Àwọn Akọrinkéwì Wọn Kì í Ṣe Akọrin Ìfẹ́ Lásán
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ
ÀWỌN akọrinkéwì àti àwọn aforindáni-lárayá tí ń káàkiri—kí ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn gbé wá sí ọkàn rẹ? Bóyá àwọn orin ìfẹ́ ìmẹ̀tọ́mẹ̀yẹ àti ti ìwà ọmọlúwàbí ni. O kò ṣàṣìṣe, àmọ́ ọ̀ràn ti àwọn akọrinkéwì ju ìyẹn lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orin canso d’amor, tàbí orin ìfẹ́ ni a mọ̀ mọ̀ wọ́n jù lọ—tí a sì sábà máa ń fi wọ́n hàn pẹ̀lú fèrè lute lọ́wọ́, tí wọ́n ń kọrin fún omidan kan—kì í ṣe ìfẹ́ nìkan ló jẹ wọ́n lógún. Àwọn akọrinkéwì máa ń kópa nínú ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìṣèlú, àti ti ìsìn ní àsìkò wọn.
Àwọn akọrinkéwì rọ́wọ́ mú ní ọ̀rúndún kejìlá àti ìkẹtàlá, ní gbogbo àgbègbè tí a ń pè ní ìhà gúúsù ilẹ̀ Faransé nísinsìnyí. Wọ́n jẹ́ akọrin tí ń kéwì, àwọn ni wọ́n ń kọ èdè Romance tí ó gbámúṣé jù lọ lára gbogbo àdúgbò tí ń sọ èdè náà. Wọ́n ń pè é ní langue d’oca—èdè àdúgbò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ni wọ́n ń sọ ní gbogbo ilẹ̀ Faransé ní ìhà gúúsù Odò Loire àti ní àwọn àgbègbè tí ó wà ní ààlà ilẹ̀ Ítálì àti Sípéènì.
Iyàn púpọ̀ ti wà lórí orírun ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “troubadour” [akọrinkéwì], àmọ́ ó jọ pé a mú un jáde láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Occitan náà, trobar, tí ó túmọ̀ sí “láti ṣàkójọ, hùmọ̀, tàbí ṣàwárí.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn akọrinkéwì lè wá ọ̀rọ̀ tàbí ewì tí ó bára jọ, tí ó yẹ wẹ́kú, tí ó lè bá ìlà orin wọn mu. Yóò lo ohùn orin sí ewì náà, yóò sì sọ ọ́ dorin. Bí àwọn akọrinkéwì náà ti ń rìnrìn àjò láti ìlú kan dé òmíràn, tí àwọn akọrindáni-lárayá amọṣẹ́dunjú, tí a ń pè ní aṣerédáni-lárayá, sábà máa ń bá kiri, wọ́n máa ń lo háàpù, gòjé, fèrè flute, fèrè lute, tàbí gìtá láti kọ orin wọn. Nínú gbọ̀ngàn àwọn ọlọ́rọ̀ àti ní àárín ọjà tàbí ní àwọn ibi ìdíje, ibi àfihàn ọjà, ibi àjọ̀dún, tàbí àpèjẹ, agbo orin sábà máa ń jẹ́ apá kan eré ìnàjú èyíkéyìí tí a ṣètò.
Ipò Àtilẹ̀wá Yíyàtọ̀síra
Àwọn akọrinkéwì ní ipò àtilẹ̀wá oríṣiríṣi. Wọ́n bí àwọn kan nínú ìdílé tó yọrí ọlá; àwọn díẹ̀ wá láti ìdílé ọba; wọ́n sì bí àwọn mìíràn nínú ìdílé tí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́lá, wọ́n sì yọrí dé ìṣọ̀wọ́ akọrinkéwì. Àwọn kan dé ipò ńlá. Àwọn kan kàwé gan-an, wọ́n sì rìnrìn àjò gan-an. Gbogbo wọn gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó pọ̀ nínú àwọn ìlànà ìkíyèsí obìnrin, ìwà ìmẹ̀yẹ tí ó bójú mu, ewì, àti orin. Orísun ìsọfúnni kan sọ pé, a retí pé kí akọrinkéwì dáradára kan “mọ gbogbo àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ dunjú, kí ó lè tún gbogbo àwọn àbá ìjiyànlé tí ó gbàfiyèsí, láti àwọn yunifásítì sọ, kí ó mọ àwọn àṣírí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ láàfin dáradára, . . . kí ó baà lè ṣàkójọ àwọn ìlà orin fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú lọ́kùnrin àti lóbìnrin lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó bá rí wọn, kí ó sì lè fi bíi méjì lára àwọn ohun èlò ìkọrin tí ó gbayì láàfin nígbà náà kọrin.”
