Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ìṣọ̀kan Kristẹni Fàyè Gba Jíjẹ́ Onírúurú?
ÌṢỌ̀KAN ṣe kókó nínú ìjọ Kristẹni. Àìṣọ̀kan nínú èrò ẹ̀kọ́ ìsìn lè dá awuyewuye, ìyapa, àti ìṣọ̀tá lílekoko pàápàá sílẹ̀. (Ìṣe 23:6-10) Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” (Kọ́ríńtì Kíní 14:33) Nítorí náà, a rọ àwọn Kristẹni láti máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, kí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.—Kọ́ríńtì Kíní 1:10
Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àwọn mìíràn tó fara jọ wọ́n nínú Bíbélì ń fún wíwà láìní ìyàtọ̀ ní gbogbo ọ̀nà níṣìírí láàárín àwọn Kristẹni ni? (Jòhánù 17:20-23; Gálátíà 3:28) Ǹjẹ́ ìsìn Kristẹni tòótọ́, bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Bíbélì, ṣàìfún ìjónírúurú níṣìírí nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ànímọ́ olúkúlùkù bí? Ǹjẹ́ a retí pé kí gbogbo Kristẹni rí bákan náà láìṣeé yí pa dà bí?
Ọlọ́run Fà Wá Mọ́ra Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan
Àwọn ènìyàn kan gbà gbọ́ gidigidi pé Bíbélì wulẹ̀ jẹ́ ohun èlò míràn kan ti a fi ń darí ògìdìgbó ènìyàn bó ṣe wuni ṣáá ni. A gbà pé àwọn ẹ̀ya ìsìn kan ti sábà máa ń ṣì í lò lọ́nà bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù gbé èrò yíyàtọ̀gidi kan lárugẹ nípa àwọn Ìwé Mímọ́ àti Olú Ọ̀run tí í ṣe Òǹṣèwé wọn. Ó ṣàpèjúwe Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tó ní ìfẹ́ ọkàn jíjinlẹ̀ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá rẹ̀.
Nínú Jòhánù 6:44, Jésù ṣàlàyé pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” Ọ̀rọ̀ ìṣe tí a lò níhìn-ín kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ń wọ́ àwọn ènìyàn tuuru, lòdì sí ìfẹ́ inú wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ń fani pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ó ń fa ọkàn àyà mọ́ra. Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa Bíbélì kan ṣe sọ ọ́, ‘ipa kan wà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí ń mú kí èrò inú gbà gbọ́.’ Ẹlẹ́dàá kì í wo àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn bí àgbájọ kan tí ẹnì kọ̀ọ̀kan kò ti ní ànímọ́ ara ẹni. Ó ń díye lé ẹnì kọ̀ọ̀kan, ó sì ń rọra fa àwọn tí ó ní ọkàn àyà títọ́ mọ́ ara rẹ̀.—Orin Dáfídì 11:5; Òwe 21:2; Ìṣe 13:48.
Ṣàkíyèsí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ń mú ara rẹ̀ bá onírúurú ipò mu. Ó mọ àwọn àìní àrà ọ̀tọ̀ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní, ó sì gbà pé àwọn èrò kan wọ́pọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tàbí ipò àtẹ̀yìnwá kan. Ó wá ń mú kí ọ̀nà ìyọsíni rẹ̀ bá a mu gẹ́lẹ́. Ó kọ̀wé pé: “Fún àwọn Júù mo dà bíi Júù, kí èmi lè jèrè àwọn Júù; . . . Fún àwọn aláìlera mo di aláìlera, kí èmi lè jèrè àwọn aláìlera. Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí èmi lè gba àwọn kan là lọ́nàkọnà.”—Kọ́ríńtì Kíní 9:20-22.
Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù kò ronú pé àwọn ènìyàn dọ́gba, kò sì bá gbogbo ènìyàn lò lọ́nà kan náà. Ó fún wọn ní ìṣírí yìí pé: “Nígbà gbogbo ẹ jẹ́ kí gbólóhùn àsọjáde yín máa jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kólósè 4:6) Bẹ́ẹ̀ ni, Pọ́ọ̀lù àti àwọn Kristẹni míràn ti ní láti gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ànímọ́ tirẹ̀, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún irú ànímọ́ bẹ́ẹ̀ láti ran ẹni náà lọ́wọ́.
Ète Ọlọ́run Nípìlẹ̀
Ọ̀wọ̀ yí fún ẹnì kan bí ẹni tó yàtọ̀ sí àwọn mìíràn ń wà nìṣó lẹ́yìn tí ó bá ti di apá kan ìjọ Kristẹni. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run kò pàdánù ànímọ́ ara ẹni láàárín àwùjọ, kí wọ́n sì yí pa dà pátápátá láti mú ara wọn bá ohun tí àwọn tó wà ní ipò àṣẹ yàn láàyò mu. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbádùn onírúurú ànímọ́ ẹ̀dá, wọ́n sì ní agbára ìlèṣeǹkan, àṣà, àti èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. A kì í wo níní tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ànímọ́ tirẹ̀ bí ìyọlẹ́nu tàbí ìdíwọ́. Ó jẹ́ apá kan ète Ọlọ́run nípìlẹ̀.
