ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/8 ojú ìwé 24-27
  • Jèhófà Mú Ipa Ọ̀nà Wa Jọ̀lọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Mú Ipa Ọ̀nà Wa Jọ̀lọ̀
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Ní Àwọn Ìbéèrè
  • Ìgbéyàwó àti Ìdílé
  • Wíwá Òtítọ́ Bíbélì
  • Rírí Òtítọ́ Bíbélì
  • Fífi Àwọn Ire Ìjọba sí Ipò Kíní
  • Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Bí A Ṣe Pa Òùngbẹ Tẹ̀mí Tó Ń Gbẹ Mí
    Jí!—2003
  • A Fara Da Ìpọ́njú, Jèhófà sì Bù Kún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Jí!—1997
g97 12/8 ojú ìwé 24-27

Jèhófà Mú Ipa Ọ̀nà Wa Jọ̀lọ̀

WỌ́N bí mi ní 1924, nítòsí Cham, ìlú kan ní àgbègbè Zug ní Switzerland. Ọmọ 13 ni àwọn òbí mi bí—ọkùnrin 10 àti obìnrin 3. Èmi ni àkọ́bí ọkùnrin. Ọkùnrin méjì kú lọ́mọdé. Wọ́n tọ́ àwa yòó kù dàgbà ní ìlànà ìsìn Kátólíìkì nínú oko kan nígbà Ìjórẹ̀yìn Ọrọ̀ Ajé Lọ́nà Gígọntiọ.

Dádì jẹ́ aláìlábòsí, tí ó ní ìwà ẹ̀dá rere, ṣùgbọ́n ó máa ń ní ìṣòro ìrunú fùfù. Ní ìgbà kan, ó tilẹ̀ lu Màmá ní àlùbolẹ̀ nígbà tí Màmá pẹ̀gàn rẹ̀ láìtọ́ nítorí ìjowú Màmá. Màmá kò lè gba àwàdà tí Bàbá ń bá àwọn obìnrin àdúgbò wa ṣe mọ́ra, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìdí kankan fún Màmá láti ṣiyè méjì ìṣòtítọ́ Bàbá. Èyí máa ń kó ìrora ọkàn bá mi gan-an.

Màmá máa ń gba ohun asán gbọ́. Yóò tilẹ̀ fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ pe àmì láti “ọ̀dọ̀ ọkàn àwọn òtòṣì ní pọ́gátórì.” Mo kórìíra irú ìgbàgbọ́ oréfèé bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà yóò kín àwọn èrò ìgbàgbọ́ asán rẹ̀ lẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ìwé kíkà tí ó ti èrò ìsìn èké tí ó ní lẹ́yìn.

Mo Ní Àwọn Ìbéèrè

Láti ìgbà ọmọdé mi ni àwọn ìbéèrè nípa Ọlọ́run àti kádàrá ènìyàn ti gbà mí lọ́kàn. Mo gbìyànjú láti dórí àwọn ìparí èrò tí ó bọ́gbọ́n mu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló ta kora! Mo ka àwọn ìtẹ̀jáde Kátólíìkì nípa àwọn ẹni mímọ́, iṣẹ́ ìyanu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwọ̀nyí kò tẹ́ ọgbọ́n ìrònú mi lọ́rùn. Mo nímọ̀lára bíi pé mo ń tá ràrà nínú òkùnkùn.

Àlùfáà àdúgbò gbà mí nímọ̀ràn láti má ṣe ronú lórí àwọn ìbéèrè tí mo ní. Ó sọ pé fífẹ́ láti lóye ohun gbogbo jẹ́ àmì ìgbéraga àti pé Ọlọ́run lòdì sí àwọn onírera. Ẹ̀kọ́ tí mo kórìíra jù lọ ni pé Ọlọ́run yóò máa dá àwọn ẹni yòó wù tí ó bá kú láìjẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn lóró títí ayérayé nínú ọ̀run àpáàdì oníná. Níwọ̀n bí èyí ti túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé ni a óò máa dá lóró títí ayérayé, mo máa ń ṣe kàyéfì lọ́pọ̀ ìgbà pé, ‘Báwo ni a ṣe lè mú èyí ṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run?’

Mo tún gbé ìbéèrè dìde sí àṣà ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn Kátólíìkì máa ń ṣe. Ẹ̀rù bà mí nígbà tí wọ́n sọ fún wa ní ilé ẹ̀kọ́ Kátólíìkì pé àwọn èrò àìmọ́ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbígbópọn tí ó béèrè fún ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ fún àlùfáà kan. Mo máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Mo ha rántí láti jẹ́wọ́ ohun gbogbo? Àbí mo ti gbàgbé ohun kan, tí ó fa kí ìjẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ mi máà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, kí a má sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí bí?’ Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n gbin iyè méjì sí mi lọ́kàn nípa àánú Ọlọ́run àti ìmúratán rẹ̀ láti dárí jini.

Fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta tàbí mẹ́rin, mo ń bá àwọn èrò amúnisoríkọ́ tí ó sọ mí di aláàárẹ̀ jà. Mo ronú nípa pípa gbogbo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tì. Ṣùgbọ́n n óò wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ‘Bí mo bá ń bá a lọ, láìṣe àní-àní n óò rí ọ̀nà tí ó tọ́.’ Bí àkókò ti ń lọ, mo mú ìgbọ́kànlé nínú wíwà Ọlọ́run dàgbà, àmọ́ àìdánilójú nípa àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn mi ń bá mi fínra.

Ní ìyọrísí títètè dá mi lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, mo gbà gbọ́ pé Jésù Kristi ní Ìjọ Roman Kátólíìkì lọ́kàn nígbà tí ó wí fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì mi lé.” (Mátíù 16:18, Douay Version ti Kátólíìkì) Mo wá gbà gbọ́ pé bópẹ́bóyá àwọn ohun rere inú ṣọ́ọ̀ṣì náà yóò borí, pẹ̀lú ète yẹn lọ́kàn, mo fẹ́ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì náà.

Ìgbéyàwó àti Ìdílé

Gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin tí ó dàgbà jù lọ nínú ìdílé, mo ń bá bàbá mi ṣiṣẹ́ ní oko títí di ìgbà tí àbúrò mi ọkùnrin tí ó tẹ̀ lé mi lè gbà ipò mi. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti Kátólíìkì, níbi tí mo ti gba oyè master. Lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá ẹni tí n óò gbé níyàwó.

Ọ̀kan lára àwọn àbúrò mi obìnrin mú mi mọ Maria. Mo gbọ́ pé ó ti gbàdúrà fún ọkọ tí òun pẹ̀lú rẹ̀ lè jọ sapá gidigidi fún ìyè àìnípẹ̀kun. A kọ ọ́ sínú ìkéde ìgbéyàwó wa pé: “A ń fi ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́ wá ayọ̀, a ń tẹjú wa mọ́ Ọlọ́run. Ọ̀nà ìyè ni a ń tọ̀, ìdùnnú ayérayé ni a sì ń lépa.” A ṣègbéyàwó ní June 26, 1958, ní ilé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti Fahr, nítòsí Zurich.

Ìgbésí ayé àtilẹ̀wá tèmi àti Maria jọra. Inú ìdílé ẹlẹ́mìí ìsìn gan-an ni ó ti wá, òun ló sì dàgbà jù lára àwọn ọmọ méje. Gbogbo wọn ń jára mọ́ṣẹ́ oko, iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, àti lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, nítorí náà kò fi bẹ́ẹ̀ sí àkókò fún eré. Àwọn ọdún àkọ́kọ́ tí a lò nínú ìgbéyàwó kò rọrùn. Nítorí àwọn ìbéèrè púpọ̀ tí mo ní nípa ọ̀ràn ìsìn, Maria wá ń ṣiyè méjì bóyá ọkùnrin tí ó yẹ ni òun fẹ́ lọ́kọ. Ó kọ̀ láti gbé ìbéèrè dìde sí àwọn ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni tàbí àṣà ṣíṣètìlẹ́yìn fún àwọn ogun, Àwọn Ogun Ìsìn, àti Àwọn Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwa méjèèjì gbẹ́kẹ̀ wa lé Ọlọ́run, a sì ní ìdánilójú pé níwọ̀n bí a ti ń wá àtiṣèfẹ́ rẹ̀ bí a ṣe lè ṣe dáradára tó, òun kò ní fi wá sílẹ̀ láé.

Ní 1959, a háyà oko kan nítòsí Homburg ní ìhà ìlà oòrùn Switzerland. Ibẹ̀ ni a gbé fún ọdún 31. Ní March 6, 1960, a bí Josef, ọmọkùnrin wa àkọ́kọ́. A bí àwọn ọmọkùnrin mẹ́fà àti ọmọbìnrin kan, Rachel, tẹ̀ lé e. Maria ti fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ ìyá tí kì í ṣe ojúsàájú, tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ sí àwọn ìlànà fífẹsẹ̀múlẹ̀. Ó ti jẹ́ ojúlówó ìbùkún fún ìdílé wa.

