ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 5/15 ojú ìwé 30-31
  • Epafírásì—“Olùṣòtítọ́ Òjíṣẹ́ fún Kristi”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Epafírásì—“Olùṣòtítọ́ Òjíṣẹ́ fún Kristi”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ajíhìnrere ti Àfonífojì Lycus
  • Ìròyìn Epafírásì
  • Ọkùnrin Tí Ó Mọyì Àdúrà
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Rìn Lọ́nà Tó Yẹ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • “Bí Ẹ Bá Mọ Nǹkan Wọ̀nyí, Aláyọ̀ Ni Yín Bí Ẹ Bá Ń Ṣe Wọ́n”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Jehofa Lè Sọ Ọ́ Di Alágbára
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 5/15 ojú ìwé 30-31

Epafírásì—“Olùṣòtítọ́ Òjíṣẹ́ fún Kristi”

TA NI ó dá àwọn ìjọ Kristẹni ní Kọ́ríńtì, Éfésù, àti Fílípì sílẹ̀? Kíá ni ìwọ yóò sọ pé: ‘Pọ́ọ̀lù, “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè” ni.’ (Róòmù 11:13) O kò parọ́.

Ṣùgbọ́n, ta ni ó dá ìjọ tí ó wà ní Kólósè, Hirapólísì, àti Laodíkíà sílẹ̀? Bí kò tilẹ̀ dá wa lójú, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọkùnrin kan tí a ń pè ní Epafírásì. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeé ṣe kí o fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa ajíhìnrere yìí, níwọ̀n bí a ti pè é ní “olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́ fún Kristi.”—Kólósè 1:7.

Ajíhìnrere ti Àfonífojì Lycus

Orúkọ náà, Epafírásì, jẹ́ ìkékúrú Ẹpafíródítù. Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rò pé Epafírásì ni Ẹpafíródítù tí ó wá láti Fílípì. Epafírásì wá láti Kólósè, ọ̀kan nínú àwọn ibùdó mẹ́ta tí ìjọ Kristẹni wà, ní àfonífojì Odò Lycus, ní Éṣíà kékeré. Kólósè wà ní kìlómítà 18 sí Laodíkíà àti kìlómítà 19 sí Hirapólísì, ní ẹkùn àtijọ́ ti Fíríjíà.

Bíbélì kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe dé Fíríjíà. Ṣùgbọ́n, àwọn ará Fíríjíà wà ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn kan lára wọn wá láti Kólósè. (Ìṣe 2:1, 5, 10) Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ní Éfésù (ní nǹkan bí ọdún 52 sí 55 Sànmánì Tiwa), ìjẹ́rìí tí a ṣe ní àgbègbè yí lágbára, ó sì múná dóko tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kì í fi í ṣe àwọn ará Éfésù nìkan ni wọ́n “gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa” ṣùgbọ́n àti “àwọn wọnnì tí ń gbé àgbègbè Éṣíà, . . . àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì.” (Ìṣe 19:10) Ó jọ bí ẹni pé Pọ́ọ̀lù kò tí ì wàásù ìhìn rere náà jákèjádò Àfonífojì Lycus, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n di Kristẹni ní ẹkùn yẹn kò ti fìgbà kan rí i sójú rí.—Kólósè 2:1.

Gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù ti sọ, Epafírásì ni ẹni tí ó kọ́ àwọn ará Kólósè nípa ‘inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run nínú òtítọ́.’ Òtítọ́ náà pé Pọ́ọ̀lù pe alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ yí ní “olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́ fún Kristi nítorí wa,” fi hàn pé Epafírásì jẹ́ ògbóṣáṣá ajíhìnrere kan ní àgbègbè náà.—Kólósè 1:6, 7.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Epafírásì ajíhìnrere ní ìdàníyàn ńláǹlà fún ire tẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n wà ní Àfonífojì Lycus. Gẹ́gẹ́ bí “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” inú Pọ́ọ̀lù ti gbọ́dọ̀ dùn láti gbọ́ ìròyìn ìtẹ̀síwájú wọn. Ní tòótọ́, ẹnu Epafírásì ni Pọ́ọ̀lù ti gbọ́ nípa ipò tẹ̀mí àwọn ará Kólósè.—Kólósè 1:4, 8.

Ìròyìn Epafírásì

Àwọn ará Kólósè dojú kọ ìṣòro líle koko débi tí ó fi sún Epafírásì láti rin ìrìn àjò gígùn lọ sí Róòmù fún ète ti jíjíròrò àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù. Ó hàn gbangba pé ìròyìn kíkún rẹ́rẹ́ tí Epafírásì ṣe ni ó sún Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà méjì sí àwọn ará wọnnì tí òun kò mọ̀. Ọ̀kan nínú wọn ni lẹ́tà sí àwọn ará Kólósè. Lẹ́tà kejì, tí ó hàn gbangba pé a kò tọ́jú, ni a fi ránṣẹ́ sí àwọn ará Laodíkíà. (Kólósè 4:16) Ó bọ́gbọ́n mu láti ronú pé a ní in lọ́kàn pé kí àwọn ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà àwọn wọ̀nyẹn kúnjú àìní àwọn Kristẹni wọnnì, gẹ́gẹ́ bí Epafírásì ti wòye. Àwọn àìní wo ni ó rí? Kí sì ni èyí sọ nípa àkópọ̀ ìwà rẹ̀?

