ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 8/1 ojú ìwé 26-30
  • Bẹ̀rù Jèhófà Kó o Lè Láyọ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bẹ̀rù Jèhófà Kó o Lè Láyọ̀!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Béèyàn Ṣe Lè Padà Rí Ayọ̀
  • Ó Sàn Kéèyàn Jìyà Ju Kó Dẹ́ṣẹ̀
  • Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ń Máyọ̀ Wá
  • ‘Gba Okun Látọ̀dọ̀ Jèhófà’
  • Ogún Tó Ṣeyebíye
  • Jẹ́ Ọlọgbọ́n, Kó o Sì Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Bẹ̀rù Jèhófà Káyé Rẹ Lè Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • “Kọ́ Mi Láti Máa Ṣe Ìfẹ́ Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 8/1 ojú ìwé 26-30

Bẹ̀rù Jèhófà Kó o Lè Láyọ̀!

“Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà.”—SÁÀMÙ 112:1.

1, 2. Kí ni ìbẹ̀rù Jèhófà lè jẹ́ ká ní?

AYỌ̀ kì í ṣàdédé wá. Ojúlówó ayọ̀ máa ń wá nípa ṣíṣe àwọn ìpinnu tó dáa, kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́, kò má sì lọ́wọ́ nínú ohun búburú kankan. Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa ti fún wa ní Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti kọ́ wa bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé lọ́nà tó dára jù lọ. Tá a bá ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà tá a sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà náà, a ó tipa bẹ́ẹ̀ máa bẹ̀rù Ọlọ́run, ìyẹn á sì fún wa ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.—Sáàmù 23:1; Òwe 14:26.

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ó gbé àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì àtàwọn àpẹẹrẹ ti òde òní yẹ̀ wò, ìyẹn àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé ojúlówó ìbẹ̀rù Ọlọ́run máa ń fúnni lókun láti dènà ohun tó lè múni hùwàkiwà, ó sì máa ń fúnni nígboyà láti ṣe ohun tó tọ́. A ó rí i pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run lè fún wa láyọ̀ nípa mímú ká ṣàtúnṣe nígbà tá a bá ṣe ohun tí kò tọ́ gẹ́gẹ́ bí Dáfídì Ọba ti ṣe. A ó tún rí i pé ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ ogún ṣíṣeyebíye táwọn òbí lè fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ wọn. Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi mú un dá wa lójú pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà.”—Sáàmù 112:1.

Béèyàn Ṣe Lè Padà Rí Ayọ̀

3. Kí ló ran Dáfídì lọ́wọ́ láti bọ̀ sípò lẹ́yìn tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá?

3 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a rí i pé ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Dáfídì kùnà láti fi ojúlówó ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn tó sì dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́ ohun tó ṣe nígbà tí Jèhófà bá a wí fi hàn pé ní ti tòótọ́, ẹnì kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni. Ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tó ní fún Ọlọ́run ló mú kó gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi, tó tún ìwà rẹ̀ ṣe, tó sì mú kó tún padà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kó òun àtàwọn mìíràn sí wàhálà, síbẹ̀ bó ṣe ronú pìwà dà látọkànwá mú kí Jèhófà máa tì í lẹ́yìn nìṣó, kó sì máa bù kún un. Ó dájú pé àpẹẹrẹ Dáfídì yìí lè ṣèrànwọ́ fáwọn Kristẹni tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lónìí.

4. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti padà láyọ̀?

4 Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn ti Sonja yẹ̀ wò.a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ajíhìnrere tó ń fi gbogbo ìgbà wàásù ni Sonja, síbẹ̀ ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ búburú, ó sì tún lọ́wọ́ nínú ìwà tí kò yẹ Kristẹni, ìyẹn sì mú kí wọ́n yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. Nígbà tí orí Sonja wálé, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tún padà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà tó yá, wọ́n gbà á padà sínú ìjọ Kristẹni. Pẹ̀lú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Sonja kò fìgbà kan sọ pé òun ò ní sin Jèhófà mọ́. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún padà. Nígbà tó sì yá, ó fẹ́ Kristẹni alàgbà kan tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Tayọ̀tayọ̀ lòun àtọkọ rẹ̀ fi ń sìn nínú ìjọ báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sonja kábàámọ̀ pé òun fìgbà kan ṣáko lọ kúrò ní ọ̀nà Kristẹni, síbẹ̀ inú rẹ̀ dùn pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run tóun ní ran òun lọ́wọ́ láti padà sọ́dọ̀ Jèhófà.

