Ayé Kan Tí A Kọ́ Láti Kórìíra
ÀWỌN ènìyàn jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan lọ́nà àbínibí. Ìmọtara-ẹni-nìkan sì lè yí pa dà di ìkórìíra bí a kò bá kápá rẹ̀. Bíi pé ìmọtara-ẹni-nìkan lọ́nà àdánidá kò burú tó, àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ń kọ́ àwọn ènìyàn láti jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan ní gidi!
Òtítọ́ ni pé àwọn ọ̀ràn gbogbogbòò kì í fìgbà gbogbo jẹ́ òtítọ́, síbẹ̀, àwọn ẹ̀mí ìrònú kan gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò lè kọ̀ wọ́n tì bí àìbẹ́gbẹ́mu lásán. Àwọn òṣèlú kò ha sábà máa ń ní ọkàn ìfẹ́ sí bíborí ìbò ju ríran àwọn àgbègbè ìdìbò wọn lọ́wọ́ lọ bí? Àwọn oníṣòwò kò ha sábà ń ní ọkàn ìfẹ́ sí rírọ́wówọlé, lọ́nà àìtẹ̀lélànà bí ó bá pọn dandan, ju ṣíṣàìjẹ́ kí àwọn ohun àṣejáde eléwu dé orí àtẹ bí? Àwọn àlùfáà kò ha ń ní ọkàn ìfẹ́ nínú lílókìkí tàbí jíjèrè owó ju ṣíṣamọ̀nà àwọn agbo wọn ní ipa ọ̀nà ìwà rere àti ìfẹ́ bí?
Bíbẹ̀rẹ̀ Lọ́dọ̀ Àwọn Ọ̀dọ́
Nígbà tí a bá tọ́ àwọn ọmọdé dàgbà ní àyíká onígbọ̀jẹ̀gẹ́, a ń tọ́ wọn dàgbà láti jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan ní gidi, nítorí pé a ń gbójú fo ìgbatẹnirò àti àìmọtara-ẹni-nìkan kí a lè tẹ́ ìfẹ́ ọkàn èwe wọn lọ́rùn. Ní ilé ẹ̀kọ́ àti ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, a ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti sapá láti wà ní ipò kíní, kì í ṣe nínú àwọn ọ̀ràn ìwé kíkọ́ nìkan, ṣùgbọ́n nínú eré ìdárayá pàápàá. Àkọmọ̀nà náà ni pé, “Bí o bá wà ní ipò kejì, ó ṣeé ṣe kí o wà ní ipò ìkẹyìn pẹ̀lú!”
Àwọn eré àṣedárayá orí fídíò tí ń gbé ìwà ipá jáde ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro lọ́nà onímọtara-ẹni-nìkan—wulẹ̀ rẹ́yìn ọ̀tá! Ó dájú pé kì í ṣe ẹ̀mí ìrònú kan tí ń fún ìfẹ́ níṣìírí! Ní èyí tí ó lé ní ẹ̀wádún kan sẹ́yìn, ọ̀gá àgbà oníṣègùn ilẹ̀ United States kìlọ̀ pé àwọn eré àṣedárayá orí fídíò ń di ewu kan fún àwọn ọ̀dọ́. Ó wí pé: “Gbogbo rẹ̀ wé mọ́ gbígbìyànjú láti rẹ́yìn ọ̀tá. Kò sí ohun kan tí ń gbàrònú nínú àwọn eré àṣedárayá náà.” Lẹ́tà kan tí wọ́n kọ sí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé ọ̀pọ̀ eré àṣedárayá orí fídíò “ń kó ìsúnniṣe àdánidá rírẹlẹ̀ jù lọ ẹ̀dá ènìyàn nífà,” ó sì fi kún un pé: “Wọ́n ń mú ìran àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà oníkanra, aláìní-làákàyè dàgbà.” Olùfarajìn fún eré àṣedárayá orí fídíò kan láti Germany ṣàìlábòsí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́wọ́ òtítọ́ tí ó wà nínú gbólóhùn ìkẹyìn yí, nígbà tí ó wí pé: “Nígbà tí mo ń ṣe wọ́n, mo bọ́ sínú ayé àdádó àfòyemọ̀ kan, níbi tí ọ̀rọ̀ ìwúrí ìgbà láéláé náà ti gbéṣẹ́ pé: ‘Pa wọ́n tàbí kí wọ́n pa ọ́.’”
