ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/8 ojú ìwé 4-8
  • Dídá Àwọn Àmì Àrùn Mọ̀ àti Ṣíṣiṣẹ́ Lé Wọn Lórí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dídá Àwọn Àmì Àrùn Mọ̀ àti Ṣíṣiṣẹ́ Lé Wọn Lórí
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Ṣẹlẹ̀
  • Ìkọlù Náà
  • Ní Ilé Ìwòsàn
  • Dókítà Ṣàlàyé
  • Ìrètí Ìkọ́fẹpadà Kò Dán Mọ́rán
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Àrùn Ọkàn-Àyà—Ewu Kan fún Ìwàláàyè
    Jí!—1996
  • Báwo Ni A Ṣe Lè Dín Ewu Náà Kù?
    Jí!—1996
  • Ọ̀nà Láti Kọ́fẹ Padà
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 12/8 ojú ìwé 4-8

Dídá Àwọn Àmì Àrùn Mọ̀ àti Ṣíṣiṣẹ́ Lé Wọn Lórí

BÍ ÀWỌN àmì àrùn ọkàn-àyá bá fara hàn, ó ṣe pàtàkì láti wá ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, níwọ̀n bí ewu ikú ti pọ̀ jù lọ láàárín wákàtí àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìkọlù kan. Ìtọ́jú kánmọ́kánmọ́ lè dáàbò bo ìṣùpọ̀ ẹran ara ọkàn-àyà lọ́wọ́ ìbàjẹ́ tí kò ní àtúnṣe. Bí ìṣùpọ̀ ẹran ara ọkàn-àyà tí a dáàbò bò bá ṣe pọ̀ tó ni ọkàn-àyà yóò ṣe lè tú ẹ̀jẹ̀ jáde lọ́nà gbígbéṣẹ́ tó lẹ́yìn ìkọlù náà.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àrùn ọkàn-àyà kán jẹ́ ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́, tí kì í fi àmì àrùn kankan hàn síta. Nínú ọ̀ràn báwọ̀nyí, ẹni náà lè má mọ̀ pé òún ní àrùn inú òpó tí ń gbẹ́jẹ̀ jáde láti inú ọkàn (CAD). Ó bani nínú jẹ́ pé, ìkọlù líle koko ni ó máa ń jẹ́ àmì àkọ́kọ́ fún àwọn kan láti mọ̀ pé àwọ́n ní àrùn ọkàn-àyà. Bí ọkàn-àyá bá dákú (ọkàn-àyà ṣíwọ́ títú ẹ̀jẹ̀ jáde), ìrètí àtilàájá kò tó nǹkan bí a kò bá kàn sí agbo adáninídè kan lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí ẹni tó wà nítòsí sì lo ìlànà ìmọ́kànsọjí lọ́gán.

Lẹ́tà ìròyìn náà, Harvard Health Letter, sọ pé, lára ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ó ní àwọn àmì àrùn CAD, nǹkan bí ìdajì yóò sún wíwá ìrànwọ́ ìṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ síwájú. Èé ṣe? “Ó sábà máa ń jẹ́ nítorí pé wọn kò mọ ohun tí àwọn àmì àrùn tí wọ́n ní túmọ̀ sí tàbí pé wọn kò kà wọ́n sí.”

John,a tí ó ní àrùn ọkàn-àyà, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wí pé: “Bí o bá róye pé ohun kan kò tọ́, má ṣe jẹ́ kí ìrònú pé àwọn ènìyàn yóò rò pé o fi ọwọ́ ìjẹ́pàtàkì ju bí ó ti yẹ lọ mú ọ̀ràn náà mú ọ jáfara láti gba ìtọ́jú ìṣègùn. Ẹ̀mí mi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ nítorí pé n kò tètè gbé ìgbésẹ̀ tó.”

