ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/8 ojú ìwé 15-19
  • Àwọn Òkè Ayọnáyèéfín—Ìwọ́ Ha Wà Nínú Ewu Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Òkè Ayọnáyèéfín—Ìwọ́ Ha Wà Nínú Ewu Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òkè Ayọnáyèéfín Afìgbàgbogboṣàn —Ibo Ni Wọ́n Wà?
  • Ewu Wo Ló Ní?
  • Ǹjẹ́ O Lè Dín Ìwuléwu Náà Kù?
  • Àwọn Erékùṣù Tí Ń Kóra Jọ
    Jí!—1998
  • Báwọn Èèyàn Ṣe Ń Dá Kún Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀
    Jí!—2005
  • Popocatepetl—Òkè Ayọnáyèéfín Ọlọ́lá Ńlá, Awuniléwu ti Mexico
    Jí!—1997
  • Máa Kọbi Ara Sí Ìkìlọ̀!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 5/8 ojú ìwé 15-19

Àwọn Òkè Ayọnáyèéfín—Ìwọ́ Ha Wà Nínú Ewu Bí?

ÀWỌN òkè ayọnáyèéfín tí ń bú gbàù, tí ń tú erùpẹ̀ àpáta gbígbóná àti ìdì àpáta gbígbóná pípọ́n fòò jáde, máa ń ṣàfihàn agbára àdánidá ilẹ̀ ayé lọ́nà tí ó gbàfiyèsí jù lọ. Bóyá o kò tí ì fojú ara rẹ rí irú ìran bẹ́ẹ̀ rí, ṣùgbọ́n o ti lè gbádùn wíwẹ̀ nínú omi odò tí òkè ayọnáyèéfín ń mú gbóná tàbí kí o gbádùn jíjẹ oúnjẹ tí a gbìn sí orí ilẹ̀ erùpẹ̀ ọlọ́ràá láti inú òkè ayọnáyèéfín. Àwọn kan tilẹ̀ ń jàǹfààní agbára ìmóoru ilẹ̀ nínú ilé wọn.

Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé ìtòsí òkè ayọnáyèéfín afìgbàgbogboṣàn ti fojú rí ikú àti ìparun tí ìjábá òkè ayọnáyèéfín mú wá lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Láti ìgbà ìbúgbàù Òkè Ńlá St. Helens ní ìhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn Ìpínlẹ̀ Washington, U.S.A., ní May 18, 1980, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ agbègbè ayé ti fara gbá ìbúgbàù aṣekúpani alákòópọ̀ tí ó jọ pé kì í dáwọ́ dúró. Iye ẹ̀mí tí ó sọ nù láàárín àkókò yìí pọ̀ ju àpapọ̀ àwọn tí a ròyìn láàárín ẹ̀wádún méje tí ó kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni owó ohun ìní tí ó bà jẹ́ ti pọ̀ tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ yọrí sí ìjábá ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn erùpẹ̀ òkè ayọnáyèéfín ti gba agbára lọ́wọ́ àwọn bàlúù, tí ó sì fipá mú wọn balẹ̀.

Èyí tí ó ṣèparun jù lọ ni ti ìbúgbàù àti ìṣàn ẹrẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e ní Òkè Ńlá Pinatubo, ní Philippines, tí ó gbá ẹgbẹẹgbàárùn-ún ilé lọ, àti ti Nevado del Ruiz, ní Colombia, tí ó pa ju 22,000 ènìyàn lọ. Àwọn ìjábá púpọ̀ sí i ṣì lè ṣẹlẹ̀. Àwọn amọṣẹ́dunjú nípa òkè ayọnáyèéfín, Robert Tilling àti Peter Lipman, ti Ibi Ìwádìí Ojú Ilẹ̀ ní United States, sọ pé “nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2000, iye ènìyàn tí yóò wà nínú ewu ìjàm̀bá òkè ayọnáyèéfín lè ti lọ sókè sí 500 mílíọ̀nù, ó kéré tán.”

Nítorí náà, o lè rí i pé ó lọ́gbọ́n nínú láti béèrè pé: ‘Mo ha ń gbé nítòsí òkè ayọnáyèéfín afìgbàgbogboṣàn tàbí èyí tí ó ṣeé ṣe kí ó di afìgbàgbogboṣàn bí? Irú ìbúgbàù wo ló léwu jù lọ, ṣé wọ́n sì lè mú oríṣi ìbúgbàù tí ó túbọ̀ lè ṣekú pani mìíràn wá? Bí mo bá ń gbé agbègbè eléwu òkè ayọnáyèéfín, kí ni mo lè ṣe láti dín ewu náà kù?’