Ìkórìíra túbọ̀ ń já sí ibi nígbà tí èrò ìran tèmi lọ̀gá bá dà pọ̀ mọ́ ọn. Nítorí náà, ó ṣe kedere pé èyí tí ń da àwọn ará Germany lọ́kàn rú ni àwọn fídíò arọ̀mọ́pìlẹ̀ tí ń gbé ìwà ipá jáde lòdì sí àwọn àjèjì, ní pàtàkì, àwọn ará Turkey. Wọ́n sì ní ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ní January 1, 1994, àwọn ará Turkey jẹ́ ìpín 27.9 nínú ọgọ́rùn-ún lára 6,878,100 àjèjì tí ń gbé ilẹ̀ Germany.
Èrò ìran tèmi lọ̀gá ní ń fún ohun tí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ń kọ́ àwọn ọmọdé láti ìgbà kékeré níṣìírí, ìyẹn ni pé, kò sí ohun tí kò tọ́ nínú kíkórìíra àwọn ọ̀tá orílẹ̀-èdè rẹ. Àròkọ kan láti ọwọ́ George M. Taber, tí ó máa ń kọ̀wé fún ìwé ìròyìn Time, sọ pé: “Nínú gbogbo èròǹgbà ìṣèlú tí ó wà nínú ìtàn, àfàìmọ̀ kó má ṣe pé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ló lágbára jù lọ.” Ó ṣàlàyé síwájú sí i pé: “A ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nítorí rẹ̀ ju bí a ti ṣe fún ìdí èyíkéyìí mìíràn lọ, yàtọ̀ sí ìsìn. Àwọn olùgbèjà mẹ̀kúnnù ti ru àwọn akọluni aláìnírònú sókè nípa dídi ẹ̀bi gbogbo ìṣòro wọn lé orí ẹ̀yà kan tí ó múlé gbè wọ́n.”
Ìkórìíra ọlọ́jọ́ pípẹ́ lòdì sí àwùjọ ẹ̀yà, ti ìran, tàbí ti orílẹ̀-èdè míràn ló fa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro inú ayé lónìí. Ẹ̀mí máfojúkànlejò, ìbẹ̀rù àwọn àlejò tàbí àjèjì, ń pọ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, ó dùn mọ́ni pé àwùjọ àwọn onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá kan láti Germany ṣàwárí pé ẹ̀mí máfojúkànlejò máa ń fara hàn jù lọ níbi tí àwọn àlejò tí iye wọ́n kéré bá wà. Ó jọ pé èyí ń jẹ́rìí sí i pé ẹ̀tanú ni ó ń fà á ju bí ìrírí ara ẹni ṣe ń fà á lọ. Àwọn onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá náà ṣàwárí pé: “Ní pàtàkì, àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé ló ń fa ẹ̀tanú tí àwọn ọ̀dọ́ ń ní.” Ní tòótọ́, ìpín 77 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò kò fìgbà kan ní àjọṣe tààrà, tàbí àjọṣe kínkínní kankan, pẹ̀lú àwọn àjèjì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fọwọ́ sí ẹ̀tanú náà.
Kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ìmọtara-ẹni-nìkan kò ṣòro, nítorí pé gbogbo wa ni a ti jogún ìwọ̀n kan nínú ìmọtara-ẹni-nìkan láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa aláìpé. Ṣùgbọ́n ipa wo ni ìsìn ń kó nínú ìforígbárí tí ó wà láàárín ìfẹ́ àti ìríra?
Kí Ni Ìsìn Ń Kọ́ni?
Àwọn ènìyàn sábà máa ń ronú pé ìsìn ń fún ìfẹ́ níṣìírí. Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, èé ṣe tí ìyàtọ̀ nínú ìsìn fi jẹ́ okùnfà àìfararọ ní Àríwá Ireland, Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, àti Íńdíà, ká wulẹ̀ mẹ́nu ba àpẹẹrẹ mẹ́ta péré? Dájúdájú, àwọn ènìyàn kan rò pé ìyàtọ̀ nínú ìṣèlú ló yẹ ká dá lẹ́bi rúkèrúdò náà, kì í ṣe ìyàtọ̀ nínú ìsìn. Ìyẹn jẹ́ kókó kan tí ó ṣeé jiyàn lé lórí. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe kedere pé ìsìn tí a ṣètò jọ ti kùnà láti gbin ìfẹ́ tí ó lágbára tó láti borí àwọn ẹ̀tanú elérò ara ẹni nípa ìṣèlú àti ẹ̀yà sínú àwọn ènìyàn. Àbáyọrí rẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àti àwọn ẹlẹ́sìn míràn, fàyè gba ẹ̀tanú, tí ń ṣamọ̀nà sí ìwà ipá.
