ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 9/8 ojú ìwé 16-19
  • Òkè Ayọnáyèéfín Tẹ́lẹ̀ Rí Di Erékùṣù Tó Pa Rọ́rọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òkè Ayọnáyèéfín Tẹ́lẹ̀ Rí Di Erékùṣù Tó Pa Rọ́rọ́
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣẹ̀dá Erékùṣù Kan
  • Gbígbé ní Ìkángun Rẹ̀
  • Erékùṣù Cocos—Ìtàn Ìṣúra Abẹ́ Ilẹ̀ Rẹ̀
    Jí!—1997
  • Pátímọ́sì—Erékùṣù Àpókálíìsì
    Jí!—2000
  • A Wàásù “Ìhìn Rere” Ní Àwọn Erékùṣù Jíjìnnà Réré Ní Àríwá Ọsirélíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àwọn Erékùṣù Tí Ń Kóra Jọ
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 9/8 ojú ìwé 16-19

Òkè Ayọnáyèéfín Tẹ́lẹ̀ Rí Di Erékùṣù Tó Pa Rọ́rọ́

BÍ ỌKỌ̀ wa ṣe yí orí padà tó forí lé etíkun erékùṣù Santorini ní ilẹ̀ Gíríìsì, a rí ohun àgbàyanu kan. Àwọn òkè gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó bani lẹ́rù, tí gíga rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀ọ́dúnrún mítà láti ibi ìtẹ́jú òkun yọ láti inú òkun. Àwọn ilé funfun tò dúró sán-ún wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ìrísí àrà ọ̀tọ̀ tí erékùṣù náà ní, àìsí èbúté kankan ní erékùṣù náà, àwọn òkè gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó so rọ̀ náà—ó jọ pé gbogbo ìwọ̀nyí fi hàn pé ohun mérìíyìírí kan ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Ohun kan ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ lóòótọ́. Erékùṣù Santorini ni ìdajì tó ṣẹ́ kù ní ìhà ìlà oòrùn òkè ayọnáyèéfín kan tó bú gbàù, orí omi tó rọ́ sí ibi tó di kòtò nítorí ìbúgbàù náà ni ọkọ̀ tí a wọ̀ sì ń gbà kọjá!

Ṣíṣẹ̀dá Erékùṣù Kan

Láyé àtijọ́, erékùṣù Santorini—tí wọ́n ṣì ń pè ní Santorin tàbí Thíra lónìí yìí—ni wọ́n ń pè ní Strongyle, tó túmọ̀ sí “Roboto.” Erékùṣù náà sì ṣe roboto lóòótọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ògbógi ti sọ, òkè ayọnáyèéfín kan tó bú gbàù ló yí ìrísí erékùṣù náà padà ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún [3,500] sẹ́yìn. Ẹ̀rí fi hàn pé ohun kan bú gbàù, ó sì gbẹ́ ihò ńlá, tó jìn gan-an sáàárín erékùṣù náà, tí omi òkun fi rọ́ lọ sínú rẹ̀.

Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín méfò pé ìró ìbúgbàù náà dún dé ilẹ̀ Yúróòpù, Éṣíà, àti Áfíríkà àti pé ó wó àwọn ilé lọ dé ibi tó jìnnà tó àádọ́jọ kìlómítà. Wọ́n ní ó lè jẹ́ pé eérú tó ń háni lọ́fun bo oòrùn lójú tí kò sì jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tàn sórí gbogbo àgbègbè òkun Mẹditaréníà fún ọjọ́ bíi mélòó kan. Lápapọ̀, ilẹ̀ ọgọ́rin kìlómítà níbùú lóròó ló pòórá ní erékùṣù náà tàbí kó ti wó sínú omi. Gbogbo ohun abẹ̀mí ibẹ̀ ló lọ sí i.

