Ẹfolúṣọ̀n Ń Jẹ́jọ́
Awọn olùfarajìn fún ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ń ké gbàjarè bayii fún títún orísun awọn ohun abẹ̀mí gbéyẹ̀wò látòkèdélẹ̀
KÍ Á sọ pé iwọ jẹ́ adájọ́ ninu ìgbẹ́jọ́ ìwà-ọ̀daràn kan. Olùjẹ́jọ́ naa polongo pé oun kò mọwọ́mẹsẹ̀, awọn ẹlẹ́rìí sì yọjú lati jẹ́rìí gbè é. Ṣugbọn bí o ṣe ń tẹ́tísí gbólóhùn-ẹ̀rí wọn, o ṣàkíyèsí pé ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ń tako òmíràn. Lẹ́yìn naa, nígbà tí o késí awọn ẹlẹ́rìí olùjẹ́jọ́ naa padà sínú àpótí ìdúrórojọ́ níkọ̀ọ̀kan, làbárè wọn ti yàtọ̀síra. Gẹ́gẹ́ bí adájọ́, iwọ yoo ha ka gbólóhùn-ẹ̀rí wọn sí bí? Iwọ yoo ha fẹ́ lati da ẹni tí a fẹ̀sùnkàn naa sílẹ̀ bí? Bóyá o kò ní fẹ́ lati ṣe bẹ́ẹ̀, nitori pé àìbáramu èyíkéyìí ninu gbólóhùn-ẹ̀rí olùjẹ́jọ́ ń sọ ìṣeégbáralé ẹ̀rí olùjẹ́jọ́ naa di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀.
Bí ọ̀ràn àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n ti rí gan-an nìyẹn. Ògídímèje awọn ẹlẹ́rìí ti yọjú lati ṣe onírúurú làbárè nipa orísun awọn ohun abẹ̀mí, tí wọn sì ń jẹ́rìí gbe àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n. Ṣugbọn gbólóhùn-ẹ̀rí wọn yoo ha múnádóko ní kóòtù bí? Awọn wọnnì tí wọn ń gbé àbá-èrò-orí naa lárugẹ ha fohùnṣọ̀kan bí?
Gbólóhùn-Ẹ̀rí Fíforígbárí
Bawo ni ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀? Bóyá ni a tíì rí ìbéèrè mìíràn tí ó ru ìméfò pupọ sókè tabi tí ó tanná ran àríyànjiyàn bí èyí. Síbẹ̀, àríyànjiyàn naa kìí wulẹ̀ ṣe lórí ẹfolúṣọ̀n ní ìlòdìsí ìṣẹ̀dá; pupọ lára ìforígbárí naa wáyé láàárín awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n fúnraawọn. Níti gidi gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nipa ẹfolúṣọ̀n—bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀, ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ati ẹni tabi ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ati bí ọ̀nà tí ó gbà ṣẹlẹ̀ ṣe gùn tó—ni wọn ń jiyàn lé lórí kíkankíkan.
Fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ti ń sọ pé ìwàláàyè bẹ̀rẹ̀ ninu alagbalúgbú “ọbẹ̀” eléròjà omiró. Awọn kan ti wà gbàgbọ́ bayii pé ó ṣeéṣe kí ìfóòfò inú òkun ti mú ìwàláàyè jáde. Awọn mìíràn tún lérò pé awọn orísun omi lílọ́wọ́wọ́ nísàlẹ̀ òkun ti lè jẹ́ ibi tí ìwàláàyè ti bẹ̀rẹ̀. Awọn kan tànmọ́ ọ̀n pé awọn ìpẹ́pẹ́ ìràwọ̀ tí wọn balẹ̀ sórí ilẹ̀-ayé ni o mú awọn ẹ̀dá abẹ̀mí jáde. Awọn mìíràn tún sọ pé, bóyá, ó lè jẹ́ pé ọ̀kan lára awọn planẹẹti rodoríndín ni ó súnnásí bí ìwàláàyè ṣe jẹ jáde, nipa rírọ́lu ayé tí ó sì yí afẹ́fẹ́ àyíká padà. Olùṣèwádìí kan sọ pé, “jẹ́ kí planẹẹti líle koránkorán rodoríndín kan tí ó tóbi ju awọn yòókù lọ rọ́lu ilẹ̀-ayé, iwọ yoo rí i pé awọn ohun yíyanilẹ́nu yoo ṣẹlẹ̀.”
