ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 5/15 ojú ìwé 25-28
  • Ìjọ Kristẹni—Orísun Àrànṣe Afúnnilókun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjọ Kristẹni—Orísun Àrànṣe Afúnnilókun
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtìlẹ́yìn àti Ìrànlọ́wọ́
  • Ìrànwọ́ Láti Ọwọ́ Àwọn Alábòójútó Onífẹ̀ẹ́
  • Ìrànwọ́ Tòótọ́ ní Àkókò Yíyẹ
  • Ọgbọ́n Láti Òkè
  • Ẹ Máa Fún Ara Yín Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Kí a Gbé Ìjọ Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Ìjọ Máa Yin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Rí Ààbò Láàárín Àwọn Ènìyàn Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 5/15 ojú ìwé 25-28

Ìjọ Kristẹni—Orísun Àrànṣe Afúnnilókun

ÌBÀNÚJẸ́ bá Popi, ọmọbìnrin kan tó lé díẹ̀ lógún ọdún nítorí ìṣòro ìdílé tó jẹ yọ látàrí àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán láàárín òun àtàwọn òbí rẹ̀.a Lẹ́yìn tó ti sọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀ jáde fún Kristẹni alàgbà kan àti aya rẹ̀, ó kọ̀wé sí wọn pé: “Ẹ ṣeun púpọ̀ fún yíyọ̀ǹda àkókò yín láti bá mi sọ̀rọ̀. Ẹ kò mọ bí mo ti mọrírì rẹ̀ tó pé ẹ bìkítà nípa mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi léèyàn bíi tiyín ti mó gbára lé, tí mo sì lè fọ̀ràn lọ̀.”

Toula, opó kan tí kò tí ì pẹ́ tí ọkọ rẹ̀ kú, tó sì láwọn ọmọ méjì tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́langba, bá ara rẹ̀ nínú ìdààmú burúkú àti ìṣòro ọ̀ràn ìnáwó. Tọkọtaya Kristẹni kan tí wọ́n wà nínú ìjọ tóbìnrin náà ń dara pọ̀ mọ́ máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ obìnrin náà àtàwọn ọmọ rẹ̀ déédéé, èyí sì máa ń fún wọn lókun. Lẹ́yìn tó ti borí ìṣòro rẹ̀, ó fi káàdì kan ránṣẹ́ sí wọn, káàdì náà kà pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń rántí yín nínú àdúrà mi. Mo máa ń rántí àìmọye ìgbà tẹ́ẹ ṣaájò mi, tẹ́ẹ sì ràn mí lọ́wọ́.”

Nígbà mìíràn, ǹjẹ́ o máa ń nímọ̀lára pé wàhálà ayé tí ń pọ̀ sí i “di ẹrù wọ̀ [ẹ́] lọ́rùn]”? (Mátíù 11:28) Ǹjẹ́ “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ti fa ìbànújẹ́ sínú ìgbésí ayé ẹ? (Oníwàásù 9:11) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ ni irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí. Ṣùgbọ́n bó ṣe jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wàhálà bá ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà nínú ìjọ Kristẹni ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìwọ pẹ̀lú lè rí irú ìrànwọ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ gbà. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé lọ́nà tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ òun kan jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fóun. (Kólósè 4:10, 11) Ìwọ pẹ̀lú lè ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀.

Ìtìlẹ́yìn àti Ìrànlọ́wọ́

Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìjọ” láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, ek·kle·siʹa, èyí tó túmọ̀ sí àwùjọ ènìyàn tí a pè jọ. Àwọn èrò tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ yẹn ni ẹ̀mí ìṣọ̀kan àti ìranra-ẹni-lọ́wọ́.

Ìjọ Kristẹni tòótọ́ máa ń gbé òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lárugẹ, ó sì máa ń polongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. (1 Tímótì 3:15; 1 Pétérù 2:9) Láfikún sí i, ìjọ tún ń pèsè ìtìlẹ́yìn àti ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí fún àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ọn. Nínú ìjọ, ẹnì kan lè rí àwùjọ àwọn ọ̀rẹ́ tó fẹ́ràn ẹni, àwọn tó bìkítà nípa ẹni, àwọn tí ń gba tẹni rò, àwọn tó fẹ́, tó sì múra tán láti ṣèrànwọ́, kí wọ́n sì tuni nínú nígbà másùnmáwo.—2 Kọ́ríńtì 7:5-7.

