Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Rìn Lọ́nà Tó Yẹ Jèhófà
“Àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè . . . máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.”—KÓLÓSÈ 1:9, 10.
1, 2. Kí ni ohun pàtàkì tó lè jẹ́ orísun ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn?
“INÚ ilé kékeré tó ṣeé fà káàkiri bí ọkọ̀ là ń gbé lábúlé. Nítorí pé a kò walé ayé máyà, a ní àkókò tó pọ̀ láti mú ìhìn rere náà tọ àwọn èèyàn lọ. A sì ti bù kún wa jìngbìnnì ní ti pé a ti láǹfààní àtiran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.”—Tọkọtaya kan, tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní Gúúsù Áfíríkà ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.
2 Ǹjẹ́ o kò ní gbà pé ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ń mú ayọ̀ wá? Àwọn kan máa ń tiraka nígbà gbogbo láti ran àwọn aláìsàn, àwọn tí a fi nǹkan dù, àtàwọn tó dá nìkan wà, lọ́wọ́—wọ́n sì ń rí ìtẹ́lọ́rùn nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ó dá àwọn Kristẹni tòótọ́ lójú pé bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi ni ìrànlọ́wọ́ tó ga jù lọ táwọn lè ṣe fúnni. Èyí nìkan ló lè mú káwọn ẹlòmíràn tẹ́wọ́ gbà ìràpadà Jésù, kí wọ́n ni àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, kí wọ́n sì wá wà ní ìlà fún ìyè àìnípẹ̀kun.—Ìṣe 3:19-21; 13:48.
3. Irú ìrànwọ́ wo ló yẹ ká fún láfiyèsí?
3 Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ nípa ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n ti ń sin Ọlọ́run, tí wọ́n ń tẹ̀ lé “Ọ̀nà Náà” ńkọ́? (Ìṣe 19:9) Ó dájú pé ìfẹ́ tóo ní sí wọn látilẹ̀ kò tíì yingin, àmọ́ o lè ṣàìrí ọ̀nà tóo lè gbà ṣe púpọ̀ sí i tàbí tóo fi lè máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nìṣó. Tàbí kẹ̀, ipò tóo wà lè máà fún ọ láyè àtiràn wọ́n lọ́wọ́, kí èyí sì tipa bẹ́ẹ̀ dín ìtẹ́lọ́rùn tó yẹ kí o ní kù. (Ìṣe 20:35) Ní sísọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà méjèèjì, a lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìwé Kólósè.
4. (a) Lábẹ́ irú ipò wo ni Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé sí àwọn ará Kólósè? (b) Báwo lọ̀rọ̀ ṣe kan Epafírásì?
4 Inú ilé tí wọ́n sé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ́ ní Róòmù ló wà nígbà tó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè gbàlejò níbẹ̀. Bóo ṣe lè retí, Pọ́ọ̀lù lo ìwọ̀nba òmìnira tó ní níbẹ̀ láti wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 28:16-31) Àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù lè wá bẹ̀ ẹ́ wò, àfàìmọ̀ ni wọn ò sì fi ń ti àwọn kan mọ́lé pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Kólósè 1:7, 8; 4:10) Ọ̀kan nínú wọn ni onítara ajíhìnrere nì, Epafírásì, tó wá láti ìlú ńlá Kólósè ní Fíríjíà, ní orílẹ̀-èdè tó lókè títẹ́jú ní ìlà oòrùn Éfésù ní Éṣíà Kékeré (ìyẹn Turkey òde òní). Epafírásì ti ṣèrànwọ́ gan-an láti dá ìjọ kan sílẹ̀ ní Kólósè, ó sì ti ṣiṣẹ́ àṣekára fún àwọn ìjọ tó wà ní Laodíkíà àti Hirapólísì tó wà nítòsí. (Kólósè 4:12, 13) Èé ṣe tí Epafírásì fi rìnrìn àjò lọ sí Róòmù láti rí Pọ́ọ̀lù, kí la sì lè rí kọ́ lára bí Pọ́ọ̀lù ṣe fèsì?
