ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/8 ojú ìwé 26-27
  • Báwo Ni O Ṣe Lè Bẹ̀rù Ọlọ́run Ìfẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni O Ṣe Lè Bẹ̀rù Ọlọ́run Ìfẹ́?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀run àti Ọláńlá Ọlọ́run
  • Ọlọ́run Tí Ń Dárí Jini
  • Bíbẹ̀rù Ìdájọ́ Ọlọ́run
  • Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kíkọ́ Láti Rí Ìgbádùn Nínú Ìbẹ̀rù Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jẹ́ Ọlọgbọ́n, Kó o Sì Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 1/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Báwo Ni O Ṣe Lè Bẹ̀rù Ọlọ́run Ìfẹ́?

“ÌBÙKÚN NI FÚN ẸNI TÍ Ó BẸ̀RÙ OLÚWA.”—Orin Dáfídì 112:1.

BÍ Ó bá jẹ́ pé “Ìfẹ́ ni Ọlọ́run” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀, èé ṣe tí ó fi pọn dandan láti bẹ̀rù rẹ̀? (Jòhánù Kíní 4:16) Ní gbogbogbòò, a kà á sí pé ìfẹ́ àti ìbẹ̀rù kò lè rìn pọ̀. Nítorí náà, ipa wo ni ìbẹ̀rù ní láti kó nínú ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run? Èé ṣe tí a fi ní láti bẹ̀rù Ọlọ́run ìfẹ́? Ṣíṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àyẹ̀wò lórí bí a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “ìbẹ̀rù,” nínú Bíbélì lè túbọ̀ jẹ́ kí a lóye ọ̀ràn yí sí i.

Nínú èdè púpọ̀ jù lọ, ẹyọ ọ̀rọ̀ kan lè ní ìtumọ̀ púpọ̀, tí àyíká ọ̀rọ̀ ń fi hàn. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwọn èdè kan, ẹnì kan lè wí pé: “Mo fẹ́ràn áísìkirìmù,” kó sì tún wí pé, “Mo fẹ́ràn àwọn ọmọ mi.” Ìyàtọ̀ ńláǹlà kan wà láàárín oríṣi ìfẹ́ tó ń sọ àti bí wọ́n ṣe rinlẹ̀ tó. Lọ́nà kan náà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa oríṣi ìbẹ̀rù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà tí ó bá ń lò ó nínú ọ̀rọ̀ tó kan jíjọ́sìn Ọlọ́run, kì í ṣe ìpayà, jìnnìjìnnì, tàbí èrò nípa ìjìyà tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ ló ń tọ́ka sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rù Ọlọ́run ń mú èrò gbígbámúṣé wá—ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, ìfọkànsìn, àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀. Àwọn èrò ọmọlúwàbí wọ̀nyí ń bá ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti òòfà àtinúwá mọ́ ọn rìn, kì í ṣe èrò àdánidá láti sá fún un tàbí láti fara pa mọ́ fún un.

Ìfẹ́ fún Ọlọ́run ń lé ìbẹ̀rù oníkàárísọ, oníjìnnìjìnnì sọ nù. Onísáàmù kọ̀wé nípa ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run pé: “Kì yóò bẹ̀rù ìhìn búburú: àyà rẹ̀ ti mú ọ̀nà kan, ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.” (Orin Dáfídì 112:7) Kò sí ìhàlẹ̀ kankan láti ọ̀dọ̀ àwọn olubi tàbí láti ọ̀dọ̀ Sátánì fúnra rẹ̀ tó lè borí ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ àti ìfọkànsìn wa fún Jèhófà. (Lúùkù 12:4, 5) Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù láti sún mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú àyíká ipò yí, ‘ìfẹ́ ń lé ìbẹ̀rù jáde.’—Jòhánù Kíní 4:18.

Àwọn Ọ̀run àti Ọláńlá Ọlọ́run

Ọba Dáfídì ìgbà láéláé jẹ́ olùbẹ̀rù-Ọlọ́run. Ẹnu yà á nígbà tí ó ronú nípa bí ìṣẹ̀dá ṣe rẹwà tí ó sì díjú tó. Ó wí pé: “Èmi ó yìn ọ́; nítorí tẹ̀rùtẹ̀rù àti tìyanutìyanu ni a dá mi: ìyanu ni iṣẹ́ rẹ; èyí ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.” (Orin Dáfídì 139:14) Bí ó ti ń bojú wo òfuurufú, ó wí pé: “Àwọn ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọ́run.” (Orin Dáfídì 19:1) O ha ronú pé ohun tí Dáfídì rí yìí da jìnnìjìnnì bò ó bí? Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, ó mú kí ó kọrin ìyìn sí Jèhófà.

Ìmọ̀ tó pọ̀ sí i tí a ní lónìí nípa àwọn ọ̀run fún wa nídìí tó túbọ̀ lágbára sí i láti ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. Láìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà túbọ̀ fi Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú ti Hubble wo inú àwọn ọ̀run ju bí ènìyàn kankan ti ṣe rí ṣáájú wọn lọ. Wọ́n yan apá kan òfuurufú tó jọ pé kò sí nǹkan níbẹ̀ bí a bá fi awò awọ̀nàjíjìn wò ó láti orí ilẹ̀, wọ́n sì darí awò awọ̀nàjíjìn gbalasa òfuurufú ti Hubble náà sórí àgbègbè kan tí gbogbo bí ó ṣe tóbi tó kò ju kí a mú ẹyọ iyanrìn kan sórí ọwọ́ tí a nà jáde lọ. Àwòrán tí a yà níbẹ̀ há gádígádí, kì í ṣe ẹyọ ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan ló wà níbẹ̀, bí kò ṣe àwọn ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀—àwọn ìgbékalẹ̀ ńláńlá tí ó ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀ nínú—tí ènìyàn kò rí nígbà kankan rí!

