ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/22 ojú ìwé 7-10
  • Oúnjẹ Rẹ—Ó Ha Lè Pa Ọ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oúnjẹ Rẹ—Ó Ha Lè Pa Ọ́ Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oúnjẹ Rẹ àti Àrùn Ọkàn Àyà
  • Ipa Tí Èròjà Cholesterol Ń Kó
  • Èròjà Cholesterol Inú Ẹ̀jẹ̀ àti Oúnjẹ
  • Ọ̀rá àti Èròjà Cholesterol
  • Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Láti Dín Ọ̀rá àti Èròjà Cholesterol Kù
  • Àrùn Jẹjẹrẹ àti Oúnjẹ
  • Báwo Ni A Ṣe Lè Dín Ewu Náà Kù?
    Jí!—1996
  • Yíyan Oúnjẹ Tí Ń Ṣara Lóore
    Jí!—1997
  • Bóo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
    Jí!—1999
  • Ẹ̀jẹ̀ Ríru—Bá A Ṣe Lè Dènà Rẹ̀ àti Bá A Ṣe Lè Kápá Rẹ̀
    Jí!—2002
Jí!—1997
g97 6/22 ojú ìwé 7-10

Oúnjẹ Rẹ—Ó Ha Lè Pa Ọ́ Bí?

“Iṣan òpójẹ̀ ọkàn àyà rẹ kan ti dí lọ́nà tí ó fi lè ṣèpalára, ìdínà náà jẹ́ nǹkan bí ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún . . . Ní báyìí, ó ṣeé ṣe kí o ní ìkọlù àrùn ọkàn àyà láìpẹ́ ọjọ́.”

AGBÁRA káká ni Joe, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 32, fi gba àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí onímọ̀ nípa àrùn ọkàn àyà kan tí ó ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀ láti mọ okùnfà àyà ríro rẹ̀ gbọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì àwọn tí àrùn ọkàn àyà yóò pa ni wọn kò tilẹ̀ mọ̀ pé àwọn ní in.

Àmọ́ kí ló sún Joe dé ipò tí ó wà? Joe kédàárò pé: ‘Fún ọdún 32, mo ń jẹ “oúnjẹ ẹlẹ́ran àti onímílíìkì nínú” tí a sábà máa ń jẹ ní America. Lọ́nà kan ṣá, mo ṣá òtítọ́ náà pé oúnjẹ àwọn ará America léwu fún ìlera mi tì.’

Oúnjẹ Rẹ àti Àrùn Ọkàn Àyà

Kí ló ṣàìtọ́ nípa oúnjẹ Joe? Ní pàtàkì, ó ní èròjà cholesterol àti ọ̀rá púpọ̀ jù, ní pàtàkì ògidì ọ̀rá. Láti ìgbà èwe ni Joe ti ń fi ara rẹ̀ sínú ewu níní àrùn iṣan ẹ̀jẹ̀ ọkàn àyà ní ti pé gbogbo oúnjẹ tí ó fi amúga bù ló ń jẹ́ ọlọ́ràá. Oúnjẹ kan tí ó ní àpọ̀jù ọ̀rá, ní gidi, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú márùn-ún lára àwọn ohun mẹ́wàá tí ń fa ikú jù lọ ní United States. Àrùn iṣan ẹ̀jẹ̀ ọkàn àyà ló wà lókè pátápátá.

A rí ìsopọ̀ tí ó wà láàárín oúnjẹ àti àrùn ọkàn àyà nínú ìwádìí kan tí a ṣe ní orílẹ̀-èdè méje ní lílo 12,000 ọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín 40 ọdún sí ọdún 49. Ní pàtàkì ni àwọn ìyàtọ̀ lílégbá kan fara hàn níbẹ̀. Ìwádìí náà fi hàn pé àwọn ọkùnrin ilẹ̀ Finland—tí ń jẹ ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lára èròjà afúnnilágbára wọn bí ògidì ọ̀rá—ní ìpele èròjà cholesterol gíga nínú ẹ̀jẹ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọkùnrin ilẹ̀ Japan—tí ń jẹ ìpín 5 péré nínú ọgọ́rùn-ún lára èròjà afúnnilágbára wọn bí ògidì ọ̀rá—ní ìpele èròjà cholesterol rírẹlẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀. Ìwọ̀n tí àrùn ọkàn àyà sì fi ń kọ lu àwọn ọkùnrin ilẹ̀ Finland fi ìlọ́po mẹ́fà pọ̀ ju bí ó ṣe ń kọ lu àwọn ọkùnrin ilẹ̀ Japan lọ!

