ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 5/1 ojú ìwé 18-22
  • Ẹ Máa Fún Ara Yín Lókun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Fún Ara Yín Lókun
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Àrànṣe Afúnnilókun”
  • Ìdí Tí Pọ́ọ̀lù Fi Nílò “Àrànṣe Afúnnilókun”
  • Bí A Ṣe Lè Jẹ́ “Àrànṣe Afúnnilókun”
  • Bí Ìjọ Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
  • Jèhófà —Orísun Okun Tó Ga Jù Lọ
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Rìn Lọ́nà Tó Yẹ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìjọ Kristẹni—Orísun Àrànṣe Afúnnilókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Jèhófà Ń fi Agbára Fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Kòṣeémáàní Làwa Kristẹni Jẹ́ Fún Ara Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 5/1 ojú ìwé 18-22

Ẹ Máa Fún Ara Yín Lókun

“Àwọn wọ̀nyí gan-an sì ti di àrànṣe afúnnilókun fún mi.”—KÓLÓSÈ 4:11.

1, 2. Kí nìdí tí àwọn ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù fi ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láìfi ewu tó lè tibẹ̀ jáde pè?

TÍ Ọ̀RẸ́ rẹ bá wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ipò tó lèwu ni ìwọ alára wà, àní bí ọ̀rẹ́ rẹ yìí ò bá tiẹ̀ mọwọ́mẹsẹ̀. Nítorí pé tó o bá lọ síbẹ̀, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n lè máa fura sí ọ, kí wọ́n máa ṣọ́ ẹ tọwọ́tẹsẹ̀ nítorí wọ́n lè rò pé o fẹ́ wá ṣe jàǹbá. Nítorí náà, àtilọ máa yọjú sí ọ̀rẹ́ rẹ tó wà lẹ́wọ̀n yìí déédéé á gba ìgboyà gan-an ni.

2 Síbẹ̀, ohun táwọn ọ̀rẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nìyẹn ní nǹkan bí ẹgbàá dín lọ́gọ́rùn-ún [1, 900] ọdún sẹ́yìn. Wọn ò lọ́tìkọ̀ láti lọ bá Pọ́ọ̀lù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, láti sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ọ̀rọ̀ ìṣírí fún un àti láti fún un lókùn nípa tẹ̀mí. Àwọn wo ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó dúró tì í yìí? Ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ onígboyà, adúróṣinṣin àti ẹni bí ọ̀rẹ́?—Òwe 17:17.

“Àrànṣe Afúnnilókun”

3, 4. (a) Àwọn márùn-ún wo ni Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí ni wọ́n sì jẹ́ fún un? (b) Kí ni “àrànṣe afúnnilókun” jẹ́?

3 Ẹ jẹ́ ká padà wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 60 Sànmánì Tiwa. Wọ́n sọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù lórí ẹ̀sùn èké pé ó ṣọ̀tẹ̀ síjọba. (Ìṣe 24:5; 25:11, 12) Pọ́ọ̀lù dárúkọ àwọn Kristẹni márùn-ún tó dúró tì í, àwọn ni: Tíkíkù tó wà láti àgbègbè Éṣíà, ó jẹ́ aṣojú rẹ̀ àti “ẹrú ẹlẹgbẹ́ [rẹ̀] nínú Olúwa”; Ónẹ́símù “olùṣòtítọ́ àti olùfẹ́ ọ̀wọ́n” láti Kólósè; Àrísítákọ́sì ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà, lákòókò kan ó jẹ́ “òǹdè ẹlẹgbẹ́” Pọ́ọ̀lù; Máàkù mọ̀lẹ́bí Bánábà tí òun àti Pọ́ọ̀lù jọ ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, tó sì tún kọ Ìwé Ìhìn Rere tá a fi orúkọ rẹ̀ pè; àti Jọ́sítù, ọ̀kan lára àwọn tó ń bá àpọ́sítélì yìí ṣiṣẹ́ “fún ìjọba Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn márààrún rèé, ó ní: “Àwọn wọ̀nyí gan-an sì ti di àrànṣe afúnnilókun fún mi.”—Kólósè 4:7-11.