Ìgbà gbogbo ni àwọn olùjọsìn Jèhófà máa ń rí ààbò àti ìbàlẹ̀-ọkàn nínú ìjọ rẹ̀. Onísáàmù náà fi hàn pé òun ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀-ọkàn nínú ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run. (Sáàmù 27:4, 5; 55:14; 122:1) Bákan náà lónìí, ìjọ Kristẹni jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn onígbàgbọ́ kan náà tí wọ́n ń gbé ara wọn ró, tí wọ́n sì ń fún ara wọn níṣìírí.—Òwe 13:20; Róòmù 1:11, 12.

A ń kọ́ àwọn mẹ́ńbà ìjọ láti “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá [wọn] tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Ẹ̀kọ́ tí a gbé ka Bíbélì tí wọ́n ń kọ́ ń sún wọn láti fi ìfẹ́ ará àti ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí ara wọn lẹ́nì kìíní kejì. (Róòmù 12:10; 1 Pétérù 3:8) A ń sún àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí nínú ìjọ láti jẹ́ onínúure, ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ẹni tí ń fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn. (Éfésù 4:3) Kàkà tí wọn á kàn jẹ́ ẹni tí ń ṣèjọ́sìn ojú ayé lásán, wọ́n ń fi ìfẹ́ alánìíyàn hàn sí àwọn ẹlòmíràn.—Jákọ́bù 1:27.

Nítorí náà, nínú ìjọ, àwọn táa ni lára máa ń rí àyíká onífẹ̀ẹ́ tó jọ ti inú ìdílé. (Máàkù 10:29, 30) Ìmọ̀lára pé wọ́n jẹ́ apá kan àwùjọ kan tí ohun kan so wọ́n pọ̀ tímọ́tímọ́, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn ń fún wọn lókun. (Sáàmù 133:1-3) Nípasẹ̀ ìjọ, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—Mátíù 24:45.

Ìrànwọ́ Láti Ọwọ́ Àwọn Alábòójútó Onífẹ̀ẹ́

Àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni lè retí pé kí àwọn rí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tí wọ́n ń gba tẹni rò, tí wọ́n sì tóótun, tí wọ́n lè pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí nípa tẹ̀mí. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ní irú ànímọ́ bẹ́ẹ̀ dà bí “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Aísáyà 32:1, 2) Àwọn alàgbà tàbí alábòójútó tí a fẹ̀mí yàn ni wọ́n ń tọ́jú àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ẹni bí àgùntàn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn aláìsàn àti àwọn tó sorí kọ́ níṣìírí, àwọn ni wọ́n sì ń wọ́nà àtimú àwọn tó ṣìnà padà bọ̀ sípò.—Sáàmù 100:3; 1 Pétérù 5:2, 3.

Àmọ́ ṣá o, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà nínú ìjọ kì í ṣe àjọ àwọn òṣìṣẹ́ afọ̀rọ̀wonisàn tàbí oníṣègùn, tó lè wo àrùn ara tàbí ti ọpọlọ tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn bá dojú kọ sàn. Nínú ètò àwọn nǹkan yìí, àwọn tí ń ṣàmódi ṣì “nílò oníṣègùn.” (Lúùkù 5:31) Síbẹ̀síbẹ̀, irú àwọn olùṣọ́ àgùntàn bẹ́ẹ̀ lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n nílò ìrànwọ́ tẹ̀mí. (Jákọ́bù 5:14, 15) Nígbà tó bá ṣeé ṣe, àwọn alàgbà tún máa ń ṣètò fún àwọn ìrànwọ́ mìíràn.—Jákọ́bù 2:15, 16.