Òwò tó balẹ̀ ní ọ̀rúndún kejìlá mú ọrọ̀ ńlá wá sí àwọn àgbègbè ìhà gúúsù ilẹ̀ Faransé. Níní tí àwọn ènìyàn ní láárí mú fàájì, ẹ̀kọ́ ìwé, àti ìfẹ́ fún iṣẹ́ ọnà òun ìgbé ayé ọlọ́lá lọ́nà ti ọ̀làjú dé. Àwọn ọ̀tọ̀kùlú jàǹkànjàǹkàn lọ́kùnirin àti lóbìnrin ní ilẹ̀ Languedoc àti Provence ni àwọn akọrinkéwì náà máa ń ṣeré fún jù lọ. Wọ́n fún àwọn akéwì náà ní ọ̀wọ̀ púpọ̀, wọ́n sì ní ipa púpọ̀ lórí ìfẹ́ fún ipò ọlá, oge, àti ìwà. Wọ́n wá di olùdásílẹ̀ ijó tí àwọn ará Yúróòpù ń jó nílé ijó. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé, “àṣeyọrí ńlá tí wọ́n ṣe ni jíjẹ́ kí àwọn omidan nímọ̀lára wíwà ní àyíká àbójútó àti ìtòròmini, tí kò sí ohun tí ó tí ì tó bẹ́ẹ̀ títí di àkókò yí.”
Ọ̀wọ̀ Tuntun fún Àwọn Obìnrin
Bí ọkùnrin bá ṣí ilẹ̀kùn fún obìnrin kan, tí ó bá a wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, tàbí tí ó ṣe èyíkéyìí lára àwọn ìwà ìmẹ̀yẹ “fífi obìnrin ṣáájú” tí àwọn ènìyàn ti ń ṣe fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù, àṣà kan tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àwọn akọrinkéwì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ló ń dá.
Àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, tí ó wò ó pé àwọn obìnrin ni wọ́n fa ìṣubú ọkùnrin sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti lílé tí a lé e kúrò nínú Párádísè, ní ipa púpọ̀ lórí ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn ní sànmánì agbedeméjì sí àwọn obìnrin. Wọ́n wo obìnrin bí atannijẹ, irin iṣẹ́ Èṣù, olubi tí ó jẹ́ kòṣeémánìí. Wọ́n sábà máa ń ka ìgbéyàwó sí ipò ìrẹ̀sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé. Òfin ṣọ́ọ̀ṣì fàyè gba lílu ìyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀, tí èyí sì ń dá kún títẹ́ àwọn obìnrin àti títẹ̀ wọ́n lórí ba. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo ọ̀nà ni wọ́n ti ka àwọn obìnrin sí ẹni tí ó rẹlẹ̀ sí ọkùnrin. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn akọrinkéwì dé, ọkàn àwọn ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà.
Akọrinkéwì tí a kọ́kọ́ mọ̀ ni William Kẹsàn-án, Ọba Aquitaine. Ewì rẹ̀ ni ó kọ́kọ́ ní àwọn apá tí ó ṣe ìyàsọ́tọ̀ èrò aláìlẹ́gbẹ́ tí àwọn akọrinkéwì ní nípa ìfẹ́, tí ó wá di èyí tí a ń pè ní ìfẹ́ ìmẹ̀tọ́mẹ̀yẹ. Àwọn akéwì ilẹ̀ Provençal fúnra wọn pè é ní verai’amors (ìfẹ́ tòótọ́) tàbí fin’amors (ìfẹ́ dáradára). Ó mú ìyípadà pàtàkì wá, ní ti pé a kò tún fi àwọn obìnrin sí ipò rírẹlẹ̀ pátápátá sí àwọn ọkùnrin mọ́.