Kò sí ohun tí ó burú nínú kí ẹnì kan kọ̀ láti gba àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà àwùjọ ìsìn kan tí òun lè rò pé kò tọ̀nà. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ èyí fún un ní ẹ̀tọ́ láti lo ìwà ipá lòdì sí ìsìn náà tàbí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ bí? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion jẹ́wọ́ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé: “Àwọn aṣáájú ìsìn ti pè fún fífi ìwà ipá kọ lu àwọn àwùjọ onísìn míràn léraléra nínú ìtàn àwọn ará Ẹ̀bá Ìlà Oòrùn àti Europe.”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yí fi hàn pé ìwà ipá jẹ́ apá kan tí kò ṣeé yà kúrò nínú ìsìn, nípa sísọ pé: “Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ti Darwin nìkan kọ́ ló fara mọ́ ọn pé ìforígbárí pọn dandan fún ìdàgbàsókè tí ń bá a lọ ní ti ẹgbẹ́ àwùjọ àti ti ìrònú òun ìhùwà. Ìsìn ti jẹ́ orísun tí kò lópin fún ìforígbárí, fún ìwà ipá, àti, nípa bẹ́ẹ̀, fún ìdàgbàsókè tí ń bá a lọ.”
A kò lè dáre fún ìwà ipá lórí ìpìlẹ̀ pé ó pọn dandan fún ìdàgbàsókè, nítorí pé èyí yóò lòdì sí ìlànà kan tí a mọ̀ dunjú, tí Jésù Kristi fi lélẹ̀ nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù gbìyàjú láti dáàbò bò ó. Pétérù “na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì fa idà rẹ̀ yọ ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà ó sì gé etí rẹ̀ dà nù. Nígbà náà ni Jésù wí fún un pé: ‘Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.’”—Mátíù 26:51, 52; Jòhánù 18:10, 11.
Dídojú ìwà ipá kọ ẹnì kan—yálà ó jẹ́ ẹni rere tàbí búburú—kì í ṣe ọ̀nà ìfẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn tí ń hu ìwà ipá ń já ìpolongo wọn pé àwọn ń gbégbèésẹ̀ ní àfarawé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ kan nírọ́. Òǹkọ̀wé Amos Oz sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn agbawèrèmẹ́sìn . . . pé ‘àwọn àṣẹ’ tí wọ́n ń rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run sábà máa ń jẹ́, ní pàtàkì, àṣẹ kan náà pé: Ìwọ gbọ́dọ̀ pànìyàn. Ó túbọ̀ jọ pé èṣù ni ọlọ́run gbogbo agbawèrèmẹ́sìn.”
Bíbélì sọ ohun kan tí ó jọra gidigidi pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òkodoro òtítọ́ yìí: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo kò pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó sì ń kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí òun kò rí. Àṣẹ yìí ni àwa sì gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, pé ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní láti máa nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.”—Jòhánù Kíní 3:10, 15; 4:20, 21.
Ó yẹ kí ìsìn tòótọ́, tẹ̀ lé ìlànà kan tí ó jẹ́ ti ìfẹ́, tí ó ní fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọ̀tá ẹni pàápàá nínú. A kà nípa Jèhófà pé: “Òun . . . ń mú kí oòrùn rẹ̀ là sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:44, 45; tún wo Jòhánù Kíní 4:7-10.) Ẹ wo bí ó ti yàtọ̀ sí Sátánì, ọlọ́run ìríra tó! Ó ń fi ẹ̀tàn fa àwọn ènìyàn, ó sì ń fi ìlérí òfo ṣì wọ́n lọ́nà sínú gbígbé ìgbésí ayé ìwà wọ̀bìà, ìwà ọ̀daràn, àti ìmọtara-ẹni-nìkan, tí ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ìrora àti ìnira kún ìgbésí ayé wọn. Gbogbo bí ó ti ń ṣe náà ló sì mọ̀ ní kíkún pé ọ̀nà ìgbésí ayé òdì yí yóò yọrí sí ìparun wọn níkẹyìn. Ṣé irú ọlọ́run tí ó yẹ ní sísìn nìyẹn, tí kò lè dáàbò bo àwọn tirẹ̀—tí ó ṣe kedere pé kò tilẹ̀ fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Ìbẹ̀rù, Ìbínú, Tàbí Èrò Ìpalára