4 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ tó lágbára nípa ìrànlọ́wọ́ táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin wọ̀nyí ṣe fún un. Ó lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà (pa·re·go·riʹa) tó túmọ̀ sí “àrànṣe afúnnilókun,” ẹsẹ yìí nìkan ṣoṣo sì ni ọ̀rọ̀ náà wà nínú Bíbélì. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà gbòòrò, wọ́n ń lò ó ní pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ ìṣègùn.a Ọ̀rọ̀ náà lè túmọ̀ sí ‘ìtùnú, dídín ìrora kù, tàbí ìtura.’ Irú okun bẹ́ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù nílò, àwọn ọkùnrin márùn-ún wọ̀nyẹn sì fún un.

Ìdí Tí Pọ́ọ̀lù Fi Nílò “Àrànṣe Afúnnilókun”

5. Láìka jíjẹ́ tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpọ́sítélì sí, kí ni ó nílò, kí sì ni gbogbo wa nílò látìgbàdégbà?

5 Ó lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn kan pé Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ àpọ́sítélì tún nílò okun. Bẹ́ẹ̀ ni o, ó nílò rẹ̀. Òótọ́ ni pé Pọ́ọ̀lù ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó sì ti bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, “lílù dé ìwọ̀n tí ó pọ̀ lápọ̀jù,” “bèbè ikú ní ọ̀pọ̀ ìgbà” àtàwọn ìrora mìíràn. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27) Síbẹ̀, ẹlẹ́ran ara lòun náà àti pé gbogbo wa la nílò ìtùnú nígbà mìíràn, gbogbo wa la sì tún nílò káwọn ẹlòmíràn ràn wa lọ́wọ́ láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Bó ṣe rí fún Jésù náà nìyẹn. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilé ayé, áńgẹ́lì kan yọ sí i ní ọgbà Gẹtisémánì, “ó sì fún un lókun.”—Lúùkù 22:43.

6, 7. (a) Àwọn wo ló já Pọ́ọ̀lù kulẹ̀ nígbà tó wà ní Róòmù, àwọn wo ló sì fún un níṣìírí? (b) Kí làwọn Kristẹni arákùnrin Pọ́ọ̀lù ṣe láti ràn án lọ́wọ́ ní Róòmù, tó mú wọn di “àrànṣe afúnnilókun”?

6 Pọ́ọ̀lù náà nílò okun. Nígbà tó dé Róòmù gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹ̀lú rẹ̀ kò tẹ́wọ́ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Èyí tó sì pọ̀ jù lára àwọn Júù ni kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn táwọn sàràkí-sàràkí láàárín àwọn Júù lọ bẹ Pọ́ọ̀lù wo ní àhámọ́ tó wà, ìwé Ìṣe sọ pé: “Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ohun tí ó sọ gbọ́; àwọn mìíràn kò sì gbà gbọ́. Nítorí náà, nítorí pé wọ́n wà ní àìfohùnṣọ̀kan pẹ̀lú ara wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ.” (Ìṣe 28:17, 24, 25) Ó mà dun Pọ́ọ̀lù gan-an o pé àwọn èèyàn náà ò mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wọn! Bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ̀ hàn nínú lẹ́tà tó kọ sí ìjọ tó wà ní Róòmù ní ọdún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, ó sọ pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn ńláǹlà àti ìrora tí kò dẹ́kun nínú ọkàn-àyà mi. Nítorí èmi ì bá fẹ́ pé kí a ya èmi fúnra mi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni ègún kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn arákùnrin mi [àwọn Júù], àwọn ìbátan mi lọ́nà ti ẹran ara.” (Róòmù 9:2, 3) Síbẹ̀, nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Róòmù, ó rí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó jẹ́ adúróṣinṣin, tí ìgboyà àti ìfẹ́ tí wọ́n ní múnú rẹ̀ dùn. Arákùnrin gidi ni wọ́n jẹ́ fún un nípa tẹ̀mí.

