ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/22 ojú ìwé 24-27
  • Àwọn Erékùṣù Tí Ń Kóra Jọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Erékùṣù Tí Ń Kóra Jọ
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsokọ́ra Erékùṣù Hawaii
  • Ṣíṣàgbékalẹ̀ Erékùṣù Kan
  • Àwọn Erékùṣù Tí Ń Káàkiri
  • Ìdásílẹ̀ Àwọn Erékùṣù Tuntun . . .
  • . . . Àti Ìparun Àwọn Erékùṣù Àtijọ́
  • Ọ̀gangan Gbígbóná Lẹ́nu Iṣẹ́
  • Àwọn Òkè Ayọnáyèéfín—Ìwọ́ Ha Wà Nínú Ewu Bí?
    Jí!—1996
  • Báwọn Èèyàn Ṣe Ń Dá Kún Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀
    Jí!—2005
  • Òkè Ayọnáyèéfín Tẹ́lẹ̀ Rí Di Erékùṣù Tó Pa Rọ́rọ́
    Jí!—2000
  • Popocatepetl—Òkè Ayọnáyèéfín Ọlọ́lá Ńlá, Awuniléwu ti Mexico
    Jí!—1997
Jí!—1998
g98 5/22 ojú ìwé 24-27

Àwọn Erékùṣù Tí Ń Kóra Jọ

“HAWAII.” Àwọn Erékùṣù Hawaii ń múni wòye párádísè ilẹ̀ olóoru, etíkun tí oòrùn ti ń mú, àti ẹ̀fúùfù tí ń tuni lára. Àmọ́ ǹjẹ́ o mọ bí àwọn erékùṣù wọ̀nyí ti wà ní àdádó tó? Bí o bá rí Hawaii lórí àwòrán ilẹ̀, ìwọ yóò rí i pé àwọn erékùṣù wọ̀nyí wà ní àáríngbùngbùn Òkun Àríwá Pàsífíìkì—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí èyí tó tún jìnnà tó bẹ́ẹ̀! Nípa bẹ́ẹ̀, o lè ṣe kàyééfì pé, ‘Báwo ni àwọn erékùṣù náà ṣe débẹ̀? Ǹjẹ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé àwọn erékùṣù mìíràn yóò tún yọrí lọ́jọ́ iwájú? Kí ni àwọn erékùṣù wọ̀nyí lè fi kọ́ wa nípa ilẹ̀ ayé tí a ń gbé orí rẹ̀?’

Ìsokọ́ra Erékùṣù Hawaii

Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn tó ti ṣèbẹ̀wò sí Hawaii ló mọ ìsokọ́ra àwọn erékùṣù mẹ́jọ tó bẹ̀rẹ̀ láti ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá dé ìhà ìlà oòrùn gúúsù dunjú, àwọn tó tóbi jù lára wọn ni Kauai, Oahu, Molokai, Lanai, Maui, àti Hawaii. Niihau tí kò tóbi tó bẹ́ẹ̀ wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Kauai, Kahoolawe sì wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn gúúsù Maui. Erékùṣù Hawaii, tí a tún ń pè ní Erékùṣù Ńlá, fẹ̀ ju 10,000 kìlómítà lọ níbùú lóròó, nígbà tí Kahoolawe kékeré fẹ̀ tó kìlómítà 117 péré níbùú lóròó. Láfikún sí i, ìsokọ́ra àwọn erékùṣù náà tún ní àwọn erékùṣù kéékèèké 124, tí ó fẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá. Erékùṣù Midway, nítòsí ìkángun ìsokọ́ra náà níhà ìwọ̀ oòrùn àríwá, fẹ́rẹ̀ẹ́ jìn tó 2,500 kìlómítà sí Erékùṣù Ńlá náà! Àwọn erékùṣù kéékèèké náà, tí o fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ti ìlẹ̀kẹ̀ omi òun iyanrìn tán, ní àpapọ̀ ìwọ̀n ojú ilẹ̀ tó jẹ́ kìlómítà mẹ́jọ péré níbùú lóròó. Lọ́nà tó ṣe rẹ́gí, àwọn kan ń pe gbogbo àgbájọ erékùṣù náà ní Ìsokọ́ra Erékùṣù Hawaii.

