ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/8 ojú ìwé 3-4
  • Àrùn Ọkàn-Àyà—Ewu Kan fún Ìwàláàyè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àrùn Ọkàn-Àyà—Ewu Kan fún Ìwàláàyè
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni A Ṣe Lè Dín Ewu Náà Kù?
    Jí!—1996
  • Dídá Àwọn Àmì Àrùn Mọ̀ àti Ṣíṣiṣẹ́ Lé Wọn Lórí
    Jí!—1996
  • O Lè Yẹra fún Àrùn Ọkàn Nípa Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ní Ọkàn-àyà Tó Tẹ́ Jèhófà Lọ́rùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Jí!—1996
g96 12/8 ojú ìwé 3-4

Àrùn Ọkàn-Àyà—Ewu Kan fún Ìwàláàyè

NÍ ỌDÚN kọ̀ọ̀kan, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin káàkiri àgbáyé ń ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń yí i dá pẹ̀lú kìkì àwọn àbájáde àtẹ̀yìnyọ díẹ̀. Àwọn kan kì í là á já. Ní ti àwọn mìíràn, gẹ́gẹ́ bí Peter Cohn, onímọ̀ ìṣiṣẹ́ àti àrùn ọkàn-àyà, ṣe wí, ọkàn-àyà náà ti ń bà jẹ́ jù, tí “pípadà sí àwọn ìgbòkègbodò wíwúlò fi mú iyè méjì lọ́wọ́,” ó fi kún un pé: “Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì kí a ṣètọ́jú àwọn àmì àrùn ọkàn-àyà lọ́gán tí wọ́n bá ti yọjú, nígbàkigbà tí ó bá ti ṣeé ṣe.”

Ọkàn-àyá jẹ́ ìṣùpọ̀ ẹran ara tí ń tú ẹ̀jẹ̀ jáde sí gbogbo ara. Nígbà tí ẹnì kán bá ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà (ìdíwọ́ ìṣànkiri ẹ̀jẹ̀ nínú ìpele ìṣùpọ̀ ẹran ara àárín ọkàn-àyà), apá kan ìṣùpọ̀ ẹran ara ọkàn-àyà ń kú nígbà tí ẹ̀jẹ̀ kò bá ṣàn débẹ̀. Láti máa ní ìlera nìṣó, ọkàn-àyá nílò afẹ́fẹ́ oxygen àti àwọn èròjà aṣaralóore mìíràn tí ẹ̀jẹ̀ ń gbé kiri. Ó ń rí ìwọ̀nyí gbà nípasẹ̀ àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ tí ó lọ́ yí po ní ara ọkàn-àyà.

Àwọn àrún lè mú apá èyíkéyìí lára ọkàn-àyà. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ni àrùn tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣe ọṣẹ́ nínú àwọn òpó ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n ń pè ní atherosclerosis [ìkójọpọ̀ ọ̀rá sínú iṣan ẹ̀jẹ̀]. Bí èyí bá ṣẹlẹ̀, kókó kan, tàbí ìgbárajọ ọ̀rá, máa ń wà nínú awọ tí ó bo òpó ẹ̀jẹ̀. Bí ó bá ṣe ń pẹ́ sí i ni kókó náà lè máa tóbi sí i, kí ó le, kí ó sì sọ àlàfo àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ náà di tóóró, kí ó sì ṣe ìdíwọ́ fún bí ẹ̀jẹ́ ṣe ń ṣàn lọ sínú ọkàn-àyà. Àrùn ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ inú àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ yìí (CAD) ní ń yọrí sí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìkọlù àrùn ọkàn-àyà.

Ìdíwọ́ inú òpó ẹ̀jẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni ó máa ń fa ìkọlù àrùn nígbà tí afẹ́fẹ́ oxygen tí ọkàn-àyà ń rí gbà bá kéré sí èyí tí ó nílò. Nínú àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ tí àlàfo wọn kò dí púpọ̀ pàápàá, kókó yìí lè fọ́, kí ó sì di ìdìpọ̀ ẹ̀jẹ̀ (thrombus). Ó tún túbọ̀ rọrùn fún àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n bá ní àrùn láti lọ́ pọ̀ mọ́ra lójijì. Ẹ̀jẹ́ lè dì pọ̀ ní ọ̀gangan ibi tí iṣu ẹran ará bá ti lọ́ pọ̀ lójijì, kí ó sì tú kẹ́míkà kan tí ń mú kí awọ tí ó bo òpó ẹ̀jẹ́ fún pọ̀, tí ó sì ń tanná ran àrùn.

Bí afẹ́fẹ́ oxygen kò bá wọ inú ìṣùpọ̀ ẹran ara ọkàn-àyà fún àkókò gígùn tó, àwọn ẹran ara tí ó wà nítòsí lè bà jẹ́. Láìdà bí àwọn ẹran ara mélòó kan, ìṣùpọ̀ ẹran ara ọkàn-àyà kì í jẹ bò. Bí àrùn náà bá ṣe ń pẹ́ tó, ni ìbàjẹ́ tí ó ń ṣe fún ọkàn-àyà yóò máa pọ̀ sí i tó, bẹ́ẹ̀ sì ni ikú ń sún mọ́ tó. Bí ìgbékalẹ̀ amúnáwá ọkàn-àyá bá bà jẹ́, ìṣedéédéé ìlùkìkì ọkàn-àyá lè dà rú, ọkàn-àyá sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ (kí ó máa yára sún kì lọ́nà tí kò ṣe déédéé láìsí ìbáramu láàárín ìlùkìkì àti ìtújáde). Nígbà tí irú àìṣedéédéé ìlùkìkì ọkàn-àyà bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, agbára ọkàn-àyà láti máa tú ẹ̀jẹ̀ lọ sí ọpọlọ bí ó ti yẹ máa ń kùnà. Láàárín ìṣẹ́jú mẹ́wàá, ọpọlọ yóò kú, ikú dé nìyẹn.

Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀ ìṣègùn tètè dá sí i níbẹ̀rẹ̀. Ó lè gba ọkàn-àyà náà sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdíbàjẹ́ tí ń tẹ̀ síwájú, kí ó dènà àìṣedéédéé ìlùkìkì ọkàn-àyà náà tàbí kí ó ṣètọ́jú rẹ̀, kí ó sì gba ẹ̀mí ènìyàn là pẹ̀lú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́