Ewì akọrinkéwì fi iyì, ọlá, àti ọ̀wọ̀ ńlá fún àwọn obìnrin. Obìnrin wá di ìṣàpẹẹrẹ ànímọ́ wíwúnilórí àti ìwà funfun. Àwọn orin kan dárò nípa bí omidan náà kò ṣe nífẹ̀ẹ́ sí akọrinkéwì tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó kéré tán, bí a ti fẹnu sọ ọ́, ó yẹ kí ìfẹ́ akọrinkéwì náà máà lábàwọ́n. Lájorí góńgó rẹ̀ kì í ṣe pé kí omidan náà di tirẹ̀ àmọ́, àtúnṣe ní ti ìwà rere tí ìfẹ́ rẹ̀ fún omidan náà ru sókè nínú rẹ̀. Láti mú kí akéwì tí ń fojú sọ́nà náà tóótun, ó di ọ̀ranyàn fún un láti ní ìrẹ̀lẹ̀, ìkóra-ẹni-níjàánu, sùúrù, ìṣòtítọ́, àti gbogbo àwọn ànímọ́ wíwúnilórí tí omidan náà ní. Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ lè yí ọkùnrin tí kò tilẹ̀ ní ìwà dáradára páàpáà pa dà.
Àwọn akọrinkéwì gbà gbọ́ pé ìfẹ́ ìmẹ̀tọ́mẹ̀yẹ ni orísun àtúnṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìwà rere, pé ìfẹ́ ni ìpìlẹ̀ àwọn ìwà ìbọ̀wọ̀fúnni àti ìwà wíwúnilórí. Bí a ti ń mú èrò yí gbilẹ̀ sí i, ó wá di ìpìlẹ̀ fún odindi ìlànà ìwà híhù kan, tí a wá gbà wọnú àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn ènìyàn gbáàtúù, bí àkókò ti ń lọ. Ní ìyàtọ̀ sí ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tí ó burú lé kenkà, tí ó sì yòkú òǹrorò, ọ̀nà ìgbésí ayé tuntun kan bẹ̀rẹ̀. Àwọn obìnrin wá ń retí kí àwọn ọkùnrin wọn jẹ́ afara-ẹni-rúbọ, olùgbatẹnirò, àti onínúrere—kí wọ́n jẹ́ ọmọlúwàbí.
Láìpẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ará Yúróòpù ti ń ṣàmúlò ìwà àwọn akọrinkéwì náà. Ilẹ̀ Sípéènì àti Potogí fayọ̀ tẹ́wọ́ gbà àwọn ànímọ́ wọn. Ìhà àríwá ilẹ̀ Faransé ṣàmúlò ìlànà ẹ̀kọ́ àwọn akéwì rẹ̀; Germany ṣàmúlò ìlànà ẹ̀kọ́ àwọn akọrinkéwì rẹ̀; Ítálì ṣàmúlò trovatori rẹ̀. Ànímọ́ ti ìfẹ́ ìmẹ̀tọ́mẹ̀yẹ àwọn akọrinkéwì náà, tí a dà pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé ti ìwà ọmọlúwàbí ṣẹ̀dá oríṣi lítíréṣọ̀ kan tí a mọ̀ sí ìtàn eré ìfẹ́.b Fún àpẹẹrẹ, nípa dída àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé ti ìfẹ́ ìmẹ̀tọ́mẹ̀yẹ pọ̀ mọ́ ìtàn àtẹnudẹ́nu àwọn ará Celt ti Brittany, akọrinkéwì Chrétien de Troyes ṣàgbéjáde àpẹẹrẹ ìwà funfun ọlọ́làwọ́ àti ìdáàbòbo àwọn aláìlera nínú àwọn ìtàn Ọba Arthur àti àwọn Ìránṣẹ́ Ọba tí wọ́n Bá Ọba Jókòó.
