ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/8 ojú ìwé 16-17
  • Àwọn Òkè Ńlá ti Òṣùpá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Òkè Ńlá ti Òṣùpá
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìran Àgbàyanu
  • ‘Ìwọ Ní Ọlá Ńlá Ju Àwọn Òkè Ńlá Lọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àwọn Àǹfààní Tá À Ń Rí Lára Òkè
    Jí!—2005
  • Mìmì Ti Ń Mi Àwọn Òkè Báyìí O
    Jí!—2005
  • Kilima—Njaro Ibi Gíga Jù Lọ ní Áfíríkà
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/8 ojú ìwé 16-17

Àwọn Òkè Ńlá ti Òṣùpá

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ

Ó JẸ́ ọ̀rọ̀ àgbọ́sọ tó jà rànyìn fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún pé: Ní ibì kan ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà, àwọn òkè ńlá kan wà tí òjò dídì bò—orísun tòótọ́ ti odò Náílì. Àmọ́ èròǹgbà náà pé òjò dídì wà nítòsí ìlà agbedeméjì ayé ní Áfíríkà dà bí èyí tí kò lè ṣeé ṣe. Síbẹ̀, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì náà, Ptolemy, tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀, ti fi hàn pé àwọn òkè ńlá wọ̀nyí wà, ó sì pè wọ́n ní Lunae Montes—Àwọn Òkè Ńlá ti Òṣùpá.a

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ìsapá láti wá àwọn òkè ńlá wọ̀nyí rí kò kẹ́sẹ járí. Àmọ́ ṣá, lọ́jọ́ kan ní apá ìparí àwọn ọdún 1800, olùṣàwárí náà, Henry Stanley—tí òkìkí rẹ̀ kàn pé ó wá Dókítà David Livingstone kàn—ṣẹlẹ́rìí ìṣẹ̀lẹ̀ èèṣì kan. Kùrukùru ṣíṣú tí ó bo òkè náà, tí kò jẹ́ kí àwọn olùṣàwárí tí ó ṣáájú rẹ̀ rí i, ká nílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ó sì jẹ́ kí Stanley kó òfìrí ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá tí òjò dídì bò tìyanutìyanu. Ó ṣàwárí àwọn Òkè Ńlá ti Òṣùpá. Ṣùgbọ́n ó pè wọ́n ní orúkọ tí àwọn olùgbé àdúgbò ń pè wọ́n nígbà náà: Ruwenzori, tí ó túmọ̀ sí “Aṣòjò.”

Lónìí, a ti fohùn ṣọ̀kan níbi gbogbo pé, àwọn òkè ńlá Ruwenzori kò kó ipa pàtàkì kan nínú pípèsè omi fún odò Náílì. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì ń pè wọ́n ní Òkè Ńlá ti Òṣùpá. Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé a ti gbìyànjú láti ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ fún ìwádìí lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá amúnikúnfún-ìbẹ̀rù yí ṣì ní ipò àyíká àràmàǹdà. Àwọn òkè ńlá Ruwenzori tí ó wà gẹ́rẹ́ ní ìhà àríwá ìlà agbedeméjì ayé jẹ́ ààlà ilẹ̀ àdánidá láàárín orílẹ̀-èdè Uganda àti Democratic Republic of Congo, wọ́n gùn tó 130 kìlómítà, wọ́n sì fẹ̀ tó 50 kìlómítà.

Láìdà bí ọ̀pọ̀ jù lọ lára òkè ńlá ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, tí wọ́n jẹ́ àbáyọrí òkè ńlá ayọnáyèéfín, ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá Ruwenzori jẹ́ àgbájọ ńlá eruku tí ipá inú ilẹ̀ kíkàmàmà kan fagbára tì jáde ní ọdún gbọ́nhan sẹ́yìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òkè ńlá Ruwenzori ga ní 5,109 mítà, àwọn òǹwòran kì í sábà lè rí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìrì àti kùrukùru máa ń bo ọ̀wọ́ òkè ńlá náà.

Bí orúkọ náà ṣe fi hàn, òjò àti òjò dídì tí ó pọ̀ ya mùrá ń wà ní òkè ńlá Ruwenzori, ìwọ̀nba díẹ̀ fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ sì ni ìgbà “ọ̀gbẹlẹ̀” fi máa ń gbẹ ju ìgbà “òjò” lọ. Rírìn lè tipa bẹ́ẹ̀ léwu; ní àwọn àgbègbè kan, ẹrẹ̀ ń muni dé ìbàdí! Àwọn òjò rẹpẹtẹ ti gbẹ́ àwọn adágún kéékèèké tí ó kọyọyọ bíi mélòó kan, tí ń pèsè ọ̀rinrin fún àwọn igbó tí ó dí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ tí ó bo gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn òkè ńlá náà. Ní tòótọ́, àwọn òkè ńlá Ruwenzori jẹ́ ibùgbé àwọn irúgbìn ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ bíi mélòó kan, tí díẹ̀ lára wọn máa ń tóbi di ńlá ràgàjì.