Wíwá Òtítọ́ Bíbélì

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àìmọ̀kan wa ní ti ìsìn túbọ̀ ń di èyí tí a kò lè mú mọ́ra mọ́. Ní apá ìparí àwọn ọdún 1960, a bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga fún Àwọn Kátólíìkì, àmọ́ a máa ń darí sílé pẹ̀lú ìdàrúdàpọ̀ tí ń pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ máa ń làdí àwọn èrò tiwọn, tí kò ní ẹ̀rí Ìwé Mímọ́. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1970, mo ronú nípa ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Bí ẹ bá béèrè fún ohunkóhun lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, òun yóò fi í fún yín. . . . Ẹ béèrè, ẹ óò sì rí gbà.”—Jòhánù 16:23, 24, Dy.

Ọ̀rọ̀ ìmúdánilójú òkè yí láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí n gbàdúrà léraléra pé: “Bàbá, bí ó bá jẹ́ Ìjọ Kátólíìkì ni ìsìn tòótọ́, jọ̀wọ́ fi hàn mí láìsí àṣìṣe. Ṣùgbọ́n bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, fi hàn mí ní kedere bákan náà, èmi yóò sì pòkìkí rẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn.” Mo tún bẹ̀bẹ̀ léraléra ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni Jésù nínú Ìwàásù lórí Òkè láti “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè.”—Mátíù 7:7, 8.

Ìjíròrò mi pẹ̀lú Maria—ní pàtàkì nípa àwọn ìyípadà nínú àwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì ní àwọn ọdún 1960 nípa ìjọsìn “àwọn ẹni mímọ́,” jíjẹ ẹran ní ọjọọjọ́ Friday, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—mú kí ó ṣiyè méjì níkẹyìn. Lẹ́ẹ̀kan, nígbà tí ó lọ fún ìsìn Máàsì ní ìgbà ìrúwé 1970, ó gbàdúrà pé: “Ìwọ Ọlọ́run, fi ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè ayérayé hàn wá. A kò mọ ọ̀nà tí ó tọ́ mọ́. Èmi yóò gba ohunkóhun, àmọ́ ṣá fi ọ̀nà tí ó tọ́ han ìdílé wa lápapọ̀.” N kò mọ̀ nípa àdúrà rẹ̀, òun pẹ̀lú kò sì mọ̀ nípa tèmi, títí di ìgbà tí a wá mọ̀ pé a ti gbọ́ àdúrà wa.

Rírí Òtítọ́ Bíbélì

Lẹ́yìn tí a darí sílé láti ṣọ́ọ̀ṣì ní òwúrọ̀ Sunday kan ní 1970, ẹnì kan kan ilẹ̀kùn. Ọkùnrin kan, tí ọmọdékùnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́wàá bá wá, sọ pé òun jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo fàyè gba ìjíròrò Bíbélì. Mo rò pé ó lè rọrùn fún mi láti já a nírọ́ nítorí láti inú àwọn ohun tí mo ti gbọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, n kò gbà gbọ́ pé wọ́n ní ìmọ̀ dáradára.

Wákàtí méjì ni a fi jíròrò láìfẹnu ọ̀rọ̀ jóná síbì kankan, bákan náà ló sì rí ní ọjọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e. Mo ń fojú sọ́nà fún ìjíròrò ẹlẹ́ẹ̀kẹta, àmọ́ Ẹlẹ́rìí náà kò yọjú. Maria sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ọkùnrin náà rí i pé kò já mọ́ nǹkan kan. Inú mi dùn nígbà tí ó pa dà wá ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo sọ pé: “Mo ti ń ṣe kàyéfì nípa ọ̀run àpáàdì fún ọdún 35. N kò kàn lè gbà pé ó yẹ kí Ọlọ́run, tí ó jẹ́ ìfẹ́, máa dá àwọn ẹ̀dá lóró lọ́nà òǹrorò bẹ́ẹ̀.”

Ẹlẹ́rìí náà fèsì pé: “Òótọ́ lo sọ. Bíbélì kò fi kọ́ni pé hẹ́ẹ̀lì jẹ́ ibi ìdánilóró.” Ó fi hàn mí pé ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì náà fún Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì, tí wọ́n sábà máa ń túmọ̀ sí “ọ̀run àpáàdì” nínú Bíbélì Kátólíìkì, wulẹ̀ tọ́ka sí sàréè lásán ni. (Jẹ́nẹ́sísì 37:35; Jóòbù 14:13; Ìṣe 2:31) Bákan náà, ó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó fẹ̀rí hàn pé ọkàn ènìyàn lè kú àti pé ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀, kì í ṣe ìdánilóró. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4; Róòmù 6:23) Èyí wá mú mi bẹ̀rẹ̀ sí í rí i kedere pé wọ́n ti fi irọ́ tí ó wà nínú ìsìn dí mi lójú ní gbogbo ìgbésí ayé mi. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì bóyá àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn míràn tí ó jẹ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì kì í ṣe òtítọ́.

