Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìkọlù Àrùn Ọkàn-Àyà Mo dúpẹ́ pé mo wà nínú ètò àjọ kan tí ń bìkítà fún ire wa nípa ti ara, láfikún sí pé ó ń tọ́ wa sọ́nà nípa tẹ̀mí. Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ìkọlù Àrùn Ọkàn-Àyà—Kí Ni A Lè Ṣe?” (December 8, 1996) fi bí a ṣe lè mọ àwọn àmì ìkọlù àrùn ọkàn àyà hàn wá. Nígbà tí bàbá ọkọ mi ní àwọn àmì àrùn wọ̀nyí, a mọ̀ pé ipò rẹ̀ lè burú, a sì gbé e lọ sílé ìwòsàn. Ó ní ìkọlù àrùn ọkàn àyà; àmọ́ lẹ́yìn tí ó lo ọjọ́ 24 nílé ìwòsàn, ó bọ́ lọ́wọ́ ewu.
E. S., Brazil
Àrùn òpójẹ̀ agbẹ́jẹ̀jáde tí ó wú pa bàbá mi ní 1995, nítorí náà, nígbà tí mo kọ́kọ́ rí ìtẹ̀jáde yìí, n kò ní ìgboyà láti kà á. Bí ó ti wù kí ó rí, mo kà á ní oṣù kan lẹ́yìn náà, àwọn àpilẹ̀kọ náà sì tù mí nínú, bí mo ti mọ̀ pé àwọn ẹlòmíràn ti nírìírí ìbànújẹ́ tí àrùn ọkàn àyà lè mú bá ìdílé.
S. J., Kánádà
Ní July tó kọjá, ọkọ mi ṣubú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ẹnu-ọ̀nà-dé-ẹnu-ọ̀nà, a sì ní láti gbé e dìgbàdìgbà lọ sílé ìwòsàn. Ó dùn mọ́ni pé ó la ipò eléwu náà já. Àwọn àpilẹ̀kọ yín jáde lákòókò yíyẹ fún wa. Ó mú wa sunkún nígbà tí a rí ẹ̀ka tí ó sọ pé “Àwọn Ìdílé Nílò Ìtìlẹ́yìn,” nítorí pé bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ìmọ̀lára wa.
M. A., Japan
Ní Sunday tó kọjá, mo ní ìrora tí kò dẹwọ́ ní apá mi òsì, àwọn ṣóńṣó orí ìka mi sì kú. Mo rò pé ìrora wíwọ́pọ̀ lásán ni. Nígbà tí mo ka àwọn àpilẹ̀kọ yín nípa ìkọlù àrùn ọkàn àyà, ó wá dá mi lójú hán-ún pé mo ní àwọn àmì àrùn náà! Mo lọ síbi ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn kan, àwọn dókítà sì rí i pé ọ̀kan lára àwọn òpójẹ̀ àlọ pàtàkì inú ọkàn àyà mi ti dí. Wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún mi lọ́jọ́ kejì. Ó ṣeé ṣe gan-an pé bí ẹ kò bá ti kọ àwọn àpilẹ̀kọ yín ni, n kì bá tí sí níhìn-ín láti kọ ìwé ìdúpẹ́ yìí!
N. S., United States
Mo mọrírì àpótí náà, “Àwọn Àmì Àrùn Ọkàn-Àyà” lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ó mú kí n mọ̀ pé ẹ dàníyàn gidigidi nípa àwọn ìṣòro wa, ẹ sì ń fún wa ní àwọn ohun tí a nílò láti kojú wọn.
M. B., Senegal
Láti ìgbà tí bàbá mi ti ní ìkọlù àrùn ọkàn àyà ni ìgbésí ayé ti yí pa dà lọ́nà àrà nínú ilé wa. Láàárín àwọn àkókò tó ṣòro wọ̀nyí, àwọn àpilẹ̀kọ náà jẹ́ ìtùnú gidigidi fún wa.
P. G., Ítálì
Ìtẹríba Aya Mo mọrírì àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ìtẹríba Aya—Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí?” (December 8, 1996), gidigidi. Ọkọ mi jẹ́ aláìgbàgbọ́, ó sì máa ń ṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti tẹrí ba fún un. Mo fẹ́ láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, bí mo bá ti lè ṣe tó, kí n lè tipa bẹ́ẹ̀ jèrè rẹ̀. (Pétérù Kíní 3:1) Síbẹ̀ mo fẹ́ láti dúró gbọnyin nínú iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà. Àpilẹ̀kọ yín fún mi níṣìírí, ó sì mú mi láyọ̀ láti mọ̀ pé Ọlọ́run mi ń pa mí mọ́.
M. S., United States
Àpilẹ̀kọ náà ṣí mi níyè gidigidi. Níwọ̀n bí àwọn pákáǹleke láti ọ̀dọ̀ Sátánì ti ń pọ̀ sí i, a nílò irú ìsọfúnni yìí láti dúró nínú ìgbàgbọ́. Mo gbádùn àpẹẹrẹ ti Ábígẹ́lì nínú Bíbélì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, àti kókó tí ẹ sọ pé aya kan gbọ́dọ̀ máa fi ìwòyemọ̀ hàn, kí ó má sì ṣe nímọ̀lára ẹ̀bi fún lílo àtinúdá nínú àwọn ọ̀ràn kan.
D. M., United States
Louis Pasteur Ọmọ ọdún 12 ni mí, mo sì fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé mo mọrírì àpilẹ̀kọ náà “Louis Pasteur—Ohun Tí Iṣẹ́ Rẹ̀ Ṣí Payá.” (December 8, 1996) A ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ lọ́wọ́ ní kíláàsì ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì. Mo lo àpilẹ̀kọ yìí nígbà tí mo ń múra iṣẹ́ ìwádìí kan, mo sì gba àfikún máàkì mẹ́wàá!
A. P., United States