Ó Sàn Kéèyàn Jìyà Ju Kó Dẹ́ṣẹ̀

5, 6. Ṣàlàyé ọ̀nà tí Dáfídì gbà dá ẹ̀mí Sọ́ọ̀lù sí lẹ́ẹ̀mejì, kó o sì sọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀.

5 Ká sòótọ́, ohun tó dára jù lọ ni kí ìbẹ̀rù Ọlọ́rùn ran èèyàn lọ́wọ́ kó má tiẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ rárá. Bí ọ̀ràn Dáfídì ṣe rí lákòókò kan nìyẹn. Ìgbà kan wà tí Sọ́ọ̀lù àtàwọn ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọmọ ogun tí wọ́n jọ ń lé Dáfídì kiri wọ inú ihò kan láìmọ̀ pé inú ihò yẹn gan-an ni Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ sá pa mọ́ sí. Àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú Dáfídì sọ fún un pé kó pa Sọ́ọ̀lù. Àbí Jèhófà tún lè fi ọ̀tá Dáfídì lé e lọ́wọ́ jùyẹn lọ ni? Dáfídì rọra lọ síbi tí Sọ́ọ̀lù wà ó sì gé etí aṣọ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pa Sọ́ọ̀lù lára, síbẹ̀ ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó ní mú kí ìwọ̀nba ohun tó ṣe yẹn máa da ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ láàmú. Ó lé àwọn ọkùnrin rẹ̀ tínú ń bí sẹ́yìn, ó sì sọ fún wọn pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n ṣe ohun yìí sí olúwa mi, ẹni àmì òróró Jèhófà.”b—1 Sámúẹ́lì 24:1-7.

6 Lákòókò mìíràn lẹ́yìn ìgbà yẹn, Sọ́ọ̀lù wà ní ibùdó kan lóru, òun àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì sun “oorun àsùnwọra láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” Dáfídì àti Ábíṣáì, ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, rọra rìn lọ sí àárín ibùdó náà wọ́n sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ Sọ́ọ̀lù gan-gan níbi tó sùn sí. Ábíṣáì fẹ́ pa á lójú ẹsẹ̀. Àmọ́ Dáfídì ò gbà kí Ábíṣáì ṣe bẹ́ẹ̀, ó bi í pé: “Ta ni ó na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró Jèhófà tí ó sì wà ní aláìmọwọ́-mẹsẹ̀?”—1 Sámúẹ́lì 26:9, 12.

7. Kí nìdí tí Dáfídì fi kọ̀ láti dẹ́ṣẹ̀?

7 Kí nìdí tí Dáfídì kò fi pa Sọ́ọ̀lù nígbà méjèèjì tó láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó bẹ̀rù Jèhófà ju bó ṣe bẹ̀rù Sọ́ọ̀lù lọ. Nítorí pé Dáfídì bẹ̀rù Ọlọ́run, ó múra tán láti jìyà ju kóun dẹ́ṣẹ̀ lọ. (Hébérù 11:25) Gbogbo ọkàn ló fi nígbàgbọ́ nínú Jèhófà pé ó ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ ó sì ń bójú tó òun alára pẹ̀lú. Dáfídì mọ̀ pé ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run àti gbígbẹ́kẹ̀lé e yóò mú ayọ̀ àti ọ̀pọ̀ ìbùkún wá, àmọ́ téèyàn ò bá fi ti Ọlọ́run ṣe, onítọ̀hún ò lè rí ojú rere rẹ̀. (Sáàmù 65:4) Ó tún mọ̀ pé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa fi Dáfídì jọba, òun á sì mú Sọ́ọ̀lù kúrò lórí ìtẹ́ yóò nímùúṣẹ nígbà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, ọ̀nà tó bá sì wu Ọlọ́run ló máa gbà ṣe é.—1 Sámúẹ́lì 26:10.

Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ń Máyọ̀ Wá

8. Báwo lohun tí Dáfídì ṣe nígbà tó wà nínú ìṣòro ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa?

8 Níwọ̀n bá a ti jẹ́ Kristẹni, a mọ̀ pé àwọn èèyàn lè fi wá ṣẹ̀sín, wọ́n lè ṣe inúnibíni sí wa, a sì tún lè kojú àwọn àdánwò mìíràn. (Mátíù 24:9; 2 Pétérù 3:3) Kódà àwọn ìgbà mìíràn wà tá a lè níṣòro pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Bó ti wù kó rí, a mọ̀ pé Jèhófà rí ohun gbogbo, ó ń gbọ́ àdúrà wa, nígbà tó bá sì tó àkókò lójú rẹ̀, yóò yanjú gbogbo ìṣòro lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Róòmù 12:17-21; Hébérù 4:16) Nítorí náà, dípò tá a ó fi máa bẹ̀rù àwọn tó ń ta kò wá, Ọlọ́run là ń bẹ̀rù, òun la sì ń wò pé yóò gbà wá. Bíi ti Dáfídì, àwa náà kì í fúnra wa gbẹ̀san, bẹ́ẹ̀ la ò kì í bẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè fìyà jẹ wá ká wá torí bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà òdodo. Èyí sì máa ń máyọ̀ wá níkẹyìn. Àmọ́, lọ́nà wo?

9. Fúnni lápẹẹrẹ ọ̀nà tí ìbẹ̀rù Ọlọ́run lè gbà yọrí sí ayọ̀ bí wọ́n tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa.

9 Ohun tí arákùnrin kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà sọ rèé, ó ní: “Mo rántí ìyá kan àti ọmọ rẹ̀ obìnrin tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, tí wọ́n kọ̀ láti ra káàdì ẹgbẹ́ òṣèlú nítorí pé Kristẹni ni wọ́n, wọn ò sì fẹ́ dá sí ọ̀ràn ìṣèlú. Àwọn ọkùnrin bíi mélòó kan lù wọ́n bí ẹní máa kú, wọ́n sì ní kí wọ́n máa lọ sílé wọn. Bí wọ́n ṣe ń lọ ni ìyá náà ń tu ọmọ rẹ̀ obìnrin yìí nínú, nítorí ó ń sunkún, kò mọ ìdí tí wọ́n fi ní láti fi irú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹ wọ́n. Inú wọn ò dùn lákòókò yẹn, àmọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn mọ́. Nígbà tó yá, inú wọn dùn gan-an pé àwọn ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ká ní wọ́n ra káàdì òṣèlú yẹn ni, inú àwọn èèyàn yẹn ì bá dùn dọ́ba. Àwọn ọkùnrin tó lù wọ́n yẹn ì bá fún wọn ní ọtí ẹlẹ́rìndòdò, wọn ì bá sì jó tẹ̀lé wọn lọ sílé. Àmọ́ inú ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ ni ì bá bà jẹ́ jù lọ láyé, nítorí wọ́n á mọ̀ pé àwọn ti ṣe ohun tí kò tọ́.” Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n ní ló yọ wọ́n nínú gbogbo ìyẹn.

10, 11. Ohun rere wo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí obìnrin kan ní yọrí sí?

10 Níní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tún máa ń yọrí sí ayọ̀ nígbà tá a bá dojú kọ àwọn àdánwò tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwàláàyè wa. Nígbà tí Mary wà nínú oyún ọmọ rẹ̀ kẹta, dókítà rẹ̀ sọ fún un pé kó ṣẹ́ oyún náà. Dókítà náà sọ fún Mary pé: “Ipò tó o wà léwu gan-an. Ìgbàkígbà ni nǹkan lè gbòdì lára rẹ lọ́wọ́ tó o wà yìí, wà á sì kú láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún. Ọmọ inú rẹ náà á sì kú pẹ̀lú. Yàtọ̀ síyẹn, kò sẹ́ni tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé ọmọ náà máa jẹ́ ọmọ gidi.” Mary ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ kò tíì ṣèrìbọmi. Mary sọ pé: “Mo ti pinnu láti sin Jèhófà, mo sì ti pinnu láti máa ṣègbọràn sí i, láìfi ohunkóhun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ pè.”—Ẹ́kísódù 21:22, 23.