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀

John ṣàlàyé pé: “Ní ọdún kan ààbọ̀ ṣáájú ìgbà tí mo ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, dókítà kán kìlọ̀ fún mi pé èròjà cholesterol, tí ó jẹ́ okùnfà pàtàkì kan fún ewu àrùn CAD, pọ̀ jù lára mi. Ṣùgbọ́n n kò ka ọ̀ràn náà sí, níwọ̀n bí mo ti rò pé mo ṣì wà ní ọ̀dọ́—n kò tí ì pé ọmọ 40 ọdún—ara mí sì le. Mo kábàámọ̀ gidigidi pé n kò gbé ìgbésẹ̀ kankan nígbà náà. Mo rí àwọn àmì ìkìlọ̀ míràn—àìlèmídélẹ̀ tí ń gbà mí lókunra, àwọn ìrora tí mo kà sí oúnjẹ tí kò dà, àti àárẹ̀ tí ó ré kọjá ààlà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù ṣáájú ìkọlù náà. Mo dẹ́bi gbogbo ìwọ̀nyí fún àìsùntó àti ọ̀pọ̀ másùnmáwo nítorí iṣẹ́. Ní ọjọ́ mẹ́ta kí ìkọlù àrùn ọkàn-àyà náà tóó ṣe mí, ohun kan tí mo kà sí ìsúnkì ìṣùpọ̀ ẹran ará ṣe mí nínú àyà mi. Ó jẹ́ ìkọlù kékeré kan tí ó ṣáájú ìkọlù ńlá tí ó dé lọ́jọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà.”

Ìrora tàbí ìfúnpọ̀ àyà, tí a ń pè ní gìrì, máa ń fún nǹkan bí ìdajì àwọn tí ó ní àrùn ọkàn-àyà ní ìkìlọ̀ ṣáájú. Àwọn kan kì í lè mí délẹ̀, tàbí ó máa ń rẹ̀ wọ́n, tí wọn kì í sì í lágbára gẹ́gẹ́ bí àmì àrùn, tí ń fi hàn pé ọkàn-àyà kò rí afẹ́fẹ́ oxygen tí ó pọ̀ tó, nítorí nǹkan kán ti dí àlàfo òpó ẹ̀jẹ̀ tí ó wọ inú ọkàn-àyà. Ó yẹ kí àwọn àmì ìkìlọ̀ wọ̀nyí mú kí ẹnì kan lọ rí dókítà fún àyẹ̀wò ọkàn-àyà. Dókítà Peter Cohn sọ pé: “Ṣíṣètọ́jú ìrora àyà, kì í ṣe ìdánilójú pé a óò dènà ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, ṣùgbọ́n ó kéré tán, ó dín ṣíṣeéṣe ìkọlù tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ kù.”

Ìkọlù Náà

John ń sọ̀rọ̀ lọ pé: “A fẹ́ẹ́ lọ gbá softball lọ́jọ́ yẹn ni. Bí mo ti ń sáré jẹ ìṣù búrẹ́dì tí a fi ẹran lílọ̀ há láàárín pọ̀ mọ́ ọ̀dùnkún dídín fún oúnjẹ ọ̀sán, mo ṣàìkọbi ara sí àìfararọ, ìrìndọ̀, àti ìṣekandi apá òkè ara tí ó yọ mí lẹ́nu. Ṣùgbọ́n nígbà tí a dé ibi ìgbábọ́ọ̀lù, tí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbá bọ́ọ̀lù, mo mọ̀ pé nǹkan burúkú kan ń ṣẹlẹ̀. Ní gbogbo ọ̀sán náà, nǹkán túbọ̀ ń burú sí i fún mi ni.

“Lọ́pọ̀ ìgbà ni mò ń tàkaakà sórí bẹ́ǹṣì àwọn agbábọ́ọ̀lù, tí mo sì ń gbìyànjú láti na àwọn ìṣùpọ̀ ẹran ara àyà mi, ṣùgbọ́n wọ́n túbọ̀ ń le sí i ni. Bí mo ti ń gbá bọ́ọ̀lù, mo ń sọ fún ara mi pé, ‘Bóyá mo ní àrùn gágá,’ nítorí òtútù ń mú mi, ó sì ń rẹ̀ mí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí mo bá sáré, ó ṣe kedere pé n kò lè mí dáadáa. Mo tún dùbúlẹ̀ sórí bẹ́ǹṣì lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà tí mo dìde, kò sí iyè méjì pé mo ní ìṣòro gidigidi. Mo ké sí James, ọmọkùnrin mi, pé: ‘Mo ní láti lọ sílé ìwòsàn NÍSINSÌNYÍ!’ Ó dà bíi pé àyà mí ti jìn wọnú. Ìrora náà pọ̀ débi tí n kò lè dìde nàró. Mo rò pé, ‘Èyí kò lè jẹ́ ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, àbí? Ọmọ ọdún 38 péré ni mí!’”

