Kíkọ́ Láti Yọ̀ǹda Wọn
ONÍSÁÀMÙ náà sọ nínú Bíbélì pé: “Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe.” (Orin Dáfídì 127:4) Ọfà kì í ṣèèṣì ba ohun tí a ta á lù. A ní láti fẹ̀sọ̀ fojú sùn ún. Ní ọ̀nà kan náà, àwọn ọmọ lè máà dé ojú ìwọ̀n dídàgbà di ẹni tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ bí kò bá sí ìtọ́sọ́nà òbí. Bíbélì gbani níyànjú pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀,” àti “nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6.
A kò lè fi ọ̀sán-kan-òru-kan yí ìgbáraléni ìgbà ọmọdé pa dà sí dídá nǹkan ṣe nígbà tí a bá dàgbà. Nítorí náà, ìgbà wo ló yẹ kí àwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́ àwọn ọmọ wọn láti lè dá nǹkan ṣe fúnra wọn? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹ́ Tímótì létí pé: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọgbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (Tímótì Kejì 3:15) Rò ó wò ná, ìyá Tímótì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ ní ohun tẹ̀mí nígbà tí ó ti wà ní ọmọdé jòjòló!
Ó dára, bí àwọn ọmọdé jòjòló bá lè jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ ohun tẹ̀mí, kò ha bọ́gbọ́n mu pé kí a tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọdé ní ẹ̀kọ́ tí wọn óò mú lò nígbà tí wọ́n bá dàgbà bí ó bá ṣe lè yá tó? Ọ̀nà kan tí a lè gbà ṣe èyí ni kí a kọ́ wọn láti jẹ́ ẹni tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, tí ó lè dá ìpinnu ṣe fúnra wọn.
Kíkọ́ Ọmọ Láti Ṣeé Fẹrù Iṣẹ́ Lé Lọ́wọ́
Báwo ni o ṣe lè fún ọmọ rẹ níṣìírí láti jẹ́ ẹni tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́? Tọkọtaya kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Jack àti Nora rántí nípa ọmọbìnrin wọn pé: “Nígbà tí kò tí ì lè rìn dáadáa, ó kọ́ láti máa kó ìbọ̀sẹ̀ tàbí àwọn ohun kéékèèké lọ sí iyàrá rẹ̀, kí ó sì kó wọn sí ibi tí ó yẹ kí wọ́n wà nínú kọ́bọ́ọ̀dù. Ó tún kọ́ láti máa kó àwọn ohun ìṣeré ọmọdé àti ìwé sí ibi tí ó yẹ kí wọ́n wà.” Ìwọ̀nyí jẹ́ bíbẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ohun kéékèèké, àmọ́ ọmọ náà ti ń kọ́ bí a ti ń ṣe àwọn ìpinnu tí ó bọ́gbọ́n mu.
Bí ọmọ kan ṣe ń dàgbà sí i, bóyá a lè fi ẹrù iṣẹ́ tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì lé e lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, Abra àti Anita ra ajá ìṣeré kan fún ọmọbìnrin wọn. Ọmọdébìnrin náà ni ó ń bójú tó ajá náà, ó sì ń fi lára owó tí wọ́n ń fún un silẹ̀ fún níná sórí ajá náà. Kíkọ́ ọmọ láti mú àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn ṣe gba sùúrù. Àmọ́ ó yẹ bẹ́ẹ̀, ó sì ń kópa nínú ìdàgbàsókè èrò ìmọ̀lára wọn.
Àwọn iṣẹ́ ilé ń pèsè àǹfààní mìíràn láti kọ́ àwọn ọmọ nípa ẹrù iṣẹ́. Àwọn òbí kan fẹ́rẹ̀ẹ́ máà máa jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn ṣe nínú iṣẹ́ ìdílé rárá, wọn kò ka ìlọ́wọ́sí wọn sí ìrànlọ́wọ́ bí kò ṣe ìyọlẹ́nu. Àwọn mìíràn ronú pé ó yẹ ki àwọn ọmọ àwọn ‘gbádùn ayé wọn ju èyí tí àwọn gbádùn lọ́mọdé lọ.’ Ìrònú yìí kò bọ́gbọ́n mu. Ìwé Mímọ sọ pé: “Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.” (Òwe 29:21, NW) Ìlànà tí ó wà nínú ẹsẹ ìwé yìí kan àwọn ọmọdé. Ó máa ń bani nínú jẹ́ tí èwe kan bá dàgbà di ẹni tí kì í ṣe pé ó jẹ́ “aláìmọ ọpẹ́ dá” nìkan, àmọ́ tí kò tún lè ṣe àwọn iṣẹ́ ilé tí ó rọrùn jù lọ pàápàá.
