Ìgbà Tí Kò Dára Láti Sanra
Rosa, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 35, kédàárò pé: “Àwọn aṣọ mi kò wọ̀ mí mọ́. Mo ti sanra tó kìlógíráàmù 86 nísinsìnyí, n kò sì finú wòye rí pé n óò tóbi tó bẹ́ẹ̀!”
ROSA nìkan kọ́ ní ń dààmú nípa bí ó ṣe ń sanra sí i. Ní United States tí ó ń gbé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámẹ́ta àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n sanra jọ̀bọ̀tọ̀.a Iye àwọn àgbàlagbà tí wọ́n sanra jọ̀bọ̀tọ̀ ní Britain ti di ìlọ́po méjì láàárín ọdún mẹ́wàá. Kódà ní Japan pàápàá—ibi tí ìsanrajù kò ti wọ́pọ̀ tẹ́lẹ̀—ìsanrajọ̀bọ̀tọ̀ ti ń wọ́ pọ̀.
Àwọn ọmọdé tí iye wọn ń pọ̀ sí i tóbi ju bí ó ṣe yẹ lọ. Nǹkan bíi mílíọ̀nù 4.7 lára àwọn èwe America tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún 6 sí 17 ni wọ́n sanra jù, nígbà tí nǹkan bí ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọdé ilẹ̀ Kánádà sanra jọ̀bọ̀tọ̀. Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, ìsanrajọ̀bọ̀tọ̀ nígbà ọmọdé ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po mẹ́ta ní Singapore.
Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, jíjẹ́ ẹni títóbi nítorí sísanra ni a wò bí ẹ̀rí ìníláárí àti ìlera pípé, ipò tí àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí ju ipò òṣì àti àìjẹunrekánú lọ. Ṣùgbọ́n ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn, níbi tí oúnjẹ ti wà ní sẹpẹ́, wọn kì í sábà ka sísanra sí ohun fífẹ́. Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, ní gbogbogbòò, ó jẹ́ okùnfà àníyàn gidi. Èé ṣe?
Dókítà C. Everett Koop, ọ̀gá àgbà oníṣègùn iṣẹ́ abẹ ní United States tẹ́lẹ̀ rí, sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn gbà gbọ́ pé ìsanrajọ̀bọ̀tọ̀ jẹ́ ìṣòro ìrísí ẹni, ní gidi, àrùn lílekoko kan ló jẹ́.” Onímọ̀ nípa ẹṣẹ́ tí ń tú àwọn èròjà ara sínú ẹ̀jẹ̀ náà, F. Xavier Pi-Sunyer, láti New York, ṣàlàyé pé: “[Sísanra àwọn ènìyàn ní America] ń fi púpọ̀ lára wọn sínú ewu àrùn àtọ̀gbẹ, ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ẹ̀gbà, àrùn ọkàn àyà, àti irú àwọn àrùn jẹjẹrẹ kan pàápàá.”
Sísanrajù Ń Mú Ewu Púpọ̀ Wá
Gbé ìwádìí kan tí a ti lo 115,000 obìnrin nọ́ọ̀sì tí wọ́n jẹ́ ará America, tí a fún ní àfiyèsí fún ọdún 16 yẹ̀ wò. Ìwádìí náà fi hàn pé, nígbà tí àwọn àgbàlagbà bá tilẹ̀ sanra sí i ní ìwọ̀n kìlógíráàmù márùn-ún sí mẹ́jọ pàápàá, ó ń yọrí sí ewu gíga jù ti àrùn ọkàn àyà. Ìwádìí yìí, tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine ti September 14, 1995, tọ́ka pé, ìdámẹ́ta nínú àwọn tí àrùn jẹjẹrẹ ń pa, àti ìdajì àwọn tí àrùn ọkàn àyà òun iṣan ẹ̀jẹ̀ ń pa ló jẹ́ nítorí ìsanrajù. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association (JAMA) ti May 22/29, 1996, ti sọ, “ìpín 78 nínú ọgọ́rùn-ún ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru láàárín àwọn ọkùnrin àti ìpín 65 láàárín ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ni a lè sọ ní tààràtà pé ìsanrajọ̀bọ̀tọ̀ ló fà á.” Ẹgbẹ́ Tí Ń Gbógun Ti Àrùn Jẹjẹrẹ ní America sọ pé, àwọn tí wọ́n “sanra jù lọ́nà lílámì” (àwọn tí wọ́n fi ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sanra ju ìwọ̀n yíyẹ lọ) “wà nínú ewu níní àrùn jẹjẹrẹ jù.”