Ọmọkùnrin John, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 15 péré nígbà náà, ròyìn pé: “Dádì mí di ẹni tí kò lókun nínú láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbígbé ni a gbé e wọkọ̀. Ọ̀rẹ́ mi ni ó wa ọkọ̀ náà, tí ó sì ń bi Dádì léèrè ọ̀rọ̀ láti mọ bí ipò rẹ̀ ti rí. Níkẹyìn, Dádì kò dáhùn mọ́. Ọ̀rẹ́ mi pariwo pé: ‘John!’ Ṣùgbọ́n bàbá mi kò dáhùn síbẹ̀. Nígbà náà ni Dádì súnra kì níbi tí ó jókòó sí, tí gìrí mú un, tí ó sì ń bì. Mo ń pariwo léraléra pé: ‘Dádì! Mo fẹ́ràn rẹ! Jọ̀wọ́, máà kú!’ Lẹ́yìn gìrì náà, ó wà láìmira lórí ìjókòó náà. Mo rò pé ó ti kú ni.”

Ní Ilé Ìwòsàn

“A sáré wọ ilé ìwòsàn náà fún ìrànlọ́wọ́. Ó ti tó ìṣẹ́jú méjì tàbí mẹ́ta lẹ́yìn tí mo rò pé Dádì ti kú, ṣùgbọ́n mo ń retí pé ó ṣì ṣeé mú sọ jí. Sí ìyàlẹ́nu mi, nǹkan bí 20 àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà níbi ìgbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ ni ó wà ní gbọ̀ngàn tí a ti ń dúró de dókítà. Wọ́n mú kí n nímọ̀lára ìtùnú àti ìfẹ́, tí ó jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá ní irú àkókò àìláyọ̀ lílé kenkà bẹ́ẹ̀. Ní nǹkan bí ìṣẹ́jú 15 lẹ́yìn náà, dókítà kán wá, ó sì ṣàlàyé pé: ‘Ó ti ṣeé ṣe fún wa láti mú dádì rẹ sọ jí, ṣùgbọ́n ó ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà líle koko kan. Kò dá wa lójú pé yóò yè é.’

“Ó yọ̀ǹda fún mi láti rí Dádì fún àkókò díẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ fún ìdílé wa tí Dádì ń sọ mú mi pòrúurùu. Pẹ̀lú ìrora ńlá, ó sọ pé: ‘Ọmọkùnrin, mo fẹ́ràn rẹ. Máa rántí nígbà gbogbo pé Jèhófà ni ẹni tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Má ṣe ṣíwọ́ sísìn ín nígbà kankan, kí o sì ran màmá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ lọ́wọ́ láti má ṣe ṣíwọ́ sísìn ín. A nírètí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú àjíǹde, bí mo bá sì kú, o wù mí láti tún rí gbogbo yín nígbà tí mo bá tún padà wá.’ Àwa méjèèjì ń sun ẹkún ìfẹ́, ìbẹ̀rù, àti ìrètí.”

Ní wákàtí kan lẹ́yìn náà, Mary, ìyàwó John, dé. “Nígbà tí mo wọ iyàrá ìtọ́jú pàjáwìrì, dókítà náà wí pé: ‘Ọkọ rẹ ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà líle koko.’ Ó fò mí láyà. Ó ṣàlàyé pé wọ́n ti mú ìlùkìkì ọkàn-àyà John wà déédéé nígbà mẹ́jọ. Ìgbésẹ̀ pàjáwìrì yìí níí ṣe pẹ̀lú lílo ìwọ̀n agbára mànàmáná láti fi dá ìlùkìkì ségesège ọkàn-àyà dúró, kí a sì mú ìṣedéédéé rẹ̀ padà bọ̀ sí bí ó ṣe yẹ kí ó rí. Láfikún sí ìlànà ìmọ́kànsọjí, fífúnni ní afẹ́fẹ́ oxygen, àti gígún abẹ́rẹ́ fúnni, ìlànà ìmúbọ̀sípò ìlùkìkì ọkàn-àyà jẹ́ ìlànà ìgbẹ̀mílà gíga kan.

