Erékùṣù Cocos—Ìtàn Ìṣúra Abẹ́ Ilẹ̀ Rẹ̀
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Costa Rica
ERÉKÙṢÙ kan wà ní nǹkan bí 480 kìlómítà sí etíkun ìhà gúúsù ìlà oòrùn Costa Rica tí àwọn ìtàn nípa ìṣúra abẹ́ ilẹ̀ rẹ̀ sọ di olókìkí. Àwọn kan gbà gbọ́ pé Robert Louis Stevenson gbé ìwé rẹ̀ tó lókìkí náà, Treasure Island, karí àwọn ìtàn nípa ìṣúra tí àwọn olè jí gbé, tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ sí ibẹ̀.
Àwọn ayàwòrán ilẹ̀ àti àwọn afòkunṣọ̀nà ti pe erékùṣù náà lóríṣiríṣi orúkọ láti ìgbà tí a ti ṣàwárí rẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Láàárín àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tí ń sọ èdè Spanish, a mọ erékùṣù náà sí Isla del Coco (Erékùṣù Àgbọn) lónìí. Orúkọ rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì ni Cocos Island.
Láàárín Costa Rica àti Àwọn Erékùṣù Galápagos ni àgbájọ ilẹ̀ kan wà tí a mọ̀ sí Òkè Abẹ́ Omi Cocos. Ìyọnáyèéfín inú òkè yí ló yọrí sí erékùṣù kan ṣoṣo tí ó wà níbẹ̀. Ilẹ̀ kékeré tí kò tẹ́jú yìí ni erékùṣù pàtàkì kan ṣoṣo tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Òkun Pacific ilẹ̀ olóoru, tí òjò tí ń rọ̀ níbẹ̀ pọ̀ tó láti mú kí igbó kìjikìji ilẹ̀ olóoru wà. Lọ́dọọdún ni òjò tí ó tó 7,000 mìlímítà ń rọ̀ sí erékùṣù náà!
Akéwì ọmọ ilẹ̀ England ní ọ̀rúndún kejìdínlógún náà, Coleridge, sọ nípa ìṣòro tí afòkunṣọ̀nà ìgbàanì kan ní, tí ó ní “omi, omi ṣáá, níbi gbogbo, láìní èyí tó ṣeé mu.” Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún, omi aláìníyọ̀ ti Erékùṣù Cocos di ìtura lójú òkun fún àwọn atukọ̀ tí wọ́n lè ṣàwárí erékùṣù náà.
Ìtàn Àtẹnudẹ́nu Nípa Ìṣúra Abẹ́lẹ̀
Ní sànmánì kan tí ọ̀nà ìkẹ́rù àti ìṣòwò lágbàáyé gbára lé ìrìn àjò ojú òkun, ìdigunjalè lójú òkun jẹ́ ewu fún ẹgbẹ́ àwùjọ. Àwọn adigunjalè-lójú-òkun tún jẹ́ ewu fún ara wọn pàápàá.
Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti piyẹ́ ìlú kékeré etíkun kan tàbí ọkọ̀ òkun kan, àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ náà yóò pín àwọn ẹrù tí wọ́n jí kó náà láàárín ara wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù adigunjalè-lójú-òkun yóò wá kojú ìṣòro bí yóò ṣe dáàbò bo ìpín tirẹ̀ lára èrè ìjẹkújẹ tí ó jẹ kí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má lè jí i kó. Ọ̀nà tí wọ́n yàn ni láti máa kó ìṣúra náà pa mọ́ síbi àṣírí kàn ní ríretí pé àwọn yóò lọ kó wọn lẹ́yìn náà. Àwòrán ilẹ̀ ibi tí ìṣúra náà wà, tí ìdarí ẹnà tí ó yé ẹni tí ó ṣe é nìkan wà lórí rẹ̀, wá di àṣírí tí a fi lè rí ìṣúra tí a rì mọ́lẹ̀.
