ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/8 ojú ìwé 13-15
  • Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Kórìíra Àwọn Abẹ́yà-Kannáà-Lòpọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Kórìíra Àwọn Abẹ́yà-Kannáà-Lòpọ̀?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Ọlọ́run
  • “Ẹ Kórìíra Ibi”
  • “Ọlọ́run Kì Í Ṣe Ojúsàájú”
  • Àwọn Kristẹni Ń Fi Tìfẹ́tìfẹ́ Gba Ẹni Tí Ó Ronú Pìwà Dà
  • Ǹjẹ́ Ìdí Kankan Wà Tí Ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ Fi Tọ̀nà?
    Jí!—2012
  • Ṣó Burú Kí Ọkùnrin Máa Fẹ́ Ọkùnrin àbí Kí Obìnrin Máa Fẹ́ Obìnrin?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kannáà-Lòpọ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀?
    Jí!—2011
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 12/8 ojú ìwé 13-15

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Kórìíra Àwọn Abẹ́yà-Kannáà-Lòpọ̀?

NÍ 1969, a ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ kan lédè Gẹ̀ẹ́sì tí ń ṣàpèjúwe ìbẹ̀rù abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ tàbí kíkórìíra wọn láìbọ́gbọ́nmu. Ọ̀rọ̀ náà ni a tú sí “ìbẹ̀rù abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀.” Ọ̀pọ̀ èdè ni kò ní irú ọ̀rọ̀ pàtó bẹ́ẹ̀ fún un, síbẹ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti èdè ti fi ẹ̀rí hàn kedere pé àwọn kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ènìyàn ti gbé ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ lárugẹ gan-an gẹ́gẹ́ bí ohun àfirọ́pò àfihàn ìbálòpọ̀ lásán. Òpìtàn Jerry Z. Muller kọ̀wé láìpẹ́ yìí nípa “ìbéèrè tí ń pọ̀ sí i fún àfiyèsí àwọn aráàlú àti ọ̀wọ̀ fún ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀.” Ó ṣàlàyé pé àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ “ti ń pẹnu pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà gíga sí i láti polongo àṣà wọn náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó yẹ fún ìgbóríyìn, àti láti béèrè pé kí àwọn ẹlòmíràn máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” A ń rí èyí ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn. Síbẹ̀síbẹ̀, ní àwọn ibi púpọ̀ jù lọ lágbàáyé, kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí a pè ní èyí tí ń gba ojú ìwòye ẹlòmíràn rò, ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì dẹ́bi fún ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, wọ́n sì kórìíra rẹ̀.

Àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ àti àwọn tí a fura sí pé wọ́n jẹ́ abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ ni a sábà máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí, tí a máa ń fòòró, tí a sì máa ń ṣe léṣe. Kódà àwọn aṣáájú ìsìn ti fi irú ìkórìíra bẹ́ẹ̀ hàn. Àwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ ohun tí ó lè dà bí ogun àdájà tiwọn lòdì sí àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ tí bíṣọ́ọ̀bù kan ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì sọ, tí wọ́n gbé jáde nínú rédíò orílẹ̀-èdè Gíríìkì láìpẹ́ yìí. Ó sọ pé: “Ọlọ́run yóò jó àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ nínú kòtò iná ọ̀run àpáàdì títí láé. Igbe tí yóò jáde lẹ́nu wọn burúkú yóò máa dún àdúntúndún títí ayé. Ara ṣìọ̀ṣìọ̀ wọn tí wọ́n yí ìlò rẹ̀ sódì yóò rí ìdálóró tí kò ṣeé mú mọ́ra.” Èyí ha rí bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́ bí? Kí ni èrò Ọlọ́run nípa àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀?

Èrò Ọlọ́run

Bíbélì kò pe àfiyèsí sí àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ ní pàtó gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan tí ó yẹ kí àwọn Kristẹni ta nù lẹ́gbẹ́ tàbí kí wọ́n kórìíra. Ní àfikún sí i, kò fi kọ́ni pé Ọlọ́run yóò fìyà jẹ àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀—tàbí èyíkéyìí lára àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀—nípa jíjó wọn nínú ọ̀run àpáàdì oníná kan títí láé.—Fi wé Róòmù 6:23.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní kedere ni Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere tí Ọlọ́run wa gbé kalẹ̀, tí ó máa ń ta ko àwọn àṣà ìhùwà òde òní. Bíbélì dẹ́bi fún ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí wọn kò ṣègbéyàwó, àti ìbẹ́rankolòpọ̀ lápapọ̀. (Ẹ́kísódù 22:19; Éfésù 5:3-5) Ọlọ́run pa Sódómù àti Gòmórà run nítorí irú àwọn ìṣekúṣe ìbálòpọ̀ bẹ́ẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 13:13; 18:20; 19:4, 5, 24, 25.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ojú abẹ níkòó nípa ìwà ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ pé: “Ohun ìkórìíra ni èyí jẹ́.” (Léfítíkù 18:22, The New Jerusalem Bible) Òfin Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì sọ pé: “Ọkùnrin tí ó bá bá ọkùnrin dà pọ̀, bí ẹni bá obìnrin dà pọ̀, àwọn méjèèjì ni ó ṣe ohun ìríra: pípa ni a óò pa wọ́n.” (Léfítíkù 20:13) Irú ìjìyà kan náà ni a kọ sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n ń hùwà ìbẹ́rankolòpọ̀, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, àti panṣágà.—Léfítíkù 20:10-12, 14-17.

A mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti ṣàpèjúwe ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí àfihàn “ìdálọ́rùn tí ń dójú tini fún ìbálòpọ̀ takọtabo” àti gẹ́gẹ́ bí “èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá.” Ó kọ̀wé pé: “Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ fún ìdálọ́rùn tí ń dójú tini fún ìbálòpọ̀ takọtabo, nítorí àwọn abo wọn yí ìlò ara wọn lọ́nà ti ẹ̀dá pa dà sí èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá; àti bákan náà àní àwọn akọ fi ìlò abo lọ́nà ti ẹ̀dá sílẹ̀ wọ́n sì di ẹni tí a mú ara wọn gbiná lọ́nà lílenípá nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn sí ara wọn lẹ́nìkínní kejì, àwọn akọ pẹ̀lú àwọn akọ, ń ṣe ohun ìbàjẹ́ akóninírìíra wọ́n sì ń gba èrè iṣẹ́ kíkúnrẹ́rẹ́ nínú ara wọn, èyí tí ó yẹ fún ìṣìnà wọn. Àti pé gan-an gẹ́gẹ́ bí wọn kò ti fi ojú rere tẹ́wọ́ gba dídi Ọlọ́run mú nínú ìmọ̀ pípéye, Ọlọ́run jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ fún ipò èrò orí tí a kò fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà, láti ṣe àwọn ohun tí kò yẹ.”—Róòmù 1:26-28.

Ìwé Mímọ́ kò fàyè gba àwíjàre, ìyọ̀ǹda, àìṣekedere; ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, panṣágà, àgbèrè, lápapọ̀ jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fojú tẹ́ńbẹ́lú ojú ìwòye Bíbélì nípa “ìdálọ́rùn tí ń dójú tini fún ìbálòpọ̀ takọtabo” kìkì nítorí kí wọ́n lè túbọ̀ di olókìkí tàbí kí wọ́n di ẹni tí àṣà ìgbàlódé túbọ̀ tẹ́wọ́ gbà. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbà pẹ̀lú àjọ ìgbòkègbodò èyíkéyìí tí a yà sọ́tọ̀ fún gbígbé ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ lárugẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìgbésí ayé tí ó bójú mu.

“Ẹ Kórìíra Ibi”

Bíbélì fúnni ní ìṣítí pé: “Ẹ̀yin tí ó fẹ́ Olúwa, ẹ kórìíra ibi.” (Orin Dáfídì 97:10) Nítorí náà, a retí pé kí àwọn Kristẹni kórìíra gbogbo àṣà tí ó bá ti tàpá sí àwọn òfin Jèhófà. Àwọn ènìyàn kan tilẹ̀ lè hùwà pa dà pẹ̀lú ìmọ̀lára ìkórìíra líle tàbí ìṣe-họ́ọ̀ sí ìwà pálapàla, ní kíka ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ sí ìbálòpọ̀ tí a gbé gbòdì lọ́nà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ha yẹ kí àwọn Kristẹni kórìíra àwọn tí ń hu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀?

Onísáàmù náà tànmọ́lẹ̀ díẹ̀ sórí ọ̀ràn náà nínú Orin Dáfídì 139:21, 22 pé: “Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ? Ǹjẹ́ inú mi kò ha sì bà jẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ? Èmi kórìíra wọn ní àkótán: èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.” Ó yẹ kí ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà àti àwọn ìlànà rẹ̀ mú kí a máà nífẹ̀ẹ́ páàpáà sí àwọn tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, tí wọ́n sì ń mú ìdúró gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá Ọlọ́run. Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù wà lára irú àwọn tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn kan tún wà lára ìṣọ̀wọ́ yìí. Síbẹ̀, ó lè ṣòro gan-an fún Kristẹni kan láti lè fi ìrísí dá irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀. A kò lè mọ ohun tó wà nínú ọkàn. (Jeremáyà 17:9, 10) Yóò jẹ́ ohun tí kò tọ̀nà láti ni èrò pé ẹnì kan jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run tí kò ṣeé yí pa dà nítorí pé ó ń hùwà búburú. Nínú ọ̀ràn púpọ̀, ó wulẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí ń hùwà búburú kò mọ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run ni.

Nítorí náà, lápapọ̀, àwọn Kristẹni máa ń lọ́ra láti kórìíra ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Bí wọ́n bá tilẹ̀ ní ìkórìíra gan-an fún irú àwọn àṣà ìgbésí ayé kan, wọn kì í wá ọ̀nà láti ṣe àwọn ẹlòmíràn léṣe, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gbin àránkàn sínú tàbí kí wọ́n di kùrùngbùn sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn láti “jẹ́ ẹlẹ́mìí-àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:9, 17-19.