7 Báwo làwọn arákùnrin márùn-ún wọ̀nyẹn ṣe jẹ́ àrànṣe afúnnilókun? Wọn ò tìtorí pé Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n kí wọ́n wá sá fún un. Dípò ìyẹn, tinútinú àti tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n fi bá Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn iṣẹ́ kan, wọ́n bá a ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò lè ṣe nítorí àhámọ́ tó wà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣe ìránṣẹ́ fún Pọ́ọ̀lù, wọ́n bá a mú lẹ́tà lọ sí onírúurú ìjọ, wọ́n tún fẹnu jíṣẹ́ tó ràn wọn fáwọn ìjọ náà; wọ́n sì tún mú ìròyìn tí ń gbéni ró nípa ipò táwọn ará ní Róòmù àti láwọn ibòmíràn wà wá fún Pọ́ọ̀lù. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n bá Pọ́ọ̀lù wá àwọn ohun èlò kan tó pọndandan, bíi ẹ̀wù òtútù, àkájọ ìwé àtàwọn ohun èlò ìkọ̀wé. (Éfésù 6:21, 22; 2 Tímótì 4:11-13) Gbogbo irú nǹkan tí wọ́n ṣe yẹn ló fún àpọ́sítélì tó wà lẹ́wọ̀n yìí lókun, ó sì tún jẹ́ ìṣírí fún un débi pé òun náà jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fáwọn ẹlòmíràn àti fún gbogbo ìjọ pátá.—Róòmù 1:11, 12.

Bí A Ṣe Lè Jẹ́ “Àrànṣe Afúnnilókun”

8. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù fi gbà pé òun nílò “àrànṣe afúnnilókun”?

8 Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìtàn Pọ́ọ̀lù àtàwọn márùn-ún tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ yìí? Ẹ jẹ́ ká gbé ẹ̀kọ́ kan yẹ̀ wò ní pàtàkì, ẹ̀kọ́ náà ni pé: Ó gba ìgboyà àti yíyááfì àwọn nǹkan kan láti lè ṣèrànwọ́ fáwọn mìíràn lákòókò ìṣòro. Yàtọ̀ síyẹn, ó gba pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ láti gbà pé àwa náà nílò ìrànlọ́wọ́ nígbà tá a bá níṣòro. Kì í wúlẹ̀ ṣe pé Pọ́ọ̀lù gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́ nìkan ni, àmọ́ ó fi ìmọrírì tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ náà, ó sì yin àwọn tó ràn án lọ́wọ́. Kò ronú pé táwọn ẹlòmíràn bá ran òun lọ́wọ́, á bu òun kù tàbí pé á rẹ òun wálẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí àwa náà ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Tá a bá sọ pé àwa ò nílò àrànṣe afúnnilókun, ńṣe là ń sọ pé agbára wa ju ti ẹ̀dá lọ nìyẹn. Rántí pé, àpẹẹrẹ Jésù fi hàn pé ìgbà mìíràn wà tí ẹ̀dà èèyàn pípé pàápàá ní láti bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.—Hébérù 5:7.

9, 10. Àbájáde rere wo ló lè wáyé tẹ́nì kan bá gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́, báwo sì ni èyí ṣe lè nípa lórí àwọn míì nínú ìdílé àti nínú ìjọ?

9 Àbájáde rere lè wáyé nígbà táwọn tó ń mú ipò iwájú bá gbà pé àwọn náà ní ìkùdíẹ̀-káàtó, tí wọ́n sì gbà pé ó yẹ káwọn gbára lé àwọn ẹlòmíràn. (Jákọ́bù 3:2) Níní tí àwọn tó ń mú ipò iwájú bá ní èrò yẹn máa ń jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín wọn àtàwọn tó wà lábẹ́ wọn túbọ̀ gún régé, èyí á sì mú kí wọ́n jọ máa sọ̀rọ̀ fàlàlà. Ẹ̀kọ́ gidi ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí àwọn tó gbà kí ẹlòmíràn ran àwọn lọ́wọ́ ń kọ àwọn tó wà ní ipò wọn. Èyí fi hàn pé èèyàn làwọn tó ń mú ipò iwájú àti pé wọ́n ṣeé sún mọ́.—Oníwàásù 7:20.