11 Ní gbogbo àkókò tí Mary fi wà nínú oyún yẹn, ńṣe ló tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ̀ tó sì ń bójú tó ìdílé rẹ̀. Níkẹyìn, ó bí ọmọ náà. Mary wá sọ pé: “Ó ṣòro díẹ̀ fún mi láti bí ọmọ náà ju ìgbà tí mo bí àwọn méjì tó ṣáájú, àmọ́ kò sí ìṣòro ńlá kan tó yọjú.” Ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ kí Mary ní ẹ̀rí ọkàn rere, ó sì ṣèrìbọmi láìpẹ́ sí àkókò yẹn. Bí ọmọ tó bí náà ṣe ń dàgbà lóun náà ń kọ́ béèyàn ṣe ń bẹ̀rù Jèhófà, ó sì ti ń sìn ní ọkàn lára àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí.

‘Gba Okun Látọ̀dọ̀ Jèhófà’

12. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe fún Dáfídì lókun?

12 Kì í ṣe pé ìbẹ̀rù Jèhófà kò jẹ́ kí Dáfídì ṣe ohun tí kò tọ́ nìkan ni. Ó tún fún un lókun láti mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe àti láti hùwà ọlọgbọ́n nígbà tó wà nínú ìṣòro. Odindi ọdún kan gbáko àti oṣù mẹ́rin ni Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fi wà ní Síkílágì tó jẹ́ àrọko àwọn ará Filísínì, tí wọ́n ń sá fún Sọ́ọ̀lù. (1 Sámúẹ́lì 27:5-7) Nígbà kan, táwọn ọkùnrin náà ò sí nítòsí, àwọn ará Ámálékì tí wọ́n máa ń kó ẹrù ẹlẹ́rù lọ wá dáná sun ìlú wọn, wọ́n sì kó àwọn aya wọn, àwọn ọmọ wọn, àtàwọn ohun ọ̀sìn wọn lọ. Nígbà tí Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ padà dé tí wọ́n rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹkún ni gbogbo wọ́n bú sí. Kíá, ìbànújẹ́ náà yí padà di ẹ̀hónú, àwọn ọkùnrin náà sì fẹ́ sọ Dáfídì lókùúta. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Dáfídì bà jẹ́, síbẹ̀ kò bọ́hùn. (Òwe 24:10) Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó ní mú kó yíjú sí Jèhófà, ó sì ‘gba okun látọ̀dọ̀ Jèhófà.’ Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, Dáfídì àtàwọn ọkùnrin náà lé àwọn ará Ámálékì náà bá, wọ́n sì gba gbogbo nǹkan wọn padà.—1 Sámúẹ́lì 30:1-20.

13, 14. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dára?

13 Bákan náà lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń bára wọn nínú ipò tó gba pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kí wọ́n sì nígboyà láti ṣèpinnu tó dára. Wo àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kristina. Nígbà tí Kristina wà ní kékeré, ó kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ iṣẹ́ dùùrù títẹ̀ lágbo ijó ló fẹ́ ṣe, ó sì ti tẹ̀ síwájú gan-an nínú ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, ojú tún ń tì í láti wàásù, ìyẹn ló fi ń bẹ̀rù àtiṣe ìrìbọmi nítorí iṣẹ́ tó máa já lé e léjìká lẹ́yìn ìrìbọmi náà. Bí Kristina ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i ló bẹ̀rẹ̀ sí í rí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní. Ó kọ́ béèyàn ṣe ń ní ìbẹ̀rù Jèhófà, ó sì wá rí i pé Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun nífẹ̀ẹ́ òun pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn, gbogbo èrò inú wọn, àti gbogbo okun wọn. (Máàkù 12:30) Èyí ló wá mú kó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tó sì ṣèrìbọmi.

