Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀?
Níbi ayẹyẹ ìfúnnilẹ́bùn kan, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo gèè nígbà tí àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu bíi pé ọkùnrin àti obìnrin ni wọ́n. Ọ̀rọ̀ yìí kọ́kọ́ ṣe àwọn òǹwòran ní kàyéfì, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hó yèè láti fi ìdùnnú wọn hàn. Àṣeyọrí làwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ kà á sí. Àmọ́ àwọn ẹlòmíì sọ pé ńṣe ni wọ́n ń fìbàjẹ́ ṣayọ̀. Ohun yòówù kó jẹ́, wọ́n máa gbé fídíò ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jáde léraléra lórí tẹlifíṣọ̀n, àìmọye èèyàn ló sì máa wò ó lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
GẸ́GẸ́ BÍ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe fi hàn, kò sóhun tó ń tà nínú ìròyìn bíi kí ẹnì kan tó jẹ́ gbajúgbajà sọ ní gbangba pé òun jẹ́ abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, . Àwọn kan máa ń gbóríyìn fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ pé wọ́n ní ìgboyà, nígbà tó jẹ́ pé àwọn míì máa ń bẹnu àtẹ́ lù wọ́n fún ìwàkiwà wọn. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn wà tí kò fara mọ́ èrò méjèèjì yìí, ńṣe ni àwọn gbà pé ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí èèyàn lè gbà ní ìbálòpọ̀. Daniel, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà níléèwé, àwọn ọ̀dọ́ tí kì í ṣe abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ pàápàá gbà pé bí o kò bá fi ojú tó dáa wo àṣà náà, á jẹ́ pé ẹlẹ́tanú àti alárìíwísí ni ẹ́.”a
Ojú táwọn èèyàn fi ń wo àṣà náà yàtọ̀ síra láti ìran kan sí òmíràn àti láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Àmọ́, ní ti àwọn Kristẹni, a kì í gbé wọn “kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a . . . ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́.” (Éfésù 4:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé.
Kí ni Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀? Ìyẹn kí ọkùnrin àti obìnrin máa bá ara wọn lò pọ̀ tàbí kí obìnrin àti obìnrin máa bá ara wọn lò pọ̀. Bó bá jẹ́ pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù lò ń tẹ̀ lé, báwo lo ṣe lè fèsì nígbà táwọn kan bá pè ẹ́ ní ẹlẹ́tanú, alárìíwísí, tàbí tí wọ́n sọ pé ńṣe lo kórìíra àwọn tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ tàbí pé ò ń bẹ̀rù wọn? Wo àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí àti bó o ṣe lè fèsì.
Kí ni Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀? Bíbélì sọ ní kedere pé àárín ọkùnrin àti obìnrin ni Ọlọ́run ṣètò pé kí ìbálòpọ̀ ti máa wáyé, èyí sì gbọ́dọ̀ jẹ́ láàárín àwọn tó ti ṣègbéyàwó nìkan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Léfítíkù 18:22; Òwe 5:18, 19) Nígbà tí Bíbélì sọ pé àgbèrè kò dáa, ìbẹ́yà-kan-náà lòpọ̀ àti ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin tí kì í ṣe ọkọ àtìyàwó ló ń sọ.b—Gálátíà 5:19-21.
Bí ẹnì kan bá bi ẹ́ pé: “Kí ni èrò rẹ nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀?”
O lè sọ pé: “Mi ò kórìíra àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ o, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe ni mi ò nífẹ̀ẹ́ sí.”
✔ Rántí pé: Bó bá jẹ́ pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù lò ń tẹ̀ lé, á jẹ́ pé irú ìgbé ayé tó o yàn nìyẹn, ẹ̀tọ́ rẹ sì ni. (Jóṣúà 24:15) Má ṣe jẹ́ kí ojú tì ẹ́ láti sọ èrò rẹ.—Sáàmù 119:46.
Ṣebí ó yẹ káwọn Kristẹni máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn láìka ọ̀nà yòówù kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa gbà ní ìbálòpọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.” (1 Pétérù 2:17) Torí náà, àwọn Kristẹni ò kórìíra àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, wọn kì í sì í bẹ̀rù wọn. Gbogbo èèyàn ni wọ́n máa ń fi inúure hàn sí, títí kan àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀.—Mátíù 7:12.
Bí ẹnì kan bá béèrè pé: “Ṣé èrò tó o ní nípa àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ yìí kò lè sọ ẹ́ di ẹlẹ́tanú?”
O lè sọ pé: “Rárá o. Ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ni mo kórìíra, kì í ṣe àwọn tó ń dá àṣà náà.”
✔ O lè fi kún un pé: “Bí àpẹẹrẹ, mi kì í mu sìgá, kódà, mo kórìíra rẹ̀ gan-an. Àmọ́, ká sọ pé ìwọ máa ń mu sìgá, o sì fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Mi ò lè torí ìyẹn kí n máa ṣe ẹ̀tanú sí ẹ, ó sì dá mi lójú pé ìwọ náà kò ní ṣe ẹ̀tanú sí mi torí pé èmi kì í mu sìgá. Àbí? Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn nípa èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a ní lórí ọ̀rọ̀ ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀.”