Bí ó ti wù kí ó rí, àrùn iṣan ẹ̀jẹ̀ ọkàn àyà kò ṣọ̀wọ́n mọ́ ní Japan. Ní àwọn ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, bí àwọn oúnjẹ àsárésèjẹ nínú àṣà Ìwọ̀ Oòrùn ti ń wọ́pọ̀ níbẹ̀, jíjẹ àwọn ọ̀rá ẹran ti lọ sókè dé ìpín 800 lórí ọgọ́rùn-ún. Nísinsìnyí, àwọn ọmọkùnrin ilẹ̀ Japan tilẹ̀ ní ìpele èròjà cholesterol gíga nínú ẹ̀jẹ̀ ju àwọn ọmọkùnrin ilẹ̀ America tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ wọn lọ! Ní kedere, ọ̀rá inú oúnjẹ àti èròjà cholesterol ní ń fa àwọn ipò tí ń wu ẹ̀mí léwu, ní pàtàkì, àrùn ọkàn àyà.

Ipa Tí Èròjà Cholesterol Ń Kó

Èròjà cholesterol jẹ́ ìda funfun, tí ó ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè. Ó wà nínú sẹ́ẹ̀lì gbogbo ẹ̀dá ènìyàn àti ti àwọn ẹranko. Ẹ̀dọ̀ wa ní ń ṣẹ̀dá èròjà cholesterol, ó sì wà ní ìwọ̀n yìyàtọ̀síra nínú oúnjẹ tí a ń jẹ. Ẹ̀jẹ̀ ń gbé èròjà cholesterol lọ sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ní ìwọ̀n àwọn molecule tí ń jẹ́ lipoprotein, tí wọ́n ní èròjà cholesterol, ọ̀rá, àti protein nínú. Oríṣi àwọn èròjà lipoprotein méjì tí ń gbé èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn èròjà cholesterol náà ni èròjà lipoprotein oníwọ̀n ìwúwo kékeré (LDL) àti àwọn èròjà lipoprotein oníwọ̀n ìwúwo ńlá (HDL).

Àwọn LDL ní ọ̀pọ̀ èròjà cholesterol nínú. Bí wọ́n ti ń káàkiri nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀, wọ́n ń gba inú àwọn ẹ̀yà tí ń gba LDL sára, tí ó wà lára sẹ́ẹ̀lì, wọnú àwọn sẹ́ẹ̀lì, wọn sì ń fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ kí àwọn sẹ́ẹ̀lì náà lè rí nǹkan lò. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara ní irú àwọn ẹ̀yà agbaǹkansára náà, wọ́n sì ń gba LDL mélòó kan sára. Ṣùgbọ́n a ṣẹ̀dá ẹ̀dọ̀ kí ó baà lè jẹ́ pé ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún yíyọ tí àwọn ẹ̀yà tí ń gba LDL sára yọ àwọn LDL kúrò nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

Ní ọwọ́ mìíràn, àwọn HDL jẹ́ molecule tí ń yán hànhàn fún èròjà cholesterol. Nígbà tí wọ́n bá ń gba inú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ kọjá, wọ́n máa ń fa àṣẹ́kù èròjà cholesterol mu, wọn óò sì gbé e lọ sínú ẹ̀dọ̀. Ẹ̀dọ̀ yóò wá tú èròjà cholesterol palẹ̀, yóò sì mú un kúrò lára. Nípa bẹ́ẹ̀, a pilẹ̀ ṣe ara náà lọ́nà àgbàyanu láti lò èròjà cholesterol tí ó nílò àti láti da ìyókù nù.