“Nígbà tí mo rí John, làásìgbò bá ọkàn-àyà mi. Àwọ̀ ara rẹ̀ ti ṣì gan-an, àwọn túùbù àti wáyà tí wọ́n fi so ara rẹ̀ mọ́ àwọn gọgọwú ẹ̀rọ́ pọ̀ jìgàngàn. Ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, mo gbàdúrà sí Jèhófà láti fún mi lókun láti fàyà rán ìdánwò yìí nítorí àwọn ọmọkùnrin wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, mo sì gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó lọ́gbọ́n nínú nípa ohunkóhun tí ó bá wà níwájú. Bí mo ti ń sún mọ́ bẹ́ẹ̀dì John, mo ronú pé, ‘Kí lènìyán lè sọ fún olólùfẹ́ rẹ̀ ní irú àkókò bí èyí? Ǹjẹ́ a ti múra sílẹ̀ fún irú ipò tí ń wu ìwàláàyè léwu bẹ́ẹ̀ bí?’

“John wí pé: ‘Olùfẹ́, o mọ̀ pé mo lè má la èyí já. Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì pé kí ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyẹ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà, nítorí pé láìpẹ́, ètò ìgbékalẹ̀ yìí yóò dópin, kì yóò sì sí àìsàn àti ikú mọ́. Ó wù mí láti jí dìde nínú ètò ìgbékalẹ̀ tuntun yẹn, kí n sì rí ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin wa níbẹ̀.’ Omijé ṣàn lójú wa.”

Dókítà Ṣàlàyé

“Lẹ́yìn náà ni dókítà pè mí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tí ó sì ṣàlàyé pé àyẹ̀wò fi hàn pé ìdípa bámúbámú inú òpó ẹ̀jẹ̀ tí ó wálẹ̀ níwájú ọkàn-àyà John ló fa ìkọlù àrùn ọkàn-àyà rẹ̀. Òpó ẹ̀jẹ̀ míràn tún dí. Dókítà náà sọ fún mi pé mo gbọ́dọ̀ ṣèpinnu kan nípa ìtọ́jú John. Méjì lára àwọn oríṣi ìtọ́jú tí a lè yàn ni ìtọ́jú elégbòogi tàbí fífi rọ́bà tẹ́ẹ́rẹ́ pààrọ̀ iṣan ẹ̀jẹ̀. Ó lérò pé èyí tí a sọ kẹ́yìn yẹn yóò sàn jù, nítorí náà, a fara mọ́ fífi rọ́bà tẹ́ẹ́rẹ́ pààrọ̀ iṣan ẹ̀jẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n àwọn dókítà náà kò ṣe ìlérí ìfojúsọ́nà fún rere kankan, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n ti ní irú ìkọlù àrùn ọkàn-àyà bí èyí kì í là á já.”

Fífi rọ́bà tẹ́ẹ́rẹ́ pààrọ̀ iṣan ẹ̀jẹ̀ jẹ́ ọ̀nà iṣẹ́ abẹ kan nínú èyí tí a máa ń ki ìhùmọ̀ catheter kan, tí góńgó rẹ̀ ṣeé fẹ́ afẹ́fẹ́ sí, kí ó sì wú, sínú òpó ẹ̀jẹ̀, tí a óò sì fẹ́ afẹ́fẹ́ sí i láti ṣí ibi tí àlàfo náà ti dí. Ìlànà yìí ń kẹ́sẹ járí gan-an ní dídá ìṣànkiri ẹ̀jẹ̀ padà sípò. Bí ó bá jẹ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òpó ẹ̀jẹ̀ ni ó dí gan-an, iṣẹ́ abẹ tí ń lo òpó ẹ̀jẹ̀ àtọwọ́dá ni a sábà máa ń dámọ̀ràn rẹ̀.