Ṣebí Jésù sọ pé ká tẹ́wọ́ gba gbogbo èèyàn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé kò wá yẹ kí àwọn Kristẹni fàyè gba ìbẹ́yà-kan-náà lò pọ̀? Jésù kò sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fara mọ́ ọ̀nà yòówù káwọn èèyàn máa gbà gbé ìgbé ayé wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, o sọ pé ọ̀nà ìgbàlà ṣí sílẹ̀ fún “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú [òun].” (Jòhánù 3:16) Láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà tí Ọlọ́run fẹ́ kéèyàn máa hù, ó sì sọ àwọn ìwà kan tí kò yẹ ká máa hù, irú bí ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀.—Róòmù 1:26, 27.
Bí ẹnì kan bá sọ pé: “Àwọn tó ń dá àṣà yìí kò lè yí pa dà, bí Ọlọ́run ṣe dá wọn nìyẹn.”
O lè sọ pé: “Bíbélì kò ṣàlàyé ohun tó ń fa bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, àmọ́ ó sọ pé àwọn ìwà kan wà tó ti wọ àwọn èèyàn kan lára gan-an. (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti mọ́ àwọn kan lára gan-an láti máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn, ohun tí Bíbélì sọ ni pé kí àwọn Kristẹni má ṣe lọ́wọ́ sí àṣà náà.”
✔ Àbá kan rèé: Dípò tí wàá fi ki ara bọ àlàyé nípa ohun tó ń mú kí ọkàn èèyàn máa fà sí bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀, ńṣe ni kó o sọ pé Bíbélì ka àṣà náà léèwọ̀. O lè ṣe ìfiwéra kan pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé ó lè jẹ́ pé àwọn tó ń hùwà ipá jogún rẹ̀ látara àwọn òbí wọn ni. (Òwe 29:22) Ká tiẹ̀ wá gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Ìwọ náà mọ̀ pé Bíbélì ní ká má ṣe máa bínú sódì. (Sáàmù 37:8; Éfésù 4:31) Ǹjẹ́ a lè sọ pé ohun tí Bíbélì sọ yìí kò dáa torí pé àwọn kan lè wà tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n jogún ìbínú yìí látara àwọn òbí wọn?”
Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè sọ fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ máa ń fà sí bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀ pé kó má ṣe bẹ́ẹ̀? Òfin yẹn ti le jù. Ohun tó máa ń fa irú èrò yìí ni ohun tí kò tọ̀nà táwọn èèyàn máa ń sọ pé, ọ̀nà yòówù tó bá wu èèyàn láti gbà ní ìbálòpọ̀ ló gbọ́dọ̀ gbà ṣe é. Bíbélì buyì kún àwa èèyàn nípa bó ṣe mú kó dá wa lójú pé, a lè yàn láti má ṣe lọ́wọ́ sí ìbálòpọ̀ lọ́nà tí kò tọ́ tó bá dìídì wù wá láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Kólósè 3:5.
Bí ẹnì kan bá sọ pé: “Ká tiẹ̀ wá sọ pé ìwọ kì í ṣe abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, ó yẹ kó o tiẹ̀ lè máa fi ojú tó dáa wo àṣà náà.”
O lè sọ pé: “Ká sọ pé mi ò fẹ́ràn tẹ́tẹ́ títa, àmọ́ ìwọ máa ń ta tẹ́tẹ́. Ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu pé kó o ní kí n yí èrò mi pa dà dandan torí pé àìmọye èèyàn ló ń ta tẹ́tẹ́?”
✔ Rántí pé: Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn, (tó fi mọ́ àwọn tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀) ló ní àwọn ìlànà ìwà rere tó mú kí wọ́n kórìíra àwọn nǹkan kan, irú bíi jìbìtì, ìwà ìrẹ́jẹ tàbí ogun. Bíbélì ka àwọn ìwà yẹn léèwọ̀; ó tún ka oríṣi àwọn ìbálòpọ̀ kan léèwọ̀, tó fi mọ́ bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
Ohun tí Bíbélì sọ bọ́gbọ́n mu, kò sì sọ pé kéèyàn máa ṣe ẹ̀tanú. Ohun tó sọ fún àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ náà ló sọ fún àwọn tí kì í ṣe abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, ó ní kí wọ́n máa “sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn tí ọkàn wọn máa ń fà sí ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin sí obìnrin ló máa ń kó ara wọn níjàánu torí pé wọ́n fẹ́ láti máa ṣègbọràn sí àwọn ìlànà Bíbélì láìka ìdẹwò tí wọ́n lè dojú kọ sí. Lára wọn ni àwọn tọkùnrin tobìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó, tí kò sì dájú pé wọ́n máa ṣè bẹ́ẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn tó ti ṣègbéyàwó àmọ́ tí ọkọ tàbí aya wọn ní àìsàn tí kò jẹ́ kí wọ́n lè ní ìbálòpọ̀. Tayọ̀tayọ̀ ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi ń gbé ìgbé ayé wọn láìsí ìbálòpọ̀. Àwọn tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn lóòótọ́.—Diutarónómì 30:19.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.
b Nígbà tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa “àgbèrè,” kì í ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àmọ́ o tún kan fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì tàbí kéèyàn máa ti ihò ìdí báni lò pọ̀.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
● Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fún àwa èèyàn ní òfin nípa ìwà tó yẹ ká máa hù?