Ipa Tí Wọ́n Ní Lórí Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà
Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára orin àwọn akọrinkéwì ti fògo fún ìwà funfun tó wà nínú ìfẹ́ ìmẹ̀tọ́mẹ̀yẹ, àwọn orin wọn mìíràn dá lórí àwọn ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ti ìṣèlú ní àkókò náà. Martin Aurell, ọmọ ilẹ̀ Faransé tí ó kọ ìwé La vielle et l’épée (Gòjé àti Idà), ṣàlàyé pé àwọn akọrinkéwì ‘kópa gidigidi nínú àwọn ìjìjàdù tí ń ya àwọn alájọgbáyé wọn sọ́tọ̀ àti pé nípasẹ̀ àwọn orin tí wọ́n kọ, wọ́n tilẹ̀ lọ́wọ́ nínú àṣeyọrí tí ẹgbẹ́ kan tàbí òmíràn ṣe.’
Nígbà tí Robert Sabatier ń sọ̀rọ̀ nípa ipò aláìlẹ́gbẹ́ tí àwọn akọrinkéwì mú nínú ẹgbẹ́ àwùjọ sànmánì agbedeméjì, ó wí pé: “A kò tí ì fún ewì ní irú iyì tí ó tó bẹ́ẹ̀ rí; kò sí ẹni tí ó tí ì ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tó bẹ́ẹ̀ rí. Wọ́n ń yinni, wọ́n sì ń báni wí; wọ́n sọ ara wọn di agbẹnusọ fún àwọn ènìyàn; wọ́n ní ipa lórí ìlànà ìṣèlú; wọ́n sì tún di agbẹnusọ fún àwọn èrò tuntun.”—La Poésie du Moyen Age.
Agbéròyìnjáde ní Àkókò Wọn
A lè sọ dáadáa pé tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí a tó hùmọ̀ àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ni àwọn akọrinkéwì àti àwọn aforindáni-lárayá tí ń káàkiri ti ń ṣiṣẹ́ ìgbéròyìnjáde ní àkókò wọn. Arìnrìn-àjò jákèjádò ayé ni àwọn akọrindáni-lárayá sànmánì agbedeméjì. Jákèjádò àwọn ààfin ilẹ̀ Yúróòpù—láti Kípírọ́sì dé Scotland àti láti ilẹ̀ Potogí dé Ìlà Oòrùn Yúróòpù, ibi yóò wù kí wọ́n lọ—wọ́n ń kó ìròyìn jọ, wọ́n sì ń ṣe pàṣípààrọ̀ ìtàn, orin atunilára, àti àwọn orin. Bí àwọn orin àwọn akọrinkéwì tí ń tàn kálẹ̀ láti ẹnu aṣerédáni-lárayá kan sí òmíràn, àwọn ènìyàn ń kọ́ àwọn orin agbàfiyèsí wọn náà, àwọn orin náà sì ń ní ipa púpọ̀ lórí èrò àwọn ará ìlú, ó sì ń ru àwọn ènìyàn gbáàtúù sípa gbígbógun kan tàbí òmíràn.
Ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ orin ewì tí àwọn akọrinkéwì lò ni a ń pè ní sirvente, tí ó túmọ̀ sí, “orin ọmọ ọ̀dọ̀,” láìlábùlà. Àwọn kan tú àṣírí ìṣègbè àwọn alákòóso. Àwọn mìíràn ṣe ìgbélárugẹ àwọn ìwà akọni, ìfara-ẹni-rúbọ, ọ̀làwọ́, àti àánú, nígbà tí wọ́n ṣàríwísí ìwà òǹrorò aláìníjàánu, ìwà ojo, àgàbàgebè, àti ìlépa àǹfààní ara ẹni. Àwọn sirvente ti ọ̀rúndún kẹtàlá fún àwọn òpìtàn ní àǹfààní rírí ìsọfúnni nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìṣèlú àti ìsìn ní ilẹ̀ Languedoc ní àkókò kan tí rúkèrúdò ṣẹlẹ̀.