Bí a bá ro ti pé àwọn erékùṣù náà wà lórí àwọn pèpéle tó ga ju ìpíndọ́gba 4,000 mítà lọ lórí ilẹ̀ abẹ́ òkun tó yí wọn ká mọ́ ọn, a bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ pé wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ṣóńṣó orí àwọn òkè ńláńlá tó hàn síta ni. Ní gidi, bí a bá wọ̀n wọ́n láti orí ilẹ̀ abẹ́ òkun, Mauna Kea àti Mauna Loa ní erékùṣù Hawaii ga ní nǹkan bí 10,000 mítà. Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́nà kan, wọ́n jẹ́ àwọn òkè ńlá gíga jù lọ lágbàáyé!

Ṣíṣàgbékalẹ̀ Erékùṣù Kan

Ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ ṣàyẹ̀wò erékùṣù Hawaii. Àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ti fohùn ṣọ̀kan pé Erékùṣù Ńlá náà ní àwọn òkè ayọnáyèéfín ńláńlá márùn-ún, tó para pọ̀ dọ̀kan. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ ló mọ àwọn mẹ́ta tó tóbi jù dunjú—Mauna Kea, tí a gbà pé kò lè bú gbàù, tí ó sì jẹ́ òkè tó ga jù ní Hawaii, tó fi 4,205 mítà ga kọjá ìtẹ́jú òkun; Mauna Loa, tí gíga rẹ̀ jẹ́ 4,169 mítà, tó sì jẹ́ òkè ayọnáyèéfín tó tóbi jù ní Hawaii; àti Kilauea, tí kò lọ́jọ́ lórí tó àwọn tó kù rárá, tí ó sì wà ní bèbè ìhà gúúsù erékùṣù náà. Láfikún sí i, òkè ayọnáyèéfín Kohala ló wà ní ìkángun erékùṣù náà, Hualalai sì wà ní etíkun Kona.

Òkè ayọnáyèéfín kọ̀ọ̀kan yọrí nípa ìkórajọ ìṣàn àpáta yíyòrò. Ìbúgbàù máa ń bẹ̀rẹ̀ lábẹ́ omi, níbi tí ìṣàn àpáta yíyòrò náà ti yára ń tutù, tó sì ń dì, tó wá ń rí bí ahọ́n nígbà tó ń ṣàn, tó ṣe pé bó bá gbára jọ tán, ńṣe ló ń dà bí àtòpọ̀ ìrọ̀rí. Nígbà tí òkè ayọnáyèéfín tí ń kóra jọ náà bá fi yọrí láti inú omi, ìṣàn àpáta yíyòrò náà yóò pa ìrísí rẹ̀ dà. Àwọn onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín ń lo ọ̀rọ̀ èdè Hawaii “pahoehoe” fún àwọn ìṣàn olómi tí ń dán, tó rí kọ́lọkọ̀lọ, tó sì dà bí okùn, wọ́n wá ń pe ìṣàn àpáta yíyòrò tí kò dán, tó rí págunpàgun, tó dà bí àfọ́kù àpáta ní “aa”. Òkè ayọnáyèéfín náà ń di òkè ńlá fífẹ̀, tó rọra ń da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, tó dà bí àwọn apata tí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Róòmù ń gbé látijọ́. Nígbà tí òkúta yíyọ́ bá rú sókè tàbí tó bá fà wọnú láti inú àwọn ibi tí àpáta náà ti sán lára lápá òkè, àwọn ihò ńláńlá máa ń yọjú. Bákan náà, àgbájọ òkúta yíyọ́ inú òkè ayọnáyèéfín náà máa ń wú. Wíwú yìí ló máa ń ti apá kan òkè náà síhà òkun, tó sì ń mú kí àwọn ibi tí àpáta náà ti sán fẹ̀. Níkẹyìn, bí ó ti rí nínú ọ̀ràn Mauna Kea, ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín tó rí bí apata túbọ̀ máa ń le sí i, ó sì ń mú kí àwọn ìdàrọ́ tó ní ìrísí òkòtó kóra jọ lára òkè ayọnáyèéfín náà.