Ìtàn àtẹnudẹ́nu kan nípa Erékùṣù Cocos sọ pé ẹgbẹ́ adigunjalè-lójú-òkun kan kẹ́sẹ járí ní jíjí ẹrù kó nínú àwọn ọkọ̀ òkun àti ìlú ńláńlá Etíkun Pacific ní Àárín Gbùngbùn America tó bẹ́ẹ̀ tí ẹrù wúrà àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ mìíràn fi ń pa wọ́n. Nítorí tí erékùṣù náà ní ọ̀pọ̀ omi aláìníyọ̀, tí ẹran sì wà dáradára (wọ́n kó ẹlẹ́dẹ̀ wọ ibẹ̀ ní ìparí ọ̀rúndún kejìdínlógún), ọ̀gákọ̀ ọkọ̀ òkun náà wéwèé láti fi Erékùṣù Cocos ṣe ibùdó iṣẹ́ rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dà kan ìtàn náà ti sọ, odindi ọjọ́ kan ni wọ́n fi pín ìkógun náà. Ìkòkò ni wọ́n fi ń wọn wúrà. Ìbẹ̀rù pípàdánù ọrọ̀ wọn sí ọwọ́ àwọn oníwọra ẹlẹgbẹ́ wọn mú kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn adigunjalè-lójú-òkun náà yàn láti ri ìpín tirẹ̀ nínú ìṣúra náà mọ́lẹ̀ síbì kan ní erékùṣù náà. Ní fífi okùn gun àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó pọ̀ létíkun erékùṣù náà, adigunjalè-lójú-òkun kọ̀ọ̀kan pòórá sínú igbó ilẹ̀ olóoru náà. Nígbà tí àwọn kan gbára lé agbára ìrántí wọn, àwọn mìíràn pa dà dé pẹ̀lú àwòrán ilẹ̀ tó jẹ́ pé àwọn nìkan ni wọ́n lè mọ ìtumọ̀ rẹ̀, tí wọn yóò tẹ̀ lé pa dà dé ibi tí ìṣúra wọn gbé wà. Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo ìsapá atánnilókun yìí já sí òtúbáńtẹ́. Ìtàn àtẹnudẹ́nu náà ń bá a lọ pé, lẹ́yìn tí wọ́n ti fi àwọn ẹrù wọn pa mọ́ síbi àṣírí tán, àwọn adigunjalè-lójú-òkun náà tukọ̀ lọ láti wá èrè tí ó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tí wọ́n dé èbúté wọn tó kàn, ọ̀gákọ̀ náà rán àwọn tí ó fura sí pé wọ́n lè dìtẹ̀ mọ́ òun jáde, ó sì ṣíkọ̀. Ìrètí rẹ̀ pé ọwọ́ yóò tẹ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí adigunjalè-lójú-òkun, wọn yóò sì pa wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ dòótọ́ tán. Ohun tí ó kùnà láti retí ni agbára àwọn òṣìṣẹ́ onípò gíga jù lọ méjì tí ń bá a ṣiṣẹ́ náà láti bá àwọn aláṣẹ tí ń fẹ́ mú ọ̀gákọ̀ náà ṣe àdéhùn ìdúnàádúrà. Àwọn Ológun Ojú Omi Ilẹ̀ Britain gbé ọkọ̀ òkun kan sọ́nà tí wọ́n fi ìtara lé ọkọ̀ òkun náà bá, èyí sì yọrí sí mímú ọ̀gákọ̀ náà àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì pa wọ́n.
Láàárín ọ̀rúndún tó kọjá, ìtàn àtẹnudẹ́nu yìí ti tanná ran ìrètí àwọn olùwá-ìṣúra-kiri. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó tẹ̀ lé e yìí ṣe fi hàn, àwọn tí yóò bá wá ìṣúra lọ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n tó dáwọ́ lé ìwákiri ìwalẹ̀ ní Erékùṣù Cocos. Àpilẹ̀kọ kan tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ti August 14, 1892, ṣàpèjúwe ìwákiri tí Ọ̀gákọ̀ August Gisler ṣe, láti ṣàwárí ìṣúra wúrà, fàdákà, àti ohun ọ̀ṣọ́, tí a díwọ̀n ìníyelórí rẹ̀ sí 60,000,000 dọ́là. Wíwá tí Gisler ń wá ìṣúra kiri yìí mú kí ó ya ara rẹ̀ láṣo sí ọ̀làjú, kí ó sì fara da ipò búburú jù lọ ní erékùṣù ojúgbó tí a pa tì yí. Ó kéré tán, ó ná owó ara rẹ̀ tí ó tó 50,000 dọ́là, ó sì lò ju ọdún 19 lọ ní wíwá ìṣúra. Ní 1908, Gisler kúrò ní Erékùṣù Cocos, láìní nǹkan kan, tí ó sì sorí kọ́, láìrí ìṣúra kankan ní àbáyọrí gbogbo ìsapá rẹ̀.
Òtítọ́ náà pé Gisler kùnà láti ṣàwárí ìṣúra kankan ní erékùṣù náà kò mú gbogbo ènìyàn rẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n ti ṣètò ẹgbẹẹgbẹ́ tí ó lé ní 500 láti lọ ṣàwárí ní erékùṣù náà. Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ti sọ, kò sí ẹni tí ó tí ì ṣàwárí àwọn ọrọ̀ inú ìtàn àtẹnudẹ́nu náà.
Àwọn Ìṣúra Àdánidá ní Erékùṣù Cocos
Láìpẹ́ yìí, Erékùṣù Cocos ti fa oríṣi olùwá-ìṣúra-kiri mìíràn kan mọ́ra. Àwọn ewéko àti ẹranko erékùṣù náà àti àwárí ìṣúra ẹ̀dá alààyè inú òkun tó yí i ká ti fa àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ohun alààyè nínú ibùgbé àdánidá rẹ̀ àti àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì míràn mọ́ra.