Òkè Ayọnáyèéfín Afìgbàgbogboṣàn —Ibo Ni Wọ́n Wà?

Mímọ̀ pé o wà ní ìtòsí òkè ayọnáyèéfín tí kò tí ì bú, àti pé o kì yóò lè yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ bí ó bá bẹ́ sílẹ̀ lè yà ọ́ lẹ́nu. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ń kọ́ nípa òkè ayọnáyèéfín (tí a mọ̀ sí àwọn onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín) ti kẹ́sẹ járí nínú dídá àwọn òkè ayọnáyèéfín afìgbàgbogboṣàn àti àwọn tí ń dúró de ọjọ́ iwájú mọ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú mímọ ìdí tí àwọn òkè ayọnáyèéfín fi máa ń wà ní àwọn àdúgbò kan.

Wo àwòrán ilẹ̀ (ojú ìwé 17), tí ń fi ibi tí àwọn kan lára 500 òkè ayọnáyèéfín tí a ti ṣàkọsílẹ̀ pé wọ́n ń fìgbà gbogbo ṣàn wà. O ha ń gbé nítòsí ọ̀kan bí? Ní àwọn ibòmíràn, àwọn ìsun omi tí ń tú omi gbígbóná jáde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ihò èéfín àti gáàsì gbígbóná níbi òkè ayọnáyèéfín, àti àwọn odò olómi gbígbóná ń fi hàn pé àwọn òkè ayọnáyèéfín tí kò tí ì bú wà nítòsí; ìwọ̀nyí pẹ̀lú lè bú gbàù lọ́jọ́ iwájú. Ó ju ìdajì lára àwọn òkè ayọnáyèéfín lọ, tí wọ́n so kọ́ra ní ẹ̀bá Òkun Pacific, tí wọ́n sì para pọ̀ di ohun tí a mọ̀ sí Òbíírí Iná. Àwọn kan lára àwọn òkè ayọnáyèéfín wọ̀nyí wà nínú àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì, irú àwọn tí ó wà ní àwọn Òkè Ńlá Cascade ní Àríwá America àti ní àwọn Òkè Ńlá Andes ní Gúúsù America, nígbà tí àwọn mìíràn sọ ara wọn di ìsokọ́ra erékùṣù òkun, irú bíi ti àwọn Erékùṣù Aleutian, Japan, Philippines, àti ìhà gúúsù Indonesia. Àwọn òkè ayọnáyèéfín tún wọ́pọ̀ ní Meditarenia àti agbègbè rẹ̀.

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti rí i pé àwọn òkè ayọnáyèéfín wọ̀nyí máa ń wà ní eteetí abala ilẹ̀ fífẹ̀, tí ń sún, tàbí ìpele abala ilẹ̀, ní pàtàkì, níbi tí ìpele abala ilẹ̀ òkun bá ti wọ abẹ́ ìpele abala ilẹ̀ kọ́ńtínẹ́ǹtì. Àsáwọ̀ ni a ń pe èyí. Ooru tí èyí ń mú wá ló ń fa magma (àpáta yíyọ́) tí ń ru wá sókè. Láfikún sí i, sísún tí àwọn ìpele abala ilẹ̀ wọ̀nyí ń sún lójijì máa ń fa ìsẹ̀lẹ̀ ní ọ̀pọ̀ agbègbè kan náà tí ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín bá ti ṣẹlẹ̀.

Àwọn òkè ayọnáyèéfín tún lè wà níbi tí àwọn ìpele abala ilẹ̀ òkun bá ti ń pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ọ̀pọ̀ lára irú ìbúgbàù yìí ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ òkun tí ènìyàn kì í sì í rí wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá ń gbé erékùṣù orílẹ̀-èdè Iceland, o ń gbé lórí Bèbè Reykjanes, tí ó so pọ̀ mọ́ Bèbè Agbedeméjì Àtìláńtíìkì, níbi tí àwọn ìpele abala ilẹ̀ tí ó kan Àríwá àti Gúúsù America ti ń sún kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó kan ìpele abala ilẹ̀ Europe àti Áfíríkà. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mélòó kan mìíràn, àwọn ibi eléwu abẹ́ ìpele òkè abala ilẹ̀ ti ṣokùnfa àwọn òkè ayọnáyèéfín ńláńlá ní Hawaii àti ní kọ́ńtínẹ́ǹtì Áfíríkà.

Ewu Wo Ló Ní?