10 Bí àpẹẹrẹ, tí àwọn ọmọ bá mọ̀ pé àwọn òbí wọn pàápàá dojú kọ irú ìṣòro táwọn ní nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé, yóò mú kó rọrùn fún wọn láti tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ táwọn òbí wọn ń fún wọn lórí bí wọ́n ṣe lè kojú ìṣòro àti ìdẹwò. (Kólósè 3:21) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn á lè jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa. Wọ́n á lè máa bá àwọn ọmọ wọn wá ojútùú tó bá Ìwé Mímọ́ mú, àwọn náà á sì lè tètè tẹ́wọ́ gbà á. (Éfésù 6:4) Bákan náà, àwọn ará nínú ìjọ á ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ táwọn alàgbà bá fún wọn tí wọ́n bá rí i pé àwọn alàgbà náà ń dojú kọ ìṣòro, ìbẹ̀rù àti ìdààmú ọkàn. (Róòmù 12:3; 1 Pétérù 5:3) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà àtàwọn ará yòókù á lè jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa, wọ́n á lè fi Ìwé Mímọ́ gba ara wọn níyànjú, ìgbàgbọ́ wọn á sì túbọ̀ lágbára sí i. Ó yẹ ká rántí pé, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin nílò okun nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ.—2 Tímótì 3:1.

11. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí fi nílò “àrànṣe afúnnilókun”?

11 Láìka ibi tá à ń gbé, ẹni tá a jẹ́ tàbí ọjọ́ orí wa sí, gbogbo wa là ń bá ara wa nínú ipò tí kò fara rọ nígbà mìíràn. Ara ohun tá à ń rí láyé yìí nìyẹn. (Ìṣípayá 12:12) Irú àwọn ipò tó máa ń ga ni lára bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká lè mọ bí ìgbàgbọ́ wa ti lágbára tó. Ipò tó le koko lè yọjú níbi iṣẹ́, nílé ìwé, láàárín ìdílé tàbí nínú ìjọ. Ó lè jẹ́ pé àìsàn lílekoko kan tàbí ràbọ̀ràbọ̀ wàhálà téèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ nínú rẹ̀ ló fa ìṣòro náà. Á mà tuni lára gan-an o bi ọkọ tàbí aya ẹni, alàgbà kan, tàbí ọ̀rẹ́ ẹni bá fún wa níṣìírí, tó sì ràn wá lọ́wọ́! Ńṣe ló dà bí oògùn ìwọ́ra! Nítorí náà, tó o bá rí arákùnrin rẹ kan ní irú ipò yìí, jẹ́ àrànṣe afúnnilókun fún un. Tó bá sì jẹ́ ìwọ ni ìṣòro kan fẹ́ ga lára, ní káwọn tó tóótun nípa tẹ̀mí ràn ọ́ lọ́wọ́.—Jákọ́bù 5:14, 15.

Bí Ìjọ Ṣe Lè Ṣèrànwọ́

12. Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ lè ṣe láti fún àwọn arákùnrin rẹ̀ lókun?

12 Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, títí kan àwọn èwe ló lè ṣe nǹkan kan láti fún àwọn ẹlòmíràn lókun. Bí àpẹẹrẹ, wíwá tó ò ń wá sípàdé àti òde ẹ̀rí déédéé ń ṣe bẹbẹ láti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn túbọ̀ lágbára sí i. (Hébérù 10:24, 25) Ṣíṣe tó ò ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ láìyẹsẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó sì fi hàn pé ó wà lójúfò nípa tẹ̀mí láìfi ìṣòro tó ò ń bá fínra pè. (Éfésù 6:18) Ṣíṣe tó ò ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìyẹsẹ̀ yóò máa fún àwọn ẹlòmíràn lókun.—Jákọ́bù 2:18.

