Popocatepetl—Òkè Ayọnáyèéfín Ọlọ́lá Ńlá, Awuniléwu ti Mexico
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ MEXICO
BÁWO ni inú rẹ yóò ti dùn tó láti máa gbé lẹ́bàá òkè ayọnáyèéfín rírẹwà kan, ṣùgbọ́n tí ń halẹ̀ mọ́ni? Bóyá ìwọ yóò baralẹ̀ ronú nípa ìyẹn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ipò tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn wà gan-an nìyí ní àwọn ìlú tí ó wà láyìíká òkè ayọnáyèéfín Popocatepetl ọlọ́láńlá, ní Mexico.
Ìtàn Òkè Ayọnáyèéfín Náà
Orúkọ rẹ̀ ní èdè Nahuatl túmọ̀ sí “Òkè Ńlá” tàbí “Òkè Tí Ń Yọ Èéfín.” Ó ga ní mítà 5,452, ó sì wà ní òkè ńlá Sierra Nevada, ní ìpínlẹ̀ Puebla, nítòsí ààlà ẹnubodè ìpínlẹ̀ Mexico àti ti Morelos. Ó ní ìrísí òkòtó rírẹwà, tí ó sì jẹ́ ọlọ́láńlá, òjò dídì sì ń wà lórí rẹ̀ jálẹ̀ ọdún. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, òkè ayọnáyèéfín àwòmálèlọ yìí ti dabarú ìgbésí ayé àwọn olùgbé àgbègbè àrọko tí a yà sọ́tọ̀ náà nípa bíbú gbàù ní ìgbà 16 láàárín 1347 sí 1927. Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí èyí tí ó gbàfiyèsí lára àwọn ìbúgbàù wọ̀nyí.
Òkè ayọnáyèéfín náà wà láàárín àwọn àgbègbè ìgboro ìlú méjì: ìlú ńlá Puebla, tí ó wà ní kìlómítà 44 ní ìhà ìlà oòrùn, àti ìlú ńlá Mexico, tí ó wà ní 70 kìlómítà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá. Ní àfikún, ìlú 307 ló wà ní ìpínlẹ̀ Puebla, tí iye àwọn olùgbé ibẹ̀ tí ó jẹ́ 400,000 sì wà nítòsí òkè ayọnáyèéfín náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n wà ní àgbègbè tí ewu wà gan-an, ipa tí ìbúgbàù Popocatepetl ńlá kan yóò ní lórí wọn ní ti ọrọ̀ ajé àti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà yóò burú jáì fún àgbègbè náà.
Lópin ọdún 1994, ọ̀nà tí òkè ayọnáyèéfín náà ń gbà yọ èéfín pọ̀ sí i—dé ìwọ̀n tí a fi kígbe ìkìlọ̀, tí àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ibẹ̀ sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ní December 21, 1994, ó kéré tán, ojú mẹ́ta fara hàn ní ìsàlẹ̀ ibi jíjinkòtò, tí gáàsì àti ooru gbígbóná ń gbà jáde. Òjò eérú náà, tí ó lọ dé ìlú ńlá Puebla, pọ̀ tó 5,000 tọ́ọ̀nù. Ìjọba wá gbé ètò kan kalẹ̀ láti kó 50,000 ènìyàn kúrò níbẹ̀ tí wọ́n pèsè ibùgbé ibi ààbò fún 30,000 lára wọn.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú gbégbèésẹ̀ nípa pípèsè ibùgbé fún àwọn tí wọ́n ṣaláìní. (Fi wé Ìṣe 4:32-35.) Ìròyìn tí ó wá láti ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ apèsè ìrànwọ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí sọ pé: “Láìka àkókò àti ìjẹ́kánjúkánjú ipò náà sí, ìgbésẹ̀ àwọn ará ní ìlú ńlá Puebla àti àyíká rẹ̀ ta yọ. Wọ́n ṣètò láti pèsè ilé fún àwọn tí iye wọn lé ní 600. Ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan sọ pé: ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbégbèésẹ̀ ní kánmọ́. Wọ́n kó àwọn arákùnrin wọn kúrò ní àgbègbè eléwu lọ́gán.’”
Òkè Ayọnáyèéfín Náà Gbéra Sọ
Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni tí a fàṣẹ sí ti sọ, ní Tuesday, March 5, 1996, ní agogo 3:50 òru, a ṣàkíyèsí pé ìyọnáyèéfín tí ń milẹ̀ tìtì ń yára pọ̀ sí i lójijì ní òkè náà, bóyá tí ó jẹ́ nítorí àwọn ọ̀nà ńlá tí gáàsì àti ooru gbígbóná tí ìyọnáyèéfín ti December 21, 1994, ṣí sílẹ̀. Àwọn fọ́tò àti ìsọfúnni tí a rí gbà fìdí ẹ̀rí múlẹ̀ pé eérú ti dí àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, tí èyí sì mú kí ìwọ̀n ipá inú òkè ayọnáyèéfín náà pọ̀ sí i. Ipá yìí wá ṣí àwọn ọ̀nà náà sílẹ̀ níkẹyìn.
Ìwé agbéròyìnjáde El Universal, ti Tuesday, April 9, 1996, sọ pé: “Ọ̀gọ̀dọ̀ ń ṣàn nínú ibi jíjinkòtò Popocatepetl, nítorí náà, àwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti àwọn aláṣẹ láti Ilé Iṣẹ́ Ìdáàbòbo Ará Ìlú wà lójúfò, lójú pé ìyọnáyèéfín òkè ayọnáyèéfín náà ń pọ̀ sí i.” Ìròyìn náà sọ pé, àwọn ìyípadà náà “di onírìísí ‘rìbìtì,’ tí yóò mú kí ‘àwọn ọ̀nà’ Popocatepetl kún láàárín oṣù bíi mélòó kan, tí ó lè ṣokùnfà àkúnya ní ìta.”
