Ìkórìíra Yóò Ha Dópin Láé Bí?
BÍ ÌWỌ bá ti wo àwọn ìkéde ìròyìn tẹlifiṣọn díẹ̀ pàápàá, ìkórìíra kò ṣàjèjì sí ọ. Ìkórìíra ni ìwà tí ó wọ́pọ̀ jùlọ tí ó wà nídìí àwọn ìpakúpa tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lójoojúmọ́ ni wọ́n ń fi àpá wọn tí ó rin gbingbin fún ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ayé yìí. Láti Belfast sí Bosnia, láti Jerusalemu sí Johannesburg, àwọn aláìdásí tọ̀túntòsì tí wọ́n ṣàgbákò ni a ń pa.
Àwọn afipákọluni kì í sábà á mọ àwọn ẹni tí wọ́n ń kọlù. Kìkì “ọ̀ràn” tí wọ́n dá ni pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ ara “ẹgbẹ́ tọ̀hún.” Nínú ìgbẹ̀san ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀, irú ikú bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ yíyáró nítorí ìwà òǹrorò tí ó ti ṣẹlẹ̀ rí, tàbí irú “ìmọ̀ọ́mọ̀ pa ẹ̀yà-ìbílẹ̀ run.” Ọ̀wọ́ àwọn ìwà-ipá kọ̀ọ̀kan ń bu epo sí iná ìkórìíra láàárín àwọn ẹgbẹ́ tí ń bá ara wọn ṣọ̀tá.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìkórìíra amúnigbọ̀nrìrì tí ń jà rànyìn wọ̀nyí dàbí ẹni pé ó ń pọ̀ síi. Ìgbẹ̀san láàárín ẹ̀jẹ̀ kan náà ń dìde láàárín àwọn ẹ̀yà, ìran, àti àwọn àwùjọ ẹ̀yà-ìbílẹ̀ tàbí ìsìn. A ha lè mú ìkórìíra wá sópin bí? Láti dáhùn ìyẹn, a níláti lóye àwọn okùnfà ìkórìíra, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé a kò bí wa láti kórìíra.
Gbígbin Àwọn Irúgbìn Ìkórìíra
Zlata Filipovic, ọ̀dọ́mọbìnrin ará Bosnia láti Sarajevo, kò tíì kọ́ láti kórìíra. Nínú ìwé rẹ̀ tí ó ń kọ ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́ sí ó kọ nípa ìwà-ipá ẹ̀yà-ìbílẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere pé: “Mo ń béèrè ṣáá pé Kí ni ó fà á? Fún kí ni? Ta ni kí a dá lẹ́bi? Mo ń béèrè ṣùgbọ́n kò sí ìdáhùn. . . . Àwọn ará Serbia àti Croatia àti Musulumi wà lára àwọn ọ̀rẹ́bìnrin mi, lára àwọn ọ̀rẹ́ wa, nínú ìdílé wa. . . . Àwọn ẹni rere ni a ń darapọ̀ mọ́, kì í ṣe àwọn ẹni burúkú. Àwọn ara Serbia àti Croatia àti Musulumi sì wà lára àwọn ènìyàn rere wọ̀nyí, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni burúkú ṣe wà láàárín wọn.”
Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ tí ó ti dàgbà, ń ronú lọ́nà tí ó yàtọ̀. Wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn ní ìdí tí ó pọ̀ tó láti kórìíra. Èéṣe?
Àìṣèdájọ́ òdodo. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ohun pàtàkì tí ń tanná ran ìkórìíra ni àìṣèdájọ́ òdodo àti ìninilára. Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, “ìnilára mú ọlọ́gbọ́n ènìyàn sínwín.” (Oniwasu 7:7) Nígbà tí a bá fígun mọ́ àwọn ènìyàn tàbí tí a bá hùwà òkúrorò sí wọn, ó máa ń rọrùn fún wọn láti mú ìkórìíra dàgbà fún àwọn tí ń ni wọ́n lára. Bí ó sì tilẹ̀ dàbí ẹni pé kò bọ́gbọ́n mu, tàbí “pé ó jẹ́ ìwà wèrè,” ìkórìíra náà ni a sábà máa ń darí sí gbogbo ẹgbẹ́ àwùjọ kan.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìṣèdájọ́ òdodo, bóyá níti gidi tàbí tí a ronúwòye, lè jẹ́ okùnfà pàtàkì fún ìkórìíra, kì í ṣe òun nìkan. Òmíràn ni ẹ̀tanú.
