Ìfẹ́ Kristẹni—Nígbà Tí Òkè Ayọnáyèéfín Bú Gbàù
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ CAMEROON
ÒKÈ ayọnáyèéfín ńlá kan bú gbàù lọ́dún tó kọjá ní orílẹ̀-èdè Cameroon ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Òkè ayọnáyèéfín ni Òkè Ńlá Cameroon tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ó sì fi ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé àádọ́rin mítà ga ju ìtẹ́jú òkun lọ. Wọ́n ní ìbúgbàù náà—tó di ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún irú rẹ̀ láàárín ọ̀rúndún ogún yìí—ló ṣì le jù lọ, tó sì burú jù lọ.
Ọ̀sán ọjọ́ Saturday, March 27, 1999, ni ìjábá náà kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. Àwọn tó tojú wọn ṣẹlẹ̀ ní ìlú Buea, tó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkè náà, sọ pé ògiri ilé, àwọn ilé, àti àwọn igi pàápàá mì tìtì. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì, ní nǹkan bí agogo mẹ́jọ ààbọ̀, ìmìtìtì tó lágbára jù, tó sì burú jù lọ ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè náà. O milẹ̀ dé Douala, tó jẹ́ àádọ́rin kìlómítà síbẹ̀. Àkọlé ìwé ìròyìn Le Messager ti Tuesday, March 30, 1999, sọ pé: “Òkè Ńlá Cameroon Bú Gbàù—Ọ̀kẹ́ Méjìlá Ààbọ̀ [250,000] Èèyàn Fara Gbá Ewu Iná.” Ó tún sọ pé: “Láàárín ọjọ́ méjì péré, ilẹ̀ mì tìtì ní ìgbà àádọ́ta; ní báyìí, òkè náà ti dá ihò lọ́nà mẹ́rin; ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ilé ló ti bà jẹ́; ilé ààrẹ tó wà ní Buea ti di àfọ́kù.”
Nǹkan bí ọgọ́rin àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń gbé Buea. Ọ̀pọ̀ ilé ló bà jẹ́ kọjá àtúnṣe, títí kan èyí táa ń lò bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ṣùgbọ́n, kò sẹ́ni tó kú.
Ìfẹ́ Kristẹni Lẹ́nu Iṣẹ́
Ìfẹ́ Kristẹni yára bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti lè ṣàtúnṣe ohun tí òkè ńlá tó bú gbàù yìí bà jẹ́. A gbé ìgbìmọ̀ tó ń pèsè ìrànwọ́ kalẹ̀, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò láti pèsè owó tí a nílò, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí sì fi tìfẹ́tìfẹ́ yọ̀ǹda àkókò, agbára, àti owó wọn láìbojúwẹ̀yìn.
Àwọn ará láti ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó oúnjẹ ránṣẹ́. Ẹlẹ́rìí kan fi ẹgbẹ̀rún búlọ́ọ̀kù tọrẹ. Òmíràn ṣètò kí a lè rí páànù ìbolé rà lówó pọ́ọ́kú. Òmíràn sì tún rin ìrìn kìlómítà mẹ́rìndínlógún láti lọ ra igi. Ọ̀dọ́kùnrin kan, tó ti ń tọ́jú owó pamọ́ láti fi san owó orí ìyàwó rẹ̀ fún àwọn àna rẹ̀, sún ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ síwájú, ó sì fi owó náà tún ayùn ìrẹ́gi rẹ̀ ṣe. Ló bá dorí kọ igbó gẹdú, ó sì gé igi tó pọ̀ tó láti fi kọ́ odindi ilé kan! Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tí wọ́n lókun forí ru àwọn igi náà lọ síbi tó jìnnà tó kìlómítà márùn-ún tí ọkọ̀ akẹ́rù sì wá kó wọn níbẹ̀.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tún àwọn ilé náà kọ́ ní pẹrẹu ní April 24, nígbà tí ọgọ́ta olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kóra jọ pọ̀ sí ibi tí ìjábá náà ti ṣẹlẹ̀. Ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, iye àwọn èèyàn náà pọ̀ gan-an, wọ́n ti di igba. Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta, tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn ń bẹ̀rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́, wá síbẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ṣíwọ́ níbi iṣẹ́, wọ́n sì ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà wọ ọ̀gànjọ́ òru. Ẹlẹ́rìí kan tó wá láti Douala fi gbogbo òwúrọ̀ ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀; lẹ́yìn náà ló wá gun alùpùpù rẹ̀ rìnrìn àjò àádọ́rin kìlómítà, ó sì ṣiṣẹ́ títí di ọ̀gànjọ́ òru kó tó padà sílé. Kò pé oṣù méjì tí wọ́n fi ṣàtúnkọ́ ilé mẹ́fà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń lọ sí ìpàdé fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ náà, ilé ẹnì kan ni àwọn ará Ìjọ Buea ṣì ti ń ṣe ìpàdé ní báyìí ná.