Ó rọrùn láti fẹ̀rí hàn pé àwọn kókó wọ̀nyí ń tanná ran ìkórìíra. Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Láti àwọn ọdún 1930 onírògbòdìyàn ni àgbájọ onírúurú ẹgbẹ́ arọ̀mọ́pìlẹ̀ aláṣerégèé kò ti lè kófà àwọn ohun tó jọ àǹfààní púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀. . . . Nítorí pé ẹ̀rù iṣẹ́ àwọn ènìyàn ń bà wọ́n, wọ́n ń fi àìtúraká oníbìínú gbógun ti àìlágbára àwọn ìjọba olójú ìwòye ṣọ̀túnṣòsì-mábàkanjẹ́, tí wọ́n sì ń sọ àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn di ẹran ìyà.” Jörg Schindler, nínú ìwé agbéròyìnjáde Rheinischer Merkur/Christ und Welt, pe àfiyèsí sí àwọn ẹgbẹẹgbàárùn-ún olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n tìtorí ọ̀ràn ìṣèlú ya wọ Germany láàárín ẹ̀wádún méjì tó kọjá. Ìwé agbéròyìnjáde The German Tribune kìlọ̀ pé: “Èrò ìran tèmi lọ̀gá ń pọ̀ sí i jákèjádò Europe.” Ìyawọlé àwọn aṣíwọ̀lú rẹpẹtẹ bẹ́ẹ̀ ń fa ìmọ̀lára ìkórìíra. A ń gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń ṣàròyé pé: ‘Wọ́n ń ná wa lówó, wọ́n ń gba iṣẹ́ wa ṣe, wọ́n sì jẹ́ ewu fún àwọn ọmọ wa obìnrin.’ Theodore Zeldin, àgbà ọmọ ẹgbẹ́ St. Antony’s College, Oxford, sọ pé àwọn ènìyàn “jẹ́ oníwà ipá nítorí pé wọ́n rò pé a ń wu àwọn léwu tàbí pé a tẹ́ àwọn lógo. Ohun tó ń fa ìbínú wọn ló yẹ ká pàfiyèsí sí.”
Akọ̀ròyìn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n, Joan Bakewell, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Britain, lo àwọn ọ̀rọ̀ yíyẹ wẹ́kú láti fi júwe ayé wa, tí ń kọ́ àwọn olùgbé rẹ̀ láti kórìíra. Ó kọ̀wé pé: “Èmi kì í ṣe Kristẹni tí ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ ìsìn fífìdí múlẹ̀, ṣùgbọ́n láti inú àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni, mo gba òtítọ́ jíjinlẹ̀ tí ó ṣe tààrà kan pé: ìṣẹ̀lẹ̀ ibi jẹ́ àìsí ìfẹ́ lọ́nà alájàálù. . . . Mo mọ̀ pé a ń gbé inú àwùjọ ènìyàn kan tí kò gba ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìfẹ́ bí ohun gidi. Ní tòótọ́, àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó jẹ́ alárèékérekè tó bẹ́ẹ̀ tí ó wulẹ̀ ka irú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ sí ohun yẹpẹrẹ, tí kò fìrònú hàn, tí kò gbéṣẹ́, àwùjọ tí ń fi àwọn èròǹgbà fífi ìníyelórí púpọ̀ jù sórí ìbìkítà àti àìmọtara-ẹni-nìkan dípò èrè àti àǹfààní ara ẹni ṣẹlẹ́yà. Ó ń wí pé ‘ká sòótọ́’ nígbà tí ó ń fìdí àjọṣe òwò lọ́ọ́lọ́ọ́ múlẹ̀, tí ń yẹ àwọn àìgbọ́dọ̀máṣe rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹ̀rí tí ń fi hàn kedere pé ohun tí ó ń ṣe kò tọ́. Irú ayé bẹ́ẹ̀ ń mú àwọn ènìyàn aláìlè-ṣàṣeyọrí, anìkànjẹ, àwọn ènìyàn tí wọ́n fìdí rẹmi nídìí àwọn ohun àkọ́múṣe ẹgbẹ́ àwùjọ ní ti àṣeyọrí, ìdára-ẹni-lójú àti ìdílé aláyọ̀ jáde.”
Ní kedere, ọlọ́run ayé yìí, Sátánì, ń kọ́ ìran ènìyàn láti kórìíra. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, a lè kẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìfẹ́. Àpilẹ̀kọ tí ó kàn yóò fi hàn pé èyí ṣeé ṣe.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn eré àṣedárayá orí fídíò ha lè máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti kórìíra bí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìwà ipá tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà ogun jẹ́ àmì àìmọ̀kan àti ìkórìíra
[Credit Line]
Pascal Beaudenon/Sipa Press