Ìrànwọ́ Tó Gbéṣẹ́ fún Àwọn Ará Kólósè
5. Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi kọ ohun tó kọ yẹn sí àwọn ará Kólósè?
5 Kí Epafírásì lè sọ fún Pọ́ọ̀lù nípa bípò nǹkan ṣe rí nínú ìjọ Kólósè ló mú kó rin ìrìn àjò atánnilókun yẹn lọ sí Róòmù. Ó ròyìn nípa ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti akitiyan àwọn Kristẹni yẹn nínú jíjíhìnrere. (Kólósè 1:4-8) Ṣùgbọ́n ó tún ti ní láti sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ń ṣàníyàn lórí ipa búburú èyí tó fi ipò tẹ̀mí àwọn ará Kólósè sínú ewu. Lẹ́tà kan táa mí sí tó tako èrò òdì tí àwọn olùkọ́ èké ń tàn kálẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù fi fèsì. Ó darí àfiyèsí sí ipa pàtàkì tí Jésù Kristi ní láti kó.a Ṣé orí títẹnu mọ́ kókó òtítọ́ Bíbélì nìkan ló fi ìrànwọ́ rẹ̀ mọ sí ni? Ọ̀nà mìíràn wo ló tún lè gbà ran àwọn ará Kólósè lọ́wọ́, kí sì ni àwọn ẹ̀kọ́ táa lè kọ́ nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?
6. Kí ni Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kólósè?
6 Ní ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà Pọ́ọ̀lù, ó fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye nípa irú ìrànwọ́ kan táa lè gbójú fò dá. Ìyẹn ni béèyàn ṣe lè ṣèrànwọ́ tó gbéṣẹ́ láti ọ̀nà jíjìn, níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù àti Epafírásì ti wà níbi tó jìnnà sí Kólósè. Pọ́ọ̀lù fi ìdálójú sọ pé: “Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kristi nígbà gbogbo tí a bá ń gbàdúrà [àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW, “gbàdúrà nígbà gbogbo”] fún yín.” Dájúdájú, àwọn àdúrà tí wọ́n dìídì gbà fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè nìwọ̀nyí. Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Ìdí tún nìyẹn tó fi jẹ́ pé, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa rẹ̀, àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí.”—Kólósè 1:3, 9.
7, 8. Kí ni a sábà máa ń mẹ́nu kàn nínú àwọn àdúrà táà ń dá nìkan gbà àti èyí táà ń gbà láwọn ìjọ?
7 A mọ̀ pé “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà, ìdí nìyẹn táa fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú bó ṣe múra tán láti gbọ́ àwọn àdúrà tí a gbà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 65:2; 86:6; Òwe 15:8, 29; 1 Jòhánù 5:14) Àmọ́ báwo làwọn àdúrà wa ṣe máa ń rí nígbà táa bá ń gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíràn?
8 A lè máa ronú nípa ‘gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará wa nínú ayé,’ ká sì máa gbàdúrà fún wọn ní gbogbo ìgbà. (1 Pétérù 5:9) A sì tún lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni àtàwọn mìíràn tó wà lágbègbè tí ìjábá tàbí àjálù ti ṣẹlẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà láwọn ibòmíràn ní ọ̀rúndún kìíní gbọ́ nípa ìyàn tó mú ní Jùdíà, wọ́n ti ní láti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà fún àwọn arákùnrin wọn kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n fi ọrẹ ránṣẹ́ sí wọn. (Ìṣe 11:27-30) Lóde òní, a sábà máa ń gbọ́ àwọn àdúrà táa máa ń gbà fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará tàbí fún ògìdìgbó àwọn arákùnrin láwọn ìpàdé Kristẹni, níbi tí ọ̀pọ̀ ti ní láti lóye ohun tí wọ́n ń sọ, kí wọ́n sì lè sọ pé “Àmín.”—1 Kọ́ríńtì 14:16.