Ìrètí Ìkọ́fẹpadà Kò Dán Mọ́rán

Lẹ́yìn fífi rọ́bà tẹ́ẹ́rẹ́ pààrọ̀ iṣan ẹ̀jẹ̀ náà, ìwàláàyè John wà nínú ewu síbẹ̀ fún wákàtí 72. Níkẹyìn, ọkàn-àyà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́fẹ padà láti inú hílàhílo náà. Ṣùgbọ́n ọkàn-àyà John ń tú ẹ̀jẹ̀ jáde ní ìwọ̀n ìdajì péré sí bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, apá púpọ̀ lára ọkàn-àyà náà sì ti di ojú àpá lásán nítorí náà, ìrètí pé ọkàn-àyà rẹ̀ yóò rọ fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.

Ní bíbojú wo àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, John gbani nímọ̀ràn pé: “A wà lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe níwájú Ẹlẹ́dàá wa, ìdílé wa, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí, àti àwa fúnra wa, láti ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ tí ara wá bá ń fún wa, kí a sì tọ́jú ìlera wa—ní pàtàkì, bí a bá wà nínú ewu. Títí dé àyè gbígbòòrò kan, a lè jẹ́ orísun ìdùnnú tàbí ẹ̀dùn ọkàn. Ó kù sọ́wọ́ wa.”

Ọ̀ràn John le koko, ó sì nílò àfiyèsí ojú ẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ẹni tí ó bá ti ní àìfararọ tí ó jọ ìjóni nínú ọkàn-àyà ni ó ní láti sáré tọ dókítà lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ìrírí rẹ̀ jẹ́ ìkìlọ̀ kan, ó sì yẹ kí àwọn tí ó bá rò pé àwọ́n ní àwọn àmì àrún lọ fún àyẹ̀wò.

Kí ni a lè ṣe láti dín ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà kù? Àpilẹ̀kọ tí ó kàn yóò jíròrò lórí èyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí padà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Àmì Àrùn Ọkàn-Àyà

• Ìmọ̀lára pákáǹleke, ìfúnpọ̀, tàbí ìrora nínú àyà, tí kì í fara rọ, tí ó sì ń pẹ́ ju ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ. A lè ṣì í mú fún ìjóni líle koko kan nínú ọkàn-àyà

• Ìrora tí ó lè tàn ká dé—tàbí kí ó wà ní kìkì—párì, ọrùn, èjìká, apá, ìgúnpá, tàbí ọwọ́ òsì

• Ìrora wíwà pẹ́ títí ní apá òkè ikùn

• Èémí tí kì í délẹ̀, òòyì, dídákú, ìlàágùn, tàbí ìmọ̀lára ojora nígbà tí ọwọ́ bá kanni

• Ìtánlókun—ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ṣáájú àrùn náà

• Ìrìndọ̀ tàbí èébì

• Ìkọlù àrùn ìrora òjijì líle koko tí ń wá lemọ́lemọ́, tí kì í ṣe ìlokunra ló fà á

Àwọn àmì àrún lè yàtọ̀ síra láti orí àwọn tí kò le dé orí àwọn tí ó le, gbogbo wọn kì í sì í ṣẹlẹ̀ pa pọ̀ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ọkàn-àyà. Ṣùgbọ́n, bí àpapọ̀ èyíkéyìí nínú àwọn wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀, yára gba ìrànlọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kán máa ń wà tí kì í sí àmì àrùn kankan; ìwọ̀nyí ni a ń pè ní àrùn ọkàn-àyà ayọ́kẹ́lẹ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Ìgbésẹ̀ fún Wíwà Láàyè Nìṣó

Bí ìwọ tàbí ẹnì kan tí o mọ̀ bá ní àmì àrùn ọkàn-àyà:

• Dá àmì àrùn náà mọ̀.

• Ṣíwọ́ lára ohunkóhun tí o bá ń ṣe lọ́wọ́, kí o sì jókòó tàbí kí o dùbúlẹ̀.