13. Kí ló lè mú káwọn kan di aláìṣiṣẹ́mọ́, kí sì ni ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?

13 Nígbà míì, pákáǹleke tàbí ìṣòro míì lè mú káwọn kan dẹra nù tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ lọ sóde ẹ̀rí mọ́. (Máàkù 4:18, 19) Àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lè má máa wá sáwọn ìpàdé ìjọ. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣì wà lọ́kàn wọn. Kí la lè ṣe láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára? Àwọn alàgbà lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa bíbẹ wọ́n wò. (Ìṣe 20:35) Wọ́n tún lè sọ fún àwọn míì nínú ìjọ pé kí wọ́n ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Ó lè jẹ́ pé irú ìbẹ̀wò yìí gan-an ló máa mú kí ìgbàgbọ́ àwọn kan tó ti di ahẹrẹpẹ padà lágbára.

14, 15. Ìmọ̀ràn wo ní Pọ́ọ̀lù fúnni nípa fífún àwọn ẹlòmíràn lókun? Sọ àpẹẹrẹ ìjọ kan tó fi ìmọ̀ràn yìí sílò.

14 Bíbélì gbà wá níyànjú pé, “ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Bóyá àwọn “ọkàn tí ó soríkọ́” rí i pé àwọn ò nígboyà bíi tí tẹ́lẹ̀ mọ́ àti pé àwọn ò lè borí ìṣòro tí wọ́n ń kojú rẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn. Ǹjẹ́ o lè ṣe irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀? Gbólóhùn náà “ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera” ni a túmọ̀ sí “láti dì mú ṣinṣin” tàbí “láti gbá” àwọn aláìlera “mú.” Jèhófà mọyì gbogbo àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Kò kà wọ́n sí ẹni tí kò jámọ́ nǹkan kan, kò sì fẹ́ kí èyíkéyìí nínú wọn dáwọ́ sísin Ọlọ́run dúró. Ǹjẹ́ o lè ran ìjọ lọ́wọ́ “láti di” àwọn aláìlera nípa tẹ̀mí “mú ṣinṣin” títí ara wọn á fi mókun nípa tẹ̀mí?—Hébérù 2:1.

15 Alàgbà kan lọ sọ́dọ̀ tọkọtaya kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ fún odindi ọdún mẹ́fà. Alàgbà náà kọ ọ́ pé: “Inú rere àti ìfẹ́ tí gbogbo ará nínú ìjọ fi hàn sí wọn nípa lórí wọn débi pé èyí mú kí wọ́n padà sáàárín agbo náà lẹ́ẹ̀kan sí i.” Báwo ní ìbẹ̀wò ará nínú ìjọ ṣe rí lára arábìnrin tó fìgbà kan rí jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ yìí? Ó sọ pé: “Ohun tó ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣeé dáadáa lẹ́ẹ̀kan sí i ni pé, àwọn arákùnrin tó ń wá sọ́dọ̀ wa àtàwọn arábìnrin tó ń bá wọn wa kò lo èdè tó fi hàn pé a ò wúlò, wọn ò sì ṣàríwísí wa rí. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ ro ara wọn wò, wọ́n sì fún wa níṣìírí látinú Ìwé Mímọ́.”

16. Ta lẹ́ni tó ṣe tán láti fi okun fún àwọn tó bá nílò rẹ̀ nígbàkigbà?

16 Dájúdájú, àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ máa ń fẹ́ láti fún àwọn mìíràn lókun. Àti pé bí ipò nǹkan ṣe ń yí padà nínú ìgbésí ayé wa, ó lè jẹ́ pé àwa gan-an lẹ́ni tó máa nílò okun látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa. Àmọ́, ká sòótọ́, àwọn ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé kò sẹ́nì kankan tó máa lè ràn wá lọ́wọ́. Síbẹ̀, ẹnì kan wà tó jẹ́ Orísun okun tí kì í kùnà tó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ nígbàkigbà, ẹni náà ni Jèhófà Ọlọ́run.—Sáàmù 27:10.