Ọ̀nà tí ìwàláàyè gbà bẹ̀rẹ̀ ni wọn tún gbéyẹ̀wò pẹlu. Ìwé ìròyìn Time sọ pé, “Ìwàláàyè kò wáyé lábẹ́ ipò wọ́ọ́rọ́wọ́, tí ó sì parọ́rọ́, bí a ṣe rò tẹ́lẹ̀, bíkòṣe lábẹ́ ipò ojú ọjọ́ gbígbóná janjan ti planẹẹti kan tí ìrujáde òkè ayọnáyèéfín rún wómúwómú tí a sì wu léwu nípasẹ̀ awọn ìràwọ̀ onírù ati awọn planẹẹti rodoríndín.” Awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ kan ti sọ nísinsìnyí pé, kí ó tó lè ṣeéṣe fún ìwàláàyè lati bẹ̀rẹ̀ láàárín irú ipò júujùu bẹ́ẹ̀, gbogbo ọ̀nà tí ó gbà ṣẹlẹ̀ ti gbọ́dọ̀ wáyé láàárín sáà àkókò kúkúrú kan ju bí a ti rò tẹ́lẹ̀ lọ.
Awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ tún ní èrò yíyàtọ̀síra nípa ipa tí Ọlọrun kó—“bí ó bá wà”—ninu ìbẹ̀rẹ̀ ìwàláàyè. Awọn kan sọ pé ìwàláàyè jẹyọ láìsí pé Ẹlẹ́dàá kan lọ́wọ́ sí i, nígbà tí awọn mìíràn pẹ́ ẹ sọ pé Ọlọrun ni ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ tí ó sì fi ìyókù lé ẹfolúṣọ̀n lọ́wọ́.
Lẹ́yìn tí ìwàláàyè bẹ̀rẹ̀, bawo ni ẹfolúṣọ̀n ṣe wáyé? Lórí kókó yii pàápàá, làbárè tún forígbárí. Ní 1958, ọ̀rúndún kan lẹ́yìn tí wọn ṣe ìwé The Origin of Species jáde, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n Sir Julian Huxley sọ pé: “Ìlànà kíkárí ayé tí ó nííṣe pẹlu ìmú-ara-ẹni-bá-ipò-mu lọ́nà ti ẹ̀dá, tí ó jẹ́ àwárí gíga jùlọ tí Darwin ṣe, ni a fìdí rẹ múlẹ̀ ṣinṣin ati nígbẹ̀yìn gbẹ́yín gẹ́gẹ́ bí irin-iṣẹ́ fún awọn ìyípadà pàtàkì ninu ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n.” Ṣugbọn, ní ọdún 24 lẹ́yìn naa, Michael Ruse ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n kọ̀wé pé: “Iye púpọ̀ síi lára awọn onímọ̀ nipa ẹ̀dá abẹ̀mí . . . ń jiyàn pé àbá-èrò-orí èyíkéyìí tí a bá gbékarí ìlànà àbá-èrò-orí Darwin—ní pàtàkì àbá-èrò-orí èyíkéyìí tí ó bá gba ìmú-ara-ẹni-bá-ipò-mu lọ́nà ti ẹ̀dá gẹ́gẹ́ bíi kọ́kọ́rọ́ naa sí ìyípadà ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n—ti kùnà pátápátá.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé ìròyìn Time sọ pé, “awọn ẹ̀rí fífìdímúlẹ̀ pupọ” ń bẹ tí ó ti àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n lẹ́yìn, ó ṣì gbà pé ẹfolúṣọ̀n jẹ́ ìtàn dídíjú pẹlu “ọ̀pọ̀ àlèébù ati ọ̀pọ̀ àbá-èrò-orí tí ń figagbága lórí bí wọn ṣe lè pèsè awọn ẹ̀rí tí wọn kù díẹ̀ káàtó.” Dípò dídámọ̀ràn pé kí a pa ẹjọ́ naa tì, lára awọn tí wọn farajìn fún ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n jùlọ ń ké gbàjarè bayii fún títún orísun awọn ohun abẹ̀mí gbéyẹ̀wò.