Ẹ̀tanú. Ẹ̀tanú sábà máa ń wá láti inú àìmọ̀kan nípa ẹ̀yà-ìbílẹ̀ kan tàbí ẹgbẹ́ àwùjọ orílẹ̀-èdè kan. Nítorí ọ̀rọ̀ àgbọ́sọ, kèéta àjogúnbá, tàbí ìrírí búburú pẹ̀lú ẹnì kan tàbí méjì, àwọn kan lè ka àwọn ànímọ́ tí kò dára sí ti ìran tàbí orílẹ̀-èdè kan lápapọ̀. Gbàrà tí ẹ̀tanú bá ti fi gbòǹgbò múlẹ̀, ó lè fọ́ àwọn ènìyàn lójú sí òtítọ́. Òǹkọ̀wé Gẹ̀ẹ́sì náà Charles Caleb Colton sọ pé: “A kórìíra àwọn ènìyàn kan nítorí tí a kò mọ̀ wọ́n; a kì yóò sì mọ̀ wọ́n nítorí tí a kórìíra wọn.”
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn olóṣèlú àti àwọn òpìtàn, lè mọ̀ọ́mọ̀ gbé ẹ̀tanú lárugẹ fún ète òṣèlú tàbí ti ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni. Hitler jẹ́ àpẹẹrẹ pàtàkì kan. Georg, tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ ti Hitler, sọ pé: “Àwọn ìgbékèéyíde Nazi lákọ̀ọ́kọ́ kọ́ wa láti kórìíra àwọn Júù, lẹ́yìn náà àwọn ará Russia, lẹ́yìn náà gbogbo ‘àwọn ọ̀tá Ìjọba Nazi.’ Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba, mo gba ohun tí a sọ fún mi gbọ́. Nígbà tí ó ṣe, mo wá rí i pé a ti tàn mí jẹ.” Bí ó ti rí ní Germany ti Nazi àti ní ibòmíràn, ẹ̀tanú ẹ̀yà-ìran tàbí ti ẹ̀yà-ìbílẹ̀ ni a ti dá láre nípa fífi ọ̀ràn lọ ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni, orísun mìíràn fún ìkórìíra.
Ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àti ẹ̀yà-ìran-tèmi-lọ̀gá. Nínú ìwé rẹ̀ The Cultivation of Hatred, òpìtàn Peter Gay ṣàpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ogun àgbáyé kìn-ínní bẹ́ sílẹ̀: “Nínú ìjàkadì láàárín àwọn adúróṣinṣin, ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni lágbára ju gbogbo ìyókù lọ. Ìfẹ́ fún orílẹ̀-èdè ẹni àti ìkórìíra fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti jẹ́ àwíjàre tí ó lágbára jùlọ fún jàgídíjàgan ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí ọ̀rúndún kọkàndínlógún mú jáde.” Àwọn èrò ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni ti Germany sọ orin ogun kan tí a mọ̀ sí “Orin Ìyìn fún Ìkórìíra” di mímọ̀. Gay ṣàlàyé pé, àwọn olùgbé ìkórìíra lárugẹ ní Britain àti France hùmọ̀ àwọn ìtàn abanijẹ́ nípa àwọn sójà Germany pé wọ́n ń fipá bá àwọn obìnrin lòpọ̀ tí wọ́n sì ń pa àwọn ọmọ-ọwọ́. Siegfried Sassoon, tí ó jẹ́ sójà ní England, ṣàlàyé àwọn kókó inú ìgbékèéyíde ogun ti Britain pé: “Ó dàbí ẹni pé a dá ènìyàn, láti pa àwọn ará Germany.”
Bíi ti ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni, gbígbé ẹ̀yà-ìbílẹ̀ kan tàbí ẹ̀yà-ìran kan ga ju bí ó ti yẹ lọ lè ru ìkórìíra ẹ̀yà-ìbílẹ̀ tàbí ẹ̀yà-ìran mìíràn sókè. Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ń báa lọ láti tanná ran ìwà-ipá ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Africa nígbà tí ẹ̀yà-ìran-tèmi-lọ̀gá ṣì ń báa lọ láti yọ Ìwọ̀-Oòrùn Europe àti North America lẹ́nu. Ohun apínniníyà mìíràn tí ó lè dàpọ̀ mọ́ ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni ni ìsìn.