Ní Thursday, May 2, 1996, wọ́n jíròrò bí òkè ayọnáyèéfín Popocatepetl ṣe ń ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́ níbi ìpàdé kan ní ìlú ńlá Puebla. Ọ̀mọ̀wé Servando de la Cruz Reyna, mẹ́ńbà Ẹ̀ka Ìmọ̀ Físíìsì Ilẹ̀ Ayé ti Yunifásítì Adádúró ní Orílẹ̀-Èdè Mexico, sọ pé: “Lọ́nà àdánidá, bí ó ṣe ń ṣe yìí ń fa àníyàn ńláǹlà . . . Ó sábà máa ń ṣeé ṣe pé òkè ayọnáyèéfín náà yóò dé ipò tí ó túbọ̀ lè bú gbàù. Èyí lè ṣẹlẹ̀, a kò sì sẹ́ ẹ rárá.”
A ti sọ ọ̀rọ̀ ìṣelámèyítọ́ jáde pé bí àwọn ìjọba bá tilẹ̀ sọ nípa ètò ilé gbígbé àti kíkó àwọn ènìyàn kúrò níbẹ̀, tí wọ́n sì ṣe àwọn ìpàdé láti fún àwọn ènìyàn ibẹ̀ ní ìdarísọ́nà, ìjótìítọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ẹkùn ilẹ̀ náà lérò pé àwọn kò tí ì rí ìtọ́sọ́nà kedere nípa ohun tí wọn óò ṣe bí òkè ayọnáyèéfín náà bá bú gbàù. Fún àpẹẹrẹ, níbi ìpàdé tí a sọ níṣàájú, onírúurú àwọn aṣojú láti àwọn ìlú tí ó sún mọ́ òkè ayọnáyèéfín náà yarí pé àwọn kò mọ ibi ààbò tàbí àwọn ibi ààbò tí àwọn yóò lọ bí ìjábá bá ṣẹlẹ̀.
A ní láti fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìkìlọ̀ tí òkè ayọnáyèéfín náà ti ń gbé jáde. Láìṣe àní-àní, àwọn onílàákàyè ènìyàn yóò ṣe ohun yòó wù tí ó bá ṣeé ṣe láti dáàbò bo ẹ̀mí wọn, kódà ní fífi àwọn ohun tí ara rúbọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń gbé ní àgbègbè yẹn tí ń múra láti kúrò ní ẹkùn ilẹ̀ náà bí ó bá pọn dandan. A ti yanṣẹ́ fún ìgbìmọ̀ apèsè ìrànwọ́ kan láti máa bẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà ní àgbègbè yẹn wò déédéé, kí wọ́n máa fún wọn ní ìdarísọ́nà nípa ohun tí wọ́n lè ṣe bí ìjábá bá ṣẹlẹ̀. A ti rọ àwọn kan tí wọ́n ń gbé ibi tí ó sún mọ́ àgbègbè eléwu náà jù láti fi àgbègbè yẹn sílẹ̀ nígbà tí àkókò ṣì wà, níwọ̀n bí àwọn onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín tí kìlọ̀ ní kedere pé, ewu tí kò ṣe é yẹ̀, tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ni òkè ayọnáyèéfín náà jẹ́. Ó hàn gbangba pé ìdílé kọ̀ọ̀kan ló ní láti ṣèpinnu tirẹ̀.
Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn ènìyàn tí ń gbé àyíká òkè ayọnáyèéfín náà ń gbé láìsí ìdààmú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, làákàyè ń béèrè pé kí àwọn olùgbé ibẹ̀ wà lójúfò sí ìkìlọ̀ èyíkéyìí tí òkè ayọnáyèéfín náà tàbí àwọn aláṣẹ bá ṣe tí ó lè fi ipò ọ̀ràn ìṣòro hàn. Kò bọ́gbọ́n mu láti kọtí ikún sí àwọn ìkìlọ̀ tí òkè ayọnáyèéfín Popocatepetl ọlọ́láńlá àmọ́ tí ń wuni léwu ń ṣe.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn Ìdámọ̀ràn Tí A Ní bí Ìjábá Bá Ṣẹlẹ̀
Ibùdó Àpapọ̀ fún Ìdènà Ìjábá ti pèsè àkọsílẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ láti gbé kí ìjábá tó ṣẹlẹ̀:
• Mọ ọ̀nà ìgbàkúrò rẹ. (Wá àwọn ibi gíga, kì í ṣe ibi rírẹlẹ̀ tí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, omi, tàbí ẹrẹ̀ ti lè ṣàn)
• Wá àpò kan tí ó ní àwọn àkọsílẹ̀ ara ẹni, egbòogi, omi, aṣọ tí o lè pààrọ̀ (tí ó lè jẹ́ èyí tí ó wúwo tí ó bo gbogbo ara), fìlà, aṣọ ìnujú láti bo imú àti ẹnu, iná oníbátìrì, rédíò, àwọn bátìrì, àti kúbùsù nínú sí àrọ́wọ́tó
• Ṣètò pẹ̀lú àwọn ẹbí tí wọ́n lè pèsè ibùgbé mìíràn, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún lílo àwọn ibi ààbò ti gbogbogbòò
• Mú kìkì àwọn ohun pípọndandan dání. Má ṣe mú ẹran ọ̀sìn tàbí àwọn ẹranko lọ́wọ́
• Mọ bí o ṣe lè rí ibi ààbò ti gbogbogbòò
• Pa iná mànàmáná, gáàsì, àti omi
• Sinmẹ̀dọ̀