Ẹ̀rí ti wà pé Mauna Loa àti Kilauea wà lára àwọn òkè ayọnáyèéfín tí ń tú nǹkan jáde jù lọ lágbàáyé. Àwọn ìtàn tí a gbọ́ lẹ́nu àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Hawaii, àwọn míṣọ́nnárì, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn mìíràn fi hàn pé Mauna Loa ti tú nǹkan jáde nígbà 48 láti 1832 wá, Kilauea sì ti tú nǹkan jáde ju ìgbà 70 lọ láti 1790 wá. Àwọn ìtúǹkanjáde wọ̀nyí ti ń wà lọ fún ọ̀pọ̀ wákàtí tàbí ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá. Èyí tó pẹ́ jù lọ nínú ìtàn ni adágún ìṣàn àpáta yíyòrò nínú ihò Halemaumau tó wà lórí Kilauea, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ láìdáwọ́dúró ló tú jáde láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1800 títí di 1924. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, Kilauea ti ń tú nǹkan jáde láti January 1983, tó ń sun iná jáde lọ́nà àrímáleèlọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí ó sì ń tú ìṣàn àpáta yíyòrò jáde bí odò tí ń ṣàn lọ sínú òkun.

Nítorí pé ìṣàn àpáta yíyòrò wọn máa ń jẹ́ olómi, ọ̀pọ̀ jù lọ ìtújáde ní Hawaii kò bú rárá, tàbí kí wọ́n ti rọra bú pàápàá. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àwọn ọ̀ràn tí kò wọ́pọ̀, omi abẹ́lẹ̀ ń dà pọ̀ mọ́ òkúta yíyọ́, tí ń fa ìtújáde olómi gbígbóná. Ní 1790, irú ìtújáde bẹ́ẹ̀ kan pa nǹkan bí 80 ènìyàn nígbà tí àwọn gáàsì gbígbóná àti àwọn ìdàrọ́ tí ń jó fọ́n jáde láti Kilauea, tí ó sì bo agbo ọmọ ogun ìbílẹ̀ kan àti àwọn ìdílé wọn mọ́lẹ̀.

Àwọn Erékùṣù Tí Ń Káàkiri

Àkọsílẹ̀ ìtàn láti 200 ọdún sẹ́yìn fi hàn pé àwọn erékùṣù méjèèjì tó wà níhà ìlà oòrùn gúúsù jù lọ, Hawaii àti Maui, nìkan ló ti ń bú. Ipò tí ń ṣeni ní kàyéfì yìí mú kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣèwádìí ìtàn àpáta àwọn erékùṣù tó so kọ́ra náà síwájú sí i. Àwọn oríṣi kánwún onítànṣán olóró àti èròjà argon tí ń mú jáde nígbà tó bá jẹrà wà nínú ìṣàn àpáta yíyòrò náà, tí wọ́n lè yẹ̀ wò ní ibi ìwádìí láti díwọ̀n bí àpáta náà ti wà pẹ́ tó. Irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Ìsokọ́ra Erékùṣù Hawaii lápapọ̀ ń fi díẹ̀díẹ̀ pẹ́ jura lọ, bí ó ti ń lọ síhà ìwọ̀ oòrùn àríwá, ó sì ti wà fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọdún.