Ìṣòro náà máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí LDL bá pọ̀ jù nínú ẹ̀jẹ̀. Èyí ń mú kí ó túbọ̀ ṣeé ṣe fún kókó kan láti lè yọ sára awọ tí ó bo òpó tí ń gbẹ́jẹ̀ jáde láti inú ọkàn àyà. Nígbà tí kókó bá yọ, àwọn òpójẹ̀ ọkàn àyà náà yóò rí tóóró, ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ tí ń gbé afẹ́fẹ́ oxygen tí ó lè gba inú wọn kọjá yóò dín kù. Ipò yí ni a ń pè ní ìkójọpọ̀ ọ̀rá sínú iṣan ẹ̀jẹ̀. Ìgbésẹ̀ náà yóò máa bá a lọ díẹ̀díẹ̀ àti láìsí àmì kankan, tí èyí sì ń gba ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún kí ó tó gbé àwọn àmì àrùn tí ó ṣeé fòye mọ̀ jáde. Àmì àrùn kan ni àrùn angina pectoris, tàbí àyà ríro, irú èyí tí ó ṣe Joe.

Bí òpójẹ̀ ọkàn àyà kan bá dí pa pátápátá, tí ó sábà máa ń jẹ́ ìdìpọ̀ ẹ̀jẹ̀ ló máa ń fà á, apá ibi tí òpójẹ̀ náà ń gbé ẹ̀jẹ̀ lọ nínú ọkàn àyà yóò kú. Ìyọrísí rẹ̀ jẹ́ dídínà àárín awọ òpójẹ̀ ọkàn àyà lójijì, lọ́nà aṣekúpani—tí a mọ̀ dáradára sí ìkọlù ọkàn àyà. Kódà dídí òpójẹ̀ ọkàn àyà lápá kan lè pa iṣan ọkàn àyà, èyí tí ó lè máa gbé àwọn àmì àrùn bí àìfararọ tí ó ṣeé fojú rí yọ. Dídí àwọn òpójẹ̀ ní àwọn apá ibòmíràn nínú ara lè fa àrùn ẹ̀gbà, egbò kíkẹ̀ lẹ́sẹ̀, kódà, ó lè fa àìṣiṣẹ́mọ́ kíndìnrín pàápàá.

Kò yani lẹ́nu pé a ń pe LDL ní èròjà cholesterol tí kò dára, tí a sì ń pe HDL ní èròjà cholesterol tí ó dára. Bí LDL bá pọ̀ tàbí tí HDL bá kéré, ewu àrùn ọkàn àyà ga.a Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ kan lọ́nà rírọrùn sábà máa ń tọ́ka ewu tí ń bọ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ẹnì kan tó rí àmì àrùn tí ó ṣeé ṣàkíyèsí, bí àrùn angina. Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì láti ṣàkóso ìpele èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀ rẹ. Ẹ jẹ́ kí a wá wo bí oúnjẹ rẹ ṣe lè nípa lórí ìpele yìí.

Èròjà Cholesterol Inú Ẹ̀jẹ̀ àti Oúnjẹ

Èròjà cholesterol jẹ́ apá àdánidá kan nínú àwọn oúnjẹ tí a mú jáde lára ẹranko. Ẹran, ẹyin, ẹja, adìyẹ, àti àwọn ìpèsè tí ń wá láti ara ẹran ni gbogbo wọn ní èròjà cholesterol. Ní ọwọ́ mìíràn, àwọn oúnjẹ tí ó jáde láti ara irúgbìn kò ní èròjà cholesterol.