Ìsìn. Púpọ̀ nínú àwọn ìforígbárí tí ó ṣòro láti yanjú nínú ayé ní ọ̀ràn ìsìn tí ó lágbára nínú. Ní Northern Ireland, ní Middle East, àti níbòmíràn, a kórìíra àwọn ènìyàn nítorí ìsìn tí wọ́n ń ṣe. Ní èyí tí ó lé ní ọ̀rúndún méjì sẹ́yìn, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà Jonathan Swift sọ pé: “A ní ìsìn tí ó pọ̀ tó gẹ́ẹ́ láti mú kí a kórìíra, ṣùgbọ́n kò pọ̀ tó láti mú kí a nífẹ̀ẹ́ ara wa.”
Ní 1933, Hitler fi tó bíṣọ́ọ̀bù Osnabrück létí pé: ‘Níti àwọn Júù, ìlànà-ètò ohun kan náà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki ti ń lò fún 1,500 ọdún ni mo ń bá nìṣó.’ Ìpakúpa oníkòórìíra rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì Germany kò dá lẹ́bi. Paul Johnson, nínú ìwé rẹ̀ A History of Christianity, ṣàkíyèsí pé “àwọn Katoliki tí wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìhágún wọn pé àwọn fẹ́ kí a sun wọ́n níná ni Ṣọ́ọ̀ṣì náà yọ lẹ́gbẹ́, . . . ṣùgbọ́n kò kà á léèwọ̀ fún wọn láti ṣiṣẹ́ nínú ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tàbí àwọn ibùdó tí a ti ń pa ènìyàn.”
Àwọn aṣáájú ìsìn kan ti ṣe ju gbígba ìkórìíra láyè—wọ́n ti yà á sí mímọ́. Ní 1936, nígbà tí Ogun Abẹ́lé Àwọn Ará Spania bẹ́ sílẹ̀, Póòpù Pius XI dá àwọn ẹgbẹ́ Republic lẹ́bi ‘ìkórìíra Ọlọrun tí Satani mí sí níti tòótọ́’—àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà Katoliki wà lẹ́yìn ẹgbẹ́ Republic. Lọ́nà kan náà, Kadina Gomá, olórí Spania nígbà ogun abẹ́lé, sọ pé ‘kò lè sí àlàáfíà láìsí ìdíje ohun ìjà.’
Ìkórìíra ìsìn kò fi ẹ̀rí rírọlẹ̀ hàn. Ní 1992 ìwé ìròyìn Human Rights Without Frontiers bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀nà tí àwọn aláṣẹ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Greek Orthodox gbà ń ru ìkórìíra sókè sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ, ó tọ́ka sí ọ̀kan, ti àlùfáà Greek Orthodox tí ó pe àwọn ọmọ-ọlọ́dún 14 méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí lẹ́jọ́. Kí ni ẹ̀sùn náà? Ó fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ‘ń gbìyànjú láti mú kí òun yí ìsìn òun padà.’
Àwọn Àbájáde Ìkórìíra
Jákèjádò ayé, irúgbìn ìkórìíra ni a ń gbìn tí a sì ń bomirin nípasẹ̀ àìṣèdájọ́ òdodo, ẹ̀tanú, ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni, àti ìsìn. Èso rẹ̀ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ ni ìbínú, jàgídíjàgan, ogun, àti ìparun. Ọ̀rọ̀ Bibeli nínú 1 Johannu 3:15 ràn wá lọ́wọ́ láti rí bí èyí tí ṣe pàtàkì tó: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn.” Dájúdájú, níbi tí ìkórìíra bá ti gbilẹ̀, àlàáfíà—bí ó bá tilẹ̀ wà rárá—léwu.
Elie Wiesel, tí ó gba Ẹ̀bùn Nobel tí ó sì la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ já, kọ̀wé pé: “Iṣẹ́ olùlà á já ni láti jẹ́rìí sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ . . . Ó níláti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn pé àwọn nǹkan wọ̀nyí lè ṣẹlẹ̀, pé ìwà ibi ni a lè gbà láàyè. Ìkórìíra ìran, ìwà-ipá, ìbọ̀rìṣà—ṣì ń gbilẹ̀.” Ìtàn ọ̀rúndún lọ́nà ogún yìí fi hàn pé ìkórìíra kì í ṣe iná kan tí yóò kú fúnra rẹ̀.
A óò ha fa ìkórìíra tu kúrò ní ọkàn-àyà àwọn ènìyàn bí? Ìkórìíra ha máa ń fìgbà gbogbo fa ìparun bí, tàbí ó ha ní ìhà tí ó dára sí bí? Ẹ jẹ́ kí a wò ó.