Bí àgbáyé ṣe tóbi tó, tó jẹ́ àràmàǹdà tó, tó sì jẹ́ àgbàyanu tó, ń mú kí ẹni tó bá lákìíyèsí ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, irú àwọn ohun ìyanu bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ àfihàn ògo àti agbára Ẹlẹ́dàá ni. Bíbélì pe Jèhófà Ọlọ́run ní “Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,” ó sì sọ fún wa pé ó “ka iye àwọn ìràwọ̀; ó sì pe gbogbo wọn ní orúkọ.”—Jákọ́bù 1:17; Orin Dáfídì 147:4.

A tún rí bí àgbáyé ṣe kàmàmà tó nínú àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ọ̀run ti gbà. Ìmọ́lẹ̀ tí Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú ti Hubble yàwòrán rẹ̀ láti inú àwọn ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ti ń rìnrìn àjò nínú gbalasa òfuurufú fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún! Kò ha yẹ kí jíjẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀dé àti kíkéré tí a kéré, ní ìfiwéra pẹ̀lú wíwà tí àwọn ọ̀run ti wà tipẹ́tipẹ́ mú kí a ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ìfọkànsìn jíjinlẹ̀ fún Ẹni tí ó dá àwọn ìràwọ̀ bí? (Aísáyà 40:22, 26) Mímọ̀ tí a mọ̀ pé Ọlọ́run tí ó dá gbogbo nǹkan wọ̀nyí tún ‘ń ṣe ìrántí ọmọ ènìyàn, ó sì ń bẹ̀ wọ́n wò’ ń mú kí ọ̀wọ̀ tí a ní fún Ẹlẹ́dàá wa jinlẹ̀ sí i, ó sì ń mú kí a fẹ́ láti mọ̀ ọ́n kí a sì tẹ́ ẹ lọ́rùn. (Orin Dáfídì 8:3, 4) Irú ọ̀wọ̀ àti ìmọrírì gígalọ́lá bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì pè ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Ọlọ́run Tí Ń Dárí Jini

Aláìpé ni gbogbo wa. Nígbà tí a ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó tọ́ pàápàá, a ń ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀. Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, ó ha yẹ kí a máa fòyà nítorí pípàdánù ojú rere Ọlọ́run bí? Onísáàmù náà sọ pé: “Olúwa, ì bá ṣe pé kí ìwọ kó máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.” (Orin Dáfídì 130:3, 4) Pé ‘Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá’ náà ní inúure tó bẹ́ẹ̀, tí ó sì ń dárí jini, ń ru ìmọrírì jíjinlẹ̀ àti ọ̀wọ̀ sókè nínú àwọn olùjọ́sìn rẹ̀.—Aísáyà 54:5-8.

Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ń sún wa ṣe ohun rere, kí a sì yàgò fún ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó burú. A lè fi ipò tí a wà sí Bàbá wa ọ̀run wé ti bàbá rere kan tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn sí àwọn ọmọ rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọdé lè ṣàìrántí ìdí tí bàbá wọn fi kà á léèwọ̀ fún wọn láti má ṣeré lójú títì. Síbẹ̀, nígbà tí nǹkan kan bá fẹ́ sún wọn láti lé bọ́ọ̀lù lọ sójú títì, ríronú nípa ìkàléèwọ̀ tí bàbá wọn fún wọn yóò mú kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀—ó sì ṣeé ṣe kí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú. Lọ́nà kan náà, ìbẹ̀rù tí àgbàlagbà kan ní fún Jèhófà lè mú kí ó yàgò fún híhu ìwà kan tí ó lè rún ìwàláàyè—tirẹ̀ àti ti àwọn ẹlòmíràn—jégéjégé.—Òwe 14:27.

Bíbẹ̀rù Ìdájọ́ Ọlọ́run

Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, ẹnì kan tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò bá dí lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́ ní ìdí láti bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà yíyàtọ̀ kan. Bí àwọn ìjọba ènìyàn ṣe ń fìyà jẹ àwọn olubi gẹ́lẹ́ ni Ọlọ́run ní ẹ̀tọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí àwọn tí ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe búburú láìronú-pìwàdà. Fífi tí Ọlọ́run fi àyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀ ti yọ̀ǹda fún àwọn mélòó kan láti yigbì ní ipa ọ̀nà ibi. Ṣùgbọ́n, Bíbélì fi hàn ní kedere pé lọ́jọ́ kan láìpẹ́, yóò mú gbogbo olubi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Orin Dáfídì 37:9, 10; Oníwàásù 8:11; Tímótì Kíní 5:24) Olubi tí kò ronú pìwà dà náà ní ìdí láti bẹ̀rù ìjìyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, irú ìbẹ̀rù yí kọ́ ni Bíbélì dámọ̀ràn.

Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì so ìbẹ̀rù Jèhófà mọ́ àwọn ohun rere inú ìgbésí ayé—orin kíkọ, ìdùnnú, ìgbẹ́kẹ̀lé, ọgbọ́n, ẹ̀mí gígùn, ìgbọ́kànlé, ìníláárí, ìrètí, àti àlàáfíà, ká wulẹ̀ mẹ́nu ba díẹ̀ níbẹ̀.a Bí a bá ń rìn nìṣó nínú ìbẹ̀rù Jèhófà, a óò gbádùn irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ títí láé.—Diutarónómì 10:12-14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ẹ́kísódù 15:11; Orin Dáfídì 34:11, 12; 40:3; 111:10; Òwe 10:27; 14:26; 22:4; 23:17, 18; Ìṣe 9:31.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Anglo-Australian Observatory, fọ́tò tí David Malin yà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́