Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Igbó Kìjikìji Amazon Ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Igbó Kìjikìji Amazon—Àwọn Àròsọ àti Ìṣẹ̀lẹ̀ Gidi” (March 22, 1997), wọ̀ mí lọ́kan gan-an. Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa ewéko tí ń bá Ẹ̀ka Iṣẹ́ Aṣọ́gbó ní United States ṣiṣẹ́, mo ní láti ka ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí àyíká. Síbẹ̀, mo ka àpilẹ̀kọ yín sí èyí tí ó dára jù lọ lára àwọn tí mo tí ì kà nípa kókó ọ̀rọ̀ náà. Ẹ ṣèwádìí dáradára lórí rẹ̀, ó kún fún ẹ̀kọ́, ó sì bá ìgbà mu, ó sì gbádùn mọ́ni láti kà. Ó ṣí mi lórí láti rí i tí àwọn èròǹgbà bí ìjónírúurú ohun alààyè, ìmújáde èròjà láti inú igbó, fífi irú ọ̀wọ́ ìṣẹ̀dá sí àdádó, àti ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn fara hàn nínú ìwé ìròyìn kan tí iye rẹ̀ tí a pín káàkiri àgbáyé pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Èyí yóò mú kí ipò nǹkan sunwọ̀n sí i.
D. S., United States
Ọmọ ọdún 12 ni mí, mo sì fẹ́ dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ yín fún àwọn àpilẹ̀kọ náà. Ó di dandan fún mi láti kà wọ́n ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí a gba ìwé ìròyìn náà gan-an! Níwọ̀n bí a ti ń ṣiṣẹ́ lórí kókó ọ̀rọ̀ yí ní ilé ẹ̀kọ́, ní kíláàsì ẹ̀kọ́ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ kejì, mo fún olùkọ́ tí ń kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀ ní ọ̀kan. Dájúdájú, ìyẹn mú kí àwọn yòó kù nínú kíláàsì fẹ́ tọ pinpin, mo sì nírètí láti fi àwọn ìwé ìròyìn díẹ̀ sí i síta fún wọn.
T. E., Germany
Àwọn àpilẹ̀kọ náà ń fani lọ́kàn mọ́ra ní tòótọ́. Àwọn irú ọ̀wọ́ kòkòrò tí a mẹ́nu kan pọ̀ gan-an níye, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní iṣẹ́ tirẹ̀ láti ṣe lábẹ́ àwọn ewé tí ó wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀ inú igbó kìjikìji náà. Jèhófà ń rí i dájú pé ìpèsè oúnjẹ wà fún gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀. Mo lè lóye ìdí tí òun yóò ṣe “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.”—Ìṣípayá 11:18.
D. K. H., United States
Bíbúmọ́ni—Ewu Wo Ló Wà Níbẹ̀? Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Bíbúmọ́ni—Ewu Wo Ló Wà Níbẹ̀?” (March 22, 1997) Gbogbo ènìyàn ló máa ń fi àwọn tí wọn kò lera tó ṣẹ̀sín ní ilé ẹ̀kọ́, èyí sì sún èmi pẹ̀lú láti ṣe ohun kan náà. Ṣùgbọ́n ìṣítí tí ẹ fúnni nínú àpilẹ̀kọ yìí láti fi ọ̀ràn onítọ̀hún ro ara ẹni wò ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti jáwọ́ bíbúmọ́ni. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ ṣeun.
M. N., ilẹ̀ Faransé
Ọmọ ọdún 17 ni mí, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gan-an fún àpilẹ̀kọ náà. Ó jẹ́ ìdáhùn sí àdúrà mi, ó sì fún mi níṣìírí gidigidi. Mímọ̀ pé Jèhófà kórìíra bíbúmọ́ni ti ràn mí lọ́wọ́ gidigidi láti ṣe àwọn ìyípadà tí ó pọn dandan nínú ọ̀nà ìhùwà mi. Òfin Oníwúrà náà àti àpẹẹrẹ ti Jésù wọ̀ mi lọ́kàn pẹ̀lú, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ láti máa hùwà bí ó ti yẹ.
V. T., Ítálì
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ní iyàrá àlejò kan, mo mú ìwé ìròyìn Jí! kan, mo sì rí àpilẹ̀kọ tí wọ́n kọ dáradára yìí. Mo lóye ìpalára tí kì í lọ bọ̀rọ̀ tí bíbúmọ́ni lè ṣokùnfà rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin máa ń bú mi, ó máa ń pa ìmọ̀lára mi lára, ó sì máa ń lù mí. Bí mo bá gbéjà kò ó, yóò gún èjìká, yóò rẹ́rìn-ín, yóò sì sọ pé òun wulẹ̀ ń ṣeré ni. Yóò wí fún mi pé, èmi ni mo ní ìṣòro nítorí pé n kò ní ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani! Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún 13 tí òun sì wà ní ọmọ ọdún 15, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fi ìbálòpọ̀ fìtínà mi. Ìgbà gbogbo ni ẹ̀rù rẹ̀ máa ń bà mí nítorí pé ó jù mí lọ, ó tóbi jù mí lọ, ó sì lágbára jù mí lọ gan-an! Àwọn òbí mi kò gbèjà mi rí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jí! fún sísọ nípa àwọn kókó pàtàkì nínú ìgbésí ayé. Mo mọ̀ pé ó gba ìgboyà. Mo ronú pé àpilẹ̀kọ yín náà ti wọ ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn.
B. S. M., United States
Àwọn Kòkòrò Tí Ń Tọ́jú Ọgbà Lẹ́yìn kíka àpilẹ̀kọ náà, “Ògbóǹkangí Olùtọ́jú Ọgbà” (March 22, 1997), mo ṣèbẹ̀wò sí ibi ìpàtẹ kan, mo sì rí àwọn ìgbòkègbodò tí ẹ ṣàpèjúwe. Ó jọ pé àwọn ewé ń rìn lórí okùn kan tí ó nà wálẹ̀ láti òrùlé. Ní gidi, àwọn kòkòrò ló ń gbé àwọn ewé náà, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ọ̀gbìn olú kan nítòsí. Rírí ohun tí ẹ mẹ́nu kan jẹ́ ìran àgbàyanu kan ní tòótọ́, ó sì mú kí èmi àti àwọn ọmọdébìnrin mi méjèèjì túbọ̀ sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, Jèhófà.
P. F., Scotland