Jẹ́ Kí Àdúrà Ṣe Pàtó
9, 10. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ó bójú mu láti gbàdúrà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan pàtó? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ẹni tí a mẹ́nu kàn pàtó nínú àdúrà?
9 Síbẹ̀, Bíbélì fúnni lápẹẹrẹ àwọn àdúrà tó ṣe pàtó táa gbà fún àwọn ẹlòmíràn, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ronú lórí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Lúùkù 22:31, 32. Àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo wọn ló máa nílò ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run láwọn àkókò ìṣòrò ọjọ́ iwájú, Jésù sì gbàdúrà fún wọn. (Jòhánù 17:9-14) Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù dá Pétérù yọ sọ́tọ̀, ó sì gbàdúrà tó ṣe pàtó fún ọmọ ẹ̀yìn kan ṣoṣo yẹn. Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn rèé: Èlíṣà gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran ọkùnrin kan ní pàtó lọ́wọ́, ìyẹn ẹmẹ̀wà rẹ̀. (2 Àwọn Ọba 6:15-17) Àpọ́sítélì Jòhánù gbàdúrà pé kí Gáyọ́sì máa wà ní àlàáfíà nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. (3 Jòhánù 1, 2) Àti àwọn àdúrà mìíràn táa gbà fún àwọn àwùjọ kan pàtó.—Jóòbù 42:7, 8; Lúùkù 6:28; Ìṣe 7:60; 1 Tímótì 2:1, 2.
10 Lẹ́tà Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọ̀ràn nípa àwọn àdúrà tó ṣe pàtó gan-an. Ó ní kí wọ́n gbàdúrà fún òun tàbí fún òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ òun. Kólósè 4:2, 3 kà pé: “Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà, kí ẹ máa wà lójúfò nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, lẹ́sẹ̀ kan náà, kí ẹ máa gbàdúrà fún àwa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ilẹ̀kùn àsọjáde fún wa, láti sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ nípa Kristi, èyí tí mo tìtorí rẹ̀ wà nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n ní ti tòótọ́.” Tún gbé àwọn àpẹẹrẹ mìíràn wọ̀nyí yẹ̀ wò: Róòmù 15:30; 1 Tẹsalóníkà 5:25; 2 Tẹsalóníkà 3:1; Hébérù 13:18.
11. Àwọn wo ni Epafírásì ń gbàdúrà fún nígbà tó wà ní Róòmù?
11 Bákan náà ló ṣe rí pẹ̀lú ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù tó wà ní Róòmù. “Epafírásì, ẹni tí ó ti àárín yín wá, . . . kí yín, nígbà gbogbo ni ó ń tiraka nítorí yín nínú àwọn àdúrà rẹ̀.” (Kólósè 4:12) Ọ̀rọ̀ táa lò fún “títiraka” lè fi “ìlàkàkà” hàn, bíi ti eléré ìdárayá kan nínú àwọn eré àṣedárayá ìgbàanì. Ṣé gbogbo onígbàgbọ́ kárí ayé tàbí àwọn olùjọsìn tó wà ní gbogbo Éṣíà Kékeré ni Epafírásì ń fi tìtaratìtara gbàdúrà fún ni? Pọ́ọ̀lù fi hàn pé àwọn tó wà ní Kólósè ni Epafírásì gbàdúrà fún ní pàtó. Epafírásì mọ ipò tí wọ́n wà. A kò mọ̀ orúkọ gbogbo wọn, bẹ́ẹ̀ ni a kò mọ àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wọ́n, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ìṣòro wà. Bóyá ṣe ni Línúsì ọ̀dọ́ ń kojú ipa tí àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tó gbòde kan ní lórí rẹ̀, Rúfọ́ọ̀sì ní tiẹ̀ sì lè nílò okun láti dènà àwọn àṣà tó ti mọ́ ọn lára nígbà tó wà nínú ìsìn àwọn Júù. Nítorí ọkọ aláìgbàgbọ́ tí wọ́n ní, ǹjẹ́ Pésísì ò nílò ìfaradà àti ọgbọ́n láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nínú Olúwa, ǹjẹ́ Asinkirítọ́sì náà, ẹni tó ní àìsàn kan tó ti di bárakú sí i lára, ò nílò ìtùnú àrà ọ̀tọ̀? Dájúdájú, Epafírásì mọ àwọn tó wà nínú ìjọ rẹ̀, ó sì fi taratara gbàdúrà nípa wọn nítorí pé òun àti Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí irú àwọn olùfọkànsìn bẹ́ẹ̀ rìn ní ọ̀nà tí ó yẹ Jèhófà.