Ní sáà kan náà, ìgbìmọ̀ tó ń pèsè ìrànwọ́ pín oògùn apakòkòrò omi tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì láti fi pa kòkòrò inú omi tó ní kòkòrò, wọ́n sì tọ́jú nǹkan bí èèyàn mẹ́wàá tí àìsàn tó jẹ mọ́ mímí ń ṣe, èyí tí afẹ́fẹ́ olóró àti àwọn èròjà àpáta kíkúnná tó tinú òkè ayọnáyèéfín jáde fà. Kí ni àwọn tó rí i bí àwọn Kristẹni ṣe fìfẹ́ hàn síra wọn yìí sọ?
Ìfẹ́ Kristẹni Tayọ
Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan lára àwọn Aṣojú Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ Àgbẹ̀ Lẹ́kùn Ilẹ̀ náà wo ọ̀kan lára àwọn ilé táwọn ará kọ́ náà, ó sọ pé: “Ẹ̀rí ńlá ni ilé náà fúnra rẹ̀ jẹ́ . . . , ó jẹ́ àmì ìfẹ́.” Olùkọ́ kan sọ pé: “Mi ò rí irú èyí rí láyé mi. . . . Àmì ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ gbáà lèyí jẹ́.”
Àwọn tí wọ́n jàǹfààní rẹ̀ pẹ̀lú ò panu mọ́. Timothy, tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin, tó sì ń ṣàìsàn, kọ̀wé pé: “Gbogbo ìgbà táa bá wo ilé wa tuntun yìí, omijé ayọ̀ máa ń bọ́ lójú wa ṣáá ni. Gbogbo ìgbà la ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ohun tó ṣe fún wa yìí.” Opó kan, tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin bára wọn nínú ìyà nígbà tí ilé wọn wó. Ẹ̀yìn yẹn làwọn tí wọ́n tún gbà láti ràn án lọ́wọ́ jí páànù ìbolé rẹ̀ lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn wọ̀nyẹn ló lọ ràn án lọ́wọ́. Obìnrin náà sọ pé: “Mi ò mọ bí mo ṣe lè dúpẹ́. Ayọ̀ kún ọkàn mi.” Elizabeth, tí í ṣe ìyàwó Kristẹni alàgbà kan, sọ pé: “Inú mi dùn pé ìfẹ́ wà nínú ètò àjọ Jèhófà. Ó fi hàn pé Ọlọ́run alààyè la ń sìn.”
Ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín náà rinlẹ̀, àmọ́, kò lè paná ìfẹ́ Kristẹni tí ẹgbẹ́ ará yìí ní. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti kọ lábẹ́ ìmísí, “ìfẹ́ kì í kùnà láé.”—1 Kọ́ríńtì 13:8.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìṣàn àpáta yíyọ́ ba nǹkan jẹ́ gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ṣiṣẹ́ kára, wọ́n tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Òkè Ńlá Cameroon