• Bí àmì àrùn kò bá lọ láàárín ìwọ̀n ìṣẹ́jú mélòó kan, tẹ àwọn òṣìṣẹ́ ìtọ́jú pàjáwìrì àdúgbò láago. Sọ fún ayárajíṣẹ́ náà pé ará fu ọ́ pé o ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, kí o sì fún un ní gbogbo ìsọfúnni tí ó wúlò láti wá ọ rí.

• Bí o bá lè wakọ̀ fúnra rẹ, kí o sì yára gbé aláìsàn náà dé iyàrá ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn kan, ṣe bẹ́ẹ̀. Bí o bá rò pé o ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, rọ ẹnì kan láti wà ọ́ lọ síbẹ̀.

Bí ẹ bá ń dúró de agbo òṣìṣẹ́ ìṣègùn pàjáwìrì:

• Dẹ aṣọ tí ó fún pinpin, títí kan ìgbànú tàbí táì ọrùn. Ran aláìsàn náà lọ́wọ́ láti ní ìrọra, kí o fi ìrọ̀rí rọ̀ ọ́ lára bí ó bá pọn dandan.

• Fọkàn balẹ̀, ì báà jẹ́ ìwọ ni àrùn náà kọ lù tàbí ẹni tí ń ṣèrànlọ́wọ́. Ìrùmọ̀lára sókè lè mú kí àìṣedéédéé ìlùkìkì ọkàn-àyà tí ń wu ìwàláàyè léwu ṣẹlẹ̀. Àdúrà lè jẹ́ àrànṣe kan tí ń fúnni lókun láti fọkàn balẹ̀.

Bí ó bá jọ pé ẹni tí àrùn kọ lù náà kò mí mọ́:

• Pẹ̀lú ohùn tí ó ròkè gan-an, béèrè pé, “Ǹjẹ́ o ń gbọ́ mi?” Bí kò bá sí ìdáhùn, tí aláìsàn náà kò sì mí, bẹ̀rẹ̀ ìlànà ìmọ́kànsọjí (CPR).

• Rántí àwọn ìgbésẹ̀ ìpìlẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ìlànà ìmọ́kànsọjí:

1. Gbé àgbọ̀n aláìsàn náà sókè, kí ọ̀nà afẹ́fẹ́ lè ṣí sílẹ̀.

2. Pẹ̀lú bí o ṣe ṣí ọ̀nà afẹ́fẹ́ náà sílẹ̀, tí o sì fi ọwọ́ tẹ ihò imú aláìsàn náà pọ̀ pinpin, rọra fẹ́ afẹ́fẹ́ lẹ́ẹ̀mejì sí ẹnu rẹ̀, títí tí àyà rẹ̀ yóò fi wú sókè.

3. Tẹ àárín àyà náà ní agbede méjì orí ọmú méjèèjì ní ìgbà 10 sí 15 láti ti ẹ̀jẹ̀ jáde kúrò ní ọkàn-àyà àti àyà. Láàárín gbogbo ìṣẹ́jú àáyá 15, mí èémí méjì sí i nínú, kí o sì tẹ̀ ẹ́ ní ìgbà 15 títí ìlùkìkì àti èémí yóò fi padà bọ̀ sípò tàbí tí agbo olùtọ́jú pàjáwìrì yóò fi dé.

  Ẹnì kan tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlànà ìmọ́kànsọjí ni kí ó ṣe é. Àmọ́, bí kò bá sí ẹni tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ lárọ̀ọ́wọ́tó, Dókítà R. Cummins, olùdarí ibùdó ìtọ́jú àrùn ọkàn-àyà ní pàjáwìrì sọ pé, “ìlànà ìmọ́kànsọjí èyíkéyìí sàn ju àìsí rárá lọ.” Láìjẹ́ pé ẹnì kán dáwọ́ lé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí, ṣíṣeéṣe láti là á já kéré gan-an. Ìlànà ìmọ́kànsọjí ń so ẹ̀mí aláìsàn náà ró de ẹni tí yóò tọ́jú rẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìtọ́jú kánmọ́kánmọ́ lẹ́yìn ìkọlù àrùn ọkàn-àyà lè gba ẹ̀mí là, kí ó sì dín ìbàjẹ́ ọkàn-àyà kù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́