Báwo Ni A Ṣe Lè Dín Ewu Náà Kù?
Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ kókó abájọ ti apilẹ̀ àbùdá, ti àyíká ibi tí a ń gbé, àti ti ọ̀nà tí a ń gbà gbé ìgbésí ayé ni ó rọ̀ mọ́ àrùn inú òpó ẹ̀jẹ̀ (CAD). Àwọn ewu tí ó rọ̀ mọ́ ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn kókó abájọ wọ̀nyí lè yọrí sí àrùn inú òpó ẹ̀jẹ̀ àti ìkọlù àrùn ọkàn-àyà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tàbí ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún pàápàá.
Ọjọ́ Orí, Ẹ̀yà, àti Àjogúnbá
Bí a ṣe ń dàgbà sí i ni ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà ń pọ̀ sí i. Nǹkan bí ìpín 55 nínú ọgọ́rùn-ún ìkọlù àrùn ọkàn-àyà ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn tí ọjọ́ orí wọ́n lé ní ọdún 65. Nǹkan bí ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ìkọlù àrùn ọkàn-àyà ń pa jẹ́ ọmọ ọdún 65 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn ọkùnrin tí kò tí ì pé ọmọ 50 ọdún dojú kọ ewu ju àwọn obìnrin ọlọ́jọ́ orí kan náà lọ. Lẹ́yìn ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù, ewu náà ń pọ̀ sí i fún obìnrin nítorí bí omi ìsúnniṣe estrogen tí ń dáàbò bo ará ṣe ń lọ sílẹ̀ gidigidi. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdíyelé kan ṣe fi hàn, ìtọ́jú àfirọ́pò omi ìsúnniṣe estrogen lè dín ewu àrùn ọkàn-àyà láàárín àwọn obìnrin kù ní ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó ṣeé ṣe kí ewu àwọn àrùn jẹjẹrẹ kán pọ̀ sí i.
Àjogúnbá lè kó ipa pàtàkì kan. Ewu ìkọlù náà pọ̀ sí i fún àwọn tí àwọn òbí wọ́n bá ní ìkọlù kí wọ́n tóó pé 50 ọdún. Àní bí àwọn òbí bá ní in lẹ́yìn tí wọ́n ti lé ní 50 ọdún pàápàá, ewu náà pọ̀ sí i. Nígbà tí ìṣòro ọkàn-àyà bá ti wà nínú ìtàn ìdílé kan, ó túbọ̀ ṣeé ṣe kí àwọn àtọmọdọ́mọ wọ́n ní irú ìṣòro kan náà.
Kókó Abájọ ti Èròjà Cholesterol
Èròjà cholesterol, tí ó jẹ́ oríṣi èròjà lipid kan, ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè. Ẹ̀dọ̀ki ní ń ṣẹ̀dá rẹ̀, ẹ̀jẹ́ sì ń gbé e lọ sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ní ìwọ̀n èérún tí a ń pè ní lipoprotein. Oríṣi lipoprotein méjì ni lipoprotein oníwọ̀n ìwúwo kékeré (LDL cholesterol) àti lipoprotein oníwọ̀n ìwúwo ńlá (HDL cholesterol). Èròjà cholesterol máa ń di kókó abájọ tí ń fa àrùn inú òpó ẹ̀jẹ̀ nígbà tí àpọ̀jù LDL cholesterol bá kóra jọ sínú ẹ̀jẹ̀.