Ta ló mú kí irú ìṣètò onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ wáyé? Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni! Wòlíì Ìsíkíẹ́lì fi Jèhófà hàn pé ó ń polongo pé: “Èmi yóò sì wá àwọn àgùntàn mi, èmi yóò sì bójú tó wọn dájúdájú. . . . Ṣe ni èmi yóò dá wọn nídè kúrò ní gbogbo ibi tí a tú wọn ká sí . . . Èmi alára yóò bọ́ àwọn àgùntàn mi, èmi alára yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀.” Ọlọ́run pàápàá bìkítà nípa àwọn ahẹrẹpẹ àgùntàn tàbí àwọn tí kò ṣe ṣámúṣámú.—Ìsíkíẹ́lì 34:11, 12, 15, 16.

Ìrànwọ́ Tòótọ́ ní Àkókò Yíyẹ

Ṣé lóòótọ́ ni ìrànwọ́ tòótọ́ wà nínú ìjọ Kristẹni? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ṣàkàwé onírúurú ipò tí ìjọ ti lè pèsè ìrànwọ́.

◆ Nígbà tí olólùfẹ́ ẹni bá kú. Ọkọ Anna kú lẹ́yìn àìsàn kan tó ti ń bá a jà fún ìgbà pípẹ́. Obìnrin náà wí pé: “Látìgbà yẹn ni mo ti ń rí ìfẹ́ ọlọ́yàyà gbà ṣáá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ará mi. Ọ̀rọ̀ onínúure tó ń tẹnu àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ mi jáde àti ìṣírí tí wọ́n ń fún mi, títí kan gbígbá mi mọ́ra tọ̀yàyà-tọ̀yàyà, ti mú kí n má ṣe rẹ̀wẹ̀sì, kí n má sì ṣe kárí sọ, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi ti jẹ́ kí n mọ̀ pé mo lẹ́ni lẹ́yìn, pé wọ́n ti mú kí ìmọ̀lára mi sunwọ̀n sí i gidigidi, pé wọ́n sì ti bójú tó mi lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.” Irú jàǹbá bẹ́ẹ̀, kí olólùfẹ́ ẹni kú ti lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Nínú irú àkókò bẹ́ẹ̀, àwọn mẹ́ńbà ìjọ lè pèsè ìtùnú àti ìtìlẹ́yìn tí a nílò.

◆ Àìsàn. Arthur, alábòójútó arìnrìn-àjò kan láti Poland, máa ń ṣèbẹ̀wò déédéé sí àwọn ìjọ tó wà ní Àárín Gbùngbùn Éṣíà láti lè fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Nígbà kan tó lọ bẹ ìjọ kan wò, ni àìsàn kì í mọ́lẹ̀, kì í sì í ṣe nǹkan díẹ̀ lójú rẹ̀ rí kí ara rẹ̀ tó yá. Pẹ̀lú ìmọrírì tó jinlẹ̀, Arthur rántí pé: “Mo fẹ́ sọ fún yín bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú [ìlú kan ní Kazakhstan] ṣe tọ́jú mi. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin, tí n kò tiẹ̀ mọ púpọ̀ nínú wọn rí—àtàwọn olùfìfẹ́hàn pàápàá—wọ́n mówó wá, wọ́n ru oúnjẹ wá, wọ́n mú oògùn wá. . . . Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì fi ṣe é.

“Wo bí ìmọ̀lára mi ti rí nígbà tí mo gba àpòòwé kan tí owó díẹ̀ wà nínú rẹ̀ àti lẹ́tà tó tẹ̀ lé e yìí: ‘Arákùnrin Ọ̀wọ́n, ẹ kú déédéé ìwòyí o. Màámi ló fún mi lówó yìí pé kí n fi mu áísìkirimù, ṣùgbọ́n mo pinnu pé ẹ̀yin ni n óò fún kẹ́ẹ fi roògùn. Ẹ dákun ẹ tètè dára yá o. Jèhófà nílò wa fún àkókò pípẹ́. Àjíǹde ara yóò máa jẹ́ o. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá sọ àwọn ìtàn tó dùn, tó dùn, tó gbámúṣé fún wa o. Vova.’” Bẹ́ẹ̀ ni, bó ṣe rí nínú ọ̀ràn yìí, tọmọdé tàgbà nínú ìjọ ló lè pèsè àrànṣe afúnnilókun ní àkókò àìsàn.—Fílípì 2:25-29.