Ọ̀pọ̀ yanturu ewéko ilẹ̀ olóoru bo erékùṣù náà ṣíbáṣíbá. A ti ṣàwárí nǹkan bí 450 irú ọ̀wọ́ àwọn kòkòrò àti ẹran tí kò léegun ẹ̀yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a fojú bù ú pé àwọn irú ọ̀wọ́ tó wà ní erékùṣù náà lé ní 800. Odò 28, tí ń lọ́ kọ́rọkọ̀rọ yí ká ojú ilẹ̀ tí kò tẹ́jú náà, tí wọ́n sì ń ya láti òkè gíga fíofío bí ìyalulẹ̀ omi kíkàmàmà ló wà níbẹ̀.
Ọ̀kan lára irú ọ̀wọ́ ẹyẹ 97 tó wà ní erékùṣù náà ni ẹyẹ tern funfun. Ó ní àṣà ìpanilẹ́rìn-ín ti pé kí ó máa fò lófuurufú ní gẹ́rẹ́ ibi orí ènìyàn, bíi pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ń ṣèbẹ̀wò sí erékùṣù náà kì í bà á. Ìtẹ̀sí amúnidunnú yìí ti fún ẹyẹ náà lórúkọ ìnagijẹ kan lédè Spanish, espíritu santo, tàbí ẹ̀mí mímọ́, tí ń tọ́ka sí ìròyìn tí Bíbélì ṣe nípa ìbatisí Jésù.—Wo Mátíù 3:16.
Lábẹ́ omi tí ó yí Erékùṣù Cocos ká ni ìṣúra àdánidá wà rẹpẹtẹ. Lára àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ sí àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn tó ń bẹ erékùṣù náà wò ni àwọn amòòkùn tí ń lo ohun èlò àfimí lábẹ́ omi wà, tí àgbájọ àwọn ẹja ekurá hammerhead tó wà níbẹ̀ yà lẹ́nu gidigidi. Ẹja ekurá hammerhead àti ẹja ekurá alágòógó funfun máa ń wá sínú omi wọ̀nyí, a sì ti rí wọn tí wọ́n ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní iye tí ó wà láàárín 40 sí 50. Bí omi náà ṣe mọ́ gaara lọ́nà aláìlẹ́gbẹ́ tún wọ àwọn amòòkùn lọ́kàn. Àwọn àwọ̀ jíjojúnígbèsè tí wọ́n ń rí bí àwọn ẹja ilẹ̀ olóoru ṣe ń wá àwọn èèhọ̀n àti àwọn ohun alààyè ojú omi kiri láti jẹ ń ru ọkàn ìfẹ́ wọn sókè.
Orílẹ̀-èdè Costa Rica ti fọwọ́ ìjẹ́pàtàkì mú ìṣúra abẹ́ omi tí ó ní látilẹ̀wá. Ní báyìí, ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ ilẹ̀ rẹ̀ ni a ti fi ṣe ọgbà ìtura àti igbó àìro ti orílẹ̀-èdè. Ní 1978, a polongo pé Erékùṣù Cocos ti di apá kan ìgbékalẹ̀ ọgbà ìtura yẹn, tí ó ní àgbègbè tí a dáàbò bò 56 nínú nísinsìnyí ní orílẹ̀-èdè náà. Ní 1991, wọ́n fi àgbègbè tí a fi ìdènà ààbò oníkìlómítà 24 yí ká kún àgbègbè tí a dáàbò bò náà. Ṣíṣọ́ àyíká òkun, àti dídáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn apẹjaṣòwò jẹ́ ìpèníjà kan. Àwọn onímọ̀ nípa àyíká ń bẹ̀rù pé pípẹja láìláàlà lè ba ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn lábẹ́ omi tí ó yí erékùṣù náà ká jẹ́.
Títí di báyìí, Erékùṣù Cocos lókìkí fún àwọn ìtàn rẹ̀ nípa àwọn ògbójú adigunjalè-lójú-òkun àti ìṣúra tí wọ́n rì mọ́lẹ̀. Ó ṣì ń jẹ́ ìyanu fún àwọn olùwá-ìṣúra-kiri lágbàáyé, ó sì ń fà wọ́n mọ́ra. Bí ó ti wù kí ó rí, ọrọ̀ títóbi jù lọ tí erékùṣù náà ní wà níbi tí a rì í mọ́ nínú àwọn ohun àdánidá rẹ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn àwòrán ojú ìwé 25 àti 26: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure José Pastora, Okeanos
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ẹja ekurá alágòógó funfun (1) àti ẹja ekurá “hammerhead” (2, 3) ń kiri nínú omi tí ó yí Erékùṣù Cocos ká lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tí iye wọn wà láàárín 40 sí 50