ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 8/1 ojú ìwé 21-25
  • Jẹ́ Ọlọgbọ́n, Kó o Sì Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Ọlọgbọ́n, Kó o Sì Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báa Ṣe Lè Kọ́ Láti Máa Bẹ̀rù Jèhófà
  • Bí Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ṣe Ń Ranni Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìṣòro
  • Téèyàn Ò Bá Bẹ̀rù Ọlọ́run Tó Bó Ṣe Yẹ
  • Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Kò Ní Jẹ́ Ká Máa Dẹ́ṣẹ̀
  • Bẹ̀rù Jèhófà Kó o Lè Láyọ̀!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Bẹ̀rù Jèhófà Káyé Rẹ Lè Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Kọ́ Mi Láti Máa Ṣe Ìfẹ́ Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 8/1 ojú ìwé 21-25

Jẹ́ Ọlọgbọ́n, Kó o Sì Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run!

“Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.”—ÒWE 9:10.

1. Kí nìdí tó fi ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti lóye ohun tí ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́?

ÌGBÀ kan wà tó jẹ́ pé ńṣe ni inú èèyàn máa ń dùn tí wọ́n bá pè é ní olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Àmọ́ lóde òní, ọ̀pọ̀ ló ka ìbẹ̀rù Ọlọ́run sí ohun tí kò bóde mu mọ́, tí kò tiẹ̀ ṣeé ṣe pàápàá. Wọ́n lè máa béèrè pé: ‘Tí Ọlọ́run bá jẹ́ ìfẹ́, kí nìdí tí màá fi máa bẹ̀rù rẹ̀?’ Lójú tiwọn, ohun tí kò dára ni ìbẹ̀rù jẹ́, kódà ohun tó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni ni wọ́n kà á sí. Àmọ́, ojúlówó ìbẹ̀rù Ọlọ́run ní ìtumọ̀ tó pọ̀, kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn pé kéèyàn kàn máa gbọ̀n jìnnìjìnnì lásán gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe rí i.

2, 3. Kí ni ojúlówó ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́?

2 Tá a bá wo ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ohun tó dára gan-an ni. (Aísáyà 11:3) Ó jẹ́ ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run, ìyẹn ni kéèyàn má fẹ́ ṣẹ Ọlọ́run rárá. (Sáàmù 115:11) Ó ní í ṣe pẹ̀lú kéèyàn fara mọ́ àwọn ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run fún wa kó sì máa tẹ̀ lé wọn, ó tún ní í ṣe pẹ̀lú kéèyàn múra tán láti fara mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́ kó sì yàgò fún èyí tó sọ pé kò tọ́. Ìwé kan tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ sọ pé irú ojúlówó ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ fi hàn pé “èèyàn ní èrò tó dáa nípa Ọlọ́run, èyí tó máa ń jẹ́ kéèyàn hùwà ọlọgbọ́n kéèyàn sì yàgò fún ohunkóhun tó jẹ́ ibi.” Lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.”—Òwe 9:10.

3 Láìsí àní-àní, ìbẹ̀rù Ọlọ́run kan gbogbo apá ìgbésí ayé ọmọ èèyàn. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń fúnni ní ọgbọ́n, ó tún máa ń fún èèyàn ní ayọ̀, àlàáfíà, aásìkí, ẹ̀mí gígùn, ìrètí, ìgbọ́kànlé, àti ìfọ̀kànbalẹ̀. (Sáàmù 2:11; Òwe 1:7; 10:27; 14:26; 22:4; 23:17, 18; Ìṣe 9:31) Ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́. Ká sòótọ́, ó wé mọ́ gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa. (Diutarónómì 10:12; Jóòbù 6:14; Hébérù 11:7) Lára ohun tó tún wé mọ́ ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni pé kó dá wa lójú gan-an pé Bàbá wa ọ̀run bìkítà nípa wa, ó sì múra tán láti dárí àwọn àṣìṣe wa jì wá. (Sáàmù 130:4) Kìkì àwọn ẹni ibi tí kò ronú pìwà dà nìkan ló lè máa gbọ̀n jìnnìjìnnì.a—Hébérù 10:26-31.