Bí àkókò ti ń lọ, àwọn olùtẹ̀dó tó wà lórí ilẹ̀ ló wá ń gbé ibi tó ṣẹ́ kù lára Strongyle, wọ́n sì wá sọ erékùṣù náà ní orúkọ mìíràn, ìyẹn ni Calliste, tó túmọ̀ sí “Ẹlẹ́wà Jù Lọ.” Ṣùgbọ́n gbígbé lórí òkè ayọnáyèéfín kò jẹ́ kí ọkàn àwọn olùtẹ̀dó náà balẹ̀ lọ́jọ́ kan ayé wọn. Láàárín ọdún 198 ṣááju Sànmánì Tiwa àti ọdún 1950 Sànmánì Tiwa, ìgbà mẹ́rìnlá ni òkè náà ti bú. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 1956, ìsẹ̀lẹ̀ kan ba ilé púpọ̀ jẹ́ ní erékùṣù náà. Ìyá arúgbó kan, tó ń jẹ́ Kyra Eleni, tí gbogbo ìjàǹbá náà ṣojú rẹ̀ sọ pé: “Ilẹ̀ ń mì tìtì, ó ń ṣe jìgìjìgì. Yangí rọ́ jọ sí iwájú àgbàlá ilé mi tó wà ní téńté orí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Lójijì, ó dà gẹ̀ẹ̀rẹ̀ sínú òkun, tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kí ó dà bíi pé kò sí nǹkan tí ilé mi dúró lé! Ńṣe ni a fi ilé yẹn sílẹ̀ tí a sì lọ kọ́ òmíràn sí orí ilẹ̀ tó tẹ́jú.”

Wọ́n tún àwọn abúlé tó ti run kọ́ ní kíákíá, àwọn àjèjì ló sì pọ̀ jù nínú àwọn tó tún wọn kọ́. Lónìí, Santorini ń gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùṣèbẹ̀wò tó ń rọ́ lọ síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lálejò. Yàtọ̀ sí Santorini, erékùṣù Thirasía tó túbọ̀ kéré àti erékùṣù kékeré tó ń jẹ́ Aspronísi, ṣì wà.

Láfikún, erékùṣù kéékèèké méjì tún wà láàárín ilẹ̀ tó jìn wọnú náà, ní erékùṣù Santorini, òkè ayọnáyèéfín sì ni wọ́n, àwọn ni, Néa Kaméni àti Palaía Kaméni. A ṣì ri tí iná òun èéfín ń rú túú lórí àwọn òkè kéékèèké tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú yìí, tí ‘èyí títóbi tó ń sinmi’ náà sì ń rú èéfín lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìrísí erékùṣù Santorini kì í yé yí padà, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé wọ́n ní láti máa tún àwòrán rẹ̀ yà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Gbígbé ní Ìkángun Rẹ̀

Ní eteetí ibi tó jìn wọnú náà ní erékùṣù Santorini, kò sí òkè tó da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, àyàfi àwọn ibi tó so rọ̀. Àwọn ilẹ̀ fífẹ̀ tó dojú kọ erékùṣù náà pèsè ojútùú tó rọrùn jù lọ fún àwọn tó ń kọ́lé níbẹ̀: Wọ́n á kàn gbẹ́ ihò gbọọrọ ní ìdábùú sí abẹ́lẹ̀ ni, wọ́n á wá mọ ògiri dí ẹnu rẹ̀, ibẹ̀ di ilé nìyẹn. Òótọ́ ni, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ilé tó wà níbi tí ilẹ̀ ti jìn wọnú náà ni wọ́n gbẹ́ láti inú àpáta.

Níwájú irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀, àgbàlá, tàbí bákónì wà níbẹ̀ tí wọ́n lè ti ibẹ̀ máa wo ilẹ̀ tó jìn wọnú náà. Àgbàlá ilé tó wà lókè ló jẹ́ òrùlé fún ilé tó wà nísàlẹ̀. O lè gbádùn wíwo bí oòrùn ṣe ń wọ̀ láti orí àwọn bákónì wọ̀nyí, bí o ti ń gbádùn oòrùn tó ní àwọ̀ èse àlùkò bó ti ń rọra lọ nínú ọlá ńlá rẹ̀ sẹ́yìn òkun níbi tí a kò ti lè rí i mọ́. Àwọn àgbàlá kan tún ní ilé ìdáná kóńkó kan, ilé kan tàbí méjì tí wọ́n ti ń sin adìyẹ, àti àwọn irúgbìn amóúnjẹ-ta-sánsán àti òdòdó tí wọ́n gbìn sínú ìkòkò.

