ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/07 ojú ìwé 18-20
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sá Fún Bíbẹ́yà Kan Náà Lò Pọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sá Fún Bíbẹ́yà Kan Náà Lò Pọ̀?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Bíbẹ́yà Kan Náà Lò Pọ̀?
  • Kọ Àwọn Ìwà Búburú Sílẹ̀
  • Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Láé!
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sá Fún Bíbá Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Lò Pọ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀?
    Jí!—2011
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kannáà-Lòpọ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Ṣó Burú Kí Ọkùnrin Máa Fẹ́ Ọkùnrin àbí Kí Obìnrin Máa Fẹ́ Obìnrin?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 4/07 ojú ìwé 18-20

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sá Fún Bíbẹ́yà Kan Náà Lò Pọ̀?

“Ọmọ ọdún méjìlá ni mí tí ọkàn mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ọmọbìnrin kan bíi tèmi nílé ẹ̀kọ́. Ó tojú sú mi, mo sì ń dààmú pé kí n má lọ ya obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Anna.a

“Ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́tàdínlógún ni mí tí ọkàn mi ti ń fà sáwọn ọkùnrin bíi tèmi. Mo sì mọ̀ nínú ọkàn mi pé irú èrò bẹ́ẹ̀ ò dáa.”—Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Olef.

“Ó tó ẹ̀ẹ̀kan sí ẹ̀ẹ̀mejì témi àti obìnrin bíi tèmi fẹnu kora wa lẹ́nu. Àmọ́, mo ṣì ń nífẹ̀ẹ́ sáwọn ọkùnrin, mo wá ń wò ó pé àfàìmọ̀ kí n má ya ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí bíbá ọkùnrin àti obìnrin lò pọ̀.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah.

ÌWÀ ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ inú ayé òde òní ti sún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láti máa dán ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yà kan náà wò. Becky, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin tá a jọ ń relé ìwé máa ń sọ pé obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀ tàbí obìnrin tó ń bá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀ làwọn. Àwọn míì á sì sọ pé kò séyìí táwọn ò nífẹ̀ẹ́ sí nínú méjèèjì.” Ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìdínlógún kan tó ń jẹ́ Christa sọ pé bọ́ràn ṣe rí nílé ìwé tàwọn náà nìyẹn. Ó ní: “Méjì lára àwọn ọmọbìnrin tá a jọ wà ní kíláàsì tiẹ̀ ti ní kí n jẹ́ ká jọ bára wa lò pọ̀. Nínú ìwé tí ọ̀kan lára wọn kọ sí mi, ó bi mí bóyá màá fẹ́ láti mọ bí ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin bíi tẹni ṣe máa ń rí.”

Léyìí ti ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá ń lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yà kan náà láìfi bò mọ́ báyìí, ó lè máa ṣe ẹ́ ní kàyéfì pé: “Ṣó tiẹ̀ burú pé kéèyàn máa bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ ni? Bí ọkàn mi bá ń fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèmi ńkọ́? Ṣé ìyẹn máa fi hàn pé abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ni mí?’

Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Bíbẹ́yà Kan Náà Lò Pọ̀?

Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn, tó fi mọ́ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, ni ò fọwọ́ tó le mú ọ̀ràn ìbẹ́ya-kan-náà-lòpọ̀. Síbẹ̀, Bíbélì ò firọ́ pé òótọ́ fún wa lórí irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ó sọ fún wa pé Jèhófà Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin, àárín àwọn méjèèjì tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya yìí ló sì fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ mọ sí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:24) Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé Bíbélì dẹ́bi fún bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀.—Róòmù 1:26, 27.

Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa sọ pé Bíbélì ò bágbà mu mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó ń jẹ́ Megan sọ pé: “Lára àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ ò bá ayé òde ìwòyí mu páàpáà.” Àmọ́, kí ló fà á táwọn kan fi tètè máa ń sọ bẹ́ẹ̀ yẹn? Lọ́pọ̀ ìgbà, ó sábà máa ń jẹ́ nítorí pé Bíbélì ta ko ohun tó wù wọ́n. Wọ́n kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ nítorí pé ohun tó fi ń kọ́ni yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n fẹ́ láti gbà gbọ́. Èrò òdì nìyẹn ṣá o, Bíbélì sì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe gba ọkàn wa láyè láti máa ro ìròkurò bẹ́ẹ̀! Kódà, Jèhófà Ọlọ́run rọ̀ wá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká má ṣe gbà gbé pé ire ara wa làwọn àṣẹ òun wà fún. (Aísáyà 48:17, 18) Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu. Àbí, ta ló mọ tinú tòde wa ju Ẹlẹ́dàá lọ?

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin, oríṣiríṣi èrò lè máa wá sí ẹ lọ́kàn. Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn ẹ ń fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ ńkọ́? Ṣé ìyẹn á ti yáa wá túmọ̀ sí pé abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ni ẹ́? Rárá o. Rántí pé o ṣì wà ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” àkókò tí ara ẹ á máa ṣàdédé wà lọ́nà fún ìbálòpọ̀. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Fún àwọn àkókò kan, ọkàn ẹ lè máa fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Àmọ́, irú òòfà ọkàn bẹ́ẹ̀ yẹn ò fi hàn pé abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ni ẹ́. Kódà, ìwádìí fi hàn pé kì í pẹ́ tírú èrò bẹ́ẹ̀ fi máa ń lọ kúrò. Síbẹ̀, ó lè máa ṣe ẹ́ ní kàyéfì pé, ‘Báwo gan-an tiẹ̀ nirú àwọn èrò yìí ṣe ń bẹ̀rẹ̀?’

Àwọn kan sọ pé inú apilẹ̀ àbùdá èèyàn ni ìfẹ́ fún bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀ máa ń wà. Àwọn míì sọ pé àṣà téèyàn lè kọ́ ni. A ò kọ àpilẹ̀kọ yìí nítorí ká lè máa jiyàn lórí bí ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ṣe ń bẹ̀rẹ̀, ìyẹn ni pé bóyá ńṣe ni wọ́n ń bí i mọ́ni tàbí pé ìwà téèyàn lè kọ́ ni tàbí kó jẹ́ àṣà ìbílẹ̀ ẹni tàbí kó jẹ́ ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe. Àní sẹ́, bí ẹní fojú ọ̀rọ̀ sílẹ̀ tó ń sọ kábakàba ló máa jẹ́ béèyàn bá sọ pé ohun kan ṣoṣo báyìí ló ń fà á téèyàn fi máa ń fẹ́ láti bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Bíi tàwọn ìwà míì téèyàn ń hù lọ̀rọ̀ bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀ rí, ó dà bí ẹni pé ohun tó ń fà á díjú gan-an ju béèyàn ṣe lè rò lọ.

Ohun yòówù kó máa fà á ṣá, ohun pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ mọ̀ ni pé Bíbélì ò lọ́wọ́ sí bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀. Nítorí náà, bí èrò bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀ bá ń da ẹnì kan láàmú, ọ̀ràn irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò tíì kọjá àtúnṣe—ẹnu kí onítọ̀hún pinnu pé òun ò ní gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè ni. Àpèjúwe kan rèé: Ẹnì kan lè jẹ́ ẹni tó máa ń “fi ara [ẹ̀] fún ìhónú.” (Òwe 29:22) Kírú ẹni bẹ́ẹ̀ tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè jẹ́ pé kọ́rọ̀ tó ṣe bí ọ̀rọ̀ pẹ́rẹ́n ló ti máa fàbínú yọ. Àmọ́ lẹ́yìn tó bá ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á ti mọ̀ pé ó pọn dandan kóun máa lo ìkora-ẹni-níjàánu. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ìbínú ò tún ní ru sókè nínú ẹ̀ mọ́ láé? Ó tì o. Àmọ́, nítorí pé ó mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa kéèyàn máa fàbínú yọ, ṣe ló máa yára kóra ẹ̀ níjàánu. Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn nínú ọ̀ràn ẹni tí ọkàn ẹ̀ ń fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ àmọ́ tó ti wá mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Èrò tí ò tọ́ ṣì lè máa wá sọ́kàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan o. Síbẹ̀, nípa kíkọbi ara sí ìmọ̀ràn inú Bíbélì, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè pinnu pé òun ò ní mú irú ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ ṣẹ.