Báa Ṣe Lè Kọ́ Láti Máa Bẹ̀rù Jèhófà

4. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ‘kọ́ bá a ó ṣe máa bẹ̀rù Jèhófà’?

4 Níwọ̀n bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn tó ó lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání kéèyàn sì rí ìbùkún Ọlọ́run gbà, báwo la ṣe lè “kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà” bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? (Diutarónómì 17:19) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run ló wà nínú Ìwé Mímọ́ “fún ìtọ́ni wa.” (Róòmù 15:4) Ká lè lóye ohun tó dìídì túmọ̀ sí láti bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká gbé ìgbésí ayé ọ̀kan lára wọn yẹ̀ wò, ìyẹn Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì.

5. Báwo ni ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́ láti ní ìbẹ̀rù Jèhófà?

5 Jèhófà kọ Sọ́ọ̀lù ọba tó kọ́kọ́ jẹ ní Ísírẹ́lì sílẹ̀ nítorí pé ó bẹ̀rù àwọn èèyàn, kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run. (1 Sámúẹ́lì 15:24-26) Àmọ́ ọ̀nà tí Dáfídì ní tiẹ̀ gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ àti àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ní pẹ̀lú Jèhófà fi hàn pé lóòótọ́, ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni. Láti kékeré ni Dáfídì ti máa ń da àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 16:11) Àwọn àkókò tí Dáfídì fi ń ṣọ́ àwọn àgùntàn wọ̀nyí lóru lábẹ́ ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀, ràn án lọ́wọ́ láti lóye ìbẹ̀rù Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni Dáfídì lè rí nínú àgbáálá ayé tó lọ salalu, síbẹ̀ ó mọ̀ pé ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run ká sì máa yìn ín. Ó wá kọ̀wé nígbà tó yá pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?”—Sáàmù 8:3, 4.

6. Kí ni Dáfídì sọ nígbà tó lóye bí Jèhófà ṣe tóbi tó?

6 Dájúdájú, ó jọ Dáfídì lójú gan-an nígbà tó rí bóun ṣe kéré tó lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tó pọ̀ lọ súà. Dípò kíyẹn dẹ́rù bà á, ńṣe ni òye tó ní yìí mú kó yin Jèhófà, tó sì sọ pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 19:1) Ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run yìí mú kó ṣeé ṣe fún Dáfídì láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó sì mú kó fẹ́ láti kọ́ nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀ pípé kó sì máa tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà náà. Fojú inú wo bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára Dáfídì nígbà tó kọrin sí Jèhófà pé: “Ẹni ńlá ni ọ́, o sì ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu; Ìwọ ni Ọlọ́run, ìwọ nìkan ṣoṣo. Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.”—Sáàmù 86:10, 11.

7. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́ láti bá Gòláyátì jà?

7 Nígbà táwọn Filísínì gbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì, Gòláyátì, ọ̀gágun wọn, tó ga ní ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án àtààbọ̀ pẹ̀gàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ohun tó sì ń sọ lédè kan ni pé: ‘Ẹ yan ọkùnrin kan láti wá bá mi jà! Tí ó bá sì ṣẹ́gun, àwa yóò di ìránṣẹ́ fún un yín.’ (1 Sámúẹ́lì 17:4-10) Jìnnìjìnnì bá Sọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀, àmọ́ ẹ̀rù ò ba Dáfídì ní tiẹ̀. Ó mọ̀ pé Jèhófà ló yẹ ká máa bẹ̀rù, a ò ní láti bẹ̀rù èèyàn, bó ti wù kí onítọ̀hún lágbára tó. Dáfídì wá sọ fún Gòláyátì pé: “Èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, . . . gbogbo ìjọ yìí yóò sì mọ̀ pé kì í ṣe idà tàbí ọ̀kọ̀ ni Jèhófà fi ń gbani là, nítorí pé ti Jèhófà ni ìjà ogun náà.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, Dáfídì ju kànnàkànnà rẹ̀ àti òkúta kan ṣoṣo péré, ó sì pa òmìrán náà pátápátá.—1 Sámúẹ́lì 17:45-47.

8. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run nínú Bíbélì?

8 Àwa náà lè láwọn ìṣòro tàbí àwọn ọ̀tá tó lágbára gan-an bí àwọn tí Dáfídì dojú kọ. Kí la lè ṣe? A lè borí wọn lọ́nà kan náà tí Dáfídì àtàwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ láyé ìgbàanì gbà borí wọn tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run lè borí ìbẹ̀rù èèyàn. Nehemáyà tó jẹ́ ìránṣẹ́ olóòótọ́ fún Ọlọ́run, rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tirẹ̀ táwọn alátakò gbógun tì pé: “Ẹ má fòyà ní tìtorí wọn. Jèhófà Ẹni ńlá tí ń múni kún fún ẹ̀rù ni kí ẹ fi sọ́kàn yín.” (Nehemáyà 4:14) Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, Dáfídì, Nehemáyà, àtàwọn mìíràn tó jẹ́ ìránṣẹ́ olóòótọ́ fún Ọlọ́run kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́. Tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa náà lè kẹ́sẹ járí.

Bí Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ṣe Ń Ranni Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìṣòro

9. Inú àwọn ipò wo ni Dáfídì ti fi hàn pé òun bẹ̀rù Ọlọ́run?

9 Lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì, Jèhófà tún ràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn mìíràn. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù òjòwú gbìyànjú láti pa Dáfídì. Ó kọ́kọ́ fẹ́ gún un pa, lẹ́yìn náà ló wá lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Níkẹyìn, ó gbé ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan dìde sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti mú un dá Dáfídì lójú pé ó máa di ọba, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ń sá kiri, tó ń jagun kiri, tó sì ń dúró de àkókò tí Jèhófà máa fòun jọba. Ní gbogbo àkókò yìí, Dáfídì fi hàn pé òun bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.—1 Sámúẹ́lì 18:9, 11, 17; 24:2.

10. Báwo ni Dáfídì ṣe fi hàn pé òun bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà tó bá ara rẹ̀ nínú ewu?

10 Ìgbà kan wà tí Dáfídì lọ sá sọ́dọ̀ Ákíṣì, ọba ìlú àwọn ará Filísínì kan tó ń jẹ́ Gátì, ìyẹn ìlú Gòláyátì. (1 Sámúẹ́lì 21:10-15) Àwọn ìránṣẹ́ ọba náà sọ pé ọ̀tá orílẹ̀-èdè àwọn ni Dáfídì. Kí ni Dáfídì wá ṣe nígbà tó bá ara rẹ̀ nínú irú ipò eléwu bẹ́ẹ̀? Ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà. (Sáàmù 56:1-4, 11-13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dá ọgbọ́n kan, tó ṣe bíi pé òun ya wèrè kó bàa lè bọ́ lọ́wọ́ wọn, síbẹ̀ ó mọ̀ dájú pé Jèhófà ló dìídì gba òun sílẹ̀ nípa bíbùkún ìsapá òun. Bí Dáfídì ṣe fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbára lé Jèhófà tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e fi hàn pé lóòótọ́ ni Dáfídì bẹ̀rù Ọlọ́run.—Sáàmù 34:4-6, 9-11.

11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà tá a bá wà nínú àdánwò gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti ṣe?