Bí òkè ayọnáyèéfín kan ṣe léwu tó ni a ń pinnu nípa yíyọná yèéfín rẹ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́, títí kan bí ìbúgbàù rẹ̀ ṣe gbòòrò tó àti àwọn ìjábá tí ó bá a rìn. A ń díwọ̀n ewu rẹ̀ nípa bí ènìyàn ṣe pọ̀ tó àti bí wọ́n ṣe gbara dì tó ní agbègbè eléwu kan. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí a yẹ àwọn ewu náà wò.

Ní gbogbogbòò, ìbúgbàù tí ó léwu jù máa ń wà níbi tí ògééré àpáta yíyọ́ bá ti ní èròjà silica púpọ̀. Irú àpáta yíyọ́ yìí máa ń dì pọ̀, ó sì lè dí ojú òkè ayọnáyèéfín náà títí tí àwọn gáàsì náà yóò fi ní agbára tó láti fọ́ òkè náà. Àpáta yíyọ́ ọlọ́pọ̀ èròjà silica máa ń dì pọ̀ di àpáta tí àwọ̀ rẹ̀ mọ́ fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ó sì sábà máa ń wà nínú àwọn òkè ayọnáyèéfín tí ó bá wà ní etí ìpele abala ilẹ̀. Bí àpáta yíyọ́ tí ń ru gùdù bá rí omi tí ó sì sọ ọ́ sínú odò ṣíṣàn lójijì, ó tún máa ń ṣokùnfà ìbúgbàù. Erùpẹ̀ gbígbóná tí ìbúgbàù náà ń tì jáde lè pani—òkè ayọnáyèéfín mẹ́ta ní ẹkùn agbègbè Caribbean-Central America pa ju 36,000 ènìyàn lọ láàárín oṣù mẹ́fà ní 1902.

Ní ọ̀nà míràn, àwọn ibi eléwu òkun àti àwọn òkè ayọnáyèéfín tí ń ṣẹlẹ̀ níbi tí ìpele abala ilẹ̀ bá ti ń sún, pa pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, máa ń ní èròjà basalt dúdú, tí kò ní ọ̀pọ̀ èròjà silica nínú, ṣùgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀ èròjà iron àti èròjà magnesium. Àpáta yíyọ́ eléròjà basalt jẹ́ olómi, ó sì sábà máa ń yọrí sí ìbúgbàù tí ó rọra ń fọ́n ká tàbí tí kì í tilẹ̀ fọ́n ká, àti lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó máa ń yọrí sí àpáta olómi tí kì í yára ṣàn, tí ó sì túbọ̀ rọrùn fún àwọn ènìyàn láti yẹra fún. Síbẹ̀, ìbúgbàù wọ̀nyí lè wà pẹ́ títí—òkè ayọnáyèéfín Kilauea ní erékùṣù Hawaii ti ń bú gbàù léraléra láti January 1983. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ìbúgbàù bẹ́ẹ̀ ti fa ìbàjẹ́ ohun ìní rẹpẹtẹ, kì í sábà fa ìpalára tàbí ikú.

Àwọn ìbúgbàù kan máa ń gbá erùpẹ̀ rẹpẹtẹ jọ sí etí òkè ayọnáyèéfín, tí ó lè fa ìyẹ̀gẹ̀rẹ̀ ilẹ̀ tàbí, nígbà tí ó bá dà pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ òjò dídì, omi dídì, tàbí omi, ó lè di ẹrẹ̀ tí ó lè tètè ṣàn lọ sísàlẹ̀ àwọn àfonífojì. Irú àwọn ìṣàn ẹrẹ̀ bẹ́ẹ̀ (tí a tún mọ̀ sí lahar, ọ̀rọ̀ èdè àwọn ará Indonesia fún àpáta olómi) lè ṣàn lọ fún ọ̀pọ̀ kìlómítà láti ibi òkè ayọnáyèéfín kan, bóyá nígbà pípẹ́ lẹ́yìn tí ìbúgbàù náà ti dáwọ́ dúró.

Èyí tí ó lágbára jù ní pàtàkì, ṣùgbọ́n tí kì í sábà ṣẹlẹ̀, ni a ń pè ní tsunami—àgbáàràgbá ìgbì òkun tí ìbúgbàù inú òkun tàbí ìyẹ̀gẹ̀rẹ̀ abẹ́ òkun ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òkè ayọnáyèéfín tí ń ru máa ń fà. Àwọn ìgbì lílágbára wọ̀nyí ń yára tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà ní wákàtí kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tsunami kì í lágbára tó bẹ́ẹ̀ lójú ibú, tí wọn kì í sì í jẹ́ ewu fún àwọn ọkọ̀ ojú omi tí ó bá ń kọjá ní ti gidi, wọ́n máa ń lágbára kíákíá bí wọ́n bá ti ń sún mọ́ ilẹ̀. Ọwọ́ àwọn ìgbì òkun yìí máa ń lọ sókè ju orí àwọn ilé àti ibùgbé lọ. Nígbà tí Krakatau bú gbàù ní 1883, 36,000 ènìyàn pàdánù ẹ̀mí wọn bí àwọn tsunami ṣe rọ́ lu etíkun Java àti Sumatra.