A lérò pé HDL ń kó ipa ìdáàbòboni kan nípa kíkó èròjà cholesterol kúrò nínú àwọn iṣu ẹran ara àti kíkó o padà sínú ẹ̀dọ̀ki, níbi tí ó ti ń yí padà, tí a sì ń kó o kúrò nínú ara. Bí LDL bá pọ̀ nínú ara, tí HDL sì kéré, ewu àrùn ọkàn-àyà pọ̀ gan-an. Dídín ìwọ̀n LDL inú ara kù lè yọrí sí dídín ewu náà kù lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìyípadà oúnjẹ ṣe pàtàkì gan-an nínú ọ̀nà ìtọ́jú, eré ìmáralé sì lè ṣèrànwọ́. Onírúurú egbòogí lè mú àṣeyọrí wá, ṣùgbọ́n àwọn kán ní àwọn àbájáde tí kò bára dé.a
Àwọn kán dámọ̀ràn oúnjẹ tí èròjà cholesterol rẹ̀ kò pọ̀, ṣùgbọ́n tí ó ní ìwọ̀n ìpín oúnjẹ tí a ń pè ní fats púpọ̀ nínú. Fífi àwọn oúnjẹ tí kò ní ọ̀pọ̀ fats nínú, irú bí òróró canola tàbí òróró ólífì, rọ́pò àwọn tí ó ní ọ̀pọ̀ fats nínú, irú bíi bọ́tà, lè dín LDL kù, kí ó sì dín ìfiṣòfò HDL kù. Ní ìdà kejì, ìwé àtìgbàdégbà náà, American Journal of Public Health, sọ pé àwọn òróró ẹ̀fọ́ tí ó ní gáàsì hydrogen púpọ̀, àti àwọn tí ó ní gáàsì hydrogen níwọ̀nba tí a máa ń rí nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ohun àṣemújáde tí ń dín margarine àti ẹ̀fọ́ kù lè sọ LDL di púpọ̀, kí ó sì dín HDL kù. Àwọn kán tún dámọ̀ràn dídín jíjẹ ẹran ọlọ́ràá púpọ̀ kù, àti fífi àwọn apá tí kò lọ́ràá púpọ̀ lára adìyẹ tàbí tòlótòló rọ́pò.
Ìwádìí ti fi hàn pé fitami E, èròjà beta-carotene, àti fitami C lè dín ìṣẹ̀lẹ̀ ìkójọpọ̀ ọ̀rá sínú iṣan ẹ̀jẹ̀ kù nínú àwọn ẹranko. Ìwádìí kán parí èrò sí pé wọ́n tún lè dín ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù àrùn ọkàn-àyà kù nínú àwọn ènìyàn. Jíjẹ àwọn ẹ̀fọ́ àti èso tí ó ní ọ̀pọ̀ èròjà beta-carotene àti àwọn èròjà carotenoid míràn àti fitami C nínú, irú bíi tòmátì, àwọn ẹ̀fọ́ eléwé tútù yọ̀yọ̀, onírúurú ata, kárọ́ọ̀tì, ọ̀dùnkún, àti ẹ̀gúsí, lè pèsè ààbò lọ́wọ́ àrùn CAD.
Àwọn ohun mìíràn tí a tún gbọ́ pé ó ṣàǹfààní ni fitami B6 àti èròjà magnesium. Àwọn odindi ọkà bí ọkà báálì àti oat pa pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀wà, lentil, àti àwọn kóró èso igí àti ẹ̀pà kán lè wúlò. Ní àfikún sí i, a lérò pé jíjẹ àwọn irú ẹja bíi salmon, mọ́ńkẹ̀rẹ̀, herring, tàbí tuna lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀, ó kéré tán, lè dín ewu àrùn CAD kù, níwọ̀n bí wọ́n ti ní àwọn èròjà ásíìdì omega-3 ọlọ́ràá nínú.
Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Ìjókòósójúkan
Ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà túbọ̀ pọ̀ sí i fún àwọn ènìyàn tí ń jókòó sójú kan. Wọ́n ń lo àkókò púpọ̀ jù lọ lójúmọ́ láìṣe nǹkan kan, wọn kì í sì í ṣe eré ìmárale déédéé. Ìkọlù àrùn ọkàn-àyà sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe àwọn iṣẹ́ agbára bí àtúnṣe ọgbà, sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́, gbígbé nǹkan wíwúwo, tàbí kíkó omi dídì dà nù, lọ́nà tí ó gba agbára. Ṣùgbọ́n ewu náà má ń dín kù láàárín àwọn tí ń ṣe eré ìmárale déédéé.
