ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/8 ojú ìwé 11-13
  • Ọ̀nà Láti Kọ́fẹ Padà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Láti Kọ́fẹ Padà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìkọ́fẹpadà
  • Kò Sí Ọkàn-Àyà Tí Ń Dá Wà
  • Àwọn Ìdílé Nílò Ìtìlẹ́yìn
  • Dídá Àwọn Àmì Àrùn Mọ̀ àti Ṣíṣiṣẹ́ Lé Wọn Lórí
    Jí!—1996
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìjọ Kristẹni—Orísun Àrànṣe Afúnnilókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 12/8 ojú ìwé 11-13

Ọ̀nà Láti Kọ́fẹ Padà

KÉTÉ lẹ́yìn ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, ènìyán sábà máa ń ní ìbẹ̀rù àti àníyàn. Ṣé n óò tún ní ìkọlù míràn? N óò ha di aláàbọ̀ ara tàbí ẹni tí ìrorá pààlà sí ohun tí ó lè ṣe, kí n sì pàdánù okun àti agbára bí?

John, tí a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ wa kejì, retí pé bí àkókò bá ṣe ń kọjá, ìnira àti ìrora inú àyà lójoojúmọ́ yóò dín kù. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn oṣù mélòó kan, ó sọ pé: “Títí di báyìí, wọn kò tí ì dín kù. Ìyẹn, pa pọ̀ pẹ̀lú títètè káàárẹ̀, àti ọkàn-àyà mi tí ń ṣe gulegule ń mú kí n máa bi ara mi léèrè léraléra pé, ‘Àbí mo tún fẹ́ẹ́ ní ìkọlù míràn ni?’”

Jane, láti United States, tí ó jẹ́ opó kan tí kò tí ì dàgbà púpọ̀ nígbà tí ó ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, jẹ́wọ́ pé: “Mo rò pé n kò níí là á já tàbí pé n óò ní ìkọlù míràn, n óò sì kú. Ojorá bẹ̀rẹ̀ sí í mú mi, nítorí mo ní àwọn ọmọ mẹ́ta láti bójú tó.”

Hiroshi, láti Japan, ròyìn pé: “Ó mú mi gbọ̀n rìrì láti gbọ́ pé ọkàn-àyà mi kò lè máa ṣiṣẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́; ìwọ̀n ìtújáde rẹ̀ ti fi ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dá mi lójú tán pé n óò ní láti dín àwọn ìgbòkègbodò mi gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kù, nítorí pé n kò lè ṣe tó ìdajì ohun tí mo ń ṣe tẹ́lẹ̀.”

Nígbà tí ẹnì kán bá ní okun tí kò tó nǹkan, àwọn àkókò ìsoríkọ́ àti ìmọ̀lára àìwúlò lè máa yọjú. Marie, ẹni ọdún 83 tí ó jẹ́ ará Australia, tí ó fi ara rẹ̀ jin iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kédàárò pé: “Ó bà mí nínú jẹ́ pé n kò lè ṣe tó bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Kàkà kí n máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, mo nílò ìrànlọ́wọ́ nísinsìnyí.” Ní Gúúsù Áfíríkà, Harold sọ pé: “N kò lè ṣiṣẹ́ fún oṣù mẹ́ta. Gbogbo ohun tí mo lè ṣe nígbà náà kò ju kí n rìn yí ká ọgbà lọ. Ìyẹn ń jáni kulẹ̀!”

Lẹ́yìn tí Thomas, láti Australia, ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà lẹ́ẹ̀kejì, ó di dandan kí ó ṣe iṣẹ́ abẹ tí ń lo òpó ẹ̀jẹ̀ àtọwọ́dá. Ó wí pé: “N kì í rára gba ìrora sí, ó sì ṣòro fún mi láti ronú pé mo lè ṣe iṣẹ́ abẹ tí ó le.” Jorge, láti Brazil, sọ̀rọ̀ nípa àtúbọ̀tán iṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà pé: “Nítorí ipò àìní mi, ẹ̀rú bà mí pé n óò fi ìyàwó mi sílẹ̀ ní òun nìkan àti láìsí ìrànlọ́wọ́. Mo rò pé n kò lè pẹ́ láyé mọ́.”

Ìkọ́fẹpadà

Kí ló ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti kọ́fẹ padà, kí èrò ìmọ̀lára wọ́n sì padà bọ̀ sípò? Jane ṣàkíyèsí pé: “Nígbà tí ojorá bá mú mi, mo sábà máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, tí mo sì ń kó àwọn ẹrù ìnira mi lé e, tí n óò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀.” (Orin Dáfídì 55:22) Àdúrà máa ń ranni lọ́wọ́ láti jèrè okun àti ìbàlẹ̀ ọkàn-àyà tí ó ṣe kókó nígbà tí a bá ń kojú hílàhílo.—Fílípì 4:6, 7.