Ó dà bí ẹni pé lẹ́tà sí àwọn ará Kólósè fi hàn pé Epafírásì dààmú pé àwọn Kristẹni ní Kólósè dojú kọ ewu ọgbọ́n èrò orí àwọn kèfèrí tí ó wé mọ́ ìfiǹkan-dura-ẹni, ìbẹ́mìílò, àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti ìbọ̀rìṣà. Ní àfikún sí i, ẹ̀kọ́ àwọn Júù nípa títa kété sí àwọn oúnjẹ àti yíya àwọn ọjọ́ kan pàtó sí mímọ́ ti lè nípa lórí àwọn mẹ́ńbà kan nínú ìjọ.—Kólósè 2:4, 8, 16, 20-23.

Òtítọ́ náà pé Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn ohun wọ̀nyí fi hàn wá bí Epafírásì ṣe wà lójúfò sí àìní àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó, àti bí ó ṣe tètè ń mọ àìní wọn. Ó fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn fún ire wọn tẹ̀mí, ní mímọ ewu àyíká tí wọ́n ń gbé. Epafírásì wá ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, èyí sì fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Bóyá ó nímọ̀lára àìní náà láti gba ìmọ̀ràn láti ọwọ́ ẹnì kan tí ó ní ìrírí jù ú lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, Epafírásì fi ọgbọ́n hùwà.—Òwe 15:22.

Ọkùnrin Tí Ó Mọyì Àdúrà

Ní ìparí lẹ́tà tí ó fi ránṣẹ́ sí àwọn Kristẹni ní Kólósè, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Epafírásì, ẹni tí ó ti àárín yín wá, ẹrú Kristi Jésù, ní kí a kí i yín, nígbà gbogbo ni ó ń tiraka nítorí yín nínú àwọn àdúrà rẹ̀, pé kí ẹ lè dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ inú Ọlọ́run. Nítòótọ́ mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó fi ara rẹ̀ ṣe ìsapá ńláǹlà nítorí yín àti nítorí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní Laodíkíà àti nítorí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní Hirapólísì.”—Kólósè 4:12, 13.

Bẹ́ẹ̀ ni, àní nígbà tí ó tilẹ̀ jẹ́ “òǹdè ẹlẹgbẹ́” Pọ́ọ̀lù ní Róòmù, Epafírásì ń ronú nípa àwọn arákùnrin rẹ̀ olùfẹ́ ní Kólósè, Laodíkíà, àti Hirapólísì, ó sì ń gbàdúrà fún wọn. (Fílémónì 23) Ní òwuuru, ‘ó làkàkà’ fún wọn nínú àdúrà. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé àkẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ D. Edmond Hiebert, ti sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a lò níhìn-ín túmọ̀ sí “ìgbòkègbodò atánnilókun, tí ń béèrè ìfara-ẹni-rúbọ,” ohun kan tí ó fara jọ “ìrora ẹ̀dùn” ọpọlọ tí Jésù Kristi nírìírí rẹ̀, bí ó ti ń gbàdúrà nínú ọgbà Gẹtisémánì. (Lúùkù 22:44) Epafírásì fi tọkàntọkàn fẹ́ kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin òun nípa tẹ̀mí dé ìwàdéédéé àti ìdàgbàdénú pátápátá ti Kristẹni. Ẹ wo irú ìbùkún tí irú arákùnrin tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn bẹ́ẹ̀ ti gbọ́dọ̀ jẹ́ fún ìjọ!

Níwọ̀n bí a ti pe Epafírásì ni “olùfẹ́ ọ̀wọ́n ẹrú ẹlẹgbẹ́ wa,” kò sí àní-àní pé ó sọ ara rẹ̀ di olùfẹ́ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. (Kólósè 1:7) Nígbà tí ipò nǹkan bá yọ̀ǹda, gbogbo mẹ́ńbà ìjọ yẹ kí wọ́n fi ara wọn fúnni tọ̀yàyàtọ̀yàyà àti tìfẹ́tìfẹ́. Fún àpẹẹrẹ, a lè fún ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn aláìsàn, fún àwọn àgbàlagbà, àti fún àwọn mìíràn tí wọ́n ní àìní àrà ọ̀tọ̀ ní àfiyèsí. Ẹrù iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè wà tí a ní láti bójú tó nínú ìjọ, tàbí ó lè ṣeé ṣe láti ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìkọ́lé ti ìṣètò ìṣàkóso Ọlọ́run.

Gbígbàdúrà fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí Epafírásì ti ṣe, jẹ́ oríṣi iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ kan tí gbogbo wa lè ṣe. Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ lè ní nínú, àwọn ọ̀rọ̀ ìdàníyàn fún àwọn olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n dojú kọ onírúurú ewu tàbí ìṣòro nípa tẹ̀mí tàbí nípa ti ara. Nípa títiraka lọ́nà yí tokuntokun, a lè dà bí Epafírásì. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ní àǹfààní àti ìdùnnú jíjẹ́ “olùfẹ́ ọ̀wọ́n ẹrú ẹlẹgbẹ́ wa” nínú ìdílé àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́