ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 11/8 ojú ìwé 10-12
  • Ǹjẹ́ Àǹfààní Kankan Wà Nínú Kéèyàn Dín Bó Ṣe Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Kù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Àǹfààní Kankan Wà Nínú Kéèyàn Dín Bó Ṣe Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Kù?
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbà Tí Kò Dára Láti Sanra
    Jí!—1997
  • Kí Ló Ń Jẹ́ Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?
    Jí!—2004
  • Ṣé Ìṣòro Ni Pé Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?
    Jí!—2004
  • Kí Lẹni Tó Bá Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Lè Rí Ṣe Sí I?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 11/8 ojú ìwé 10-12

Ǹjẹ́ Àǹfààní Kankan Wà Nínú Kéèyàn Dín Bó Ṣe Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Kù?

AṢOJÚ ìwé ìròyìn Jí! fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn èèyàn mélòó kan tí wọ́n ti borí àwọn ìṣòro tí sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ fà. Ṣé wọ́n kẹ́sẹ járí? Ìdámọ̀ràn wo ni wọ́n ní fún àwọn míì tí ìṣòro kárí ayé yìí ń yọ lẹ́nu?

◼ Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Míke, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta tí gíga ẹ̀ jẹ́ sẹ̀ǹtímítà mẹ́tàlélọ́gọ́sàn-án [183] tàbí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà, tó sì tẹ̀wọ̀n tó àádóje [130] kìlógíráàmù tàbí nǹkan bí àpò sìmẹ́ǹtì méjì àtààbọ̀ ní báyìí sọ. Ó ti tẹ̀wọ̀n tó kìlógíráàmù mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ [157] rí, ìyẹn ni pé ó wúwo tó nǹkan bí àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́ta.

Mike: “Kódà, nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, mo ki ju bó ṣe yẹ lọ. Bí gbogbo wa ṣe rí nínú ìdílé wa nìyẹn, bùrọ̀dá mi àtàwọn àǹtí mi méjèèjì àti àbúrò mi obìnrin náà sanra. Ó ti mọ́ wa lára pé ká máa jẹ́ gbogbo oúnjẹ tó bá wà nínú àwo wa tán, ì báà tiẹ̀ ga gègèrè. Kí ló mú kí n yí ọ̀nà tí mò ń gbà jẹun padà? Sísọ tí dókítà sọ fún mi pé mo máa ní àrùn àtọ̀gbẹ ni! Ti pé kí n máa gba abẹ́rẹ́ insulin sára títí ayé dẹ́rù bà mí gan-an ni. Mo tún ní ìṣòro àpọ̀jù èròjà cholesterol nínú ara, mo sì ti ń lo oògùn sí i.

“Iṣẹ́ ìjókòó ni mò ń ṣe, kò sì tíì yí padà. Ìyẹn ló mú kí n máa ṣe eré ìmárale déédéé, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wa kẹ̀kẹ́ àkànṣe kan tí wọ́n fi ń ṣeré ìmárale ní àwàlàágùn fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, ní ìgbà mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́sẹ̀. Ìgbésẹ̀ pàtàkì tí mo gbé tẹ̀ lé ìyẹn ni ṣíṣe àkọsílẹ̀ ohun tí mò ń jẹ lójoojúmọ́. Níwọ̀n bí mo ti mọ̀ pé ògbógi onímọ̀ nípa oúnjẹ á wo àkọsílẹ̀ yẹn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, mo máa ń kó ara mi níjàánu. Èrò tó máa ń wá sọ́kàn mi ni pé, ‘Bí o kì í bá jẹ ẹ́, o ò wulẹ̀ ní kọ ọ́ sílẹ̀!’

“Gẹ́gẹ́ bí àbájáde èyí, mo ti fi kìlógíráàmù méjìdínlọ́gbọ̀n joro sí i níwọ̀n oṣù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó kọjá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí n joro sí i. Ó wù mí pé kí n já wálẹ̀ sí kìlógíráàmù méjìlélọ́gọ́rùn-ún. Kó bàa lè ṣeé ṣe, mo ti jáwọ́ nínú jíjẹ àwọn oúnjẹ pàrùpárù, ànàmọ́ díndín àtàwọn oúnjẹ mìíràn tí wọ́n máa ń dín. Ewébẹ̀ tútù àti ẹ̀fọ́ tí mo ti jẹ láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn pọ̀ ju èyí tí mo tíì jẹ rí látọjọ́ tí mo ti dáyé!