12. Báwo la ṣe lè túbọ̀ ṣe pàtó nínú àwọn àdúrà táa ń dá nìkan gbà?
12 Ǹjẹ́ o rí àpẹẹrẹ tí wọ́n fi lélẹ̀ fún wa—tó jẹ́ ọ̀nà kan táa lè gbà ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́? Gẹ́gẹ́ bí a ti kíyè sí i, àwọn àdúrà táa ń gbà láwọn ìpàdé Kristẹni kì í sábà ṣe pàtó nítorí onírúurú ènìyàn tó pésẹ̀ síbẹ̀. Àmọ́, àdúrà táa dá nìkan gbà tàbí èyí táa gbà pẹ̀lú ìdílé wa lè jẹ́ èyí tó ṣe pàtó. Nígbà tó jẹ́ pé ìgbà mìíràn wà táa lè bẹ Ọlọ́run pé kó ṣamọ̀nà gbogbo àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí kó sì bù kún wọn, a ò ṣe kúkú dárúkọ wọn ní pàtó láwọn ìgbà mìíràn? Fún àpẹẹrẹ, o ò ṣe dárúkọ alábòójútó àyíká tó ń bẹ ìjọ rẹ wò tàbí olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ nígbà tóo bá ń gbàdúrà? Fílípì 2:25-28 àti 1 Tímótì 5:23 fi hàn wá bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàníyàn nípa ìlera Tímótì àti ti Ẹpafíródítù. Ǹjẹ́ a lè fi irú àníyàn kan náà hàn sí àwọn táa mọ orúkọ wọn tí wọ́n wà nídùbúlẹ̀ àìsàn?
13. Irú àwọn ipò wo ló jẹ́ ọ̀ràn tó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún wa láti mẹ́nu kàn nínú àdúrà wa?
13 Lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ yẹra fún títojúbọ ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n ó dára kí àdúrà wa fi ojúlówó ìfẹ́ táa ní sí àwọn táa mọ̀, táa sì bìkítà nípa wọn hàn. (1 Tímótì 5:13; 1 Pétérù 4:15) Iṣẹ́ ti lè bọ́ lọ́wọ́ arákùnrin kan, a kò sì níṣẹ́ mìíràn táa lè fún un. Síbẹ̀, a lè dárúkọ rẹ̀ nígbà táa bá ń dá nìkan gbàdúrà, ká sì mẹ́nu kan ìṣòro rẹ̀ pẹ̀lú. (Sáàmù 37:25; Òwe 10:3) Ǹjẹ́ a mọ̀ nípa arábìnrin kan tó ti dàgbà, tí kò lọ́kọ, tí kò sì bímọ nítorí pé ó pinnu láti ṣe ìgbéyàwó “kìkì nínú Olúwa”? (1 Kọ́ríńtì 7:39) Nínú àdúrà tóo ń dá nìkan gbà, o ò ṣe bẹ Jèhófà pé kó bù kún un, kó sì ràn án lọ́wọ́ láti máa bá bó ṣe dúró ṣinṣin nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó? Àpẹẹrẹ mìíràn ni pé, àwọn alàgbà méjì ti lè fún arákùnrin kan tó ṣi ẹsẹ̀ gbé ní ìmọ̀ràn. Kí ló dé tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn kò fi lè máa dárúkọ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nínú àdúrà tí wọ́n ń dá nìkan gbà?