14 Kristina bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kóun lè tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé gbogbo ìgbà lẹni tó bá ń tẹ dùùrù lágbo ijó máa ń rìnrìn àjò, tó sì máa ń gba iṣẹ́ tó lè mú kó lọ ṣeré tí ó tó irínwó [400] láàárín ọdún kan. Mo wá pinnu láti ṣe iṣẹ́ olùkọ́ kí n lè gbọ́ bùkátà ara mi kí n sì lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún pẹ̀lú.” Lákòókò yẹn, ètò ti wà nílẹ̀ pé kí Kristina wá ṣeré fúngbà àkọ́kọ́ ní gbọ̀ngàn ìṣeré kan tó gbayì jù lọ lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo lọ dá àwọn èèyàn lára yá yẹn náà ni ìgbà tí mo ṣeré kẹ́yìn.” Kristina ti fẹ́ Kristẹni kan tó jẹ́ alàgbà báyìí. Àwọn méjèèjì sì jọ ń sìn ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú rẹ̀ dùn pé Jèhófà fóun lókun láti ṣe ìpinnu tó dára àti pé òun lè wá máa lo àkókò òun àti agbára òun nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà báyìí.

Ogún Tó Ṣeyebíye

15. Kí ni Dáfídì fẹ́ fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ọ̀nà wo ló sì gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

15 Dáfídì kọ̀wé pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi. Ìbẹ̀rù Jèhófà ni èmi yóò kọ́ yín.” (Sáàmù 34:11) Bàbá ni Dáfídì, ó sì múra tán láti fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ogún tó ṣeyebíye, ìyẹn ni ojúlówó ìbẹ̀rù Jèhófà tó ti ọkàn wá. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Dáfídì àti ìṣe rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣẹni tó ń fagbára múni ṣe nǹkan bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣẹni tó ń kó jìnnìjìnnì báni, tó ń retí ẹni tó máa rú òfin òun kóun lè fìyà jẹ onítọ̀hún. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́, tó bìkítà fáwọn ọmọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé tó sì ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. Dáfídì béèrè pé: “Àwọn àṣìṣe—ta ní lè fi òye mọ̀ wọ́n?” Lẹ́yìn náà, kí Dáfídì lè fi hàn pé ó dá òun lójú pé kì í ṣe àwọn ìṣìnà wa ni Jèhófà ń wá nígbà gbogbo, ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kéde mi ní aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀!” Ó dá Dáfídì lójú pé tóun bá sa gbogbo ipá òun, ọ̀rọ̀ àti èrò òun lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Jèhófà.—Sáàmù 19:12, 14.

16, 17. Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìbẹ̀rù Jèhófà?

16 Dáfídì jẹ́ àpẹẹrẹ fáwọn òbí lónìí. Arákùnrin Ralph tóun àti àbúrò rẹ̀ jọ ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Àwọn òbí wa tọ́ wa lọ́nà tó mú kí wíwà tá a wà nínú òtítọ́ jẹ́ ohun tó dùn mọ́ wa. Nígbà tá a wà lọ́mọdé, wọ́n máa ń pè wá láti dá sí ìjíròrò wọn nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgbòkègbodò ìjọ, ìyẹn sì jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ gan-an báwọn náà ṣe nífẹ̀ẹ́ sí i. Wọ́n tọ́ wa lọ́nà tó mú ká gbà gbọ́ pé a lè ṣe àwọn ohun tó dára gan-an nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kódà, ó níye ọdún tí ìdílé wa fi gbé lórílẹ̀-èdè kan táwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí, a sì ṣèrànwọ́ láti dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀.