Àmọ́ kì í wulẹ̀ ṣe pé sísanra sí i ni ó léwu; àwọn ibi tí ọ̀rá wà nínú ara pẹ̀lú ń nípa lórí ewu àrùn. Àwọn tí wọ́n ní àpọ̀jù ọ̀rá ní ikùn wà nínú ewu tí ó ga ju ti àwọn tí wọ́n sanra sí ìgbáròkó àti itan ní gidi. Ọ̀rá ní àyíká ikùn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ewu àtọ̀gbẹ, àrùn ọkàn àyà, jẹjẹrẹ ọmú, àti jẹjẹrẹ ilé ọlẹ̀ lọ́nà púpọ̀ sí i.
Bákan náà, àwọn èwe tí wọ́n sanra jù ń ní àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru, ìwọ̀n èròjà cholesterol gíga, àti ipò àìbáradé tí ń ṣáájú níní àrùn àtọ̀gbẹ. Wọ́n sì sábà máa ń sanra jọ̀bọ̀tọ̀ tí wọ́n bá dàgbà. Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ń lo ìsọfúnni oníṣirò tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn ìṣègùn ti Britain náà, The Lancet, ó ròyìn pé, “àwọn ènìyàn tí wọ́n sanra nígbà ọmọdé máa ń tètè kú, wọ́n sì máa ń ní àrùn púpọ̀ gan-an nígbà tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré gan-an ju àwọn aráàlú ní gbogbogbòò.”
Àwọn Ìlànà Tuntun Nípa Ìsanra
Nígbà tí ìjọba United States rí i dájú pé ìṣòro eléwu kan wà nípa ìsanra, ó mú kí ìwọ̀n ìlànà ìsanra tí ó dámọ̀ràn ní 1995 túbọ̀ le. (Wo àpótí ní ojú ìwé tí ó kàn.) Àwọn ìlànà tí a mú bágbà mu tọ́ka sí “ìwọ̀n ìsanra tí ó bójú mu,” “ìwọ̀n ìsanrajù tí ó wà déédéé,” àti “ìwọ̀n ìsanrajù tí ó burú.” Ìlànà náà kan àwọn àgbàlagbà ọkùnrin àti obìnrin lápapọ̀, láìka ọjọ́ orí wọn sí.
Ìlànà tí wọ́n ṣe ní 1990 fàyè sílẹ̀ fún títóbi ní agbedeméjì ara lẹ́yìn pípé ogójì ọdún, tí a sábà máa ń pè ní ìsanra ẹ̀yìn pípé ogójì ọdún. Àwọn ìlànà tuntun náà kò fi àyè yí sílẹ̀ níwọ̀n bí àwọn ìtọ́ka ti fi hàn pé, kò yẹ kí àwọn àgbàlagbà jèrè ìwọ̀n ìsanra pẹ̀lú bí àkókò ti ń lọ.b Nípa bẹ́ẹ̀, ẹnì kan tí a kà sí ẹni tí ìwọ̀n ìtóbi rẹ̀ dára tẹ́lẹ̀ lè wá rí ara rẹ̀ ní ẹgbẹ́ àwọn tí wọ́n sanra jù nísinsìnyí. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan tí ó ga ní sẹ̀ǹtímítà 168 tí ó wà láàárín ọdún 35 sí 65 tí ó wọn kìlógíráàmù 75 ì bá ti wà ní ìsọ̀rí ìwọ̀n ìsanra tí ó bójú mu lábẹ́ ìlànà ti 1990. Ṣùgbọ́n lábẹ́ ìlànà tuntun náà, yóò fi kìlógíráàmù márùn-ún sanra jù!
Báwo Ni A Ṣe Di Ẹni Sísanra Tó Bẹ́ẹ̀?
Àwọn apilẹ̀ àbùdá tí a jogún lè nípa lórí ìtẹ̀sí ẹnì kan láti sanra jọ̀bọ̀tọ̀, àmọ́ àwọn kọ́ ló ń fa sísanra ní àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìwọ̀ Oòrùn. Ohun mìíràn ló ń fa ìṣòro náà.