Ara ń mú gbogbo èròjà cholesterol tí ó nílò jáde, nítorí náà, èròjà cholesterol tí a bá jẹ nínú oúnjẹ jẹ́ àfikún. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára èròjà cholesterol inú oúnjẹ wa máa ń darí sínú ẹ̀dọ̀. Bí ó ti máa ń rí, bí èròjà cholesterol inú oúnjẹ ṣe ń wọnú ẹ̀dọ̀, ẹ̀dọ̀ máa ń lò ó, ó sì ń dín ìmújáde èròjà cholesterol tirẹ̀ kù. Èyí ń mú kí a lè ṣàkóso àpapọ̀ èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí ní ń ṣẹlẹ̀ tí oúnjẹ náà bá ní èròjà cholesterol tí ó pọ̀ gan-an débi pé ẹ̀dọ̀ kò lè tètè lò ó? Ó túbọ̀ ń mú kí ó ṣeé ṣe pé kí èròjà cholesterol wọnú àwọn sẹ́ẹ̀lì awọ òpójẹ̀ ní tààràtà. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìkójọpọ̀ ọ̀rá sínú iṣan ẹ̀jẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀. Ipò náà léwu ní pàtàkì nígbà tí ara bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìwọ̀n èròjà cholesterol kan náà láìka ìwọ̀n èròjà cholesterol inú oúnjẹ tí a jẹ sí. Ní United States, ẹnì 1 nínú ẹni 5 ló ní ìṣòro yìí.

Nígbà náà, dídín ìwọ̀n èròjà cholesterol inú oúnjẹ tí a ń jẹ kù jẹ́ ìgbésẹ̀ ọlọgbọ́n. Ṣùgbọ́n èròjà míràn nínú oúnjẹ wa ní ipa tí ó tilẹ̀ pọ̀ jù lórí ìpele èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀—ògidì ọ̀rá.

Ọ̀rá àti Èròjà Cholesterol

Àwọn ọ̀rá pín sí ìsọ̀rí méjì: ògidì àti àtọwọ́dá. Àwọn ọ̀rá àtọwọ́dá lè jẹ́ àtọwọ́dá onípò kíní tàbí àtọwọ́dá onípò kejì. Àwọn ọ̀rá àtọwọ́dá dára jù fún ọ ju èkejì rẹ̀ tí ó jẹ́ ògidì, níwọ̀n bí jíjẹ ògidì ọ̀rá ti ń mú kí ìpele èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀ ga. Ògidì ọ̀rá ń ṣe èyí ní ọ̀nà méjì: Wọ́n ń ṣèrànwọ́ láti ṣẹ̀dá èròjà cholesterol púpọ̀ sí i nínú ẹ̀dọ̀, wọ́n sì ń tẹ àwọn tí ń gba LDL sára lórí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀dọ̀ rì, èyí sì ń dín ìwọ̀n ìyára mímú LDL kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ kù.

Àwọn ògidì ọ̀rá ni a sábà máa ń rí nínú oúnjẹ tí ó wá láti ara ẹran, bíi bọ́tà, pupa inú ẹyin, ọ̀rá ẹlẹ́dẹ̀, mílíìkì, ice cream, ẹran, àti adìyẹ. Wọ́n tún wọ́pọ̀ nínú ṣokoléètì, àgbọn àti òróró rẹ̀, ewébẹ̀ tí a fi òróró sí, àti epo pupa. Àwọn ògidì ọ̀rá máa ń dì lábẹ́ ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù wíwà déédéé.

Ní ọwọ́ mìíràn, àwọn ọ̀rá àtọwọ́dá jẹ́ ohun olómi ní ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù wíwàdéédéé. Àwọn oúnjẹ tí wọ́n ní ọ̀rá àtọwọ́dá onípò kíní àti ọ̀rá àtọwọ́dá onípò kejì nínú lè ṣèrànwọ́ láti dín ìpele èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀ rẹ kù bí o bá fi wọ́n rọ́pọ̀ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ní ògidì ọ̀rá nínú.b Nígbà tí àwọn ọ̀rá àtọwọ́dá onípò kejì, tí ó wọ́pọ̀ nínú òróró àgbàdo àti hóró èso abóòrùnyí, ń dín èròjà cholesterol dáradára àti èyí tí kò dára kù, àwọn ọ̀rá àtọwọ́dá onípò kíní, tí wọ́n pọ̀ nínú òróró ólífì àti òróró canola, máa ń dín kìkì èròjà cholesterol tí kò dára kù láìfaragbún èròjà cholesterol dáradára.