Àwọn ìjábá òkè ayọnáyèéfín mìíràn tí ó lè pa ìwàláàyè lára tàbí dabarú ìwàláàyè ní erùpẹ̀ àti èérún òkè ayọnáyèéfín tí ń já bọ́ nínú, títí kan ìgbì agbonijìgì afẹ́fẹ́ àyíká tí ń wá láti inú ìbúpẹ̀ẹ́ aláriwo, èéfín onímájèlé, òjò omiró, àti ìsẹ̀lẹ̀. Pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òkè ayọnáyèéfín eléwu ńlá tí a ń rí jákèjádò ayé, àti ẹgbàágbèje ewu tí wọ́n lè fà, àyẹ̀wò ìjàm̀bá òkè ayọnáyèéfín lọ́nà tí ó nítumọ̀ jẹ́ iṣẹ́ dídíjú kan tí ń peni níjà.

Ǹjẹ́ O Lè Dín Ìwuléwu Náà Kù?

Bí iye olùgbé ayé ṣe ń pọ̀ sí i, ènìyàn púpọ̀ sí i ń gbé ní àwọn agbègbè tí ó lè di eléwu nítorí òkè ayọnáyèéfín. Nítorí ìdí yìí, pa pọ̀ mọ́ ìbísí lọ́ọ́lọ́ọ́ nínú iye ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín kárí ayé, àwọn onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín ti ń mú kí ìsapá wọn lágbára sí i láti dín ewu ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín kù. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, wọ́n ti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìbúgbàù pẹ̀lú àṣeyọrí, a sì ti dáàbò bo ìwàláàyè. Kí ni ìdí ìpìlẹ̀ fún irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀?

Ìsẹ̀lẹ̀ sábà máa ń kọ́kọ́ wáyé nínú àwọn òkè ayọnáyèéfín tàbí nínú ìṣètò omi abẹ́ òkè náà, tí ń ṣèkìlọ̀ pé magma ń ru bọ̀ wá òkè, kí wọ́n tó bú gbàù. Bí magma ti ń gbára jọ pelemọ nínú òkè ayọnáyèéfín, yóò máa jà gùdù. Yóò tú gáàsì jáde, omi abẹ́lẹ̀ sì lè túbọ̀ gbóná kí ó sì kan sí i. Àwọn ìbúgbàù kéékèèké lè kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ṣáájú ńlá. A lè ṣọ́ gbogbo ìgbòkègbodò wọ̀nyí.

Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìbúgbàù kan, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣètò ìrísí ilẹ̀ ti lè mọ̀ nípa ewu tí ó lè fà nípa yíyẹ àkọsílẹ̀ àpáta náà wò. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn oríṣi ìṣàn òkè ayọnáyèéfín àti ewu tí ń bá wọn rìn kan náà máa ń wá léraléra, tàbí kí àwọn ìbúgbàù fara wé ti àwọn òkè ayọnáyèéfín tí a ti ṣèwádìí lé lórí. Lórí ìpìlẹ̀ irú àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò bẹ́ẹ̀, a ti ya àwọn àwòrán ilẹ̀ tí ń fi àwọn agbègbè eléwu jù lọ hàn nípa ọ̀pọ̀ òkè ayọnáyèéfín.

