ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/22 ojú ìwé 12-13
  • Ìjọ Kátólíìkì àti Ẹfolúṣọ̀n

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjọ Kátólíìkì àti Ẹfolúṣọ̀n
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣáájú Darwin
  • Ìdí Tí “Ìgbóguntì Ojúkojú” Fi Wáyé
  • “Ìdáwọ́-Ìjà-Dúró” àti “Àdéhùn Ìbọ́ra-Ogun-Sílẹ̀”
  • Kí Ni Èrèdí Àlàáfíà Àfẹnujẹ́wọ́ Náà?
  • Ẹfolúṣọ̀n Ń Jẹ́jọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Ni Ẹfolúṣọ̀n?
    Jí!—2006
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Bá Bíbélì Mu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Jí!—1997
g97 10/22 ojú ìwé 12-13

Ìjọ Kátólíìkì àti Ẹfolúṣọ̀n

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Ítálì

NÍ April 26, 1882, ayẹyẹ ìsìnkú Charles Darwin wáyé ní Westminster Abbey, London. Lójú àwọn kan, ṣọ́ọ̀ṣì kan ti lè jọ ibi tí kò ti yẹ rárá láti sìnkú ọkùnrin náà tí a fẹ̀sùn ‘lílé Ọlọ́run kúrò lórí ìtẹ́’ kàn nítorí àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n rẹ̀, ti àṣàyàn àdánidá. Síbẹ̀, ó ti lé ní ọ̀rúndún kan tí sàréè Darwin ti wà níbẹ̀.

Lẹ́yìn tí Darwin gbé ìwé rẹ̀, Origin of Species, jáde ní 1859, ìṣarasíhùwà àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn sí ẹfolúṣọ̀n yí pa dà díẹ̀díẹ̀. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Carlo Molari, kọ̀wé lórí bí sáà “ìgbóguntì ojúkojú” ṣe kúrò lọ́nà fún “ìdáwọ́-ìjà-dúró” ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé, “àdéhùn ìbọ́ra-ogun-sílẹ̀” kan wáyé lágbedeméjì àwọn ọdún 1900, “àlàáfíà” òde òní sì dé níkẹyìn.

Ṣáájú Darwin

Ó dájú pé Darwin kọ́ ló pilẹ̀ èròǹgbà ẹfolúṣọ̀n. Àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí àtayébáyé ti dábàá èrò orí nípa ìparadà oríṣi ohun alààyè kan sí òmíràn. Àbá ìjiyànlé àkọ́kọ́ lórí ẹfolúṣọ̀n lóde òní ṣeé tọpa lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ohun alààyè nínú ibùgbé àdánidá rẹ̀ mélòó kan ní ọ̀rúndún kejìdínlógún.

Láàárín ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún, ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé dá oríṣiríṣi àbá èrò orí nípa ẹfolúṣọ̀n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà, “ẹfolúṣọ̀n,” kò fi bẹ́ẹ̀ fara hàn. Bàbá Darwin àgbà, Erasmus Darwin (1731 sí 1802), gbé àwọn èrò ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n mélòó kan jáde nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé rẹ̀, wọ́n sì to orúkọ ìwé yẹn mọ́ àwọn ìwé tí Ìjọ Kátólíìkì kà léèwọ̀.

Ìdí Tí “Ìgbóguntì Ojúkojú” Fi Wáyé

Àwọn aláìlẹ́mìí-ìsìn kan rí àbá èrò orí Darwin bí ohun èlò lílágbára kan láti fi dín agbára àwùjọ àlùfáà kù. Nítorí náà, àríyànjiyàn gbígbóná kan bẹ́ sílẹ̀. Ní 1860, àwọn bíṣọ́ọ̀bù ilẹ̀ Germany fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé: “Ọlọ́run ló dá àwọn baba ńlá wa ní tààrà. A tipa bẹ́ẹ̀ polongo pé, èrò àwọn tí ń sọ pé ènìyàn, ní ti ohun tó jẹ mọ́ ara rẹ̀, wá láti inú ẹ̀dá aláìpé kan, nípa píparadà fúnra rẹ̀, lòdì pátápátá sí Ìwé Mímọ́ àti Ìgbàgbọ́.”