Nitori naa, àríyànjiyàn fún fífaramọ́ ẹfolúṣọ̀n—ní pàtàkì fún ìbẹ̀rẹ̀ ìwàláàyè gẹ́gẹ́ bí ẹfolúṣọ̀n ti sọ—ni wọn kò gbékarí gbólóhùn-ẹ̀rí bíbáramu. Onímọ̀-ìjìnlẹ̀ T. H. Janabi ṣàkíyèsí pé awọn wọnnì tí wọn ń ṣalágbàwí ẹfolúṣọ̀n “ti mú ọ̀pọ̀ awọn àbá-èrò-orí tí ó kún fún ìṣìnà jáde wọn sì ti yááfì ọ̀pọ̀lọpọ̀ lati awọn ọdún wọnyi wá, ati pé kò tíì ṣeéṣe fún awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ lati fohùnṣọ̀kan lórí àbá-èrò-orí kan títí di bayii.”
Ó dùnmọ́ni pé, Charles Darwin fojúsọ́nà fún irú ìforígbárí bẹ́ẹ̀. Ninu ìnasẹ̀-ọ̀rọ̀ ìwé The Origin of Species, ó kọ̀wé pé: “Mo mọ̀ dájúdájú pé bóyá ni kókó kan fi wà tí mo ṣàlàyé ninu àdìpọ̀ ìwé yii tí kò ní ẹ̀rí tí ó múnádóko, lọ́pọ̀ ìgbà ni ó sì máa ń jálẹ̀ sí ìparí-èrò tí ó jẹ́ òdìkejì pátápátá sí iwọnyi tí mo ní lọ́wọ́.”
Ní tòótọ́, irú awọn ẹ̀rí fíforígbárí bẹ́ẹ̀ gbé ìbéèrè dìde sí ìṣeégbáralé àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n.
Ẹfolúṣọ̀n Ha Wà fún Awọn Ọlọ́gbọ́nlóye Bí?
Ìwé naa Milestones of History sọ pé, lati ìbẹ̀rẹ̀, àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n “fa ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ́ra nitori pé ó jọ bí ẹni pé ó bá ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ mu ju àbá-èrò-orí ìṣẹ̀dá irú ọ̀wọ́ awọn ẹ̀dá.”
Jù bẹ́ẹ̀ lọ, awọn gbólóhùn olójú-ìwòye tèmi-ni-kí-o-gbà tí awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n kan ń sọ lè máyàpami. Fún àpẹẹrẹ, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ H. S. Shelton tẹnumọ́ ọn pé èrò naa nipa ìṣẹ̀dá irú ọ̀wọ́ awọn ẹ̀dá jẹ́ “èrò òmùgọ̀ gbáà ju èyí tí a lè fún ní ìgbéyẹ̀wò jíjinlẹ̀.” Richard Dawkins onímọ̀ nipa awọn ẹ̀dá abẹ̀mí sọ gbangba pé: “Bí o bá pàdé ẹnìkan tí kò nígbàgbọ́ ninu ẹfolúṣọ̀n, òpè, òmùgọ̀ tabi asínwín ni onítọ̀hún.” Bákan naa, Ọ̀jọ̀gbọ́n René Dubos sọ pé: “Ọ̀pọ̀ awọn olóye ènìyàn ti wá gbà bayii pé òtítọ́ ni pé ohun gbogbo tí ó wà ní àgbáálá-ayé—lati orí awọn ẹ̀dá ọ̀run títíkan ẹ̀dá ènìyàn—wá wọn sì ń báa nìṣó lati wá nípasẹ̀ ọ̀nà ẹfolúṣọ̀n.”
Lati inú awọn gbólóhùn wọnyi yoo jọ bí ẹni pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìwọ̀nba òye díẹ̀ yoo gba pẹlu ẹfolúṣọ̀n láìjanpata. Ó ṣetán, lati ṣe bẹ́ẹ̀ yoo túmọ̀sí pé ẹnìkan jẹ́ “olóye” kìí sì ṣe “òmùgọ̀.” Síbẹ̀, awọn ọ̀mọ̀wé ń bẹ lọ́kùnrin ati lóbìnrin tí kò ṣalágbàwí àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n. Francis Hitching ninu ìwé rẹ̀ The Neck of the Giraffe kọ̀wé pé, “Mo ti rí ọ̀pọ̀ awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ tí wọn ń ṣiyèméjì, ati awọn díẹ̀ tí wọn lọ jìnnà débi sísọ pé àbá-èrò-orí Darwin jásí èyí tí kò bá àbá-èrò-orí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ mu rárá.”