Àwọn amọṣẹ́dunjú nínú ọ̀ràn ìlera gbà pé jíjẹ ohun ọlọ́ràá lè mú wa sanra. Ẹran púpọ̀ àti àwọn ìpèsè tí ń wá láti ara ẹran, àwọn oúnjẹ yíyan, oúnjẹ àsárésèjẹ, oúnjẹ ìpápánu, oúnjẹ dídín, omi ọbẹ̀, omi ẹran tí a fi sebẹ̀, àti ohun elépo kún fún ọ̀rá, jíjẹ wọ́n sì lè yọrí sí sísanrajọ̀bọ̀tọ̀. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Ó dára, jíjẹ àwọn èròjà afúnnilágbára púpọ̀ nínú oúnjẹ wa, ju èyí tí ara wa ń lò lọ, ń mú kí a sanra. Àwọn èròjà ọlọ́ràá ní èròjà afúnnilágbára mẹ́sàn-án nínú gíráàmù kọ̀ọ̀kan, ní ìfiwéra pẹ̀lú èròjà afúnnilágbára mẹ́rin nínú gíráàmù kan èròjà protein tàbí gíráàmù kan èròjà carbohydrate. Nítorí náà, a ń gba èròjà afúnnilágbára púpọ̀ nígbà tí a bá ń jẹ ohun ọlọ́ràá. Ṣùgbọ́n kókó abájọ pàtàkì míràn wà—ọ̀nà tí ara ẹ̀dá ènìyàn ń gbà lo agbára tí ó ń rí láti inú àwọn èròjà carbohydrate, protein, àti èròjà ọlọ́ràá. Ara máa ń kọ́kọ́ lo èròjà carbohydrate àti protein, lẹ́yìn náà ni yóò lo èròjà ọlọ́ràá. Àwọn èròjà ọlọ́ràá afúnnilágbára tí kò lò ní ó ń sọ di ọ̀rá inú ara. Nítorí náà, dídín àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá kù ni ọ̀nà pàtàkì kan láti dín ìwọ̀n ìsanra kù.
Síbẹ̀, àwọn kan tí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ti dín iye ọ̀rá tí àwọn ń jẹ kù rí i pé ara àwọn ṣì ń tóbi. Kí ló fà á? Ìdí kan ni pé wọ́n ń jẹ oúnjẹ púpọ̀ jù. Ẹnì kan tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore ní United States sọ pé: “A ń jẹun ju bó ṣe yẹ lọ nítorí pé ohun tí wọ́n ń gbé sílẹ̀ fún jíjẹ ti pọ̀ jù. Ohun tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó là ń jẹ.” Ó tún jọ pé àwọn ènìyàn ń jẹ àwọn oúnjẹ oníwọ̀nba-ọ̀rá-nínú tàbí èyí tí kò lọ́ràá nínú lájẹjù. Ṣùgbọ́n ògbóǹkangí kan tí ń bá ilé iṣẹ́ apèsè òye iṣẹ́ ìṣèmújáde oúnjẹ kan ní United States ṣiṣẹ́ ṣàlàyé pé: “Ìmújáde èròjà tí a dín ọ̀rá inú rẹ̀ kù sábà máa ń mú kí ìtọ́wò sunwọ̀n sí i nípa mímú kí ṣúgà [eléròjà afúnnilágbára] pọ̀ sí i.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé: “Àwọn ìtẹ̀sí méjì ní àwọn ọdún 1990—fífi owó ra nǹkan púpọ̀ rẹpẹtẹ àti jíjẹ oúnjẹ tí kò lọ́ràá púpọ̀ nínú, tàbí èyí tí kò lọ́ràá nínú—ti di ohun tí ń súnni jẹ àjẹkì,” tí ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ sinni sí sísanra.
Ìgbésí ayé ìjókòó-gẹlẹtẹ tún máa ń dá kún sísanra. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Britain ṣàwárí pé, ó lé ní ìdámẹ́ta àwọn àgbàlagbà tí ń gbé ilẹ̀ yẹn tí kì í ṣeré ìmárale tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó 20 ìṣẹ́jú lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kò tó ìdajì wọn tí ó tí ì kópa rí nínú àwọn eré ìdárayá àfigbogbo-ara-ṣe. Fífi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rìnrìn àjò ti rọ́pò fífẹsẹ̀rìn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn, wíwo tẹlifíṣọ̀n jù lọ́nà púpọ̀ sí i sì ń fún ìmẹ́lẹ́ àti àjẹkì níṣìírí. Ní United States, àwọn ọmọ máa ń jókòó ti tẹlifíṣọ̀n, tí wọ́n sì máa ń wò ó fún iye àkókò tí a fojú díwọ̀n sí wákàtí 26 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, láìka àkókò tí wọ́n ń lò nídìí àwọn eré àṣedárayá orí fídíò mọ́ ọn. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan bí ìpín 36 nínú ọgọ́rùn-ún péré lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà ṣì ní ẹ̀kọ́ eré ìmárale.
Àwọn ìdí ti ó tan mọ́ ìrònú òun ìhùwà tí ó máa ń fa sísanrajù tún wà níbẹ̀. Dókítà Lawrence Cheskin, ti Ibùdó Àbójútó Ìwọ̀n Ìsanra ti Johns Hopkins, sọ pé: “A máa ń jẹun ré kọjá ààlà àwọn àìní èrò ìmọ̀lára wa. A máa ń jẹun nígbà tí inú wa bá ń dùn, a máa ń jẹun nígbà tí inú wa bá bà jẹ́. A ti dàgbà lọ́nà kan tí a fi gbà gbọ́ pé oúnjẹ jẹ́ àfirọ́pò fún ọ̀pọ̀ ohun mìíràn.”