Ó wọ́pọ̀ pé kí wọ́n yan iṣẹ́ fún àwọn èwe ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀dọ́mọdé Jósẹ́fù ṣì jẹ́ ọmọ ọdún 17 péré, ó kópa nínú ẹrù iṣẹ́ bíbójútó àwọn agbo ẹran ìdílé. (Jẹ́nẹ́sísì 37:2) Èyí kì í ṣe iṣẹ́ kékeré, nítorí pé àwọn agbo ẹran bàbá rẹ̀ tóbi gan-an. (Jẹ́nẹ́sísì 32:13-15) Lójú òtítọ́ náà pé Jósẹ́fù dàgbà di aṣáájú tí ó lágbára, kò ṣòro láti gbà gbọ́ pé ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ ọ yìí kópa púpọ̀ láti mú kí ìwà rẹ̀ dára. Bákan náà ni wọ́n tún fi àwọn agbo ẹran ìdílé Dáfídì, ẹni tí yóò wá jé ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú náà, sí ìkáwọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ èwe.—Sámúẹ́lì Kíní 16:11.
Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn òbí kọ́ lónìí? Ẹ gbé iṣẹ́ ilé tí ó ṣe gúnmọ́ fún àwọn ọmọ yín. Pẹ̀lú àkókò, ìsapá, àti sùúrù, ẹ lè kọ́ àwọn ọmọ yín láti ṣàjọpín nínú títọ́jú ilé, gbígbọ́únjẹ, bíbójútó àgbàlá ilé, àti ṣíṣàtúnṣe ilé àti ọkọ̀. Lótìítọ́, púpọ̀ sinmi lé ọjọ́ orí àti bí ọmọ náà ti tóótun tó. Àmọ́ àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá lè lọ́wọ́ nínú ‘ríran Dádì lọ́wọ́ láti tún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ṣe’ tàbí nínú ‘ríran Mọ́mì lọ́wọ́ láti gbọ́únjẹ.’
Kíkọ́ àwọn ọmọ ní iṣẹ́ ilé tún ń béèrè pé kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀bùn kan tí ó ṣeyebíye jù lọ—àkókò wọn. A bi tọkọtaya kan, tí wọ́n ti bímọ méjì, ní ohun tí ó jẹ́ àṣírí kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ó kẹ́sẹ járí. Wọ́n fèsì pé: “Àkókò, àkókò, àkókò!”
Ìbáwí Onífẹ̀ẹ́
Nígbà tí àwọn ọmọ bá ṣe iṣẹ́ wọn dáradára, tàbí tí wọ́n bá tilẹ̀ sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀, fún wọn ní ìṣírí nípa gbígbóríyìn fún wọn ní fàlàlà àti látọkànwá! (Fi wé Mátíù 25:21.) Lótìítọ́, àwọn ọmọ kì í lè ṣe iṣẹ́ dáadáa tó bí àgbàlagbà ṣe lè ṣe é. Bí a bá sì gba àwọn ọmọdé láyè láti dá ìpinnu tiwọn ṣe, wọn óò ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n ṣọ́ra fún kíkanra jù! Ṣé ìwọ tí o jẹ́ àgbàlagbà kò ṣàṣìṣe rí ni? Nítorí náà, èé ṣe tí o kò ṣe sùúrù nígbà tí ọmọ rẹ bá ṣàṣìṣe? (Fi wé Orin Dáfídì 103:13.) Fi àyè àṣìṣe sílẹ̀. Wò wọ́n bí ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́.
Òǹkọ̀wé Michael Schulman àti Eva Mekler ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ tí a ń hùwà bí ọ̀rẹ́ sí kì í bẹ̀rù pé a óò fìyà jẹ àwọn nítorí pé àwọn dá nǹkan ṣe.” Àmọ́, “àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn kò lọ́yàyà tàbí tí wọ́n ń kanra máa ń bẹ̀rù láti dánú ṣe ohunkóhun, títí kan èyí tí ó wúlò, nítorí ìbẹ̀rù pé àwọn òbí àwọn yóò rí àwọn àṣìṣe kan nínú ohun tí àwọn ṣe, wọn óò sì rí wí sí àwọn tàbí kí wọ́n fìyà jẹ̀ àwọn.” Ọ̀rọ̀ yí fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìkìlọ̀ tí Bíbélì fún àwọn òbí pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà sorí kodò.” (Kólósè 3:21) Nítorí náà, bí ìsapá ọmọ kan kò bá kúnjú ìwọ̀n ohun tí ẹ retí, ó kéré tán, ẹ kò ṣe yìn ín nítorí pé ó tilẹ̀ gbìyànjú? Ẹ fún un níṣìírí láti túbọ̀ ṣe dáradára nígbà míràn. Ẹ jẹ́ kí ó mọ̀ pé ìtẹ̀síwájú rẹ̀ jẹ́ orísun ìdùnnú fún yín. Ẹ mú un dá a lójú pé ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Òtítọ́ ni pé a kò lè ṣàìbọ́mọwí nígbà míràn. Èyí lè hàn kedere ní pàtàkì ní àwọn ọdún ìṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà, nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ ń làkàkà láti fìdí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ múlẹ̀, láti jẹ́ ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà bí ẹni tí ó já mọ́ nǹkan. Nítorí náà, yóò bọ́gbọ́n mu fún àwọn òbí láti fòye wo irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ láti jèrè òmìnira dípò kí wọ́n máa fìgbà gbogbo túmọ̀ rẹ̀ sí ẹ̀mí ọ̀tẹ̀.