“Ọlọ́run Kì Í Ṣe Ojúsàájú”

Jèhófà yóò dárí ji ẹni tí ó bá ronú pìwà dà ní tòótọ́, láìka irú ìwà pálapàla yòó wù kí ẹnì yẹn máa hù tẹ́lẹ̀ sí. Kò sí ẹ̀rí pé Jèhófà ń wo irú ìwà pálapàla kan bí èyí tí ó burú ju òmíràn lọ. “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34, 35) Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ọ̀ràn ìjọ ọ̀rúndún kìíní náà ní Kọ́ríńtì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn pé: “Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra ènìyàn, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn kan tí wọ́n jẹ́ àgbèrè, panṣágà, abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, àti olè tẹ́lẹ̀ rí ni a ti gbà sínú ìjọ Kristẹni ní Kọ́ríńtì. Ó ṣàlàyé pé: “Síbẹ̀ ohun tí àwọn kan lára yín sì ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—Kọ́ríńtì Kíní 6:9-11.

Ó dájú pé Jèhófà kì í fàyè gba títẹ̀síwájú nínú ìtàpá sí àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n ìwà pípé rẹ̀ lọ́nàkọnà kí wọ́n má sì jáwọ́ nínú rẹ̀. Dájúdájú, ó kórìíra fífi orí kunkun ṣàìka àwọn ìlànà rẹ̀ sí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìlàjà. (Orin Dáfídì 86:5; Aísáyà 55:7) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn Kristẹni kì í di kùnrùngbùn sí àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, tàbí àwọn ẹlòmíràn, wọn kì í fi wọ́n ṣẹ̀sín, tàbí kí wọ́n fòòró wọn. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń wo àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó lè wá di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, wọ́n sì ń fún wọn ní ọ̀wọ̀ àti iyì. Bíbélì sọ pé: “Èyí dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ inú rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—Tímótì Kíní 2:3, 4.

Àwọn Kristẹni Ń Fi Tìfẹ́tìfẹ́ Gba Ẹni Tí Ó Ronú Pìwà Dà

Léraléra ni Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni tí ń dárí jini. Ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run tí ó múra láti dárí jì, olóore ọ̀fẹ́, àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀.” (Nehemáyà 9:17; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:11; Pétérù Kejì 3:9) Bíbélì tún fi í wé bàbá inú òwe àkàwé Jésù, tí ó sọ nípa ọmọ onínàákúnàá, tí ó ti fi wọ̀bìà ná ogún rẹ̀ ní ìnákúnàá ní ilẹ̀ òkèèrè. Bàbá rẹ̀ dúró, ó na ọwọ́ rẹ̀ láti kí ọmọkùnrin rẹ̀ káàbọ̀ nígbà tí ó ṣe tí ọmọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà títọ́, tí ó ronú pìwà dà, tí ó sì pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀.—Lúùkù 15:11-24.

Òtítọ́ ni, oníwà búburú kan lè yí pa dà. Ìwé Mímọ́ jẹ́rìí sí èyí nípa rírọ àwọn ènìyàn láti bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ kí wọ́n sì gbé tuntun wọ̀, kí wọ́n sì ‘di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú ṣiṣẹ́.’ (Éfésù 4:22-24) Àwọn tí ń ṣe ohun búburú, títí kan àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, lè ṣe àwọn ìyípadà pátápátá nínú ìrònú àti ìhùwà wọn, àwọn púpọ̀ sì ti ṣàṣeyọrí gidi ní ṣíṣe ìyípadà yí.a Jésù fúnra rẹ̀ wàásù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀; nígbà tí wọ́n sì fi ìrònúpìwàdà hàn, ó tẹ́wọ́ gbà wọ́n.—Mátíù 21:31, 32.

Àwọn Kristẹni ń fi tìfẹ́tìfẹ́ gba onírúurú ènìyàn tí ó ronú pìwà dà. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi irú àwọn àṣà oníwà pálapàla èyíkéyìí tó wù kí ó jẹ́ sílẹ̀, gbogbo wọn lè gbádùn àǹfààní kíkún ti ìdáríjì Ọlọ́run nítorí pé “Olúwa ṣeun fún ẹni gbogbo; ìyọ́nú rẹ̀ sì ń bẹ lórí iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.”—Orin Dáfídì 145:9.

Àwọn Kristẹni ṣe tán láti pèsè ìtìlẹ́yìn tẹ̀mí tí ó pọn dandan, kódà fún àwọn tí wọ́n ṣì ń bá àwọn ìtẹ̀sí ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ jà. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àfihàn ìfẹ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, nítorí Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún ìtẹ́wọ́gbà wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.”—Róòmù 5:8.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Ìmọ̀lára Wọ̀nyí Lọ Kúrò?,” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde March 22, 1995.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Àwọn Kristẹni kì í fojú tẹ́ńbẹ́lú ojú ìwòye Bíbélì nípa ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Punch

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́