“Ohun mìíràn tó fà á tí mo fi fẹ́ dín bí mo ṣe sanra kù ni pé gẹ́gẹ́ bí awakọ̀ akẹ́rù, dandan ni kí n máa ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ dókítà lọ́dọọdún bí mo bá fẹ́ sọ ìwé àṣẹ ìwakọ̀ mi dọ̀tun. Bí mo bá ní àrùn àtọ̀gbẹ pẹ́nrẹ́n, wọ́n lè gba ìwé àṣẹ ìwakọ̀ lọ́wọ́ mi. Nǹkan ti wá yí padà báyìí ṣá o. Mi ò nílò àtimáa lo oògùn mọ́ nítorí àtidín ìwọ̀n èròjà cholesterol tó wà lára mi kù. Ìfúnpá mi ti wálẹ̀, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ lo oògùn sí i mọ́. Mo ní okun púpọ̀ sí i, ẹ̀yìn tó sì máa ń ro mí goorogo ò fi bẹ́ẹ̀ yọ mí lẹ́nu mọ́. Èmi náà sì ti ń kúrò lágbo àwọn tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ báyìí!”

Jí!: “Ṣé ìyàwó ẹni lè kópa pàtàkì nínú dídín béèyàn ṣe sanra kù?”

Mike: “Nígbà tó o bá ń kojú ìṣòro kíki pọ́pọ́ ju bó ṣe yẹ lọ, o nílò ẹni tí yóò máa tì ọ́ lẹ́yìn. Ìyàwó mi rò pé ìfẹ́ jíjinlẹ̀ lòun ń fi hàn sí mi nípa bíbọ́ tó ń bọ́ mi yó dáadáa. Ṣùgbọ́n, ní báyìí o, ó ti ń dín oúnjẹ tó ń bù fún mi kù. Èmi náà ò sì gbọ́dọ̀ jẹ àjẹjù, nítorí pé bí mo bá jẹ àjẹjù pẹ́nrẹ́n, màá tún sanra sí i.”

◼ Ronú nípa ọkùnrin mìíràn kan tó ń jẹ́ Mike, láti ìpínlẹ̀ Kansas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógójì ni, gíga rẹ̀ sì jẹ́ sẹ̀ǹtímítà mẹ́tàléláàádọ́sàn-án [173], ìyẹn nǹkan tó fẹ́rẹ̀ tó bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà. A ṣèwádìí nípa bó ṣe tẹ̀wọ̀n tó àtàwọn nǹkan tó fà á tó fi ki tó bẹ́ẹ̀.

Mike: “Mo ti tẹ̀wọ̀n tó kìlógíráàmù márùnléláàádóje [135] rí, ìyẹn ni pé mo wúwo ju àpò sìmẹ́ǹtì méjì àtààbọ̀ lọ. Ó sábà máa ń rẹ̀ mí gan-an, n kì í sì í ní agbára láti ṣe ohunkóhun. N kì í róorun sùn nítorí pé ó máa ń ṣòro fún mi láti mí. Nítorí náà, mo lọ sọ́dọ̀ dókítà, nígbà tó sì yẹ̀ mí wò tán, ó rí i pé ọ̀kan lára ohun tó mú kí n sanra jọ̀kọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ìṣòro síséèémí lójú oorun.a Ó tún rí i pé ìfúnpá mi ga.”

Jí!: “Báwo lo ṣe wá yanjú àwọn ìṣòro náà?”