Níwọ̀n bí àwọn ìtújáde ní Hawaii ti ń ṣẹlẹ̀ púpọ̀ sí i níhà ìlà oòrùn gúúsù ìsokọ́ra erékùṣù náà, ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé ibi tí òkúta yíyọ́ abẹ́ wọn ti ń ṣàn wá pẹ̀lú ń sún kiri ni? Ní gidi, àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ti fohùn ṣọ̀kan pé orísun òkúta yíyọ́ náà, tí wọ́n pè ní ọ̀gangan gbígbóná, wà lójú kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ilẹ̀ abẹ́ Òkun Pàsífíìkì ló ń kọjá lórí ọ̀gangan gbígbóná náà, tí ó sì ń gbé àwọn òkè ayọnáyèéfín tó wà lérékùṣù náà kúrò lórí ọ̀gangan gbígbóná ọ̀hún bí ìgbà tí bẹ́líìtì tí ń kẹ́rù láti ibì kan lọ sí ibòmìíràn ń kó ẹrù òkúta. Ìṣínípò kan náà yìí ń jẹ́ kí ilẹ̀ abẹ́ òkun Pàsífíìkì náà máa ha àwọn ilẹ̀ kọ́ńtínẹ́ǹtì tó fara kàn án àti àwọn apá mìíràn nínú ilẹ̀ abẹ́ òkun náà, tí ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà tí ń sẹ̀ ní Ààlà Pàsífíìkì. Bí o bá ń gbé Hawaii, ilé rẹ ti sún ní nǹkan bí sẹ̀ǹtímítà 7.5 síhà ìwọ̀ oòrùn àríwá láti èṣí!

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì dábàá pé àwọn ọ̀gangan gbígbóná mìíràn bí irú èyí tó wà lábẹ́ Hawaii ló ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn òkè ayọnáyèéfín tó wà kárí ayé, lórí ilẹ̀ àti nínú òkun. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀gangan gbígbóná wọ̀nyí pẹ̀lú ń fi ẹ̀rí ìtújáde tí ń ṣípò padà hàn, tó túmọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe kí ojú ilẹ̀ ayé ti máa ṣípò padà níbi tí o ń gbé pẹ̀lú.

Ìdásílẹ̀ Àwọn Erékùṣù Tuntun . . .

Níwọ̀n bí ó ti gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún láti ṣàgbékalẹ̀ àwọn òkè ayọnáyèéfín ńláńlá tó wà ní Erékùṣù Ńlá náà, a lè retí pé erékùṣù yìí ti ń sún lọ kúrò ní ọ̀gangan gbígbóná náà ní gbogbo ìgbà náà. Ó yẹ kí àwọn òkè ayọnáyèéfín àti àwọn erékùṣù tuntun ti tún máa yọrí lórí ọ̀gangan gbígbóná náà bí àwọn ilẹ̀ abẹ́ òkun tí kò kàn tẹ́lẹ̀ ti ń sún sí orí rẹ̀. Ǹjẹ́ ohun kan tí ó lè rọ́pò àwọn òkè ayọnáyèéfín Erékùṣù Ńlá náà ti ń fi ara rẹ̀ hàn ní báyìí?

Dájúdájú, ó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Òkè ńlá abẹ́ omi kan tí ó ń tú ìṣàn àpáta yíyòrò jáde, Loihi, ti ń kóra jọ níhà gúúsù erékùṣù Hawaii. Bí ó ti wù kí ó rí, má retí pé yóò yọrí jáde lábẹ́ òkun láìpẹ́. Ó ṣì ní láti ga ní 900 mítà sí i, tí èyí sì lè gba ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọdún sí i.

. . . Àti Ìparun Àwọn Erékùṣù Àtijọ́

Àwọn òkè ayọnáyèéfín tó rí bí apata ràgàjìràgàjì àti àwọn ìṣàn àpáta yíyòrò alára págunpàgun tó para pọ̀ di àwọn Erékùṣù Hawaii fara hàn lọ́nà ẹ̀tàn bí pé wọn kò lè tún rì sábẹ́ òkun mọ́. Àmọ́, àwọn erékùṣù kéékèèké àti àwọn àpáta òkun tó ti rì níhà ìwọ̀ oòrùn àríwá Hawaii kò fi hàn bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn iyanrìn àti òkìtì ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ ti àwọn erékùṣù Midway àti Kure wà lórí àwọn òkè ńlá ayọnáyèéfín tí orí wọn fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún mítà wà lábẹ́ ìtẹ́jú òkun nísinsìnyí. Kí ló dé tí àwọn erékùṣù olókè ayọnáyèéfín ń pòórá?