Òtítọ́ ni pé àwọn èwe kì í ronú jinlẹ̀ kí wọ́n tó ṣe nǹkan tàbí kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ fún “àwọn ìfẹ́ ọkàn tí ó sábà máa ń bá ìgbà èwe rìn.” (Tímótì Kejì 2:22) Nítorí náà, kíkùnà láti pààlà sí ìwà tí ó bá ìgbà èwe rìn lè ba ọmọ kan jẹ́ ní ti èrò ìmọ̀lára; kò ní í kọ́ bí a ti ń kóra ẹni níjàánu tí a sì ń ká ara ẹni lọ́wọ́ kò. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ọmọ tí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ fún ara rẹ̀, a dójú ti ìyá rẹ̀.” (Òwé 29:15) Ṣùgbọ́n àǹfààní wà nínú ìbáwí tí ó ṣe wẹ́kú, tí a fi ìfẹ́ ṣe, ó sì ń múra èwe kan sílẹ̀ fún àwọn pákáǹleke àti ohun tí ó nílò nígbà tí ó bá dàgbà. Bíbélì gbani níyànjú pé: “Ẹni tí ó bá fa ọwọ́ pàṣán sẹ́yìn, ó kórìíra ọmọ rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ ẹ a máa tètè nà án.” (Òwe 13:24) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, rántí pé pàtàkì ohun tí ìbáwí wà fún ni ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́—kì í ṣe ìfìyàjẹni. Ó ṣeé ṣe kí ohun tí a pè ní “pàṣán” níhìn-ín tọ́ka sí ọ̀pá tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn fi ń da ẹran wọn. (Orin Dáfídì 23:4) Ó jẹ́ àmì ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́—kì í ṣe ìwà òkú òǹrorò adánilágara.
Ẹ̀kọ́ Tí Ń Fúnni Ní Ìyè
A nílò ìtọ́sọ́nà òbí ní pàtàkì tí ó bá di ti ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ọmọ kan. Ní ọkàn ìfẹ́ nínú ẹ̀kọ́ ọmọ rẹ. Ràn án lọ́wọ́ láti yan ìlà ẹ̀kọ́ tí ó tọ̀nà ní ilé ẹ̀kọ́ àti láti ṣe ìpinnu tí ó ní láárí nípa bóyá yóò nílò àfikún ẹ̀kọ́ èyíkéyìí.a
Ní tòótọ́, ẹ̀kọ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo rẹ̀ ni ẹ̀kọ́ nípa ti ẹ̀mí. (Aísáyà 54:13) Àwọn ọmọ yóò nílò ìlànà oníwà bí Ọlọ́run láti là á já bí wọ́n bá dàgbà. A gbọ́dọ̀ kọ́ “agbára ìwòye” wọn. (Hébérù 5:14) Àwọn òbí lè ṣe ohun púpọ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́nà yí. A rọ àwọn ìdílé tí ń dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa bá àwọn ọmọ wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ ìyá Tímótì, tí ó kọ́ ọ ní Ìwé Mímọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló, bákan náà ni àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ń kọ́ àwọn ọmọ wọ́n kéékèèké.
Òbí kan tí ó jẹ́ anìkàntọ́mọ, tí ń jẹ́ Barbara mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé jẹ́ ìrírí gbígbádùnmọ́ni jù lọ fún àwọn ọmọ rẹ̀. “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, màá rí i dájú pé mo se oúnjẹ tí ó dára fún àwọn ọmọ, tí ó ní mindinmín-ìndìn tí wọ́n fẹ́ràn nínú. Màá gbé orin Kingdom Melody sí i láti múra wọn sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí a bá ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà, a sábà máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ṣùgbọ́n bí àìní pàtàkì kan bá wà, mo lè lo àwọn ìtẹ̀jáde bí Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.”b Gẹ́gẹ́ bí Barbara ti sọ, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti “mọ èrò Jèhófà lórí àwọn ọ̀ràn.”