Ìrìn kánmọ́kánmọ́ láàárín 20 ìṣẹ́jú sí 30 ìṣẹ́jú nígbà mẹ́ta tàbí mẹ́rin lọ́sẹ̀ ń dín ewu ìkọlù kù. Ṣíṣe eré ìmárale déédéé ń mú kí ọkàn-àyà túbọ̀ lágbára sí i láti tú ẹ̀jẹ̀ jáde, ó ń dín ìwọ̀n ìwúwo kù, ó sì lè dín ìpele èròjà cholesterol àti ìwọ̀n ìfúnpá kù.
Ẹ̀jẹ̀ Ríru, Ìwúwo Jù, àti Àtọ̀gbẹ
Ìwọ̀n ìfúnpá gíga (ẹ̀jẹ̀ ríru) lè pa awọ òpó ẹ̀jẹ̀ lára, kí ó sì jẹ́ kí èròjà LDL cholesterol wọnú ìtẹ́nú òpó ẹ̀jẹ̀ náà, kí ó sì gbé ìkórajọ kókó lárugẹ. Bí kókó ṣe ń kóra jọ sí i ni ìdíwọ́ ń wà fún ṣíṣàn ẹ̀jẹ̀, tí ìwọ̀n ìfúnpá sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ga sí i.
Ó yẹ kí a máa yẹ ìwọ̀n ìfúnpá wò déédéé, níwọ̀n bí ó ti ṣeé ṣe kí ó máà sí àmì tí ó ṣeé fojú rí kan tí a óò fi mọ̀ pé ìṣòró wà. Fún ìlọsílẹ̀ ìwọ̀n kọ̀ọ̀kan nínú ìwọ̀n ìgbòòrò ọkàn-àyà láti gba ẹ̀jẹ̀ wọlé (nọ́ḿbà ìsàlẹ̀ ìwọ̀n ìfúnpá), ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà lè fi ìpín 2 sí 3 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù. Lílo egbòogi láti dín ìwọ̀n ìfúnpá kù lè gbéṣẹ́. Ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ, àti nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan, pípààlà sí ìwọ̀n iyọ̀ tí a ń jẹ, pa pọ̀ pẹ̀lú ṣíṣe eré ìmárale déédéé láti dín ìwọ̀n ìwúwo kù lè ṣèrànwọ́ láti kápá ìwọ̀n ìfúnpá gíga.
Ìwúwo jù máa ń dá kún ìwọ̀n ìfúnpá gíga àti àìṣedéédéé èròjà lipid. Yíyẹra fún ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ tàbí gbígbàtọ́jú nítorí rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan láti ṣèdènà àtọ̀gbẹ. Àtọ̀gbẹ máa ń mú kí àrùn CAD pọ̀ sí i, ó sì ń ṣàléékún ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà.
Sìgá Mímu
Sìgá mímu jẹ́ kókó abájọ lílágbára kan nínú ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn CAD. Ní tààrà, òun ló ń fa nǹkan bí ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn tí àrùn ọkàn-àyà ń pa àti iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún ìkọlù àrùn ọkàn-àyà tí ń ṣe àwọn obìnrin tí ọjọ́ orí wọn kò tó ọdún 55 ní United States. Sìgá mímu ń mú kí ìwọ̀n ìfúnpá lọ sókè, ó sì ń fa àwọn kẹ́míkà onímájèlé, bíi nicotine àti carbon monoxide, sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, àwọn kẹ́míkà wọ̀nyí ń ba àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ jẹ́.
Àwọn tí ń mu sìgá tún ń fi àwọn tí ń fa èéfín sìgá wọn símú sínú ewu. Ìwádìí fi hàn pé àwọn aláìmusìgá tí ń bá àwọn amusìgá gbé túbọ̀ dojú kọ ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà púpọ̀ sí i. Nítorí èyí, nípa ṣíṣíwọ́ sìgá mímu, ẹnì kán lè dín ewu ti ara rẹ̀ kù, ó sì lè dáàbò bo ìwàláàyè àwọn olólùfẹ́ tí kì í mu sìgá.