11 Bíi ti Dáfídì, àwa náà lè fi hàn pé a bẹ̀rù Ọlọ́run nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí tó ṣe fún wa pé òun á ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro wa. Dáfídì sọ pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” (Sáàmù 37:5) Èyí ò túmọ̀ sí pé ká kàn kó gbogbo ìṣòro wa lé Jèhófà lọ́wọ́ láìṣe ohun tó yẹ ká ṣe o, ká wá máa retí pé Jèhófà yóò bá wa yanjú àwọn ìṣòro náà. Kì í ṣe pé Dáfídì kàn gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìrànwọ́ lásán tó sì wá fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ láìṣe ohunkóhun. Ó lo ọpọlọ tí Jèhófà fún un láti borí ìṣòro rẹ̀ lákòókò yẹn. Síbẹ̀, Dáfídì mọ̀ pé ìsapá èèyàn nìkan kò lè mú àṣeyọrí wá. Ohun tó yẹ káwa náà mọ̀ nìyẹn. Lẹ́yìn tá a bá ti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, a gbọ́dọ̀ fi èyí tó kù sílẹ̀ fún Jèhófà. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ní kì í sí ohunkóhun tá a lè ṣe ju pé ká gbára lé Jèhófà. Irú àkókò yìí gan-an la máa ń fi hàn pé lóòótọ́ la bẹ̀rù Ọlọ́run. A lè rí ìtùnú látinú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ látọkànwá pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.”—Sáàmù 25:14.

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú àdúrà wa, irú ẹ̀mí wo ni kò sì yẹ ká ní láé?

12 Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àdúrà wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ “gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6; Jákọ́bù 1:5-8) Nígbà tó bá sì ràn wá lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa dúpẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá. (Kólósè 3:15, 17) A ò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn kan tí Kristẹni ẹni àmì òróró kan sọ nípa wọn pé: “Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń rò pé Ọlọ́run wulẹ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ kan lọ́run ni. Pé táwọn bá nílò nǹkan kan, ẹnu pé káwọn kàn tàka sí i ni, kó sì dá àwọn lóhùn lójú ẹsẹ̀. Tọ́wọ́ wọn bá sì ti tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́ tán, wọ́n á fẹ́ kó máa bá tiẹ̀ lọ.” Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ fi hàn pé wọn ò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá.

Téèyàn Ò Bá Bẹ̀rù Ọlọ́run Tó Bó Ṣe Yẹ

13. Ìgbà wo ni Dáfídì kùnà láti bọ̀wọ̀ fún Òfin Ọlọ́run?

13 Bí Jèhófà ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́ nígbà tó wà nínú ìṣòro mú kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó ní túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, ó sì tún jẹ́ kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Ọlọ́run lágbára sí i. (Sáàmù 31:22-24) Àmọ́, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí Dáfídì ní lọ sílẹ̀, àbájáde rẹ̀ sì burú gan-an. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tó ṣètò pé kí wọ́n fi kẹ̀kẹ́ tí ẹran ń fà gbé àpótí ẹ̀rí Jèhófà lọ sí Jerúsálẹ́mù dípò káwọn ọmọ Léfì gbé e lé èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Òfin Ọlọ́run ti sọ. Nígbà tí Úsà tó ń ṣamọ̀nà kẹ̀kẹ́ ọ̀hún gbá Àpótí ẹ̀rí náà mú kó má bàá jábọ́, ojú ẹsẹ̀ ni Úsà kú nítorí “ìwà àìlọ́wọ̀” rẹ̀. Lóòótọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni Úsà dá, àmọ́ ní ti gidi, torí pé Dáfídì kùnà láti bọ̀wọ̀ fún Òfin Ọlọ́run ló fa àbájáde bíburú jáì yẹn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run túmọ̀ sí kéèyàn máa ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu.—2 Sámúẹ́lì 6:2-9; Númérì 4:15; 7:9.

14. Kí ni àbájáde kíkà tí Dáfídì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

14 Lẹ́yìn ìyẹn, Sátánì mú kí Dáfídì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ jagunjagun. (1 Kíróníkà 21:1) Ohun tí Dáfídì ṣe yẹn fi hàn pé kò bẹ̀rù Ọlọ́run tó bó ṣe yẹ, ìyẹn sì yọrí sí ikú ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ [70,000] àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ronú pìwà dà níwájú Jèhófà, síbẹ̀ ojú òun àtàwọn tó yí i ká rí màbo.—2 Sámúẹ́lì 24:1-16.