Díẹ̀díẹ̀ ni ìṣàn omi, agbára ìgbì omi, àti àwọn nǹkan alágbára mìíràn tí ń ṣẹlẹ̀ déédéé ń ṣan àwọn erékùṣù náà dà nù. Àwọn erékùṣù náà fúnra wọn tẹ̀wọ̀n, wọ́n sì ń rì bí wọ́n ṣe ń tẹ ilẹ̀ abẹ́ òkun lọ sílẹ̀. Àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó ń wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn erékùṣù kan ń táṣìírí ọ̀nà mìíràn tí àwọn erékùṣù ayọnáyèéfín gbà ń bàjẹ́—ìyẹ̀gẹ̀rẹ̀ ilẹ̀. Àwọn àwòrán ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àwọn òkè náà lábẹ́ omi, tí a fi ohun èlò tí ń bá ìgbì ṣiṣẹ́ yà, fí àwọn ìyẹ̀gẹ̀rẹ̀ ilẹ̀ tí ó gbòòrò tó ọ̀pọ̀ kìlómítà lórí ilẹ̀ abẹ́ òkun hàn.

Ọ̀gangan Gbígbóná Lẹ́nu Iṣẹ́

Ní erékùṣù Hawaii, àwọn tó bá ṣèbẹ̀wò sí Ọgbà Ẹ̀dá Àwọn Òkè Ayọnáyèéfín ti Orílẹ̀-Èdè Hawaii lè fúnra wọn rí àwọn ìrísí ojú ilẹ̀ tí ń fìgbà gbogbo yí padà tí ìṣiṣẹ́ ọ̀gangan gbígbóná ayọnáyèéfín ń mú wá. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Òkè Ayọnáyèéfín Ilẹ̀ Hawaii, tó wà ní ìkángun ihò Kilauea, ń fìṣọ́ra kíyè sí àwọn ìtújáde tí ń bá a lọ, tó sì ń wuni léwu. Àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe ti yọrí sí títúbọ̀lóye bí àwọn òkè ayọnáyèéfín ṣe ń ṣiṣẹ́ àti bí ojú ilẹ̀ ayé ṣe ń sún kiri. Tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù, a lè mọrírì rẹ̀ pé àwọn ipá ìṣẹ̀dá inú ilẹ̀ ayé ti ṣẹ̀dá àwọn Ìsokọ́ra Òkè Ayọnáyèéfín Hawaii—ìsokọ́ra àwọn àgbàyanu erékùṣù tó wà láàárín Òkun Pàsífíìkì wọ̀nyí—wọ́n sì ti fún un ní ìrísí.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn Erékùṣù Hawaii

Niihau

Kauai

Oahu

Molokai

Lanai

Maui

Kahoolawe

Hawaii

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìtújáde kan ní Kilauea

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ìlà àwọn orísun iná ní ìlà oòrùn kòtò Kilauea

[Credit Line]

Àwọn òkè ayọnáyèéfín: Dept. of Interior, National Park Service

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Odò ìṣàn àpáta yíyòrò ní Mauna Loa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìkélé oníná kan lórí òkè Mauna Loa

[Credit Line]

Lápá òsì lókè àti lápá ọ̀tún nísàlẹ̀: Dept. of Interior, National Park Service

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìtújáde oníná kan ní Kilauea

[Credit Line]

U.S. Geological Survey

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Adágún ìṣàn àpáta yíyòrò ní Kilauea

[Credit Line]

Lápá òsì lókè àti lápá ọ̀tún nísàlẹ̀: Dept. of Interior, National Park Service

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́