◆ Ìsoríkọ́. Ó wu Teri látọkànwá láti ṣe aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn ni olùpòkìkí Ìjọba náà lákòókò kíkún. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ìṣòro kan, ó pọndandan pé kó fi ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀. Ọ̀dọ́mọbìnrin náà wí pé: “Ọkàn mi gbọgbẹ́ gidigidi pé n kò tilẹ̀ lè sìn tó ọdún kan nínú ipò yẹn. Èrò òdì tí Teri ní ni pé bí ohun tí òun ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bá ṣe pọ̀ tó ni yóò pinnu bóyá yóò tẹ́wọ́ gba òun. (Fi wé Máàkù 12:41-44.) Inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an, ló bá bẹ̀rẹ̀ sì dá nǹkan tirẹ̀ ṣe. Ṣùgbọ́n ìrànwọ́ tó tura wá látọ̀dọ̀ ìjọ.

Teri rántí pé: “Arábìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà ṣàdédé tọ̀ mí wá láti ràn mí lọ́wọ́, ó tẹ́tí sí mi bí mo ti ń sọ ohun ti ń ṣe mí fún un. Nígbà tí mo kúrò nílé rẹ̀, ṣe ló dà bí ẹni pé wọ́n ti gbé ẹrù wíwúwo kan kúrò lórí mi. Láti ìgbà yẹn, arábìnrin aṣáájú ọ̀nà yìí àti ọkọ rẹ̀, tí òun náà jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, ti pèsè ìrànlọ́wọ́ tó ṣeyebíye fún mi. Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń fóònù mi láti béèrè bí mo ti ń ṣe sí. . . . Wọ́n ti gbà kí ń báwọn jókòó nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn lọ́pọ̀ ìgbà, èyí sì ti tẹ ìjẹ́pàtàkì kí ìdílé wà papọ̀ mọ́ mi lọ́kàn.”

Kò ṣàjèjì rárá fún ọ̀pọ̀ èèyàn—kódà àwọn Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ pàápàá—láti sorí kọ́, láti rẹ̀wẹ̀sì, àti láti nímọ̀lára pé àwọn dá wà. Ẹ wo bí a ti kún fún ìmoore tó pé ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́, tí kò lẹ́mìí ìmọtara-ẹni-nìkan nínú wà nínú ìjọ Ọlọ́run!—1 Tẹsalóníkà 5:14.

◆ Àjálù àti Jàǹbá. Fi ara rẹ sípò ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́rin tí wọ́n pàdánù gbogbo ohun ìní wọn nígbà tí ilé wọn jóná kanlẹ̀. Kò pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n ní ohun tí wọ́n pè ní “ìrírí afúnni níṣìírí tí a óò máa ronú lé lórí títi ayérayé, tó sì tẹ ìfẹ́ tòótọ́ tó wà láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà mọ́ wa lọ́kàn.” Wọ́n ṣàlàyé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lójú ẹsẹ̀ ni ìrànlọ́wọ́ àti àánú tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí fi hàn ti wú wa lórí gidigidi. Fóònù kì í yéé dún. Ojúlówó àníyàn àti ìfẹ́ tí olúkúlùkù fi hàn wú wa lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí omijé ìmoore fi dà lójú wa.”

Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn alàgbà ìjọ ti ṣètò àwùjọ àwọn arákùnrin, láàárín ọjọ́ díẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ ilé tuntun fún ìdílé yìí. Aládùúgbò wọn fi ìyàlẹ́nu sọ pé: “Ìròyìn ò tó àfojúbà! Onírúurú èèyàn ló ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀—ọkùnrin, obìnrin, àwọn aláwọ̀ dúdú, aláwọ̀ funfun pàápàá ń bẹ níbẹ̀!” Èyí fi hàn kedere pé ìfẹ́ ará ń bẹ láàárín wọn.—Jòhánù 13:35.

Àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tún fún ìdílé yìí ní aṣọ, oúnjẹ, àti owó. Baba náà sọ pé: “Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà Kérésìmesì tí ẹni gbogbo ń rí ẹ̀bùn gbà, ṣùgbọ́n a lè sọ láìṣàbòsí pé kò sí ẹni tó rí ojúlówó ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó fani mọ́ra tó bẹ́ẹ̀ gbà tó wa.” Wọ́n sì fi kún un pé: “A ti ń gbàgbé jàǹbá iná náà, a sì ti ń fi àwọn ìrántí tí a lè ṣìkẹ́, ti inú rere àti ọ̀rẹ́ àtàtà rọ́pò rẹ̀. Ọpẹ́ wa lọ sọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, Jèhófà, fún níní irú ìdílé àgbàyanu, ìdílé tó wà níṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, inú wa sì dùn gan-an pé a jẹ́ apá kan rẹ̀!”

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ibi tí wàhálà bá ti ṣẹlẹ̀ ló ti ṣée ṣe láti dá sí ọ̀ràn náà, tàbí la ti lè retí irú ohun táa ṣe yẹn. Ṣùgbọ́n ohun tí àpẹẹrẹ yìí wulẹ̀ ń ṣàkàwé ni ìtìlẹyìn tí ìjọ lè pèsè.

Ọgbọ́n Láti Òkè

Ọ̀pọ̀ ti rí orísun ìrànwọ́ àti okun mìíràn nínú ìjọ Kristẹni. Kí ni orísun yẹn? Àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè ni. Àwọn tó lókìkí jù lọ lára wọn ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Láti lè pèsè ìmọ̀ràn tó kún fún ìjìnlẹ̀ òye àti ìtọ́ni tó gbéṣẹ́, àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí gbára lé ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. (Sáàmù 119:105) A máa ń fi àwọn ìwádìí tó ṣeé gbára lé, táa fàṣẹ tì lẹ́yìn kún àwọn ìsọfúnni inú Ìwé Mímọ́ lórí àwọn kókó ẹ̀kọ́ bí ìsoríkọ́, báa ṣe lè bọ́ nínú ìdààmú ìwà ìkà táa ti hù síwa rí, onírúurú ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ti ọrọ̀ ajé, àwọn ìpèníjà táwọn èwe ń dojú kọ, àti àwọn ìṣòro tó jẹ́ ti àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nìkan. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ń gbé ọ̀nà Ọlọ́run lárugẹ pé òun ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ.—Aísáyà 30:20, 21.

Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lẹ́tà ìmọrírì ni Watch Tower Society ń rí gbà. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní Rọ́ṣíà kọ̀wé nípa àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Jí! tó sọ̀rọ̀ lórí pípa ara ẹni, ó ní: “Nítorí ìsoríkọ́ tó dé bá mi, . . . ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti gbèrò àtipa ara mi. Àpilẹ̀kọ yìí fún ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Ọlọ́run láti bá mi yanjú àwọn ìṣòro mi lókun. Ó fẹ́ kí n wà láàyè. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ tó ṣe fún mi nípasẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.”

Bí ìjì ayé yìí bá le tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi dà bíi pé kò sọ́nà àbájáde, mọ̀ dájú pé ibi ààbò wà nínú ìjọ Kristẹni. Ní tòótọ́, bí ètò ìsinsìnyí ẹlẹ́mìí ìkórìíra tí gbogbo rẹ̀ gbẹ táútáú yìí bá ń gba agbára rẹ, o lè rí ibi ìtura tí ń fúnni lókun nínú ètò àjọ Jèhófà. Lẹ́yìn tí o bá ti gbádùn irú ìtìlẹyìn tí Kristẹni obìnrin kan tó kojú àìsàn tó dá ọkọ̀ rẹ̀ wólẹ̀ gbádùn, o lè sọ ohun tí obìnrin náà kọ síwèé pé: “Nítorí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí wa àti bí wọ́n ṣe tọ́jú wa, ṣe ló dà bí pé Jèhófà gbé wa sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ títí táa fi la wàhálà náà já. Mo dúpẹ́ púpọ̀ pé mo jẹ́ apá kan ètò àjọ Jèhófà tó kọyọyọ!”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti pa àwọn orúkọ wọ̀nyí dà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

A lè fún àwọn tí ń ṣàìsàn, àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀, àtàwọn mìíràn ní àrànṣe afúnnilókun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́