Òótọ́ kan ni pé, ìfẹ́ láti bá ẹlòmíì lò pọ̀ máa ń lágbára gan-an lórí ẹni. Síbẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé bó ti wù kí ìfẹ́ láti ṣe ohun tí ò tọ́ lágbára tó, kò lè le kọjá ohun téèyàn lè ṣe nǹkan nípa ẹ̀ lọ. (1 Kọ́ríńtì 9:27; Éfésù 4:22-24) Ó ṣì dájú gbangba pé ọwọ́ ẹ ni bí wàá ṣe máa darí ìgbésí ayé ẹ wà. (Mátíù 7:13, 14; Róòmù 12:1, 2) Ohun yòówù káwọn tí ò fẹ́ jáwọ́ máa sọ, ṣì mọ̀ dájú pé o lè kọ́ bí wàá ṣe máa darí èrò ọkàn rẹ tàbí, bó bá tiẹ̀ wá burú pátápátá, o lè pinnu pé o ò ní lọ́wọ́ sí ohun búburú èyíkéyìí.

Kọ Àwọn Ìwà Búburú Sílẹ̀

Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa lọ́wọ́ sí bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀?

◼ Àkọ́kọ́ Kó gbogbo àníyàn rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà nínú àdúrà, kó o sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “ó bìkítà fún [ẹ].” (1 Pétérù 5:7; Sáàmù 55:22) Jèhófà lè sọ ẹ́ di alágbára nípa fífún ẹ ni àlàáfíà tó “ta gbogbo ìrònú yọ.” Àlàáfíà yìí á ‘máa ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ àti agbára èrò orí rẹ’ á sì fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” èyí tí kò ní jẹ́ kó o hùwà búburú náà. (Fílípì 4:7; 2 Kọ́ríńtì 4:7) Sarah tó jà fitafita nítorí ẹ̀rù tó ń bà á pé bóyá obìnrin tó ń bá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀ lòun fẹ́ yà, sọ pé: “Nígbàkigbà tí èrò ọkàn mi bá ń dà mí láàmú, mo máa ń gbàdúrà; Jèhófà sì máa ń gbé mi ró. Láìsí ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń pèsè yìí, kì bá tí ṣeé ṣe fún mi láti kojú ìṣòro náà. Àdúrà ló gbà mí sílẹ̀!”—Sáàmù 94:18, 19; Éfésù 3:20.

◼ Ìkejì Fi àwọn èrò tẹ̀mí tí ń gbéni ró kún inú ọkàn rẹ. (Fílípì 4:8) Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Má ṣe fojú kéré agbára tí Bíbélì ní láti mú kó o máa ronú lọ́nà rere kó o sì máa fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. (Hébérù 4:12) Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jason sọ pé: “Nínú Bíbélì, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10 àti Éfésù 5:3, nípa gidigidi lórí mi. Mo máa ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí nígbàkigbà tí èrò búburú bá wá sí mi lọ́kàn.”

◼ Ìkẹta Sá fún àwọn nǹkan tó bá ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe àti ohunkóhun tó bá ń gbé ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ lárugẹ, tí wọn ò ní í ṣe ju kí wọ́n máa gbé èròkerò wá séèyàn lọ́kàn.b (Sáàmù 119:37; Kólósè 3:5, 6) Àwọn àwòrán sinimá kan àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tún máa ń mú kéèyàn gbà gbọ́ pé wíwulẹ̀ gbé irú ìgbési ayé kan tó yàtọ̀ ni bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀. Anna sọ pé: “Èrò òdì táwọn èèyàn ní nípa ìbálòpọ̀ ló nípa lórí ìrònú mi tí ò sì jẹ́ kí n mọ èwo gan-an ló yẹ ní ṣíṣe mọ́. Àmọ́ ní báyìí ṣá o, n kì í tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ sétí.”—Òwe 13:20.