Nítorí náà, nínú ayé tuntun tí a ṣèlérí nínú Bíbélì fún àwọn olódodo, ìjẹ́pípé láàárín ẹ̀dá ènìyàn yóò fàyè gba ìjónírúurú rẹpẹtẹ. (Pétérù Kejì 3:13) Lábẹ́ àkòrí náà, “Perfection” [Ìjẹ́pípé], ìwé gbédègbẹ́yọ̀ lórí Bíbélì náà, Insight on the Scriptures,a ṣàlàyé yìí lọ́nà yíyẹ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ìjẹ́pípé kò túmọ̀ sí òpin ìjónírúurú bí àwọn ènìyàn ti sábà máa ń rò. Àwùjọ àwọn ẹranko, tó jẹ́ àmújáde ‘iṣẹ́ pípé’ ti Jèhófà (Jẹ́[nẹ́sísì] 1:20-24; Di[utarónómì] 32:4), kún fún onírúurú lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight fi kún un pé: “Ìjẹ́pípé pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé bákan náà kò yapa sí ìjónírúurú, ìyípadà, tàbí ìyàtọ̀síra; ó fàyè gba èyí tó rọrùn àti èyí tó díjú, èyí tí kò ní ọ̀ṣọ́ àti èyí tó ní ọ̀ṣọ́, èyí tó kan àti èyí tó dùn, èyí tó rí págunpàgun àti èyí tó ń dán, ilẹ̀ eléwéko tútù àti ilẹ̀ ọ̀dàn; àwọn òkè ńlá àti àwọn àfonífojì. Ó kó ìtura ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé, ooru ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn òun ojú òfuurufú rẹ̀ aláwọ̀ búlúù mímọ́gaara, àwọn àwọ̀ fífanimọ́ra ti ìgbà ìwọ́wé, ògidì ẹwà òjò dídì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́, mọ́ra. (Jẹ́[nẹ́sísì] 8:22) Nípa bẹ́ẹ̀, a kò ní wòye àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé bí irú kan tí ó ní ànímọ́ ẹ̀dá, ẹ̀bùn, àti agbára ìlèṣeǹkan, tí kò yàtọ̀ síra.”
Ìdàníyàn fún Àwọn Ẹlòmíràn
Bí ó ti wù kí ó rí, ìsìn Kristẹni tòótọ́ kò fún ìmọtara-ẹni-nìkan láìdàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn láyìíká wa níṣìírí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fìṣọ́ra kíyè sí gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ̀ àti ìwà rẹ̀, kí ó lè yẹra fún mímú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, ó wí pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má baà rí àléébù pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.” (Kọ́ríńtì Kejì 6:3) Nígbà míràn, ó di dandan kí a kápá ìfẹ́ ọkàn ara ẹni wa, kí a sì gbé àìní àwọn ẹlòmíràn lékè àwọn ohun tí àwa fúnra wa yàn láàyò. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní Róòmù pé: “Ó dáa láti má ṣe jẹ ẹran tàbí mú ọtí wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.”—Róòmù 14:21.
Bákan náà lónìí, ẹnì kan lè yàn láti má mu ọtí líle níbi tí ẹlòmíràn tó ní ìṣòro kíkó ara rẹ̀ níjàánu nídìí ọtí mímu bá wà. (Kọ́ríńtì Kíní 10:23, 24) A kò ṣe èyí nítorí pé ó jẹ́ ọ̀ràn-anyàn láti bá ipò náà mu, ṣùgbọ́n a ṣe é gẹ́gẹ́ bí ìwà inúrere àti ìfẹ́ wíwúnilórí. “Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” Jésù jẹ́ ẹnì kan tí ó yàtọ̀, ṣùgbọ́n kò ṣe àwọn ohun tí ó fúnra rẹ̀ yàn láàyò láìka èrò àwọn ẹlòmíràn sí.—Róòmù 15:3.
Síbẹ̀, ọ̀kan lára àwọn apá tó wọni lọ́kàn jù lọ nínú ìsìn Kristẹni tòótọ́ ni ọ̀wọ̀ tó ní fún òmìnira àti ohun tó wu ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ko bá ti kọjá àwọn ààlà ìlànà Bíbélì. Ó ń kọ́ni pé Ọlọ́run dá wa láti dá yàtọ̀ kí a sì ní àwọn ànímọ́ ara ẹni. Nínú Kọ́ríńtì Kíní 2:11, a kà pé: “Nítorí ta ni láàárín àwọn ènìyàn ni ó mọ àwọn nǹkan ti ènìyàn bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn, èyí tí ń bẹ nínú rẹ̀?” A ń gbìyànjú bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti lóye àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n ẹsẹ yìí túmọ̀ sí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ànímọ́ yíyàtọ̀ tó jẹ́ pé àwa fúnra wa àti Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló yé. A ní “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà” tí a ń fi hàn bí a bá ṣe fẹ́.—Pétérù Kíní 3:4.