Òtítọ́ ni, kò sí ẹ̀bùn tí ó tóbi tí a lè fún ọmọ kan ju ìmọ̀ àti òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, lọ. Ó lè “fi òye fún aláìmọ̀kan, láti fún ọ̀dọ́mọkùnrin ní ìmọ̀ àti ìrònú.” (Òwe 1:4) Bí a bá ti múra èwe kan sílẹ̀ lọ́nà yí, òun yóò dàgbà di ẹni tí ó tóótun láti kojú àwọn pákáǹleke àti ìṣòro tuntun.
Síbẹ̀síbẹ̀, fífi tí àwọn ọmọ ń fi ilé sílẹ̀ máa ń fa ìyípadà ńlá nínú ọ̀nà ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ jù lọ òbí. Bí wọ́n ṣe lè kojú gbígbé ilé tí ó ṣófo lọ́nà tí ó ní àṣeyọrí ni a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ wa tí ó tẹ̀ lé èyí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ẹyin Obi—Iṣẹ́-Ilé Wà fun Ẹyin Naa Pẹlu!” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, September 8, 1988.
b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn kò lọ́yàyà tàbí tí wọ́n ń kanra máa ń bẹ̀rù láti dánú ṣe ohunkóhun, títí kan èyí tí ó wúlò, nítorí ìbẹ̀rù pé àwọn òbí àwọn yóò rí àwọn àṣìṣe kan nínú ohun tí àwọn ṣe, wọn óò sì rí wí sí àwọn tàbí kí wọ́n fìyà jẹ̀ àwọn.”—Bringing Up a Moral Child, tí Michael Schulman àti Eva Mekler ṣe
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Òbí Anìkàntọ́mọ—Ìpèníjà Yíyọ̀ǹda Wọn
Òbí kan tí ó jẹ́ anìkàntọ́mọ, tí ń jẹ́ Rebecca, ṣàlàyé pé: “Ó ṣòro gan-an fún àwọn òbí anìkàntọ́mọ láti yọ̀ǹda àwọn ọmọ wọn. Bí a kò bá ṣọ́ra, a ń ní ìtẹ̀sí láti dáàbò bò wọ́n ju bó ti yẹ lọ, a sì ń tẹ ìdàgbàsókè wọn rì.” Ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé,* ojú ìwé 106 sí 107, pèsè àwọn àkíyèsí wíwúlò wọ̀nyí pé:
“Lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn òbí anìkàntọ́mọ lè sún mọ́ àwọn ọmọ wọn pẹ́kípẹ́kí, síbẹ̀, ó gba ìṣọ́ra láti ka àwọn ààlà tí Ọlọrun fi lélẹ̀ láàárín òbí àti ọmọ sí. Bí àpẹẹrẹ, ìṣòro ńlá lè yọjú, bí ìyá anìkàntọ́mọ kan bá retí kí ọmọkùnrin rẹ̀ máa kó ipa baálé ilé, tàbí tí ó fi ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe agbọ̀ràndùn, tí ó ń di ẹrù ìnira ìṣòro ọ̀ràn ara ẹni rẹ̀ lé ọmọdébìnrin náà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò tọ́, ó ń máyé súni, ó sì ṣeé ṣe kí ó máa da ọmọdé lọ́kàn rú.
“Fi dá àwọn ọmọ rẹ lójú pé ìwọ, gẹ́gẹ́ bí òbí, ni yóò bójú tó wọn—kì í ṣe àwọn ni yóò bójú tó ọ. (Fi wé 2 Korinti 12:14.) O lè nílò ìmọ̀ràn tàbí ìtìlẹ́yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Wá a sọ́dọ̀ àwọn Kristian alàgbà tàbí bóyá sọ́dọ̀ àwọn obìnrin Kristian adàgbàdénú, kì í ṣe sọ́dọ̀ àwọn ọmọ rẹ kéékèèké.—Titu 2:3.”
Bí àwọn òbí anìkàntọ́mọ bá gbé àwọn ààlà bíbẹ́tọ̀ọ́mu kalẹ̀, tí wọ́n sì bá àwọn ọmọ wọn lò lọ́nà tí ó gbámúṣé, ó sábà máa ń rọrùn fún wọn láti yọ̀ǹda wọn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹ̀kọ́ tí ó gbéṣẹ́ lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti dàgbà di ẹni tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé lè fún àwọn ọmọ ní ọgbọ́n tí wọ́n nílò láti kojú ìgbésí ayé nígbà tí wọ́n bá dàgbà