N kò fẹ́ kí wọ́n máa tàn mí jẹ mọ́, nítorí náà mo ra ìwé atúmọ̀ èdè ti Bíbélì Kátólíìkì àti ìwé ìtàn àwọn póòpù tí ó wà nínú ìdìpọ̀ márùn-ún. Àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí gba àṣẹ ìtẹ̀wéjáde, ìyẹn ni pé, bíṣọ́ọ̀bù apàṣẹ ti fọwọ́ sí títẹ̀ wọ́n. Kíka ìtàn àwọn póòpù mú mi mọ̀ pé àwọn kan nínú wọn wà lára àwọn ọ̀daràn bíburú jù lọ lágbàáyé! Àti nípa yíyẹ ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì náà wò, mo mọ̀ pé Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀run àpáàdì, pọ́gátórì, àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni ni kò sí nínú Bíbélì.

Ní báyìí, mo ti ṣe tán láti jẹ kí Ẹlẹ́rìí náà kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lákọ̀ọ́kọ́, Maria máa ń jókòó tì wá kìkì kí ó lè fi ìwà yíyẹ hàn, àmọ́ láìpẹ́, ó fayọ̀ tẹ́wọ́ gbà ohun tí ó kọ́. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, mo fi Ìjọ Kátólíìkì sílẹ̀, mo sì fi tó àlùfáà létí pé àwọn ọmọ wa kò ní máa wá sí àwọn kíláàsì ẹ̀kọ́ ìsìn mọ́. Ní ọjọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e, àlùfáà náà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo gbégbèésẹ̀ láti gbèjà ìgbàgbọ́ mi, ní lílo Bíbélì, àmọ́ àlùfáà náà kò fàyè gba irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀.

Lẹ́yìn ìyẹn, a ní ìtẹ̀síwájú kánmọ́kánmọ́. Níkẹyìn, èmi àti ìyàwó mi fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa fún Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi ní December 13, 1970. Ọdún kan lẹ́yìn náà, mo ní láti lo oṣù méjì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀ràn àìdásí-tọ̀tún-tòsì Kristẹni. (Aísáyà 2:4) Kò rọrùn láti fi aya mi àti àwọn ọmọ mẹ́jọ sílẹ̀, kódà fún àkókò tí ó kúrú tó bẹ́ẹ̀. Ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà wulẹ̀ jẹ́ láti oṣù 4 sí ọdún 12. Àti pé a ní oko kan àti àwọn ẹran ọ̀sìn tí a ní láti bójú tó. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, wọ́n lè kojú ipò náà láìsí mi níbẹ̀.

Fífi Àwọn Ire Ìjọba sí Ipò Kíní

Kò sí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé wa tó jẹ́ pa ìpàdé ìjọ jẹ àyàfi bí ara rẹ̀ kò bá yá. A sì ṣètò iṣẹ́ wa lọ́nà tí ó fi jẹ́ pé a kò pa èyíkéyìí lára àwọn àpéjọpọ̀ ńláńlá jẹ rí. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn eré àṣedárayá tí àwọn ọmọ máa ń ṣe ní abẹ́ òrùlé wa ń dá lé fífi ohun tí wọ́n rí ní àwọn ìpàdé Kristẹni ṣeré. Fún àpẹẹrẹ, wọn óò yan àwọn ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ fún ara wọn, wọn óò sì fi àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ dánra wò. A láyọ̀ pé gbogbo wọn tẹ́wọ́ gba ìtọ́ni tẹ̀mí tí a fún wọn. Mo ṣìkẹ́ rírántí bí wọ́n ṣe fọ̀rọ̀ wá èmi àti ìyàwó mi lẹ́nu wò ní àpéjọ àyíká kan, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ní ìjókòó—láti orí èyí tí ó dàgbà jù sí èyí tí ó kéré jù—tí wọ́n ń tẹ́tí sílẹ̀ dáradára.

