Ìkórìíra Èé Ṣe Tí Ó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GERMANY
“ÈÉ ṢE”—ọ̀rọ̀ kúkúrú kan, síbẹ̀, tí ó fẹ́ ìdáhùn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí a rí i lára bébà pélébé kan láàárín àkójọ òdòdó àti àwọn àtọwọ́dá béárì ìṣeré tí wọ́n tò sí ìta ilé ẹ̀kọ́ kan ní Dunblane, Scotland, ní March 1996. Ní ọjọ́ mélòó kan ṣáájú, ọkùnrin kan ti já wọ ibẹ̀, ó sì yìnbọn pa àwọn ọmọdé 16 àti olùkọ́ wọn. Ó ṣèpalára fún àwọn mélòó kan sí i, kí ó tó yìnbọn jẹ. Ní kedere, ó ní ìkórìíra gan-an—fún ara rẹ̀, fún àwọn ẹlòmíràn, àti fún ẹgbẹ́ àwùjọ lápapọ̀. Àwọn òbí àti àwọn ọ̀rẹ́ àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn kárí ayé tí ń kẹ́dùn ló ń béèrè ìbéèrè kan náà, ‘Èé ṣe? Èé ṣe tí àwọn ọmọdé aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ fi ń kú báyìí?’
Ó ṣeé ṣe kí o ti ṣàkíyèsí pé ayé kún fún ìkórìíra tí kò bọ́gbọ́n mu, tí kò sì ṣeé ṣàlàyé. Ní gidi, nítorí ìdí kan tàbí òmíràn, ìwọ fúnra rẹ lè ti jìyà ìkórìíra. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ pẹ̀lú ti béèrè pé, ‘Èé ṣe?’—bóyá ju ìgbà kan lọ pàápàá.
Ìkórìíra Títọ́ àti Èyí Tí Kò Tọ́
A túmọ̀ “ìríra” àti “ìkórìíra” sí “ìkóguntì gbígbóná janjan àti ìsáfúnni jíjinlẹ̀.” Dájúdájú, ó ṣàǹfààní láti ní “ìkóguntì gbígbóná janjan àti ìsáfúnni jíjinlẹ̀” ní ti àwọn ohun tí ó léwu tàbí tí ó lè fa ìbàjẹ́ nínú àjùmọ̀ṣe ẹni. Bí gbogbo ènìyàn bá ní irú ìkórìíra yìí, ayé yóò jẹ́ ibi tí ó sàn jù láti gbé ní tòótọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé máa ń kórìíra àwọn ohun tí kò tọ́ nítorí àwọn ìdí tí kò tọ́.
A gbé ìkórìíra tí ń ṣèparun lérí ẹ̀tanú, àìmọ̀kan, tàbí ìsọfúnni òdì, lọ́pọ̀ ìgbà sì ni “ìbẹ̀rù, ìbínú, tàbí èrò ìpalára” máa ń fà á gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ kan ṣe sọ. Nítorí pé kò ní ìpìlẹ̀ yíyẹ, ìkórìíra yìí máa ń yọrí sí ipò àìláyọ̀, léraléra ni ó sì máa ń ṣe okùnfà ìbéèrè náà pé, ‘Èé ṣe?’
Gbogbo wa mọ àwọn ènìyàn tí àwọn ànímọ́ ìwà àti àṣà wọn lè máa bí wa nínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí ó sì ṣòro fún wa láti bá ní àjọṣe. Ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ìmúnibínú; ọ̀tọ̀ sì ni ìfẹ́ ọkàn láti ṣe àwọn ènìyàn ní ìjàǹbá. Nítorí náà, ó lè ṣòro fún wa láti lóye bí ẹnì kan ṣe lè mú èrò ìkórìíra dàgbà fún odindi àwùjọ ènìyàn, tí ó máa ń jẹ́ àwọn ènìyàn tí òun pàápàá kò mọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ó lè jẹ́ pé wọn kò fara mọ́ èrò rẹ̀ nípa ìṣèlú, wọ́n lè jẹ́ ti ìsìn míràn, tàbí kí wọ́n jẹ́ ti ẹ̀yà ìran mìíràn, àmọ́ ìyẹn ha tó ìdí láti kórìíra wọn bí?
Síbẹ̀síbẹ̀, irú ìkórìíra bẹ́ẹ̀ wà! Ní Áfíríkà, ìkórìíra ló sún àwọn ẹ̀yà Hutu àti Tutsi máa pa ara wọn ní Rwanda ní 1994, tí ó mú kí oníròyìn kan béèrè pé: “Báwo ni ìríra púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ṣe kóra jọ ní orílẹ̀-èdè tí ó kéré tó bẹ́ẹ̀?” Ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, ìkórìíra ti ṣokùnfà àwọn ìkọlù láti ọ̀dọ̀ àwọn apániláyà tí wọ́n jẹ́ onítara ìsìn ará Arébíà tàbí ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ní Europe, ìkórìíra ló mú kí Yugoslavia àtijọ́ fọ́ sí wẹ́wẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde kan sì ṣe sọ, ní United States nìkan, “nǹkan bí 250 àwùjọ àwọn onírìíra” ń tan àwọn èròǹgbà ẹlẹ́yàmẹ̀yà kálẹ̀. Èé ṣe tí ìkórìíra fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Èé ṣe?
Ìkórìíra fìdí múlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé, nígbà tí a bá yanjú àwọn ìforígbárí tí ó dá sílẹ̀ tán pàápàá, ó ṣì ń wà. Àbí kí tún ni ì bá jẹ́ ìdí fún ìṣòro tí ó wà nínú wíwà lálàáfíà àti dídáwọ́ ogun dúró ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ àti àwọn tí àwọn apániláyà ń pọ́n lójú? Kí tún ni ì bá jẹ́ ìdí fún ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àdéhùn àlàáfíà tí a fọwọ́ sí ní ìparí ọdún 1995 ní Paris tí ó sọ pé kí ìlú ńlá Sarajevo pa dà di ọ̀kan lábẹ́ Orílẹ̀-Èdè Alájọṣe Bosnia àti Herzegovina-Croat? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀yà Serb tí ń gbé ibẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sá kúrò ní ìlú náà àti àwọn àrọko rẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù ìforóyaró. Nígbà tí ìwé ìròyìn Time ń ròyìn pé àwọn ènìyàn ń piyẹ́ àwọn ilé tí wọ́n ń fi sílẹ̀ lọ, wọ́n sì ń dáná sun wọ́n, ó parí ọ̀rọ̀ pé: “Sarajevo ti pa dà ṣọ̀kan; àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ì ṣe bẹ́ẹ̀.”
Pátápátá rẹ̀, àlàáfíà láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n kórìíra ara wọn jẹ́ ayédèrú àlàáfíà, kò níye lórí bí ayédèrú owó kò ṣe níye lórí. Láìsí ohun tí ó níye lórí kankan láti tì í lẹ́yìn, ìwọ̀n ipá kíkéré jù lọ pàápàá lè bì í lulẹ̀. Àmọ́ ìkórìíra ti pọ̀ jù nínú ayé, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ ti kéré jù. Èé ṣe?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
A gbé ìkórìíra tí ń ṣèparun lérí ẹ̀tanú, àìmọ̀kan, tàbí ìsọfúnni òdì