Mike: “Dókítà ní kí n máa lo ohun èlò kan tó máa ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ ráyè kọjá sọ́nà ọ̀fun mi dáadáa nígbà tí mo bá ń sùn. Ìyẹn ni kì í jẹ́ kí ọ̀nà ọ̀fun mi dí, tó sì máa ń jẹ́ kí n lè mí dáadáa. Nítorí náà, ara mi máa ń gbé kánkán bí ojúmọ́ bá ti mọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í jò. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí wa kẹ̀kẹ́ àkànṣe tí wọ́n fi ń ṣeré ìmárale lẹ́ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀. Mo sì ń ṣọ́ oúnjẹ tí mò ń jẹ, ìyẹn ni pé mo máa ń jẹun níwọ̀nba, n kì í sì í padà lọ bu abọ́ oúnjẹ kejì. Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, mo ti fi ogún kìlógíráàmù joro sí i ní ọdún kan ó lé díẹ̀ péré, mo ṣì fẹ́ kí n fi ogún kìlógíráàmù mìíràn joro sí i. Díẹ̀díẹ̀ ni, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé màá ṣe é.”

Jí!: “Kí ni ohun mìíràn tó tún mú kó o fẹ́ láti dín bó o ṣe sanra kù?”

Mike: “Kì í bá èèyàn lára mu bó bá ń gbọ́ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ nípa bí ara rẹ̀ ṣe rí. Àwọn èèyàn á kàn máa rò pé òkú ọ̀lẹ lásán ni olúwarẹ̀. Wọn ò mọ̀ pé oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń fa kéèyàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Ní tèmi o, mo gbà pé ara nǹkan tó lè fa ìṣòro náà ni irú apilẹ̀ àbùdá tí mo ní, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nínú ìdílé wa, àwa tá a sanra jọ̀kọ̀tọ̀ la pọ̀ jù.

“Àmọ́ ṣá o, mo gbà pé kí n bàa lè dín bí mo ṣe sanra kù, mi ò gbọ́dọ̀ máa jókòó sójú kan ṣáá mo sì gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ oúnjẹ tí mo bá ń jẹ.”

◼ Aṣojú ìwé ìròyìn Jí! tún fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu Wayne, ọmọ ọdún méjìdínlógójì tó wá láti ìpínlẹ̀ Oregon. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n, ó tẹ̀wọ̀n tó kìlógíráàmù méjìléláàádọ́fà [112], ìyẹn ni pé ó wúwo ju àpò sìmẹ́ǹtì méjì lọ.

Wayne: Iṣẹ́ ìjókòó ni mò ń ṣe, n kì í sì í ṣeré ìdárayá. Nígbà tí mo tọ dókítà mi lọ, ẹ̀rù bà mí nígbà tó sọ fún mi pé mo ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, tó sì tún sọ pé àyà lè bẹ̀rẹ̀ sí dùn mí. Ó ní kí n lọ rí ògbógi nípa oúnjẹ. Ògbógi náà ní kí n máa ṣeré ìmárale déédéé, ó sì sọ ìwọ̀n oúnjẹ tí mo gbọ́dọ̀ máa jẹ fún mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ rin ìrìn kìlómítà márùn-ún lóòjọ́, mo sì máa ń tètè jí lóròòwúrọ̀ kí n lè ṣeré ìdárayá. Mo ní láti bá ara mi sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mò ń jẹ àti ohun tí mò ń mu. Mo jáwọ́ nínú jíjẹ àwọn oúnjẹ pàrùpárù, mo dín búrẹ́dì àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí mo máa ń mu kù, mo sì fi ọ̀pọ̀ èso àti ẹ̀fọ́ rọ́pò wọn. Mo ti wá jò báyìí, mi ò sì tẹ̀wọ̀n ju ọgọ́rin kìlógíráàmù (tó fi díẹ̀ wúwo ju àpò sìmẹ́ǹtì kan àbọ̀) lọ!”

Jí!: “Àwọn àǹfààní wo lo ti wá rí látinú jíjò tó o jò yìí?”

Wayne: “Mo rí i pé ara mi le sí i, ó sì tún dá ṣáṣá bó ṣe rí kó tó di pé mo sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Tẹ́lẹ̀, ńṣe ló dà bí ẹni pé mo ti kú sára, àfi bíi pé ara mi ti bẹ̀rẹ̀ sí kọṣẹ́. Àǹfààní míì ni pé mi ò lo oògùn tí mò ń lò nítorí ìfúnpá tó ga mọ́. Ojú ò sì tì mí mọ́ bí mo bá rí àwọn èèyàn, nítorí pé mo mọ̀ pé kò sẹ́ni tá á máa fi bú mi pé mo tóbi ju bó ṣe yẹ lọ.”