15. Kí ló sún Dáfídì ṣe panṣágà?

15 Ìgbà mìíràn tí Dáfídì ò tún bẹ̀rù Ọlọ́run tó bó ṣe yẹ ni àkókò kan tó bá Bátí-ṣébà, ìyàwó Ùráyà ṣèṣekúṣe. Dáfídì mọ̀ pé kò dáa kéèyàn ṣe panṣágà tàbí kéèyàn ṣojú kòkòrò aya tàbí ọkọ ọmọnìkejì ẹni. (Ẹ́kísódù 20:14, 17) Ìgbà tí Dáfídì rí Bátí-ṣébà níbi tó ti ń wẹ ni ìṣòro ọ̀hún bẹ̀rẹ̀. Ojú ẹsẹ̀ yẹn ló yẹ kí ojúlówó ìbẹ̀rù Ọlọ́run ti mú kí Dáfídì yí ojú rẹ̀ síbòmíràn kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ro nǹkan míì. Dípò ìyẹn, ó dájú pé ńṣe ni Dáfídì “ń bá a nìṣó ní wíwo” obìnrin náà títí ìfẹ́ ìṣekúṣe fi borí ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó ní. (Mátíù 5:28; 2 Sámúẹ́lì 11:1-4) Dáfídì gbàgbé pé kò yẹ kóun ṣe ohunkóhun láìfi ti Jèhófà ṣe.—Sáàmù 139:1-7.

16. Kí làwọn ohun tójú Dáfídì rí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá?

16 Ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí Dáfídì àti Bátí-ṣébà dá mú kí wọ́n bí ọmọkùnrin kan. Kété lẹ́yìn náà ni Jèhófà rán wòlíì Nátánì láti lọ tú ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì fó. Nígbà tí wòlíì náà pe orí Dáfídì wálé, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì ronú pìwà dà. Ó bẹ Jèhófà pé kó má ta òun nù kó má sì mú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kúrò lára òun. (Sáàmù 51:7, 11) Jèhófà dárí ji Dáfídì ó sì dín ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kù, àmọ́ Jèhófà ò gbà Dáfídì lọ́wọ́ gbogbo ohun burúkú tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fà. Ọmọkùnrin tí Bátí-ṣébà bí fún un kú, ìbànújẹ́ àti àjálù sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìdílé rẹ̀ látìgbà náà lọ. Ẹ ò rí i pé wàhálà tó bá Dáfídì ò kéré nítorí pé ìbẹ̀rù tó ní fún Ọlọ́run dín kú láwọn àkókò kan!—2 Sámúẹ́lì 12:10-14; 13:10-14; 15:14.

17. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi ìbànújẹ́ ọkàn tí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ máa ń fà hàn.

17 Bákan náà ni kíkùnà láti bẹ̀rù Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ìwà rere ṣe lè ní àbájáde bíburú jáì lóde òní. Fojú inú wo bí ọkàn ìyàwó ilé kan tó kéré lọ́jọ́ orí ṣe bà jẹ́ tó nígbà tó gbọ́ pé ọkọ òun tó jẹ́ Kristẹni lọ ní àjọṣe pẹ̀lú obìnrin mìíràn nígbà tó wà lókè òkun. Ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ débi pé ńṣe ló dọwọ́ bojú tó sì bú sẹ́kún. Ǹjẹ́ kò ní pẹ́ gan-an kí obìnrin yìí tó lè padà fọkàn tán ọkọ rẹ̀ kó sì tún máa bọ̀wọ̀ fún un? Téèyàn bá bẹ̀rù Ọlọ́run tinútinú, ó lè bọ́ lọ́wọ́ irú àwọn nǹkan búburú bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 6:18.

Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Kò Ní Jẹ́ Ká Máa Dẹ́ṣẹ̀

18. Kí ni Sátánì fẹ́ ṣe gan-an, ọ̀nà wo ló sì ń gbà ṣe é?

18 Gbogbo ọgbọ́n ni Sátánì ń dá láti ba ìwà ọmọ aráyé jẹ́ pátápátá, àwọn Kristẹni tòótọ́ gan-an ló sì ń wá bóun ṣe máa sọ dìdàkudà jù. Ọ̀nà tó ń gbà ṣe èyí ni pé, ó máa ń lo àwọn ẹ̀yà ara wa tó ń bá ọkàn àti èrò inú wa ṣíṣẹ́, ìyẹn ojú wa àti etí wa. (Éfésù 4:17-19) Kí ni wàá ṣe tó o bá ṣàdédé rí àwọn àwòrán ìṣekúṣe, tàbí tó o gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe, tàbí tó o tiẹ̀ rí àwọn èèyàn tó ń ṣe ìṣekúṣe pàápàá?

19. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti borí ìdẹwò?

19 Gbé ọ̀ràn Andréb tó jẹ́ alàgbà yẹ̀ wò, ó láwọn ọmọ, ó sì tún ń ṣe iṣẹ́ dókítà nílẹ̀ Yúróòpù. Nígbà tí André bá wà níṣẹ́ alẹ́, àwọn obìnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sábà máa ń lẹ bébà tí wọ́n kọ́ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ sí mọ́ pílò rẹ̀, wọ́n á máa rọ̀ ọ́ pé kó wá bá àwọn ṣèṣekúṣe. Àmọ́ André kọ̀ jálẹ̀, kò gbà fún wọn rárá. Kò tán síbẹ̀ o, kí André lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn oníṣekúṣe náà, ó fi ibi iṣẹ́ yẹn sílẹ̀ ó sì wáṣẹ́ síbòmíràn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó ní yìí bọ́gbọ́n mu gan-an, ó sì yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbùkún, nítorí pé lónìí, André ti wá ń ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan báyìí ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.

20, 21. (a) Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá?

20 Téèyàn bá ń ní èrò búburú lọ́kàn, ìyẹn lè sún onítọ̀hún débi tí kò ti ní kọ̀ láti pàdánù àjọṣe ṣíṣeyebíye tó ní pẹ̀lú Jèhófà nítorí ohun kan tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. (Jákọ́bù 1:14, 15) Àmọ́, tá a bá bẹ̀rù Jèhófà, a ò ní sún mọ́ àwọn èèyàn tó lè mú ká hùwà pálapàla, kódà a ó rìn jìnnà síbikíbi tíyẹn bá ti lè ṣẹlẹ̀, a ò sì ní lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò àti eré ìnàjú tó lè sọ wá dẹni tí kò kíyè sára mọ́. (Òwe 22:3) Bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá tiẹ̀ mú káwọn èèyàn máa fojú tí kò dáa wò wá tàbí kó mú ká fi àwọn nǹkan kan du ara wa, síbẹ̀ gbogbo ìyẹn kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ kéèyàn pàdánù ojú rere Ọlọ́run. (Mátíù 5:29, 30) Láìsí àní-àní, ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe, títí kan wíwo àwòrán èyíkéyìí tó lè mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, kàkà bẹ́ẹ̀, a ó jẹ́ kí ojú wa “kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa á balẹ̀ pé Jèhófà yóò ‘pa wá mọ́ láàyè’ yóò sì pèsè gbogbo ohun tá a dìídì nílò fún wa.—Sáàmù 84:11; 119:37.

21 Dájúdájú, kéèyàn máa hùwà tó fi ojúlówó ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn ló mọ́gbọ́n dání jù lọ. Kódà ìyẹn ló lè fúnni láyọ̀ tòótọ́. (Sáàmù 34:9) Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò jẹ́ kí èyí túbọ̀ yéni yékéyéké.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Báwo Ni O Ṣe Lè Bẹ̀rù Ọlọ́run Ìfẹ́?” nínú ìwé ìròyìn Jí! ti January 8, 1998. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

b A ti yìí orúkọ rẹ̀ padà.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Àwọn ànímọ́ Kristẹni wo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run wé mọ́?

• Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ń borí ìbẹ̀rù èèyàn?

• Báwo la ṣe ń fi hàn pé a fi ọwọ́ pàtàkì mú àdúrà?

• Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ń mú ká yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Dáfídì lóye ìbẹ̀rù Ọlọ́run nígbà tó ń kíyè sí iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Kí lo máa ṣe tó o bá ṣàdédé bára rẹ nínú ìdẹwò tó ò retí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́