Ìṣọ̀kan àti Ìjónírúurú—Ìwàdéédéé Ẹlẹgẹ́
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ rere ti ìwàdéédéé Kristẹni lélẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ipò àṣẹ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Kristi, ó ṣọ́ra kí ó má baà gbé èrò tirẹ̀ karí àwọn ẹlòmíràn.
Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù ní èrò lílágbára nípa àwọn àǹfààní ipò àpọ́n nínú ayé aláìpé yìí. Òun fúnra rẹ̀ jẹ́ àpọ́n nígbà tó kọ̀wé pé “Àwọn wọnnì tí wọ́n [ṣègbéyàwó] yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn,” àti pé, “[opó kan] láyọ̀ jù bí ó bá dúró bí ó ti wà, gẹ́gẹ́ bí èrò mi.” Òtítọ́ náà pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ di apá kan Ọ̀rọ̀ Onímìísí ti Ọlọ́run fi hàn pé kò sí ohun tí kò tọ́ nípa èrò rẹ̀. Síbẹ̀, ó tún ṣàlàyé pé: “Bí ìwọ bá tilẹ̀ gbéyàwó, ìwọ kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.”—Kọ́ríńtì Kíní 7:28, 40.
Ní kedere, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àpọ́sítélì ló gbéyàwó, bí Pọ́ọ̀lù ti sọ nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Àwa ní ọlá àṣẹ láti máa mú arábìnrin kan káàkiri gẹ́gẹ́ bí aya, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn àpọ́sítélì yòó kù àti àwọn arákùnrin Olúwa àti Kéfà, àbí a kò ní?” (Kọ́ríńtì Kíní 9:5) Àwọn Kristẹni mọ̀ pé nínú ọ̀ràn yí, wọ́n lè ṣe yíyàn tí ó yàtọ̀ sí ti Pọ́ọ̀lù, kí ó sì bọ̀wọ̀ fún wọn síbẹ̀.
Lọ́pọ̀ ìgbà ni a ti yọ̀ǹda fún àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run láti fi ìgbàgbọ́ wọn hàn ní ìbámu pẹ̀lú ànímọ́ yíyàtọ̀ tiwọn. Ní tòótọ́, Ọlọ́run tilẹ̀ yọ̀ǹda fún àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì láti lo ọ̀nà ìṣọwọ́kọ̀wé ara ẹni nígbà tí wọ́n ń kọ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, Nehemáyà ní ìrẹ̀lẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè asọ̀rọ̀ ló fi kọ àkọsílẹ̀ rẹ̀. (Nehemáyà 5:6, 19) Ní ìhà kejì, nítorí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, àpọ́sítélì Jòhánù kò fìgbà kankan lo orúkọ ara rẹ̀ nínú Ìhìn Rere tó kọ, kò sì fi bẹ́ẹ̀ tọ́ka sí ara rẹ̀. Ọlọ́run fọwọ́ sí ọ̀nà ìṣọwọ́kọ̀wé méjèèjì, ó sì jẹ́ kí a pa wọ́n mọ́ sínú Bíbélì.
A rí àwọn àpẹẹrẹ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìfòyebánilò tó jọra jálẹ̀jálẹ̀ àwọn Ìwé Mímọ́. Ó ṣe kedere pé ìṣọ̀kan Kristẹni fàyè gba ìjónírúurú. Dájúdájú, ìyàtọ̀ nínú ipò àtẹ̀yìnwá àti èrò lè yọrí sí ìyapa nígbà tí kò bá sí àwọn ànímọ́ ti jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí. (Róòmù 16:17, 18) Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ‘fi ìfẹ́, tó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé, wọ ara wa láṣọ,’ a ń kọ́ láti tẹ́wọ́ gba àwọn ànímọ́ ìwà yíyàtọ̀ tí àwọn ẹlòmíràn ní, a sì ń jẹ̀gbádùn rẹ̀.—Kólósè 3:14.
Bíbélì wí pé: “Nítorí náà ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá, pẹ̀lú ògo fún Ọlọ́run ní iwájú.” (Róòmù 15:7) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, àwọn Kristẹni lè ṣàṣeyọrí ìwàdéédéé ẹlẹgẹ́ ti níní ìṣọ̀kan nìṣó, bí wọ́n ti ń gbádùn onírúurú ànímọ́ ẹ̀dá yíyàtọ̀ nínú ìjọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
Ẹlẹ́dàá kì í wo àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn bí àgbájọ kan tí ẹnì kọ̀ọ̀kan kò ti ní ànímọ́ ara ẹni
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ànímọ́ yíyàtọ̀ tó jẹ́ pé àwa fúnra wa àti Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló yé