A Ha Lè Ṣàṣeyọrí Bí?
Ọ̀ràn ti sísanrajù díjú pọ̀. Lọ́dọọdún, àwọn 80 mílíọ̀nù tí a fojú bù ní America ní ìlànà ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ. Àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ń pa dà sí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jẹun tẹ́lẹ̀ rí gbàrà lẹ́yìn tí ìwọ̀n ìsanra wọn bá ti dín kù díẹ̀. Láàárín ọdún márùn-ún, ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún ń jèrè ìwọ̀n ìsanra tí wọ́n pàdánù tẹ́lẹ̀.
Ohun tí a nílò láti dín ìwọ̀n ìsanra kù, kí a sì má sanra ni yíyí ọ̀nà ìgbésí ayé wá pa dà. Irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ béèrè fún ìsapá àti ìfarajìn, pa pọ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a lè nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọ́n mọṣẹ́ ìlera dunjú pẹ̀lú.c Bí ó ti wù kí ó rí, kí ìsapá rẹ lè yọrí sí rere, ìsúnniṣe olójú ìwòye títọ́ jẹ́ kòseémánìí. Ó dára láti bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ló dé tí mo fẹ́ dín ìwọ̀n ìsanra mi kù?’ Ó ṣeé ṣe gan-an kí àwọn ìsapá rẹ láti dín ìwọ̀n ìsanra rẹ kù yọrí sí rere bí ìfẹ́ ọkàn láti wà ní ipò dídára, kí o sì ní ìrísí dídára àti láti mú kí ìjójúlówó ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i, bá ń wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn láti yẹra fún àwọn ewu ìlera.
O lè jẹ ọ̀pọ̀ oúnjẹ aládùn, tí ó sì ń tẹ́ni lọ́rùn, tí ń ṣara lóore, tí ó sì ní ìwọ̀n èròjà afúnnilágbára díẹ̀ nínú. Ṣùgbọ́n kí o tó gbé oúnjẹ tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dín ìwọ̀n ìsanra rẹ kù yẹ wò, jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò bí àwọn èròjà kan nínú oúnjẹ ṣe lè di ewu fún ìlera.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A sábà máa ń túmọ̀ ìsanrajọ̀bọ̀tọ̀ sí fífi ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tóbi ju ohun tí a gbà gbọ́ pé ó jẹ́ ìwọ̀n ìsanra yíyẹ.
b Ìlànà ti 1995 náà kan ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀wọ́ ọjọ́ orí, àmọ́ kì í ṣe gbogbo rẹ̀. Dókítà Robert M. Russell sọ nínú ìwé ìròyìn JAMA ti June 19, 1996, pé: “Ìfohùnṣọ̀kan wà pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìlànà ìwọ̀n ìsanra tuntun náà má kan àwọn tí ọjọ́ orí wọn lé ní ọdún 65. Ìwọ̀n ìsanrajù díẹ̀ nínú ẹni tí ó túbọ̀ dàgbà náà tilẹ̀ lè ṣàǹfààní nípa pípèsè agbára àfipamọ́ fún àwọn àkókò àìlera àti nípa ṣíṣèrànwọ́ láti dáàbò bo ìṣùjọ iṣan àti egungun.”
c Fún ìmọ̀ràn lórí dídín ìwọ̀n ìtóbi kù, wo Jí!, May 8, 1994, ojú ìwé 20 sí 22; January 22, 1993, ojú ìwé 12 sí 14; àti June 8, 1990, ojú ìwé 3 sí 12.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 6]
Ṣé ìṣọ̀rí “ìwọ̀n ìsanra tí ó bójú mu,” “ìwọ̀n ìsanra tí ó wà déédéé,” tàbí ti “ìwọ̀n ìsanra tí ó burú,” ni o wà? Àwòrán tí a fi hàn níhìn-ín yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn
Ìwọ̀n Ìlànà Ìsanra ti 1995 fún Tọkùnrintobìnrin
Ìwọ̀n gíga*
198cm
190cm
180cm
170cm ÌWỌ̀N ÌSANRA TÍ Ó BÓJÚ MU ÌWỌ̀N ÌSANRA TÍ Ó WÀ DÉÉDÉÉ ÌWỌ̀N ÌSANRA TÍ Ó BURÚ
160cm
150cm
30kg 40kg 50kg 60kg 70kg 80kg 90kg 100kg 110kg
Ìwọ̀n ìsanra†
Ìṣirò tí a gbé karí ìsọfúnni: U.S. Department of Agriculture, U.S. Department of Health and Human Services
* Láìwọ bàtà.
† Láìwọṣọ. Àwọn tí wọ́n ní iṣan ara àti egungun púpọ̀, bí ó ti rí nínú ọ̀pọ̀ ọkùnrin, ni ìwọ̀n ìsanra gíga kàn.