Àwọn ọ̀nà pàtàkì fún dídáàbò bo ìwàláàyè lọ́wọ́ ewu òkè ayọnáyèéfín kan kí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín máa ṣàyẹ̀wò ewu, kí wọ́n sì máa sọ́ òkè ayọnáyèéfín, àti kí àwọn aláṣẹ àdúgbò máa kìlọ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú nípa ewu tí ó lè ṣẹlẹ̀. Láìdàbí ìsẹ̀lẹ̀ tí kò tí ì ṣeé fi bẹ́ẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀, a lè ṣọ́ ọ̀pọ̀ ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín dáadáa débi tí àwọn ènìyàn tí ó lè wu léwu fi lè sá kúrò ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ amúnibanújẹ́ kan. Ó ṣe pàtàkì láti kúrò ní agbègbè eléwu, nítorí àwọn ohun tí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ní gbogbogbòò kò lè pèsè ààbò tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ lójú ìrugùdù àti ìgbóná janjan òkè ayọnáyèéfín àti ìbúgbẹ̀ẹ́ àti ipá aṣèparun àwọn ìyẹ̀gẹ̀rẹ̀ ilẹ̀, ìṣàn ẹrẹ̀, àti tsunami.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìsapá tí a ń ṣe láti dín ikú ènìyàn kù nínú ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín àti àwọn ewu tí ń bá a rìn tó gbóríyìn fún, ènìyàn kò tí ì lè sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìbúgbàù àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aṣekúpani tí ń bá a rìn lọ́nà pípéye tó, láti mú ààbò pátápátá lọ́wọ́ ewu òkè ayọnáyèéfín dáni lójú. Àní àwọn díẹ̀ lára àwọn tí ń ṣọ́ ìbúgbàù pàápàá ti ṣòfò ẹ̀mí nítorí ìbúgbàù àìròtẹ́lẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá ń gbé nítòsí òkè ayọnáyèéfín tí ó lè bú gbàù nígbàkugbà, o gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ èyíkéyìí tí àwọn aláṣẹ àdúgbò bá ṣe. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò túbọ̀ lè mú àǹfààní ṣíṣeé ṣe rẹ láti la ewu òkè ayọnáyèéfín já pọ̀ sí i.—A kọ ọ́ ránṣẹ́ láti ọwọ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìbátan ilẹ̀ ayé òun ìràwọ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]

Sísọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìbúgbàù Òkè Ayọnáyèéfín Láti Gbalasa  Òfuurufú Kẹ̀?

Ronú wíwọn bí òkè ayọnáyèéfín se ń sún dé orí ìwọn rẹ́gí ti sẹ̀ǹtímítà kan láti inú sátẹ́láìtì tí ó wà ní 20,000 kìlómítà lókè ilẹ̀ ayé—tí ó ń rìn ní ìwọ̀n kìlómítà márùn-ún ní ìṣẹ́jú àáyá kan, láìpẹ̀dín! Ìṣètò Ìgbékapò Àgbáyé (GPS), tí ó ní iye sátẹ́láìtì mélòó kan ní àfikún sí àtagbà rédíò tí a gbé ka àwọn ibi yíyẹ lórí ilẹ̀ ayé ti mú èyí ṣeé ṣe. A ń tọpa ipò sátẹ́láìtì mẹ́rin, ó kéré tán, fún ìwọ̀n kọ̀ọ̀kan. A ń fi àwọn agogo tí a fi átọ́ọ̀mù ṣe, tí wọ́n péye jù díwọ̀n àkókò. Àwọn ìdíwọ̀n wọ̀nyí, tí ó ṣeé lò láìka ipò ojú ọjọ́ sí, ṣàǹfààní púpọ̀ ju àwọn ọ̀nà ìtọpa ti orí ilẹ̀ lọ. Àwọn ìdíwọ̀n GPS lè mú kí ìsọtẹ́lẹ̀ nípa ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín, tí ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí òkè ayọnáyèéfín náà ti ń gbòòrò sunwọ̀n sí i. A ti ń lo ọgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí fún àwọn òkè ayọnáyèéfín ní Iceland, Itali, Japan, àti United States.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 17]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Òkè ayọnáyèéfín tí ń ṣàn àti ìpele òkè ilẹ̀ ayé

Òkè ayọnáyèéfín tí ń ṣàn

Àwọn ààlà ìpele abala ilẹ̀

A ṣàfihàn díẹ̀ lára iye tí ó lé ní 500 òkè ayọnáyèéfín tí ń ṣàn lókè yìí

[Credit Line]

Mountain High Maps™ copyright © 1993 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìṣàn erùpẹ̀ láti òkè ayọnáyèéfín Unzen, Japan, tí ń ṣàn wá sí àdúgbò kan

[Credit Line]

Orion Press-Sipa Press

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Òkè Ńlá St. Helens ń bú gbàù

[Credit Line]

USGS, David A. Johnston, Cascades Volcano Observatory

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Òkè Ńlá Etna, Sicily, láìpẹ́ yìí, tú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ jáde fún oṣù 15

[Credit Line]

Jacques Durieux/Sipa Press

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Òkè Ńlá Kilauea, Hawaii, ti fi nǹkan bí 200 ẹ́kítà kún erékùṣù náà

[Credit Line]

©Soames Summerhays/ Photo Researchers

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́