Títọ́ àwọn ọmọ wa dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” di lájorí àníyàn wa. (Éfésù 6:4) A pinnu láti palẹ̀ tẹlifíṣọ̀n wa mọ́, a sì sábà máa ń pe àwọn onítara Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa wá sí ilé wa kí àwọn ọmọ wa lè jàǹfààní láti inú àwọn ìrírí àti ìtara ọkàn wọn. A máa ń ṣọ́ra láti má ṣe sọ àwọn ọ̀rọ̀ aláìgbatẹnirò, kí a má sì ṣe àríwísí àwọn ẹlòmíràn. Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀, a óò jíròrò ọ̀ràn náà, a óò sì wá àwọn ipò tí yóò dín ìṣòro náà kú. A gbìyànjú láti ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti fojú díwọ̀n ipò kan lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu tí ó sì tọ́. A fi ìṣọ́ra yẹra fún ṣíṣe ìfiwéra pẹ̀lú àwọn èwe mìíràn. A sì mọ ìjẹ́pàtàkì kí àwọn òbí máṣe kẹ́ ọmọ ní àkẹ́bàjẹ́ tàbí dídáàbò bò wọ́n láti máṣe jìyà ìyọrísí ìgbésẹ̀ wọn.—Òwe 29:21.

Síbẹ̀, a kò ṣàìní ìṣòro nínú títọ́ àwọn ọmọ wa. Fún àpẹẹrẹ, nígbà kan, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tàn wọ́n sínú mímú mindin-mín-ìndìn ní ilé ìtajà kan láìsanwó rẹ̀. Nígbà tí a gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, a ní kí àwọn ọmọ wa pa dà lọ sí ilé ìtajà náà láti san owó rẹ̀, kí wọ́n sì tọrọ àforíjì. Ó kó ojútì bá wọn, àmọ́ wọ́n kọ́ ohun kan nípa àìṣàbòsí.

Dípò wíwulẹ̀ fipá mú àwọn ọmọ wa láti bá wa lọ nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù, a ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa fífi irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ sí ipò kíní. Àwọn ọmọ rí i pé a fi ìpàdé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ṣáájú iṣẹ́ oko wa. Dájúdájú, àwọn ìsapá wa láti tọ́ àwọn ọmọ wa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ dàgbà lọ́nà ti Jèhófà ni a bù kún.

Josef, ọmọkùnrin wa tó dàgbà jù, jẹ́ Kristẹni alàgbà, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì sìn fún ọdún bíi mélòó kan ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Switzerland. Alàgbà ni Thomas, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Alàgbà ni Daniel, tí ó jọ̀wọ́ iṣẹ́ àṣejẹun rẹ̀ bí olùborí nínú ìdíje kẹ̀kẹ́ gígùn, aṣáájú ọ̀nà sì ni òun àti ìyàwó rẹ̀ ní ìjọ mìíràn. Benno àti ìyàwó rẹ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ tí ó gbó ṣáṣá ní àárín gbùngbùn Switzerland. Christian, ọmọkùnrin wa karùn-ún, ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ní ìjọ tí a wà. Ó ti gbéyàwó, ó sì ti bímọ méjì. Aṣáájú ọ̀nà ni Franz, ó sì tún jẹ́ alàgbà nínú ìjọ kan ní Bern, Urs, tí ó ti sìn nígbà kan rí ní ọ́fíìsì ẹ̀ka ti Switzerland, ti gbéyàwó, ó sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Rachel, obìnrin kan ṣoṣo tí a bí àti ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà rí fún ọdún bíi mélòó kan.

Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn ọmọ mi, èmi pẹ̀lú di aṣáájú ọ̀nà nígbà tí mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ní June 1990. Ní bíbojúwẹ̀yìn wo ìgbésí ayé èmi àti ìdílé mi, mo lè fi ìdánilójú sọ pé, Jèhófà ti mú ipa ọ̀nà wa jọ̀lọ̀, ó sì ti tú ìbùkún dá sórí wa “títí kì yóò fi sí àìní mọ́.”—Málákì 3:10, NW.

Ẹsẹ Bíbélì tí ìyàwó mi ọ̀wọ́n fẹ́ràn jù lọ ni: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Olúwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.” (Orin Dáfídì 55:22) Tèmi sì ni: “Ṣe inú dídùn sí Olúwa pẹ̀lú, òun óò sì fi ìfẹ́ inú rẹ fún ọ.” (Orin Dáfídì 37:4) Àwa méjèèjì ti rí bí àwọn ọ̀rọ̀ dáradára wọ̀nyẹn ṣe jẹ́ òtítọ́. Ohun tí a ń lépa jẹ́ láti yin Ọlọ́run wa, Jèhófà, títí ayérayé, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wa àti àwọn ìdílé wọn.—Gẹ́gẹ́ bí Josef Heggli ṣe sọ ọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́