Jèhófà —Orísun Okun Tó Ga Jù Lọ

17, 18. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fún Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ lókun?

17 Nígbà tí Jésù wà lórí òpó igi tí wọ́n kàn án mọ́, ó kígbe pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” (Lúùkù 23:46) Lẹ́yìn tó sì sọ ọ̀rọ̀ yẹn, ó gbẹ́mìí mì. Ní wákàtí díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kòríkòsùn fi í sílẹ̀ wọ́n sì sá lọ nítorí ìbẹ̀rù. (Mátíù 26:56) Orísun okun kan ṣoṣo tó wá kù fún Jésù ni Baba rẹ̀ ọ̀run. Síbẹ̀, ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Jèhófà kò jásí asán. Jésù jèrè jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ sí Baba rẹ̀ nítorí pé Jèhófà alára dúró tì í.—Sáàmù 18:25; Hébérù 7:26.

18 Jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, Jèhófà pèsè ohun tí Ọmọ rẹ̀ nílò láti pa ìwà títọ́ mọ̀ títí dójú ikú. Bí àpẹẹrẹ, kété tí Jésù ṣe ìrìbọmi, tó jẹ́ àmì pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ó gbọ́ ohun Baba rẹ̀ tó sọ pé òun tẹ́wọ́ gbà á àti pé Òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Jésù nílò ìrànlọ́wọ́, Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì láti lọ fún un lókun. Nígbà tí Jésù kojú ìdánwò tó le koko jù lọ níparí ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ̀. Dájúdájú, àrànṣe afúnnilókun ni gbogbo èyí jẹ́ fún Jésù.—Máàkù 1:11, 13; Lúùkù 22:43.

19, 20. Báwo ló ṣe dá wa lójú pé Jèhófà yóò fún wa lókun lákòókò ìṣòro?

19 Ó yẹ kí àwa náà fi Jèhófà ṣe olórí Orísun okun wa. (2 Kíróníkà 16:9) Orísun okun tòótọ́ àti agbára ńlá yìí lè jẹ́ àrànṣe afúnnilókun fún wa nígbà tá a bá nílò rẹ̀. (Aísáyà 40:26) Ogun, òṣì, àìsàn, ikú tàbí àìpé àwa fúnra wa lè mú ká dààmú gidigidi. Nígbà tí ìṣòro ìgbésí ayé bá fẹ́ bò wá mọ́lẹ̀ bíi ‘ọ̀tá alágbára,’ Jèhófà lè jẹ́ okun àti agbára ńlá fún wa. (Sáàmù 18:17; Ẹ́kísódù 15:2) Ó tún fún wa ní àrànṣe alágbára kan, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Jèhófà lè tipa ẹ̀mí mímọ́ yìí “fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀” kí ó bàa lè “fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì.”—Aísáyà 40:29, 31.

20 Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ipá tó lágbára jù lọ láyé lọ́run. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” Bẹ́ẹ̀ ni, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” kí á bàa lè máa fara da gbogbo ìṣòro tó ń ga wá lára títí yóò fi sọ “ohun gbogbo di tuntun” nínú Párádísè tó ṣèlérí tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dé.—Fílípì 4:13; 2 Kọ́ríńtì 4:7; Ìṣípayá 21:4, 5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé Vine’s Complete Expository Dictionary of Old and New Testament Words, látọwọ́ W. E. Vine sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ìṣe fún ọ̀rọ̀ náà [pa·re·go·riʹa] dúró fún egbòogi tó máa ń mára tuni.”

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo làwọn arákùnrin ní Róòmù ṣe jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún Pọ́ọ̀lù?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” nínú ìjọ?

• Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ Orísun okun wa tó ga jù lọ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn arákùnrin jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún Pọ́ọ̀lù nípa dídúró tí í, gbígbà á níyànjú àti nípa bíbá a ṣe àwọn iṣẹ́ kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn alàgbà ń mú ipò iwájú nínú fífún agbo lókun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́