● Báwo lo ti ṣe jàǹfààní látinú ṣíṣègbọràn sí àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
TÉÈYÀN BÁ Ń BÁ TỌKÙNRIN TOBÌNRIN LÒ PỌ̀ ŃKỌ́?
Òótọ́ ni pé àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin ló ń lọ́wọ́ sí àṣà kéèyàn máa bá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀, síbẹ̀ ó jọ pé àárín àwọn obìnrin ni àṣà yìí wá ń pọ̀ sí jù lọ báyìí. Gbé àwọn ohun tó ń fà á yẹ̀ wò.
● Wọ́n ń fẹ́ àfiyèsí
“Àwọn ọkùnrin máa ń sọ ní gbangba pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí àwọn obìnrin tó bá ń bá obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀. Ó fẹ́ẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí àwọn obìnrin tí kò bá dá ara wọn lójú ò lè ṣe láti fa ojú ọkùnrin mọ́ra.”—Jessica, ọmọ ọdún 16.
● Wọ́n fẹ́ tọ pinpin
“Tí wọ́n bá gbé àwòrán àwọn obìnrin tó ń fi ẹnu ko obìnrin bíi tiwọn lẹ́nu jáde nínú fíìmù, lórí Tẹlifíṣọ̀n àti nínú orin, àwọn ọ̀dọ́ á fẹ́ gbìyànjú ẹ̀ wò, pàápàá jù lọ tí wọn kò bá rí ohun tó burú ńbẹ̀.”—Lisa, ọmọ ọdún 26.
● Àwọn ẹlòmíì nífẹ̀ẹ́ sí wọn
“Mo bá àwọn ọmọbìnrin méjì kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí bíbá ọkùnrin àti obìnrin lò pọ̀ pà dé níbi ayẹyẹ kan. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni ọ̀rẹ́ mi kan wá sọ fún mi pé àwọn ọmọbìnrin méjèèjì yẹn fẹ́ràn mi. Nígbà tó yá, mọ bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù sí ọ̀kan lára wọn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bíi pé ọkùnrin ni.”—Vicky, ọmọ ọdún 13.
Tó o bá fẹ́ kí inú Ọlọ́run dùn sí ẹ, o ò gbọ́dọ̀ dán àṣà tí Bíbélì pè ní ìwà àìmọ́ wò. (Éfésù 4:19; 5:11) Àmọ́, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ sí bíbá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀ ńkọ́? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ fún ẹ pé kò sí nǹkan tó burú ńbẹ̀ àti pé kó o má ṣe tijú láti sọ ní gbangba pé o nífẹ̀ẹ́ sí bíbá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀. Àmọ́, nǹkan pàtàkì kan tó yẹ kó o mọ̀ ni pé téèyàn bá ń nífẹ̀ẹ́ sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀, kì í sábà pẹ́ tí irú èrò bẹ́ẹ̀ fi máa ń kúrò lọ́kàn ẹni. Ohun tí Lisette, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], wá mọ̀ nígbà tó yá nìyẹn. Ó sọ pé: “Ara máa ń tù mí tí n bá sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára mi fún àwọn òbí mi. Nígbà tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ níléèwé nípa àwọn nǹkan alààyè, wọ́n kọ́ wa pé téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, bí àwọn omi ara tó máa ń súnni ṣe nǹkan, ìyẹn hormone, ṣe máa ń sun nínú ara máa ń yàtọ̀ síra. Ó dá mi lójú pé bí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ bá túbọ̀ mọ bí ara wọn ṣe ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ó máa yé wọn pé ìfẹ́ téèyàn máa ń ní láti bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀ kì í pẹ́ lọ títí, wọn ò sì ní fẹ́ láti máa bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀.”
Bí ìmọ̀lára tó ò ń ní láti lọ́wọ́ sí àṣà yìí bá lágbára gan-an débi pé ó ṣòro gan-an fún ẹ láti mọ́kàn kúrò nínú rẹ̀, má gbàgbé pé Bíbélì sọ nǹkan kan tó o lè ṣe: O lè pinnu pé o ò ní ṣe ohun búburú èyíkéyìí tó bá wá sí ẹ lọ́kàn.c
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, lọ wo orí 28 tí àkòrí rẹ̀ sọ pé “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sá Fún Bíbá Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Lò Pọ̀?,” nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ Apá Kejì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Tó bá dọ̀rọ̀ ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí, àwọn Kristẹni ní ìgboyà láti kẹ̀yìn síbi tí ayé kọjú sí