14. Báwo ni àdúrà tó ṣe pàtó ṣe tan mọ́ ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?
14 Nígbà tóo bá ń dá nìkan gbàdúrà, o ṣeé ṣe fún ọ dáadáa láti mẹ́nu kan àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tóo mọ̀ pé wọ́n nílò ìtìlẹ́yìn, ìtùnú, ọgbọ́n, àti ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tàbí èyíkéyìí nínú àwọn èso tí ẹ̀mí rẹ̀ ń mú jáde. Nítorí ọ̀nà jíjìn tàbí àwọn ipò mìíràn, nǹkan ti ara tí o lè fún wọn tàbí ìrànlọ́wọ́ tóo lè ṣe fún wọn lè máà tó nǹkan. Síbẹ̀, má ṣe gbàgbé láti gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ. O mọ̀ pé wọ́n fẹ́ rìn ní ọ̀nà tó yẹ Jèhófà, àmọ́ wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè ṣe bẹ́ẹ̀ títí láé. Àdúrà rẹ ni lájorí ọ̀nà tóo fi lè ṣèrànwọ́.—Sáàmù 18:2; 20:1, 2; 34:15; 46:1; 121:1-3.
Sapá Láti fún Àwọn Ẹlòmíràn Lókun
15. Èé ṣe tó fi yẹ kí apá tí ó kẹ́yìn nínú ìwé Kólósè fà wá lọ́kàn mọ́ra?
15 Àmọ́ ṣá o, àdúrà tóo fi taratara gbà, tó sì ṣe pàtó nìkan kọ́ ni ọ̀nà tí o lè gbà ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àgàgà àwọn tó sún mọ́ ọ, tí wọ́n sì jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí ọ. Ìwé Kólósè mú kí ìyẹn ṣe kedere. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló gbà pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti fúnni ní àwọn ìdarí lórí ẹ̀kọ́ ìsìn àti ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́, ó tún fi ìkíni kún un. (Kólósè 4:7-18) Yàtọ̀ síyẹn, a ti rí i pé apá tí ó kẹ́yìn nínú ìwé náà ní àwọn ìmọ̀ràn tó yẹ fún àfiyèsí nínú, ọ̀pọ̀ nǹkan la sì ní láti kọ́ látinú apá tí ó kẹ́yìn yìí.
16, 17. Kí la lè sọ nípa àwọn arákùnrin táa mẹ́nu kàn nínú Kólósè 4:10, 11?
16 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àrísítákọ́sì òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi kí yín, Máàkù mọ̀lẹ́bí Bánábà sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, (nípa ẹni tí ẹ rí àwọn àṣẹ gbà pé kí ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á bí ó bá wá sọ́dọ̀ yín,) àti Jésù tí a ń pè ní Jọ́sítù, àwọn wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn tí ó dádọ̀dọ́. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn wọ̀nyí gan-an sì ti di àrànṣe afúnnilókun fún mi.”—Kólósè 4:10, 11.
17 Níbẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan àwọn arákùnrin kan tí wọ́n yẹ fún àfiyèsí pàtàkì. Ó ní wọ́n wà lára àwọn tó dádọ̀dọ́, tí wọ́n jẹ́ Júù. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó dádọ̀dọ́ ló wà ní Róòmù, àwọn kan lára wọn sì ti di Kristẹni báyìí. Àmọ́, àwọn tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn yẹn ni àwọn tó ràn án lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọn kò kọ̀ láti dára pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Kèfèrí tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti ní láti fi tayọ̀tayọ̀ bá Pọ́ọ̀lù kópa nínú wíwàásù fún àwọn Kèfèrí.—Róòmù 11:13; Gálátíà 1:16; 2:11-14.
18. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe gbóríyìn fún àwọn kan tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀?