Chandra Wickramasinghe, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Britain kan tí a kansáárá sí gidigidi, mu irú ìdúró kan naa. Ó sọ pé “Kò sí ẹ̀rí kankan fún èyíkéyìí lára awọn èrò ìpìlẹ̀ àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n ti Darwin. Ó jẹ́ ipá ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí ó bi ayé ṣubú ní 1860, mo sì lérò pé ó ti jẹ́ ìjábá fún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ lati ìgbà naa wá.”
T. H. Janabi ṣe ìwádìí àríyànjiyàn tí awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n gbé kalẹ̀. Ó sọ pé, “Mo ríi pé ipò nǹkan ti yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí a fipá mú wa gbàgbọ́. Ẹ̀rí naa kò pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni kò kún tó lati ti irú àbá-èrò-orí dídíjú bíi ti orísun awọn ohun abẹ̀mí lẹ́yìn.”
Nitori ìdí èyí, a kò wulẹ̀ níláti fọwọ́ rọ́ awọn tí wọn tako àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí “òpè, òmùgọ̀ tabi asínwín.” Níti awọn èrò tí ó pe ẹfolúṣọ̀n níjà, kódà George Gaylord Simpson alátìlẹ́yìn gbágbágbá kan fún ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n pàápàá níláti gbà pé: “Dájúdájú yoo jẹ́ àṣìṣe lati fi ọwọ́ rọ́ awọn ojú-ìwòye wọnyi sẹ́yìn nipa fífi wọn ṣe ọ̀ràn ẹ̀rín tabi àwàdà lásán. Awọn alátakò àbá-èrò-orí yìí ti jẹ́ (wọn ṣì tún jẹ́) ọ̀jáfáfá akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn sì dáńgájíá.”
Ọ̀ràn Ìgbàgbọ́
Awọn kan lérò pé èrò-ìgbàgbọ́ ninu ẹfolúṣọ̀n ni a gbékarí òkodoro òtítọ́, nígbà tí a gbé èrò-ìgbàgbọ́ ninu ìṣẹ̀dá karí ìgbàgbọ́. Òtítọ́ ni pé kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí. (Johannu 1:18; fiwé 2 Korinti 5:7.) Síbẹ̀, àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n kò ṣàǹfààní kankan lọ́nà yii, níwọ̀n bí wọn ti gbé e ka awọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ẹ̀dá ènìyàn kan kò tíì fojúrí rí tabi ṣe àfijọ rẹ̀.
Fún àpẹẹrẹ, awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ kò tíì kíyèsí ìyípadà òjijì ninu apilẹ̀ àbùdá rí—àní iwọnyi tí ó ṣàǹfààní pàápàá—tí ń mú ohun alààyè titun jáde; síbẹ̀ ó dá wọn lójú pé bí irú ọ̀wọ́ awọn ohun titun ṣe ń wáyé nìyẹn. Wọn kò tíì fojúrí wíwáyé awọn ẹ̀dá abẹ̀mí lati inú ẹ̀dá aláìlẹ́mìí rí; síbẹ̀ wọn tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
Irú àìsí ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí T. H. Janabi pe àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n ní “‘ìgbàgbọ́’ asán.” Fred Hoyle onímọ̀ nipa physics pè é ní “Ìhìnrere ti Darwin.” Dókítà Evan Shute tilẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ tí ó lágbára jù ìyẹn lọ. Ó sọ pé “Mo wòye pé awọn olùfọkànsìn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ní ọ̀pọ̀ àdììtú lati ṣàlàyé jú awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́dàá-ń-bẹ lọ.”
Awọn ògbógi mìíràn fohùnṣọ̀kan. Robert Jastrow jẹ́wọ́ bayii, “Nígbà tí mo bá ń ṣàṣàrò lórí awọn ohun tí ó parapọ̀ di ènìyàn, bí ẹ̀dá ènìyàn àrà-ọ̀tọ̀ yìí ṣe wáyé lati inú alagbalúgbú omi lílọ́wọ́wọ́ tí kẹ́míkà yọrósí, jọ bí iṣẹ́ ìyanu lọ́nà gíga gẹ́gẹ́ bíi ti àkọsílẹ̀ Bibeli nípa orísun awọn ohun abẹ̀mí.”
Èéṣe, nígbà naa, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì fi ń lòdìsí èrò naa pé dídá ni a dá ìwàláàyè?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Awọn gbólóhùn olójú-ìwòye tèmi-ni-kí-o-gbà tí awọn kan ń sọ lè máyàpami