◼ Charles (kì í ṣe orúkọ ẹ̀ gan-an) ga tó sẹ̀ǹtímítà mẹ́rìndínnígba [196], ìyẹn nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà àbọ̀. Ó ti wọ̀n tó kìlógíráàmù méjìdínláàádọ́sàn-án [168] rí, ìyẹn ni pé ó wúwo ju àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́ta lọ.

Charles: “Oríṣiríṣi àìsàn bẹ̀rẹ̀ sí kọ lù mí, ó sì ń burú síwájú àti síwájú sí i. Mi ò lè gun òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì. Agbára tó yẹ kí n fi ṣiṣẹ́ ò sí mọ́. Iṣẹ́ ìjókòó ni mò ń ṣe, iṣẹ́ náà sì dá lé ṣíṣe ìwádìí àti àwọn ohun àìgbọ́dọ̀máṣe mìíràn. Mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan nípa bí mo ṣe sanra jọ̀kọ̀tọ̀, pàápàá lẹ́yìn tí mo ti lọ rí dókítà mi. Ó kìlọ̀ fún mi pé bí mi ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí i, àrùn rọpárọsẹ̀ lè kọ lù mí. Mo mọ bí àrùn náà ṣe ń ṣe àwọn èèyàn. Ìyẹn gan-an ló wá jẹ́ kí n rí i pé mo gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Dókítà mi ní kí n máa ṣeré ìdárayá nípa wíwa kẹ̀kẹ́ àkànṣe tí wọ́n fi ń ṣeré ìmárale, kò sì yé wẹ́yìn mi wò. Ó sì tún yan irú oúnjẹ tí mo gbọ́dọ̀ máa jẹ fún mi. Wàyí o, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, bí mo ṣe tẹ̀wọ̀n tó ti dín kù sí kìlógíráàmù mẹ́rìndínlógóje [136], ìyẹn ò wúwo ju àpò sìmẹ́ǹtì méjì àtààbọ̀ lọ, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ dín kù sí i. Àwọn àǹfààní tí mo ti rí níbẹ̀ bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí ti mú kí n rí i pé ó dáa kéèyàn ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti dín bó ṣe sanra kù. Mo lè gun òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì báyìí, mo sì ní okun púpọ̀ sí i.”

◼ Marta, tó wá láti orílẹ̀-èdè El Salvador, sanra débi tó fi wọn kìlógíráàmù mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83]. Èyí mú kí wọ́n kà á sí ẹni tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ nítorí pé ó ga tó sẹ̀ǹtímítà márùnlélọ́gọ́jọ, ìyẹn nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún àbọ̀.

Marta: “Mo lọ bá dókítà, ó sì sọ fún mi pé mo gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dín bí mo ṣe sanra kù láìjáfara. Mo fara mọ́ ohun tó sọ gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Ó ní kí n lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹnì kan tó mọwá mẹ̀yìn oúnjẹ. Obìnrin tí mo lọ bá náà ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé fún mi nípa irú àwọn oúnjẹ tó sọ pé kí n máa jẹ. Ó ṣàlàyé bí mo ṣe lè máa dín oúnjẹ mi kù àti bí mo ṣe lè máa ṣọ́ oúnjẹ jẹ. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ní kí n wá máa rí òun lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀; nígbà tó yá, lóṣooṣù, kó lè máa rí bí ìyípadà ṣe ń bá ara mi sí. Dókítà náà àti obìnrin yìí jùmọ̀ fún mi níṣìírí nítorí ìyípadà tí wọ́n kíyè sí lára mi. Nígbà tó ṣe, bí ara mi ṣe tẹ̀wọ̀n sí ti fi kìlógíráàmù méjìlá dín kù, látìgbà náà ni bí mo ṣe tẹ̀wọ̀n tó ti wà ní kìlógíráàmù méjìdínláàádọ́rin èyí tó fi díẹ̀ wúwo ju àpò sìmẹ́ǹtì kan lọ.”

Jí!: “Ṣé o máa ń ṣeré ìmárale, irú àwọn oògùn wo lo sì ń lò?”