Ohun kan tó wọ́pọ̀ nípa àwọn abúlé náà lápapọ̀ ni pé gbogbo ilé tó wà níbẹ̀ ni wọ́n kọ́ kọ́lọkọ̀lọ kò sí èyí tí ó tò gbọọrọ. Kódà àwọn ilé tó wà lábẹ́ ilẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú kò bára mu. Gbogbo ìrísí kọ́lọkọ̀lọ yìí, tí wọ́n para pọ̀ di ohun tí a fẹ́rẹ̀ẹ́ máà rí irú rẹ̀ rí, ló jẹ́ kí àwọn ilé tó ṣù jọ náà jẹ́ ẹlẹgẹ́, èyí tó ń yani lẹ́nu bó ti wà lórí irú erékùṣù págunpàgun bẹ́ẹ̀.

Santorini gbẹ táútáú. Kìkì omi tí a lè rí níbẹ̀ ni omi òjò táwọn èèyàn gbè sínú àmù. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá. Nítorí náà, ilẹ̀ kékeré àárín erékùṣù náà ń mú onírúurú irè oko jáde.

Lójú àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ àti àwọn ọmọ onílẹ̀, ohun ìrántí àgbàyanu tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan lára ẹwà tí pílánẹ́ẹ̀tì wa ní ni Santorini jẹ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]

Ọ̀KAN-Ò-JỌ̀KAN ÀLÀYÉ NÍPA ÀTÌLÁŃTÍÌSÌ

Ó lè jẹ́ ilẹ̀ Íjíbítì ni ìtàn àròsọ kan báyìí pé kọ́ńtínẹ́ǹtì, erékùṣù, tàbí ìlú tó ń jẹ́ Àtìláńtíìsì sọ nù ti wá, àròsọ náà sì rọ́nà wọnú ìkọ̀wé àwọn ará Gíríìsì àtijọ́, ó sì tún wá yọjú nínú àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ sànmánì agbedeméjì láti ọ̀dọ̀ àwọn Arébíà tó jẹ́ onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ohun alààyè inú rẹ̀. Wọ́n ronú pé ìsẹ̀lẹ̀ àti ìkún omi ló mú kí òkun bo Àtìláńtíìsì mọ́lẹ̀. Àwọn awalẹ̀pìtàn kan dámọ̀ràn pé ìtàn àròsọ yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí òkè ayọnáyèéfín Santorini bú gbàù.

Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wa ilẹ̀ ibi tí a ń sọ yìí ní ọdún 1966 àti 1967, wọ́n rí ìlú ọlọ́lá, tó gbajúmọ̀ kan ní ilẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì tí àwọn pàǹtírí òkè ayọnáyèéfín tó bú gbàù bò mọ́lẹ̀, síbẹ̀ ó sì rí bí ìgbà tí ìbúgbàù náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀. Ó jọ pé ìkìlọ̀ tí wọ́n tètè ṣe ló mú kí àwọn olùgbé ibẹ̀ tètè sá kúrò níbẹ̀. Àwọn olùwádìí kan méfò pé nítorí pé àwọn olùgbé ibẹ̀ kò fẹ́ gbà pé ìlú àwọn tó jẹ́ àgbàyanu tẹ́lẹ̀ rí ti pòórá ló ṣokùnfà ìtàn pé Àtìláńtíìsì ṣì wà, tó ṣì ń gbá yìn lábẹ́ òkun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Santorini

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn ìwàásù wọn ní Santorini

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

A ń rí Aegean láti ibi títẹ́jú ní Santorini

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́