Kaba—Oríṣi Aṣọ Agbógoyọ Kan Nílẹ̀ Áfíríkà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÁNÀ
KABA—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ níbi gbogbo ni o ti lè rí i níhìn-ín ní Gánà àti ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà tó múlé gbè é. A ń wọ̀ ọ́ ní onírúurú àkókò—láti orí ìsìnkú dé orí àwọn ìkórajọ aláyọ̀ ti àwọn Kristẹni. Kaba sì wà ní oríṣiríṣi ọnà àti àwọ̀.
Kí ló tilẹ̀ ń jẹ́ kaba? Ó jẹ́ oríṣi aṣọ kan fún àwọn obìnrin. Orúkọ náà ń tọ́ka sí aṣọ àwọ̀lékè kan tí ó gùn láti ìsàlẹ̀ ọrùn dé ìbàdí. Bí ó ti wù kí ó rí, a kì í wọ òun nìkan. Oríṣi aṣọ ọ̀pá méjì kan tí a mọ̀ dunjú sí wax, tàbí java, tí ó sinmi lórí bí ó ti dára tó, ni a máa ń wọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. A máa ń ró aṣọ yìí, tí a ń pè ní asetam, ó sì ń balẹ̀ dé kókósẹ̀. Aṣọ náà ń pé nígbà tí a bá tún ró ọ̀pá aṣọ méjì míràn, tí a ń pè ní nguso lé e. Nguso wúlò gidigidi fún ọ̀pọ̀ nǹkan, a sì tún lè lò ó bíi gèlè tí ó bá aṣọ mu délẹ̀, tàbí kí a fi pọn ọmọ.
Ilẹ̀ Áfíríkà nìkan ló ni Kaba, ṣùgbọ́n orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la fi ń pè é jákèjádò kọ́ńtínẹ́ǹtì náà. Àwọn ará Liberia ń pè é ní lappa. Wọ́n ń pè é ní genwu ní Benin. Àwọn ará Sierra Leone ń pè é ní docket àti lappa. Síbẹ̀síbẹ̀, ní àkókò kan tí kò ì pẹ́ púpọ̀, a kò mọ kaba ní ilẹ̀ Áfíríkà. Bí àpẹẹrẹ, níhìn-ín ní Gánà, oríṣi aṣọ tí ń jẹ́ dansenkran ni ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn obìnrin tí ń sọ èdè Akan. Abala aṣọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èyí, tí ó sì máa ń jẹ́ irú kan náà nígbà míràn. Wọ́n ń ró abala kan, wọ́n sì ń dì í lámùrè. Abala kejì, tí ó sábà máa ń tóbi ju èkíní lọ, ni wọ́n máa ń fi pakájà gba èjìká òsì. Oríṣi ọnà irun dídì kan, tí wọ́n tún ń pè ní dansenkran, ni wọ́n sábà máa ń dì nígbà tí wọ́n bá wọ aṣọ yìí.
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n kó maṣín-ìnnì ìránṣọ dé, àwọn obìnrin ará Áfíríkà kan bẹ̀rẹ̀ sí í mú oríṣi aṣọ tí ó jọ blouse ti ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn jáde. Èrò náà jẹ́ láti máa bo èjìká bí àwọn obìnrin ti ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn ti ń ṣe. Ìtàn kan sọ pé kò rọrùn fún àwọn kan láti sọ pé “cover the shoulders [bo èjìká].” Ọ̀rọ̀ náà, “cover” wá di kaba.
Kaba Di Àmúṣẹ̀yẹ
Láti orí òṣìṣẹ́ ọ́fíìsì dé orí àgbẹ̀, àwọn obìnrin ń wọ kaba nìṣó. Ní gidi, ó ti di ọjà àkóròkè-òkun! Bí ó ti wù kí ó rí, kò ì pẹ́ púpọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í ní irú òkìkí bẹ́ẹ̀.
Ohun kan ni pé, gbogbo obìnrin kọ́ ló fẹ́ràn àwọn oríṣi kaba tó bágbà mu ní nǹkan bí 40 ọdún sẹ́yìn. Òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan tó ti fẹ̀yìn tì, tí ń jẹ́ Agnes, ẹni ọdún 62, sọ fún Jí! pé àwọn kan lára àwọn oríṣi tó wà nígbà náà jẹ́ “àfiṣẹ̀sín.” Ní ti àwọn obìnrin mìíràn, ó gba sùúrù àti ojú ọnà jù láti wọ kaba bó ti yẹ, kí a sì ró asetam àti nguso rẹ̀ pẹ̀lú. Elizabeth, tí ó ní ilé iṣẹ́ aṣọ rírán kan, sọ pé: “Ó ṣòro fún àwa ọ̀dọ́ ọlọ́mọge láti mọ asetam àti nguso í ró nígbà náà.” Ó jẹ́wọ́ pé: “N kò mọ̀ ọ́n ró nígbà kankan.”
Ìyàtọ̀ ẹlẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ pẹ̀lú kó ipa kan tí ó dín ìlókìkí oríṣi aṣọ yìí kù. Serwah, ẹni ọdún 65, sọ fún Jí! pé, títí di ẹnu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ló ń rò pé àwọn aṣọ tí a rán bíi ti àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn wà fún àwọn alákọ̀wé, nígbà tí kaba wà fún àwọn tí kò mọ̀wé.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìtanijí nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ lọ́tun ti mú kí ọ̀pọ̀ obìnrin ará Áfíríkà tún inú rò nípa kaba. Àwọn tí ń gbé àṣà aṣọ tó lòde jáde pẹ̀lú ti buyì kún aṣọ náà. Lọ́nà kan, wọ́n hùmọ̀ oríṣi aṣọ kan tí a ń pè ní slit. Wọ́n ṣe é bíi síkẹ́ẹ̀tì, ṣùgbọ́n ó balẹ̀ dé kókósẹ̀, ó sì yanjú ìṣòro tí àwọn obìnrin kan ní láti ró asetam àti nguso bó ti yẹ. Àwọn ìpàtẹ ọjà àti àfihàn ọjà pẹ̀lú kópa gidigidi ní gbígbé kaba lárugẹ bí àṣà tó lòde.
Dájúdájú, bíi ti àṣà aṣọ tó lòde ní àwọn ilẹ̀ míràn, àwọn kan lára àwọn oríṣi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ń tẹnu mọ́ èrò ti ayé. Clara, ẹni ọdún 69, sọ pé, ó jọ pé irú àwọn aṣọ tí ń fara sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń dojú “ète ìpìlẹ̀ tí kaba ní” bolẹ̀, èyí tí ó jẹ́ láti “bo èjìká.” Nítorí náà, àwọn Kristẹni obìnrin ń fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, mo ní ìfẹ́ ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.”—Tímótì Kíní 2:9; Kọ́ríńtì Kíní 10:29.
Ní ti àwọn obìnrin tí ń fi ọgbọ́n ṣe yíyàn, kaba lè jẹ́ oríṣi aṣọ kan tí ń gbógo yọ, tí ó sì wúlò. Nígbà tí ọ̀pọ̀ aṣọ ìbílẹ̀ Áfíríkà sì ti di aláìbágbàmu, kaba ti là á já gẹ́gẹ́ bí oríṣi aṣọ kan tí ń fi àṣà ìbílẹ̀ Áfíríkà àti àyíká Áfíríkà hàn lọ́nà wíwuni, tí ó sì ń gbógo yọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Nguso, tí a fi ṣe gèlè níhìn-ín
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Nguso, tí a fi pọnmọ