John àti Hiroshi kópa nínú àwọn ìṣètò ìmúpadàbọ̀sípò. Jíjẹ oúnjẹ dídára àti ṣíṣe eré ìmárale fún ọkàn-àyà wọn lókun tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn méjèèjí tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́. Wọ́n sì sọ pé agbára ìgbéniró tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ó mú kí àwọ́n lè kọ́fẹ padà ní ti èrò orí àti èrò ìmọ̀lára.

Nípasẹ̀ ìtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀, Thomas rí ìgboyà tí ó nílò láti kojú iṣẹ́ abẹ rẹ̀. Ó wí pé: “Ṣáájú iṣẹ́ abẹ náà, alábòójútó kan wáá bẹ̀ mí wò, ó sì gbàdúrà pẹ̀lú mi. Pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ onímọ̀lára jíjinlẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà fún mi lókun. Ní òru yẹn, mo pa ọkàn pọ̀ sórí àdúrà tí ó gbà, mo sì nímọ̀lára pé a bù kún mi gan-an láti ní irú àwọn alàgbà bíi tirẹ̀, tí ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò wọn ní àwọn àkókò tí ìmọ̀lára ń ru sókè jẹ́ apá kan ọ̀nà ìmúláradá náà fúnra rẹ̀.”

Anna, láti Ítálì, kojú ìsoríkọ́ ní ọ̀nà yìí: “Nígbà tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì, mo máa ń ronú lórí gbogbo ìbùkún tí mo ti rí gbà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ìbùkún tí ń bọ̀ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Èyí ń ràn mí lọ́wọ́ láti padà jèrè ìparọ́rọ́ ọkàn-àyà.”

Marie ṣọpẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Ìdílé rẹ̀ ti tì í lẹ́yìn, ó sì wí pé: “Àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi nípa tẹ̀mí, pẹ̀lú ẹrù ara ẹni tí olúkúlùkú ní láti rù, wá àkókò láti bẹ̀ mí wò, láti tẹ̀ mí láago, tàbí láti fi káàdì ránṣẹ́. Báwo ni inú mi ṣe lè bà jẹ́ pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ tí a fi hàn yìí?”

Kò Sí Ọkàn-Àyà Tí Ń Dá Wà

Wọ́n ti máa ń sọ pé ọkàn-àyà tí ń san kò gbọ́dọ̀ dá wà. Ìtìlẹ́yìn ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ ń kópa pàtàkì, tí ó sì gbòòrò, nínú ìkọ́fẹpadà àwọn tí ọkàn-àyà wọn ní láti san ní ti gidi àti lọ́nà àfiṣàjúwe.

Michael, láti Gúúsù Áfíríkà, sọ pé: “Ó ṣòro láti ṣàlàyé ohun tí níní ìjákulẹ̀ jọ fún àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá wọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba, àníyàn tí àwọn ará ń fi hàn ń mú ọkàn mi yọ̀, ó sì ń gbé mi ró.” Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti ìmòye tí ìjọ rẹ̀ fi hàn sí Henry, láti Australia, fún òun pẹ̀lú lókun. Ó wí pé: “Mo nílò àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ wọ̀nyẹn ní ti gidi.”

Jorge mọrírì bí àníyàn tí àwọn ẹlòmíràn fi hàn, nípa fífún ìdílé rẹ̀ ní owó títí tí ó fi lè máa ṣiṣẹ́, ṣe jinlẹ̀ tó. Bákan náà ni Olga, láti Sweden, mọrírì ìrànlọ́wọ́ gbígbéṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí ṣe fún òun àti ìdílé rẹ̀. Àwọn kán lọ bá a ra ọjà, nígbà tí àwọn mìíràn bá a túnlé ṣe.

Nígbà púpọ̀, àwọn alárùn ọkàn-àyá ní láti pààlà sí bí wọn yóò ṣe máa lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tí wọ́n ti yàn láàyò tẹ́lẹ̀ tó. Sven, láti Sweden, sọ pé: “Nígbà míràn, mo ní láti ta kété sí kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà tí afẹ́fẹ́ bá le jù tàbí tí òtútù bá gba ojú ọjọ́ níwọ̀n bí ó ti máa ń súnná sí ìsúnkì iṣan ara. Mo mọrírì ẹ̀mí ìmòye tí púpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mí fi hàn nínú ọ̀ràn yìí.” Nígbà tí kò sì lè dìde kúrò lórí ibùsùn, Sven lè tẹ́tí sí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé nítorí pé àwọn ará fi tìfẹ́tìfẹ́ gbà wọ́n sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì. “Wọ́n ń fi àwọn ohun tí ń lọ nínú ìjọ tó mi létí, ó sì ń mú kí n nímọ̀lára bíi pé mo jẹ́ olùkópa nínú wọn.”

Bí àwọn tí Marie, tí kò lè dìde kúrò lórí ibùsùn, ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ mú kí ó nímọ̀lára pé a bù kún òun. Lọ́nà yìí, ó ṣeé ṣe fún un láti máa jíròrò ọjọ́ iwájú àgbàyanu tí ó ń fojú sọ́nà fún nìṣó. Thomas dúpẹ́ fún àníyàn tí a fi hàn sí i pé: “Àwọn alàgbà ti jẹ́ olùgbatẹnirò gan-an, wọ́n sì ti dín iye àwọn iṣẹ́ àyànfúnni tí wọ́n ń fún mi kù.”