18 Kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn wọ̀nyí gan-an sì ti di àrànṣe afúnnilókun fún mi.” Ó lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó jẹ́ pé ìgbà kan ṣoṣo yìí ló fara hàn nínú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ atúmọ̀ èdè ló pè é ní “ìtùnú.” Àmọ́ ọ̀rọ̀ Gíríìkì mìíràn tún wà (pa·ra·ka·le’o) tí wọ́n sábà máa ń túmọ̀ sí “ìtùnú.” Pọ́ọ̀lù lo irú rẹ̀ níbòmíràn nínú lẹ́tà yìí gan-an, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú Kólósè 4:11.—Mátíù 5:4; Ìṣe 4:36; 9:31; 2 Kọ́ríńtì 1:4; Kólósè 2:2; 4:8.
19, 20. (a) Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù lò fún àwọn arákùnrin tí wọ́n ń ràn án lọ́wọ́ ní Róòmù? (b) Àwọn ọ̀nà wo làwọn arákùnrin wọ̀nyẹn ti lè gbà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?
19 Àwọn tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan yẹn ti ní láti ṣe ju kí wọ́n kàn fọ̀rọ̀ ẹnu lásán tù ú nínú lọ. Ìgbà mìíràn wà tí àwọn ìwé ayé máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa túmọ̀ sí “àrànṣe afúnnilókun” nínú Kólósè 4:11 yẹn fún oògùn tó ń lé ìrora ọkàn lọ. Ẹ̀dà ti New Life Version kà pé: “Ẹ wo ìrànlọ́wọ́ ńlá tí wọ́n ti jẹ́ fún mi!” Today’s English Version lo ẹ̀dà ọ̀rọ̀ náà pé: “Wọ́n ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá fún mi.” Kí ni àwọn Kristẹni arákùnrin tó wà nítòsí Pọ́ọ̀lù yẹn ti ní láti ṣe láti ràn án lọ́wọ́?
20 Pọ́ọ̀lù lè gbàlejò, àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tí kò lè ṣe, irú bíi ríra àwọn ohun tó nílò—ìyẹn oúnjẹ àti aṣọ fún ìgbà òtútù. Báwo ló ṣe máa rí àwọn àkájọ ìwé tó máa lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àbí báwo ló ṣe máa ra àwọn ohun tó fi ń kọ̀wé? (2 Tímótì 4:13) Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo àwọn arákùnrin tí wọ́n ń ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, tí wọ́n ń bá a ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bíi ríra àwọn nǹkan tàbí bíbá a ṣe àwọn iṣẹ́ kan? Ó lè fẹ́ bẹ àwọn ìjọ kan wò, kó sì gbé wọn ró. Àmọ́ kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìtìmọ́lé tó wa, nítorí ìdí èyí, àwọn arákùnrin wọ̀nyẹn ti lè bá Pọ́ọ̀lù bẹ àwọn ìjọ wò, kí wọ́n lọ jíṣẹ́ rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì mú ìròyìn padà wá fún un. Ẹ ò ri bí ìyẹn ṣe fúnni lókun tó!
21, 22. (a) Èé ṣe tó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Kólósè 4:11 fà wá lọ́kàn mọ́ra? (b) Kí ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ táa lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó wà lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù?
21 Ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ nípa jíjẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye nípa bí a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Wọ́n lè máa rìn ní ọ̀nà tó yẹ Jèhófà nípa pípa àwọn ìlànà rẹ̀ lórí ìwà rere mọ́, lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, àti kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Nítorí bẹ́ẹ̀, a ní láti máa bá wọn sọ̀rọ̀ tó fi ìmọrírì hàn. Àmọ́, ǹjẹ́ a lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, nípa jíjẹ́ ‘àrànṣe tí ń fúnni lókun’ bíi ti àwọn tó wà lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù?