Lọ́nà kan náà, ní May 1877, Póòpù Pius Kẹsàn-án kan sáárá sí oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Constantin James, nítorí ìtẹ̀jáde kan lòdì sí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, tí ó sì ti àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì nípa ìṣẹ̀dá lẹ́yìn. Apá àkọ́kọ́ nínú ìforígbárí náà dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tí Póòpù Gbé Kalẹ̀ tẹ ọ̀wọ́ àwọn lẹ́tà kan jáde láàárín 1905 sí 1909. Nínú ọ̀kan lára ìwọ̀nyí, ìgbìmọ̀ náà kéde pé àwọn orí mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtàn, a sì gbọ́dọ̀ lóye rẹ̀ bí “ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an.”

“Ìdáwọ́-Ìjà-Dúró” àti “Àdéhùn Ìbọ́ra-Ogun-Sílẹ̀”

Síbẹ̀, bí ipò iyì tí àbá èrò orí Darwin ní ti ń gbilẹ̀ láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì, bí ọmọ ẹgbẹ́ Jesuit ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Teilhard de Chardin, bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà sí ìgbàgbọ́ ẹfolúṣọ̀n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èrò Teilhard yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ti gbogbogbòò, láti 1921 síwájú, ó ka “ẹfolúṣọ̀n ohun alààyè sí . . . ohun tí ìjóòótọ́ rẹ̀ ń dáni lójú sí i.” Títẹ̀ tí ìsìn Kátólíìkì àti ìgbàgbọ́ ẹfolúṣọ̀n ń tẹ̀ síhà ìpadàrẹ́ túbọ̀ ń hàn kedere sí i.

Ní 1948, ọmọ ẹgbẹ́ Jesuit míràn sọ pé: “Fún ohun tí ó lé ní 20 ọdún, iye àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ti pọ̀ sí i lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, ré kọjá iyè méjì, láàárín àwọn ojúlówó ẹlẹ́sìn, tí ń polongo ìpadàrẹ́ [láàárín ẹfolúṣọ̀n àti ìsìn Kátólíìkì] bí ohun tó ṣeé ṣe, bí a bá fi mọ sí àwọn ààlà kan.” Ní nǹkan bí àkókò kan náà, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tí Póòpù Gbé Kalẹ̀ yí ọ̀pọ̀ lára ohun tí ó ti kọ ní 1909, ní ìtìlẹ́yìn àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì nípa ìṣẹ̀dá, pa dà.

Lẹ́yìn náà, ní 1950, lẹ́tà póòpù sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù ìjọ rẹ̀ tí Pius Kejìlá kọ, Humani generis, sọ pé àwọn ọ̀mọ̀wé Kátólíìkì lè bojú wo àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n bí àbá èrò orí tó ṣeé gbà gbọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, póòpù náà sọ pé: “Ìgbàgbọ́ Kátólíìkì kàn án nípá fún wa láti gbà pé Ọlọ́run ni ó dá ọkàn ní tààrà.”

Kí Ni Èrèdí Àlàáfíà Àfẹnujẹ́wọ́ Náà?

Carlo Molari, sọ pé, yàtọ̀ sí nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan, láti ìgbà àpérò àjọ Vatican Kejì tí ń ṣojú fún gbogbo ìjọ ni “a ti borí àwọn èrò yíyàtọ̀ nípa àwọn àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n.” Ó gbàfiyèsí pé, ní October 1996, Póòpù John Paul Kejì polongo pé: “Lónìí, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì ọ̀rúndún lẹ́yìn tí a tẹ lẹ́tà [Pius Kejìlá] jáde, àwọn ìmọ̀ tuntun tí a ní ti mú kí a mọ̀ pé àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n kì í ṣe àbá ìpìlẹ̀ kan lásán. Ní gidi, ó gbàfiyèsí pé àbá èrò orí yìí ti jèrè ìtẹ́wọ́gbà síwájú sí i láti ọ̀dọ̀ àwọn olùwádìí.”