17 “Kì í ṣe ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òfin kàn-ń-pá ló mú ká ṣe ohun tó tọ́, bí kò ṣe pé àwọn òbí wa gbà pé Jèhófà wà lóòótọ́, pé ó jẹ́ onínúure gan-an àti pé ẹni rere ni. Wọ́n wá ọ̀nà láti túbọ̀ mọ Jèhófà dáadáa, wọ́n sì tún wá bí wọ́n ṣe máa múnú rẹ̀ dùn, a sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú ojúlówó ìbẹ̀rù àti ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run. Kódà nígbà tá ò bá ṣe ohun kan bó ṣe tọ́, àwọn òbí wa kì í jẹ́ ká lérò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa mọ́ nìyẹn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tìtorí bẹ́ẹ̀ fìbínú gbé àwọn òfin kan tí kò pọn dandan kalẹ̀ fún wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń pè wá jókòó tí wọ́n á sì máa bá wa sọ̀rọ̀, ìgbà mìíràn tiẹ̀ wà tí omi máa ń bọ́ lójú Mọ́mì nígbà tó bá ń gbìyànjú láti jẹ́ ká lóye ohun tó ń bá wa sọ. Ìsapá náà sì kẹ́sẹ járí lóòótọ́. A kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn òbí wa pé ohun tó dára gan-an ni kéèyàn bẹ̀rù Jèhófà àti pé nǹkan ayọ̀ ni kéèyàn jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀, kì í ṣe ohun tó nira.”—1 Jòhánù 5:3.

18. Kí ni yóò jẹ́ èrè wa tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́?

18 Lára àwọn “ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì” la ti kà á pé: “Nígbà tí ẹni tí ń ṣàkóso lórí aráyé bá jẹ́ olódodo, tí ó ń ṣàkóso nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run, nígbà náà, yóò dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, nígbà tí oòrùn ràn.” (2 Sámúẹ́lì 23:1, 3, 4) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ náà yé Sólómọ́nì tó jẹ́ ọmọ Dáfídì tó sì tún jọba tẹ̀ lé bàbá rẹ̀, nítorí ó bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà fún òun ní “ọkàn-àyà ìgbọràn” àti ọgbọ́n “láti fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú.” (1 Àwọn Ọba 3:9) Sólómọ́nì mọ̀ pé ìbẹ̀rù Jèhófà ló ń fúnni ní ọgbọ́n àti ayọ̀. Lẹ́yìn náà, ó wá ṣàkópọ̀ gbogbo ohun tó wà nínú ìwé Oníwàásù, ó sì sọ pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn. Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.” (Oníwàásù 12:13, 14) Tá a bá fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, a ó rí i pé lóòótọ́ kì í ṣe ọgbọ́n àti ayọ̀ nìkan ni “ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà” máa ń yọrí sí, àmọ́ ó tún ń fúnni ní “ọrọ̀ àti ògo àti ìyè” pẹ̀lú.—Òwe 22:4.

19. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti lóye “ìbẹ̀rù Jèhófà”?

19 Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní fi hàn pé ojúlówó ìbẹ̀rù Ọlọ́run ń kó ipa tó dára nínú ìgbésí ayé àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ olóòótọ́ fún Jèhófà. Kì í ṣe pé irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ká ṣe ohun tí kò ní múnú Bàbá wa ọ̀run dùn nìkan ni, àmọ́ ó tún lè fún wa nígboyà láti kojú àwọn tó ń gbógun tì wá. Ó sì tún lè fún wa lókun láti fara da àwọn àdánwò àti ìṣòro tó lè dé bá wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa, lọ́mọdé lágbà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kọ́, ká sì máa sún mọ́ Jèhófà nípa gbígba àdúrà àtọkànwá déédéé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé a ó rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” nìkan, àmọ́ a ó tún lóye “ìbẹ̀rù Jèhófà” pẹ̀lú.— Òwe 2:1-5.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

b Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lè jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó mú kí Dáfídì kọ Sáàmù kẹtàdínlọ́gọ́ta [57] àti ìkejìlélógóje [142].

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run

• ṣe lè ran ẹnì kan tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lọ́wọ́ láti bọ̀ sípò?

• ṣe lè fúnni láyọ̀ nígbà tá a bá ń kojú àdánwò àti inúnibíni?

• ṣe lè fún wa lókun láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

• ṣe lè jẹ́ ogún tó ṣeyebíye fún àwọn ọmọ wa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìbẹ̀rù Jèhófà ni kò jẹ́ kí Dáfídì pa Sọ́ọ̀lù Ọba

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ ogún ṣíṣeyebíye táwọn òbí lè fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́