Dájúdájú, ọ̀rá jẹ́ ohun pípọndandan nínú oúnjẹ wa. Fún àpẹẹrẹ, láìsí wọn, ara wa kò ní lè lo fítámì A, D, E, àti K. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwọ̀n ọ̀rá tí ara nílò kéré gan-an. Ó rọrùn láti rí wọn gbà nípasẹ̀ jíjẹ ewébẹ̀, ẹ̀wà, oúnjẹ oníhóró, àti èso. Nítorí náà, dídín ìwọ̀n ògidì ọ̀rá tí a ń jẹ kù kò fi èròjà aṣaralóore tí ara nílò dù ú.

Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Láti Dín Ọ̀rá àti Èròjà Cholesterol Kù

Oúnjẹ tí ó ní ọ̀rá àti èròjà cholesterol nínú yóò ha máa fìgbà gbogbo mú kí ìwọ̀n èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i bí? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Thomas, tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, pinnu láti lọ ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Jí! Àwọn àbáyọrí rẹ̀ fi hàn pé ìpele èròjà cholesterol rẹ̀ wà láàárín ààlà ìwọ̀n tí a fọkàn fẹ́. Ó hàn dájúdájú pé, ẹ̀dọ̀ rẹ̀ lè máa ṣàkóso ìpele èròjà cholesterol náà.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé Thomas ti bọ́ lọ́wọ́ ewu. Àwọn ìwádìí àìpẹ́ tọ́ka sí i pé, èròjà cholesterol inú oúnjẹ lè nípa lórí ewu àrùn iṣan ẹ̀jẹ̀ ọkàn àyà láìsí pé ó fara gbún ipa rẹ̀ lórí èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀. Dókítà Jeremiah Stamler, láti Yunifásítì Northwestern, sọ pé: “Àwọn oúnjẹ tí wọ́n ní èròjà cholesterol nínú ń dá kún àrùn ọkàn àyà kódà nínú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìwọ̀n èròjà cholesterol tí kò pọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn. Ìdí sì nìyẹn tí gbogbo ènìyàn fi gbọ́dọ̀ ṣàníyàn nípa jíjẹ ìwọ̀nba èròjà cholesterol díẹ̀, láìka ìpele tí èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀ wọn lè wà sí.”

Ọ̀ràn ti ọ̀rá nínú oúnjẹ tún wà níbẹ̀. Àpọ̀jù ọ̀rá nínú ẹ̀jẹ̀, yálà ògidì ọ̀rá tàbí ọ̀rá àtọwọ́dá nínú oúnjẹ, ń fa kí sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ máa ṣù pọ̀. Irú ẹ̀jẹ̀ tí ó nípọn bẹ́ẹ̀ kì í gba inú àwọn òpójẹ̀ wẹ́wẹ́ tí ó ṣe tóóró kọjá, tí èyí sì ń fi èròjà aṣaralóore tí àwọn ẹ̀yà ara nílò dù wọ́n. Àwọn sẹ́ẹ̀lì ṣíṣùpọ̀ tí ń lọ láàárín àwọn òpójẹ̀ tún ń dí ìgbékiri afẹ́fẹ́ oxygen lọ sínú àwọn òpójẹ̀ lọ́wọ́, tí èyí sì ń fa ìbàjẹ́ lókè, níbi tí kókó ti lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí í yọ. Ṣùgbọ́n ewu mìíràn tún wà nínú jíjẹ ìwọ̀n ọ̀rá púpọ̀ jù.

Àrùn Jẹjẹrẹ àti Oúnjẹ

Dókítà John A. McDougall sọ pé: “Gbogbo ọ̀rá—ògidì àti àtọwọ́dá—ń kópa nínú ìdàgbàsókè àwọn sẹ́ẹ̀lì àrùn jẹjẹrẹ kan.” Ìwádìí kan tí a ṣe káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè nípa àrùn jẹjẹrẹ ìfun ńlá àti àrùn jẹjẹrẹ ọmú fi àwọn ìyàtọ̀ dídániníjì hàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìwọ̀ Oòrùn, níbi tí ọ̀rá ti ń pọ̀ nínú oúnjẹ, àti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Fún àpẹẹrẹ, ní United States, àrùn jẹjẹrẹ ìfun colon ni irú àrùn jẹjẹrẹ tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ṣìkejì fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin lápapọ̀, nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ ọmú jẹ́ èyí tí ó wọ́pọ̀ jù lọ fún àwọn obìnrin.

Gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ Tí Ń Gbógun Ti Àrùn Jẹjẹrẹ ní America ti sọ, àwùjọ àwọn ènìyàn tí wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn jẹjẹrẹ ti pọ̀, wá ń ní ìwọ̀n àrùn jẹjẹrẹ bí ó ti wà ní orílẹ̀-èdè yẹn, èyí sì sinmi lórí bí àkókò tí ó gbà wọ́n láti yí pa dà sí ọ̀nà ìgbésí ayé àti ọ̀nà ìjẹun tuntun náà ti gùn tó. Ìwé ìgbọ́únjẹ ẹgbẹ́ tí ń gbógun ti àrùn jẹjẹrẹ náà sọ pé: “Àwọn ará Japan tí wọ́n ṣí lọ sí Hawaii ń ní àrùn jẹjẹrẹ lọ́nà tí àwọn ènìyàn ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ń gbà ní in: ìṣẹ̀lẹ̀ gíga àrùn jẹjẹrẹ ìfun colon àti ti àrùn jẹjẹrẹ ọmú, ìṣẹ̀lẹ̀ rírẹlẹ̀ fún àrùn jẹjẹrẹ ikùn—tí ó jẹ́ òdì kejì ọ̀nà tí ó ń gbà ṣẹlẹ̀ ní Japan.” Dájúdájú, àrùn jẹjẹrẹ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú oúnjẹ.

Bí oúnjẹ rẹ bá ní àpapọ̀ ọ̀rá, ògidì ọ̀rá, èròjà cholesterol, àti èròjà afúnnilágbára púpọ̀ nínú, o ní láti ṣe àwọn ìyípadà kan. Oúnjẹ dáradára lè ṣamọ̀nà sí ìlera pípé, ó sì tilẹ̀ lè yí àwọn àbájáde búburú oúnjẹ tí kò dára púpọ̀ pa dà. Lójú irú àwọn yíyàn tí ó burú bí iṣẹ́ abẹ tí ń lo òpójẹ̀ àtọwọ́dá bẹ́ẹ̀, tí ó sábà máa ń náni ní 40,000 dọ́là tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ń fọkàn fẹ́ èyí ní tòótọ́.

Nípa fífọgbọ́n yan ohun tí o ń jẹ, o lè dín ìwọ̀n ìsanra rẹ kù, kí o mú ìmọ̀lára rẹ sunwọ̀n sí i, kí o sì ran ara rẹ lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn àrùn kan tàbí kí o yí wọn pa dà. A jíròrò àwọn àbá nípa èyí nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ń díwọ̀n èròjà cholesterol ní iye mìlígíráàmù inú dẹ̀sílítà kọ̀ọ̀kan. Ìpele àpapọ̀ èròjà cholesterol tí a fọkàn fẹ́—àpapọ̀ LDL, HDL, àti èròjà cholesterol nínú àwọn èròjà lipoprotein míràn nínú ẹ̀jẹ̀—kò tó 200 mìlígíráàmù nínú dẹ̀sílítà kọ̀ọ̀kan. A ka ìpele HDL kan tí ó ní mìlígíráàmù 45 nínú dẹ̀sílítà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sí èyí tí ó dára.

b Ìlànà Ṣíṣọ́ Oúnjẹ Jẹ 1995 fún Àwọn Ará America dámọ̀ràn jíjẹ àpapọ̀ ọ̀rá tí kò ní ju ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún èròjà afúnnilágbára nínú lọ lójúmọ́, ó sì dámọ̀ràn dídín ògidì ọ̀rá kù sí ìwọ̀n tí kò tó ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún èròjà afúnnilágbára. Ẹ̀dín ìpín 1 nínú ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n èròjà afúnnilágbára inú ògidì ọ̀rá sábà máa ń ṣamọ̀nà sí ẹ̀dín mìlígíráàmù 3 nínú dẹ̀sílítà kan nínú ìpele èròjà cholesterol inú ẹ̀jẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwòrán àwọn òpójẹ̀ ọkàn àyà: (1) ó ṣí tán lódindi, (2) ó dí lápá kan, (3) ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dí pátápátá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́