Òpìtàn Lucio Villari pe gbólóhùn tí póòpù sọ náà ní “ìfaramọ́ pátápátá.” Àkọlé ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde arọ̀mọ́pìlẹ̀ ti Ítálì náà, Il Giornale, kà pé: “Póòpù Sọ Pé A Lè Jẹ́ Àtìrandíran Ọ̀bọ.” Ìwé ìròyìn Time sì parí ọ̀rọ̀ pé bí póòpù ṣe fara mọ́ ọn náà “fi bí ìjọ náà ṣe tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n hàn.”

Kí ni èrèdí ohun tí a ti pè ní “ìrẹ̀sílẹ̀ èrò nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n dé àyè kan ṣáá yìí” níhà àwọn aṣáájú Kátólíìkì? Èé ṣe tí Ìjọ Roman Kátólíìkì pa dà bá ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n rẹ́?

Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì ka Bíbélì sí “ọ̀rọ̀ ènìyàn,” wọn kò kà á sí “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Tẹsalóníkà Kíní 2:13; Tímótì Kejì 3:16, 17) Ìjọ Kátólíìkì fi ìjẹ́pàtàkì púpọ̀ fún ohun tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n òde òní sọ ju ohun tí Ọmọkùnrin Ọlọ́run, Jésù Kristi, sọ lọ, ẹni tí ó fìdí àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì nípa ìṣẹ̀dá múlẹ̀, nípa wíwí pé: “Ẹ̀yin kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo?” (Mátíù 19:4) Èrò ti ta ni ìwọ gbà pé ó yẹ láti fún ní ìjẹ́pàtàkì púpọ̀ jù?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹfolúṣọ̀n

Ìgbà gbogbo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ẹ̀kọ́ tí Kristi fi kọ́ni pé Ọlọ́run ni ó dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn kíní ní tààrà, ó sì “ṣe wọ́n ní akọ àti abo.” (Mátíù 19:4; Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:24) Ní 1886, Ìdìpọ̀ Kíní ìwé náà, Millennial Dawn (tí a wá pè ní Studies in the Scriptures lẹ́yìn náà), tọ́ka sí ẹ̀kọ́ èrò orí Darwin gẹ́gẹ́ bí “àbá èrò orí kan tí kò ṣeé fẹ̀rí tì lẹ́yìn,” nígbà tí ó sì di 1898, ìwé kékeré náà, The Bible Versus the Evolution Theory, gbé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá lékè. A tún ṣagbátẹrù àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá nínú àwọn ìwé náà, The New Creation (1904) àti Creation (1927), pa pọ̀ mọ́ àwọn àpilẹ̀kọ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ nínú Ilé Ìṣọ́ àti The Golden Age.

Nígbà tí Póòpù Pius Kejìlá ń ṣàgbékalẹ̀ Humani generis, lẹ́tà póòpù sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù ìjọ, ní 1950, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ ìwé kékeré náà, Evolution Versus the New World, jáde. Ìwé kékeré yìí ní àwọn ẹ̀rí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ẹ̀rí inú ìtàn, lórí àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá, nínú, ó sì bẹnu àtẹ́ lu àwọn ìgbìdánwò àwọn àlùfáà ìjọ mélòó kan, láti mú “ìṣọ̀kan láàárín ẹfolúṣọ̀n àti Bíbélì” wá. Ìwé náà, Did Man Get Here by Evolution or by Creation? (1967), pẹ̀lú gbé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá lárugẹ, lọ́nà kan náà tí ìwé náà, Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?, tí a tẹ̀ jáde ní 1985, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àpilẹ̀kọ tí a tẹ̀ jáde nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, gbà gbé e lárugẹ.

Nípa bẹ́ẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti di ojúlùmọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀rí tí ó wà pé Ọlọ́run ni ó “ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa.”—Orin Dáfídì 100:3, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́