Fún àpẹẹrẹ, irúgbìn bí ọwọ́ ńlá, onírun tí ń jẹ́ lobelia kì í sábà ga tó 30 sẹ̀ǹtímítà níbòmíràn, àmọ́ ní àwọn òkè ńlá Ruwenzori, wọ́n lè ga tó mítà 6. Àwọn irúgbìn senecio, tàbí irúgbìn groundsel ńlá, rí bí irúgbìn cabbage ńláńlá tí ó hù sára ẹ̀ka igi. Àwọn igi heath tí wọ́n ga tó mítà 12 tí ewédò bò wà níbẹ̀. Òdòdó tí ó ní oríṣiríṣi àwọ̀ àti òórùn ìtasánsán fi ẹwà kún ìrísí àyíká náà. Oríṣiríṣi àwọn ẹyẹ tí wọ́n lẹ́wà, tí ó jẹ́ pé ní orí àwọn òkè ńlá Ruwenzori nìkan ni a ti lè rí irú wọn, wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn erin, ọṣà, ẹtu, àmọ̀tẹ́kùn, àti àwọn ọ̀bọ colobus ní ń gbé ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ẹsẹ̀ òkè náà.

Ìran Àgbàyanu

Àwọn tí wọ́n pọ́nkè gba ipa ẹsẹ̀ tó lọ sórí òkè náà gba àárín igbó kìjikìji ilẹ̀ olóoru kan, wọ́n sì sọdá Odò Bujuku ní ìgbà bíi mélòó kan. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí ó ga ní 3,000 mítà, wọ́n lè bojú wẹ̀yìn, kí wọ́n sì rí Àfonífojì Ńlá náà—ìran kíkàmàmà gbáà ni!

Níbi jíjìnnà gan-an lọ́hùn-ún ni Irà Bigo ti ìsàlẹ̀ wà, àgbègbè tí koríko tussock àti igi heath wà. Ẹrẹ̀ tó wà níbí sábà máa ń muni dé orúnkún. Pípọ́nkè fíofío dé Irà Bigo ti òkè àti Adágún Bujuku, ní orí Àfonífojì Bujuku, tí ó ga ní nǹkan bí 4,000 mítà, jẹ́ kí a rí ìran àgbàyanu kan ti Òkè Ńlá Baker, Òkè Ńlá Luigi di Savoia, Òkè Ńlá Stanley, àti Òkè Ńlá Speke, àwọn òkè ńlá tí a mọ̀ jù lọ lára ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá náà.

Ìṣàn Òkìtì Yìnyín Elena wíwàtítílọ wà níbi tí ó túbọ̀ ga sí i. Níbí, ènìyàn gbọ́dọ̀ ní irin ìwaǹkanmú, irin ìpọ́nkè, lọ́wọ́ kí ó sì lo àáké ìgékùn àti àáké ìgéyìnyín bí ó bá fẹ́ pọ́n ìṣàn òkìtì yìnyín náà. Lẹ́yìn náà ni a óò gba àárín ìtẹ́jú gíga Stanley kọjá lójú ọ̀nà tó lọ sí ibi gíga Margherita lórí Òkè Ńlá Stanley, òkè ńlá tí ó ga jù lára ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá Ruwenzori. Wíwo ìsàlẹ̀ láti ibi gíga yẹn, láti ibi tí a ti lè rí àwọn ibi gíga, àfonífojì, igbó, odò, àti àwọn adágún láti ìhà gbogbo jẹ́ ohun amúnikúnfún-ìbẹ̀rù ní tòótọ́.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé kò tí ì sí ẹni tí ó tí ì pọ́n àwọn òkè ńlá wọ̀nyí dókè pátápátá rí. Àwọn òkè ńlá Ruwenzori ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn àṣírí wọn hàn ni. Ohun púpọ̀ ni a kò tí ì mọ̀ nípa ìtàn àwọn ohun inú ọ̀wọ́ àwọn òkè náà, àwọn ẹranko ibẹ̀, àti irúgbìn ibẹ̀. Èyí ló mú kí àwọn òkè ńlá Ruwenzori ṣì jẹ́ àdììtú—àwọn àṣírí tí ó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn, ọlọgbọ́n àti alágbára gbogbo nìkan, ló mọ̀ ọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni, òun ni Ẹni tí ‘gíga àwọn òkè ńlá jẹ́ tirẹ̀’ ní tòótọ́.—Orin Dáfídì 95:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a  Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The Nile, tí Emil Ludwig kọ, ti sọ, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ibẹ̀ láyé ọjọ́un kò lè ṣàlàyé kankan nípa òjò dídì tó wà lórí òkè ńlá náà. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ gbà gbọ́ pé, “ńṣe ni àwọn òkè ńlá náà fa ìtànṣán òṣùpá mọ́ra.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

1. Kùrukùru ṣíṣúdùdù sábà máa ń bo àwọn òkè ńlá Ruwenzori

2. Àwọn òjò rẹpẹtẹ ti “Aṣòjò” máa ń rin àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ rẹ̀ tí ewéko ṣíṣùjọ bò

3. A ń rí àwọn òdòdó, a sì ń gbọ́ òórùn ìtasánsán púpọ̀ lójú ọ̀nà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́