22 Bí o bá mọ arábìnrin kan tó fọgbọ́n pa ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:37 mọ́, àmọ́ tí kò wá sí mẹ́ńbà ìdílé kankan nítòsí rẹ̀, ǹjẹ́ o lè pè é kó wá lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò díẹ̀ nínú ìdílé rẹ, bóyá kó wá bá yín jẹun tàbí kó wá síbi táwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn ẹbí kóra jọ sí? Tóo bá ní kó tẹ̀ lé ìdílé rẹ̀ lọ sí àpéjọpọ̀ kan tàbí kí ẹ jọ lọ fún ìsinmi ráńpẹ́ ńkọ́? Tàbí kí o sọ fún un pé kó bá ọ jáde láti lọ ra oúnjẹ sílé nígbà tó bá rọrùn fún un. Ohun kán náà la lè ṣe fún àwọn opó tàbí àwọn ọkùnrin tí ìyàwó wọ́n ti kú, tàbí àwọn tí kò lè wakọ̀ mọ́. O lè ri pé ó ṣàǹfààní láti gbọ́ ìrírí wọn tàbí láti gba ìmọ̀ lọ́dọ̀ wọn lórí àwọn nǹkan bíi dídá èso tó dára mọ̀ tàbí yíyan aṣọ fún àwọn ọmọ. (Léfítíkù 19:32; Òwe 16:31) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí àjọṣe yín túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè rọrùn fún wọn láti wá bá ọ fún ìrànlọ́wọ́ bí wọ́n bá fẹ́ gba oògùn nílé oògùn, tàbí fún nǹkan mìíràn. Àwọn arákùnrin tó wà lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Róòmù ti ní láti fún un ni àrànṣe afúnnilókun tó gbéṣẹ́, bí irú èyí tí ìwọ náà lè fúnni. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún àti nísinsìnyí, àfikún ìbùkún tó wà níbẹ̀ ni pé ìdè ìfẹ́ ń lágbára sí i, a sì ń pinnu láìyẹhùn pé a ó jìjọ fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà.
23. Yóò dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lo àkókò láti ṣe kí ni?
23 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ronú lórí àwọn ipò táa mẹ́nu kan nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àpẹẹrẹ ni wọ́n jẹ́ lóòótọ́, àmọ́ ìwọ̀nyí lè rán wa létí àwọn ipò táa ti lè túbọ̀ jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Kì í ṣe pé ká wá máa ṣe bíi tàwọn òṣìṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re là ń sọ o. Ìyẹn kọ́ ni góńgó àwọn arákùnrin táa mẹ́nu kan nínú Kólósè 4:10, 11. Wọ́n jẹ́ ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìjọba Ọlọ́run.’ Ohun náà gan-an tí ipa afúnnilókun náà tan mọ́ nìyẹn. Ǹjẹ́ kí ọ̀ràn tiwa náà rí bẹ́ẹ̀.
24. Kí ni ìdí pàtàkì táa fi ń gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíràn, táa sì ń gbìyànjú láti fún wọn lókun?
24 Ìdí kan tí a fi ń dárúkọ àwọn mìíràn nínú àdúrà táa dá nìkan gbà, tí a sì ń sapá láti fún wọn lókun ni pé: A gbà gbọ́ pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa fẹ́ “rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Kólósè 1:10) Kókó yẹn ní í ṣe pẹ̀lú nǹkan mìíràn tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn nígbà tó ń kọ̀wé nípa àdúrà tí Epafírásì gbà fún àwọn ará Kólósè, pé kí wọ́n lè “dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Kólósè 4:12) Báwo ni àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè ṣe ìyẹn láṣeyọrí? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ kìíní, ojú ìwé 490 sí 491, àti “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” ojú ìwé 226 sí 228, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Kí Lo Kíyè Sí?
• Báwo la ṣe lè túbọ̀ fi àdúrà táa dá nìkan gbà ṣèrànwọ́?
• Báwo làwọn Kristẹni kan ṣe jẹ́ ‘àrànṣe afúnnilókun’ fún Pọ́ọ̀lù?
• Nínú irú àwọn ipò wo la ti lè jẹ́ ‘àrànṣe afúnnilókun’?
• Kí ni olórí ète táa fi ń gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, táa sì ń gbìyànjú láti fún wọn lókun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ o lè pe Kristẹni mìíràn láti bá ìdílé rẹ jáde?
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Green Chimney’s Farm