Másùnmáwo
Nígbà tí wọ́n bá wà lábẹ́ másùnmáwo ti èrò orí tàbí ti èrò ìmọ̀lára, àwọn tí wọ́n ní àrùn CAD túbọ̀ dojú kọ ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà gíga àti ikú òjijì tí ìkọlù àrùn ọkàn-àyà ń fà. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kán ṣe fi hàn, másùnmáwo lè mú kí àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ tí ó ní kókó súnra kì, ìwọ̀n tí èyí sì fi ń dín ìṣàn ẹ̀jẹ̀ kù pọ̀ tó ìpín 27 nínú ọgọ́rùn-ún. A ṣàkíyèsí ìsúnrakì gbígbàfiyèsí nínú àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ tí àrún wà ní fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Ìwádìí mìíràn dábàá pé másùnmáwo líle kokó lè pèsè àyíká tí ó lè fọ́ kókó inú awọ òpó ẹ̀jẹ̀, kí ó sì tanná ran ìkọlù àrùn ọkàn-àyà.
Ìwé ìròyìn Consumer Reports on Health sọ pé: “Ó jọ pé àwọn ènìyàn kan ń gbé ìgbésí ayé pẹ̀lú ìṣarasíhùwà tí kò dára. Wọn kì í gbára lé ènìyàn, wọ́n máa ń bínú, a sì lè tètè mú wọn bínú. Nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyán máa ń gbójú fo àwọn ìmúnibínú pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, àwọn ènìyàn tí kò níwà bí ọ̀rẹ́ máa ń hùwà padà lọ́nà líle ju bí ó ti yẹ lọ.” Ìbínú fùfù àti ìkóguntini tí ó ti di bárakú máa ń mú kí ìwọ̀n ìfúnpá lọ sókè, ó ń mú kí iye ìlùkìkì ọkàn-àyà pọ̀ sí i, ó sì ń sún ẹ̀dọ̀ki láti da èròjà cholesterol sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀. Èyí máa ń ba àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ jẹ́, ó sì ń ṣàlékún àrùn CAD. A lérò pé ìbínú máa ń sọ ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà di ìlọ́po méjì, tí èyí sì máa ń jẹ́ ewu ojú ẹsẹ̀ fún wákàtí méjì, ó kéré tán. Kí ni ó lè ṣèrànwọ́?
Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ṣe wí, Dókítà Murray Mittleman sọ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń gbìyànjú láti fọkàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nígbà ìdàrú èrò ìmọ̀lára lè dín ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà wọn kù. Èyí jọ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú Bíbélì ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn pé: “Àyà tí ó yè korokoro ni ìyè ara.”—Òwe 14:30.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ ohun tí wíwà lábẹ́ másùnmáwo túmọ̀ sí. Ó sọ nípa àwọn àníyàn tí ń rọ́ wọlé tọ̀ ọ́ lójoojúmọ́. (Kọ́ríńtì Kejì 11:24-28) Ṣùgbọ́n ó rí ìrànwọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.
Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn kókó abájọ mìíràn tún wà tí ó tan mọ́ àwọn ìṣòro ọkàn-àyà, àwọn tí a jíròrò níbí lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti dá ewu mọ̀, kí ó lè gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn kán ti ṣe kàyéfì lórí bí nǹkán ṣe ń rí fún àwọn tí wọ́n ní láti máa mú àtúbọ̀tán ìkọlù àrùn ọkàn-àyà mọ́ra. Báwo ni ìkọ́fẹpadà ṣe lè ṣeé ṣe tó?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jí! kò fọwọ́ sí àwọn ìtọ́jú ìṣègùn, eré ìmárale, tàbí ìyípadà oúnjẹ, ṣùgbọ́n ó ń fúnni ní ìsọfúnni tí a ti ṣèwádìí lé lórí kínníkínní. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni ó ní láti pinnu ohun tí òun fúnra rẹ̀ yóò ṣe.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Sìgá mímu, yíyára bínú, jíjẹ àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá, àti gbígbé ìgbésí ayé ìjókòósójúkan ń ṣàlékún ewu ìkọlù àrùn ọkàn-àyà