ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 9-10
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn—Àmì Òpin Ayé Ni Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àjàkálẹ̀ Àrùn—Àmì Òpin Ayé Ni Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àjàkálẹ̀ Àrùn àti Òpin Ayé
  • Párádísè Tí Ń Bọ̀
  • Ayé Yìí Yóò Ha Là á Já Bí?
    Ayé Yìí Yóò Ha Là Á Já Bí?
  • Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ṣé Òpin Ayé Ti Sún Mọ́lé?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 9-10

Àjàkálẹ̀ Àrùn—Àmì Òpin Ayé Ni Bí?

ǸJẸ́ àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ wa fi hàn pé òpin ayé ti sún mọ́lé bí? Kí a tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ọ̀rọ̀ náà “òpin ayé” túmọ̀ sí.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé òpin ayé túmọ̀ sí pé Ọlọ́run yóò pa ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun alààyè inú rẹ̀ run. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé, ó “mọ [ilẹ̀ ayé] kí a lè gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Ète rẹ̀ jẹ́ láti fi àwọn ènìyàn aláyọ̀, tí ara wọ́n yá gágá, tí wọ́n ń yán hànhàn láti ṣègbọràn sí àwọn ìlànà pípé rẹ̀, kún inú pílánẹ́ẹ̀tì yí. Nítorí náà, òpin ayé kò túmọ̀ sí òpin ilẹ̀ ayé àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí òpin ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí àti ti àwọn tí wọ́n kọ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nínú rẹ̀.

Àpọ́sítélì Pétérù fi èyí hàn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ayé [ọjọ́ Nóà] jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” Nígbà tí a pa ayé run ní ọjọ́ Nóà, àwọn ènìyàn búburú ni wọ́n ṣègbé. Ilẹ̀ ayé ṣì wà, Nóà olódodo àti ìdílé rẹ̀ sì wà pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ lẹ́yìn náà, Ọlọ́run yóò tún gbégbèésẹ̀ lọ́jọ́ iwájú láti mú “ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” wá.—Pétérù Kejì 3:6, 7.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì míràn ti èrò yí lẹ́yìn látòkèdélẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Òwe 2:21, 22 sọ pé: “Ẹni ìdúróṣinṣin ni yóò jókòó ní ilẹ̀ náà, àwọn tí ó pé yóò sì máa wà nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú ni a óò ké kúrò ní ilẹ̀ ayé, àti àwọn olùrékọjá ni a óò sì fà tu kúrò nínú rẹ̀.”—Tún wo Orin Dáfídì 37:9-11.

Àwọn Àjàkálẹ̀ Àrùn àti Òpin Ayé

Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Mẹ́rin lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bi í ní ìbéèrè yẹn. Wọ́n béèrè pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan [tàbí, bí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan ti sọ, “òpin ayé”]?” Jésù fèsì pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ yóò sì wà láti ibi kan dé ibòmíràn.” (Mátíù 24:3, 7) Nínú àkọsílẹ̀ tí ó jọra nínú Lúùkù 21:10, 11, Jésù fi kún un pé: ‘Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn yóò wà . . . láti ibì kan dé ibòmíràn . . . , àwọn ohun ìran akúnfúnbẹ̀rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run.’

Ṣàkíyèsí pé Jésù kò sọ pé àwọn àjàkálẹ̀ àrùn nìkan ni yóò fi hàn pé òpin ti sún mọ́lé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ nípa àwọn ogun ńláǹlà, ìmìtìtì ilẹ̀, àti àìtó oúnjẹ. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó kún rẹ́rẹ́ náà tí a rí nínú Mátíù 24 àti 25, Máàkù 13, àti Lúùkù 21, Jésù sàsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀ ohun mìíràn tí yóò ṣẹlẹ̀. Gbogbo wọn yóò ṣẹlẹ̀ pa pọ̀ kí Ọlọ́run tó gbégbèésẹ̀ láti fi òpin sí ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ̀rí tí ó ṣe gúnmọ́ wà pé a ti ń gbé ní àkókò yẹn báyìí.

Párádísè Tí Ń Bọ̀

Lọ́jọ́ iwájú, a kì yóò pa ìran aráyé run yálà nípa àjàkálẹ̀ àrùn tàbí láti ọwọ́ Ọlọ́run. Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí láti yí ilẹ̀ ayé yìí pa dà sí párádísè kan. (Lúùkù 23:43) Lára àwọn ohun mìíràn tí yóò ṣe ni pé yóò mú àwọn àrùn tí ń yọ aráyé lẹ́nu kúrò.

Èyí dá wa lójú nígbà tí a ṣàgbéyẹ̀wò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi, tí ó gbé àwọn ànímọ́ Bàbá rẹ̀ yọ lọ́nà pípé. Bí Bàbá rẹ̀ tí ó wà lọ́run ti fún un lágbára, Jésù wo àwọn arọ, aláàbọ̀ ara, afọ́jú, tàbí odi sàn. (Mátíù 15:30, 31) Ó tún wo àwọn tí àrùn ẹ̀tẹ̀ ń pọ́n lójú sàn. (Lúùkù 17:12-14) Ó wo obìnrin kan tí ó ní ìṣàn ẹ̀jẹ̀, àti ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ rọ, àti ọkùnrin alárùn ògùdùgbẹ̀ kan sàn. (Máàkù 3:3-5; 5:25-29; Lúùkù 14:2-4) Ó wo àwọn “alárùn wárápá àti àwọn alárùn ẹ̀gbà” sàn. (Mátíù 4:24) Ó tilẹ̀ jí òkú dìde lẹ́ẹ̀mẹta!—Lúùkù 7:11-15; 8:49-56; Jòhánù 11:38-44.

Àwọn ìwòsàn oníṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí ṣàfihàn òtítọ́ ìlérí Ọlọ́run pé, lọ́jọ́ iwájú kan tí òun yàn, “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.” (Aísáyà 33:24) Àjàkálẹ̀ àrùn kì yóò já ìlera àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn gbà lọ́wọ́ wọn mọ́ láé. Ẹ wo bí ó ti yẹ kí a kún fún ọpẹ́ tó pé Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ní agbára àti ìfẹ́ inú láti mú àìsàn àti àrùn kúrò pátápátá, títí láé!—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti wo àwọn aláìlera sàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀, Jèhófà yóò mú àìsàn àti àrùn kúrò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́