún, ó máa ń ṣe é lọ́nà ìyanu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bíbélì sọ pé: “Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìṣàn omi jáde wá láti inú àpáta gàǹgà, ó sì ń mú kí omi ṣàn gẹ́gẹ́ bí àwọn odò. Wò ó! Ó lu àpáta, kí omi lè ṣàn, kí àwọn ọ̀gbàrá sì lè ya jáde.”—Orin Dáfídì 78:16, 20, NW.
Ohun Tí Ọlọ́run Yóò Ṣe
Ọlọ́run kì yóò jẹ́ kí ìṣòro omi máa bá a lọ títí ayé. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí òun yóò ṣe nǹkan nítorí ti gbogbo àwọn ènìyàn jákèjádò ayé tí wọ́n dàníyàn láti gbé lábẹ́ ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ ti ìjọba rẹ̀ ọ̀run, tí yóò gba àkóso orí ilẹ̀ ayé láìpẹ́.—Mátíù 6:10.
Ìṣàkóso, tàbí Ìjọba, yẹn yóò fòpin sí àwọn àrùn tí a ń kó nínú omi, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn àìsàn míràn. Bíbélì mú un dá àwọn tí wọ́n dúró ṣinṣin síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lójú pé: “[Ọlọ́run] yóò sì bù kún oúnjẹ rẹ àti omi rẹ dájúdájú; [òun yóò] sì mú àrùn kúrò ní àárín rẹ ní ti gidi.” (Ẹ́kísódù 23:25, NW) Síwájú sí i, àwọn tí ń ba omi ilẹ̀ ayé jẹ́ ni a óò mú kúrò nígbà tí ó bá ń “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.”—Ìṣípayá 11:18.
Gbogbo ilẹ̀ ayé yóò gbèrú lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run. Kì yóò ṣẹlẹ̀ mọ́ láé pé àwọn ènìyàn ń dààmú kí wọ́n tó rí omi aláìníyọ̀, tí ó mọ́. Ọlọ́run Olódùmarè, tí ó máa ń sọ òtítọ́ nígbà gbogbo, mí sí wòlíì rẹ̀ láti kọ̀wé nípa ọjọ́ ọ̀la pé: “Nítorí pé omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀. Ilẹ̀ tí ooru ti mú gbẹ hán-ún hán-ún yóò sì ti wá rí bí odò adágún tí ó kún fún esùsú, ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò sì ti wá rí bí àwọn ìsun omi.”—Aísáyà 35:6, 7, NW; Hébérù 6:18.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Omi yóò ti ya jáde ní aginjù, . . . ìyàngbẹ ilẹ̀ [yóò sì rí] bí àwọn ìsun omi.”—Aísáyà 35:6, 7, NW