ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp22 No. 1 ojú ìwé 3
  • A Lè Borí Ìkórìíra!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Lè Borí Ìkórìíra!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Ìkórìíra Fi Pọ̀ Láyé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ò Ní Sí Ìkórìíra Mọ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ibi Gbogbo Ni Ìkórìíra Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
wp22 No. 1 ojú ìwé 3
Àwòrán: Inú ọkùnrin kan bà jẹ́ torí pé àwọn tó lẹ́mìí ìkórìíra ló yí i ká. 1. Obìnrin kan tó mú fóònù dání kàn án lábùkù. 2. Obìnrin míì ń wò ó tìkà-tẹ̀gbin. 3. Ọkùnrin kan tó ń ka ìwé ìròyìn fìbínú pariwo mọ́ ọn. 4. Oníròyìn kan ń ka ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n.

A Lè Borí Ìkórìíra!

Ṣẹ́nì kan ti ṣohun tí ò dáa sí ẹ rí torí pé ó kórìíra ẹ?

Ká tiẹ̀ sọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, ó ṣeé ṣe kó o ti rí i táwọn kan hùwà ìkà sẹ́nì kan torí pé wọ́n kórìíra ẹ̀. A máa ń gbọ́ nípa báwọn kan ṣe ń fìyà jẹ àwọn míì torí pé wọn kì í ṣọmọ ìlú kan náà tàbí ẹ̀yà kan náà. Ó sì lè jẹ́ torí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀. Èyí ló mú káwọn ìjọba ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ṣòfin pé tí wọ́n bá rí ẹnikẹ́ni tó ń fìyà jẹ ẹnì kan torí pé ó kórìíra ẹ̀, onítọ̀hún á jẹ palaba ìyà.

Àwọn kan máa ń kórìíra àwọn ẹlòmíì torí ohun tójú wọn ti rí báwọn èèyàn ṣe kórìíra wọn. Wọ́n tiẹ̀ lè bá a débi táwọn náà á fi máa hùwà ìkà sáwọn míì, tí nǹkan bá sì ń lọ bẹ́ẹ̀, ìkórìíra ò ní tán nílẹ̀.

Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i táwọn kan ṣe ẹ̀tanú sáwọn míì, tí wọ́n ní èrò burúkú nípa wọn, tí wọ́n ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n ń kàn wọ́n lábùkù tàbí tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ wọn. Kódà, ó máa ń le débi pé àwọn kan máa ń lu àwọn míì nílùkulù, wọ́n máa ń ba nǹkan àwọn èèyàn jẹ́, wọ́n máa ń fipá báwọn kan lò pọ̀, àwọn míì tiẹ̀ lè pa àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà wọn.

Nínú ìwé yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè borí ìkórìíra, a sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tí ìkórìíra fi pọ̀ láyé?

  • Báwo la ṣe lè borí ìkórìíra?

  • Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn ò ní máa kórìíra ara wọn mọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́