Àwọn Ìdílé Nílò Ìtìlẹ́yìn

Ọ̀nà náà lè ṣòro fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé bí ó ti ṣòro fún aláìsàn náà gan-an. Wọ́n bọ́ sábẹ́ másùnmáwo àti ìbẹ̀rù gígọntiọ. Nígbà tí Alfred, láti Gúúsù Áfíríkà, ń sọ̀rọ̀ nípa ìdàníyàn ìyàwó rẹ̀, ó sọ pé: “Nígbà tí mo ti ilé ìwòsàn dé, ìyàwó mi máa ń jí mi níye ìgbà láàárín òru láti mọ̀ bóyá ara mí ṣì le síbẹ̀, ó sì máa ń fòòté lé e pé kí n lọ rí dókítà fún àyẹ̀wò lóṣù mẹ́tamẹ́ta.”

Òwe 12:25 sọ pé ‘ìbìnújẹ́ ní àyà ènìyàn níí dorí rẹ̀ kọ odò.’ Carlo, láti Ítálì, sọ pé, láti ìgbà tí òún ti ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà ni ìyàwó òun onífẹ̀ẹ́ àti alátìlẹ́yìn “ti ní ìsoríkọ́.” Lawrence, láti Australia, sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tí o ní láti pàfiyèsí sí ni kí ẹnì kejì rẹ ní àbójútó. Ó lè nípa lórí ẹnì kejì náà gidigidi.” Nípa bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa fi àìní gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìdílé sọ́kàn, títí kan àwọn ọmọdé. Ipò náà lè nípa lórí wọn ní ti èrò ìmọ̀lára àti ní ti ara ìyára.

James, tí a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ wa kejì kì í túra ká mọ́, lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ ti ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà. Ó wí pé: “Mo rò pé n kò lè ní ìmóríyá kankan mọ́, nítorí mo rò pé gbàrà tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, ohun búburú kan yóò ṣẹlẹ̀.” Sísọ ohun tí ń bà á lẹ́rù fún bàbá rẹ̀ àti sísapá láti ṣàgbékalẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ dídán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ràn án lọ́wọ́ láti lé ìdààmú ọkàn rẹ̀ jáde. James ṣe ohun mìíràn kan tí ó nípa gidigidi lórí ìgbésí ayé rẹ̀ láàárín àkókò náà. Ó wí pé: “Mo fi kún ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi àti ìmúrasílẹ̀ mi fún àwọn ìpàdé Kristẹni wa.” Ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣàfihàn rẹ̀ nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Ó wí pé: “Láti ìgbà yẹn ni mo ti mú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Jèhófà. Mo ní ohun púpọ̀, tí mo ní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ní ti gidi.”

Lẹ́yìn ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, ènìyán ní àkókò láti ṣàtúnyẹ̀wò ìgbésí ayé. Fún àpẹẹrẹ, ojú ìwòye John yí padà. Ó sọ pé: “O rí i bí àwọn ìlépa ayé ṣe jẹ́ asán tó, o sì mọ bí ìfẹ́ ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ ṣe ṣe pàtàkì tó, àti bí a ti já mọ́ nǹkan tó lójú Jèhófà. Ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà, ìdílé mi, àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi nípa tẹ̀mí wáá wà ní ipò àkọ́kọ́ nísinsìnyí.” Nígbà tí ó ń ronú sẹ́yìn nípa hílàhílo ìrírí rẹ̀, ó fi kún un pé: “N kò lè ronú bí mo ṣe lè kojú ipò yìí láìsí ìrètí tí a ní pé àkókò kan ń bọ̀ tí àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò ní àtúnṣe. Nígbà tí mo bá ní ìsoríkọ́, mo ń ronú lórí ọjọ́ ọ̀la, àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí sì ń di aláìjámọ́ǹkan.”

Bí wọ́n ṣe ń nírìírí kòtò àti gegele ojú ọ̀nà sí ìkọ́fẹpadà, àwọn tí ó la ìkọlù àrùn ọkàn-àyà já wọ̀nyí fìdí ìrètí wọn múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ìjọba tí Jésù Kristi kọ́ wa láti máa gbàdúrà fún. (Mátíù 6:9, 10) Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìyè àìnípẹ̀kun nínú ìjẹ́pípé wá fún ẹ̀dá ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà náà ni a óò mú àrùn ọkàn-àyà àti gbogbo àbùkù ara kúrò láéláé. Ayé tuntun náà kò jìnnà mọ́ rárá. Ní tòótọ́, ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ kò tí ì dé!—Jóòbù 33:25; Aísáyà 35:5, 6; Ìṣípayá 21:3-5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìtìlẹ́yìn ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ ń kópa pàtàkì nínú ìkọ́fẹpadà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́