◼ Ìkẹrin Wá ẹni tó o lè fọ̀rọ̀ pa mọ́ sí lọ́wọ́, kó o sì sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún un. (Òwe 23:26; 31:26; 2 Tímótì 1:1, 2; 3:10) Olef rántí ohun tó ṣẹ̀lẹ̀ nígbà tó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ alàgbà kan, ó ní: “Ìmọ̀ràn tó fún mi múná dóko gan-an ni. Ká ní mo mọ̀ ni, ǹ bá ti sọ fún un tipẹ́.”

Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Láé!

Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lè sọ pé àwọn ò rí sí ṣíṣe gbogbo èyí tá à ń sọ yìí o jàre, wọ́n á ní ó sàn kéèyàn kúkú fara mọ́ ìbálòpọ̀ èyíkéyìí tó bá ti bá a lára mu, kó sì gbà pé bọ́rọ̀ tòun ṣe rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé o lè ṣe ohun tó dáa jùyẹn lọ! Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún wa nípa àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti bẹ́yà kan náà lò pọ̀ rí, àmọ́ tí wọ́n yí padà. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ìwọ pẹ̀lú lè ja ìjà náà ní àjàyege, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe lo ṣì ń rún un mọ́ra ní báyìí ná.

Bí èròkérò ò bá yé wá sí ẹ lọ́kàn, má ṣe juwọ́ sílẹ̀, má sì ṣe kà á sí pé aláṣetì ni ẹ́. (Hébérù 12:12, 13) Gbogbo wa náà lá máa ń bá àwọn èrò òdì fà á lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Róòmù 3:23; 7:21-23) Bó o bá kọ̀ láti mú ìfẹ́ búburú tó wá sí ẹ lọ́kàn ṣẹ, bó bá yá ìfẹ́ búburú náà á wábi gbà. (Kólósè 3:5-8) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbára lé Jèhófà kó bàa lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó fẹ́ràn rẹ, ó sì mọ ohun tó máa mú ẹ láyọ̀. (Aísáyà 41:10) Bẹ́ẹ̀ ni, “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere. . . , òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”—Sáàmù 37:3, 4.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.

b Irú ìgbésí ayé kan táwọn èèyàn tún ń gba wèrè ẹ̀ báyìí ni tàwọn ọkùnrin tí wọ́n ń ki àṣejù bọ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà pàfiyèsí síra wọn, pàápàá ọ̀nà tí wọ́n ń gbà múra, débi tó fi ṣòro láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ẹni tó ń bẹ́yà kan náà lò pọ̀ àtẹni tó ń bá ẹ̀yà kejì lò pọ̀. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé, ẹni tó bá ń gbé irú ìgbésí ayé yìí ‘lè jẹ́ abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ tí òfin fọwọ́ sí, ó lè jẹ́ ẹni tó ń bá ẹ̀yà kejì lò pọ̀, ó sì lè jẹ́ ẹni tó ń bá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀. Àmọ́, kékeré lèyí jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti ṣe ki àṣejù bọ ìfẹ́ tó ń ní síra ẹ̀, débi pé irú ìbálòpọ̀ tó bá ṣáà ti wù ú lá á máa fi tẹ́ra ẹ̀ lọ́rùn.’ Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tiẹ̀ sọ pé ohun tó mú kírú àṣà yìí gbajúmọ̀ ni “kíkà táwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ sí ẹni ìtẹ́wọ́gbà láwùjọ tí wọn ò sì ka bíbẹ́yà kan náà lò pọ̀ sí ohun tó burú mọ́, térò àwọn èèyàn ò sì ṣọ̀kan mọ́ nípa ànímọ́ tá a lè fi sọ pé ọkùnrin lẹnì kan.”

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Kí nìdí tí Ọlọ́run fi kórìíra ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀?

◼ Kí lo lè ṣe bí ọkàn ẹ bá ń fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ?

◼ Ta lo lè sọ fún bó bá jẹ́ pé èrò tó ń wá sí ẹ lọ́kàn ṣáá ni pé kó o máa bẹ́yà kan náà lò pọ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Wá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ àgbàlagbà kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́