Marta: “Mi ò ní ìṣòro àpọ̀jù cholesterol nínú ara, nítorí náà n kì í lo oògùn sí i. Àmọ́, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí rìn kánmọ́kánmọ́ lójoojúmọ́ báyìí.”

Jí!: “Kí lo máa ń ṣe bó o bá lọ kí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ, tí wọ́n sì fi dandan lé e pé kó o jẹ oúnjẹ tó pọ̀ ju èyí tó o máa ń jẹ lọ?”

Marta: “Màá wulẹ̀ sọ fún wọn pé, ‘Dókítà mi ò fẹ́ kí n máa jẹ ju báyìí báyìí lọ nítorí ìlera mi,’ bí wọ́n bá sì ti gbọ́ bẹ́ẹ̀ àwọn náà á dákẹ́.”

Nítorí náà, bó o bá ki pọ́pọ́ jù tàbí bó o bá sanra jọ̀kọ̀tọ̀, kí lo lè ṣe nípa rẹ̀? Òótọ́ ni òwe àtijọ́ náà pé, “Bó bá ti yá kì í tún pẹ́ mọ́.” Ṣé lóòótọ́ ló wù ẹ́ pé kó o wá nǹkan ṣe sí ìṣòro kíki pọ́pọ́ jù tàbí ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀? Yálà o jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, bó o bá ki pọ́pọ́ jù, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe? Dín bó o ṣe sanra tó kù, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o lè dá ẹ̀mí ara ẹ légbodò o. Má ṣe máa jókòó gẹlẹtẹ sójú kan, kó o bàa lè máa rí ìtẹ́lọ́rùn àti àṣeyọrí tó wà nídìí ẹ̀, àní nínú àwọn ohun kéékèèké pàápàá bíi káwọn aṣọ ẹ máà tóbi mọ́!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó o bá fẹ́ kà síwájú sí i nípa ìṣòro síséèémí lójú oorun, wo Jí! February 8, 2004, ojú ìwé 10 sí 12.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Ṣé iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi ń fa ọ̀rá jáde lára lá á yanjú ìṣòro ẹ?

Kí ni iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi ń fa ọ̀rá jáde lára yìí? Bí ìwé atúmọ̀ èdè kan ṣe túmọ̀ rẹ̀ nìyí: “Irú iṣẹ́ abẹ kan tí wọ́n sábà máa ń ṣe fún ẹni tó bá fẹ́ yí ẹ̀yà ara ẹ̀ padà ni, wọ́n á fa àpọ̀jù ọ̀rá kúrò ní ibi kan pàtó nínú ara, bíi ní apópó itan tàbí nínú ikùn, nípa fífi ohun èlò kan tí wọ́n ń kì bọ inú ara fa ọ̀rá jáde. Wọ́n tún ń pè é ní iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi n yọ ìṣùpọ̀ ẹran ara tó lọ́ràá.” (American Heritage Dictionary) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé iṣẹ́ abẹ yìí ló máa bá ọ tán ìṣòro ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀?

Ìwé Mayo Clinic on Healthy Weight sọ pé iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi ń yí ìrísí ara padà ni iṣẹ́ abẹ yìí. Kì í ṣe ọ̀nà téèyàn máa ń gbà dín bó ṣe sanra kù. Iṣẹ́ abẹ náà máa ń fa àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń pèsè ọ̀rá jáde kúrò nínú ara nígbà tí wọ́n bá ki irin oníhò bọ abẹ́ awọ ara. Wọ́n lè rí ìwọ̀n tó pọ̀ gan-an fà jáde lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Àmọ́ sá o, “iṣẹ́ abẹ náà ò sí fún dídín ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ kù o.” Ṣé iṣẹ́ abẹ yìí kò léwu ni? “Ńṣe làwọn tó ní ìṣòro kíki pọ́pọ́ ju bó ṣe yẹ lọ tàbí tí wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀, tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n ní àrùn àtọ̀gbẹ àti àrùn àyà máa mú kí ohun tó ń ṣe wọ́n túbọ̀ dojú rú sí i bí wọ́n bá lọ ṣe iṣẹ́ abẹ́ náà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́