Àríwísí Nípa Ṣọ́ọ̀ṣì
Pẹ̀lú bí àwọn Ogun Ìsìn kò ti ṣàṣeyọrí, ọ̀pọ̀ ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa agbára Ìjọ Kátólíìkì nípa ti ẹ̀mí àti ti ara. Àwùjọ àlùfáà sọ pé àwọn ń ṣojú fún Kristi, àmọ́ àwọn ìṣe wọn kò dà bíi ti Kristi rárá. Àgàbàgebè, ìwọra, àti ìwà ìbàjẹ́ wọn wá di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Bí àwọn bíṣọ́ọ̀bù àti àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti ń fìgbà gbogbo wá ọrọ̀ àti agbára ìṣèlú púpọ̀ sí i, wọ́n ń ṣe ohun tí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fẹ́. Pípa tí wọ́n pa àwọn àìní tẹ̀mí ti àwọn òtòṣì àti àwọn kò-là-kò-ṣagbe tì ru àìfohùnṣọ̀kan yíyàtọ̀ sókè lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.
Ní ilẹ̀ Languedoc, ọ̀pọ̀ lára àwọn kò-là-kò-ṣagbe àti àwọn ọ̀tọ̀kùlú ló kàwé. Òpìtàn H. R. Trevor-Roper ṣàkíyèsí pé, àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n kàwé díẹ̀ ń ṣàwárí pé ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀rúndún kejìlá “yàtọ̀ gan-an sí ti ìgbà ìjímìjí tí ó sọ pé òun ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.” Ó fi kún un pé, ọ̀pọ̀ ọkùnrin ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: “Ẹ wo bí . . . Ìjọ àwọn Àpọ́sítélì, Ìjọ tí ó wà ṣáájú Constantine, tí a kò sọ di ti orílẹ̀-èdè, . . . ti àwọn inúnibíni: Ìjọ tí kò ní póòpù tàbí àwọn bíṣọ́ọ̀bù aṣàkóso tàbí ìdáwó rẹpẹtẹ tàbí ẹ̀kọ́ àwọn kèfèrí tàbí àkọsílẹ̀ òfin tuntun tí a ṣe láti mú kí ọrọ̀ àti agbára rẹ̀ pọ̀ sí i, tilẹ̀ ṣe yàtọ̀ gan-an tó!”
Languedoc jẹ́ ilẹ̀ amúǹkanmọ́ra. Àwọn ọ̀tọ̀kùlú alákòóso ilẹ̀ Toulouse àti àwọn alákòóso mìíràn láti ìhà gúúsù fún àwọn ènìyàn ní òmìnira ìsìn. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldoc ti túmọ̀ Bíbélì sí langue d’oc, wọ́n sì ń fi ìtara wàásù rẹ̀, ní méjì-méjì jákèjádò ẹkùn ilẹ̀ náà. Àwọn Cathari (tí a tún ń pè ní Albigenses) pẹ̀lú ń tan ẹ̀kọ́ wọn kálẹ̀, wọ́n sì ń rí ọmọlẹ́yìn púpọ̀ lára àwọn ọ̀tọ̀kùlú.
Púpọ̀ lára àwọn orin ìsìn tí àwọn akọrinkéwì kọ fi ìjákulẹ̀ òun àìbọ̀wọ̀fúnni àti ìríra tí àwọn ènìyàn ní fún àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì hàn. Ọ̀kan tí Gui de Cavaillon kọ bẹnu àtẹ́ lu àwùjọ àlùfáà nítorí pé wọ́n “pa lájorí iṣẹ́ wọn tì,” láti mú àwọn nǹkan tí ó túbọ̀ jẹ́ ti ayé ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ orin àwọn akọrinkéwì fi ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì, àgbélébùú, ìjẹ́wọ́, àti “omi mímọ́” ṣẹ̀sín. Wọ́n fi ìsanpadà owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ òun ère ìsìn ṣẹlẹ́yà, wọ́n sì fi àwọn àlùfáà oníwà-pálapàla àti àwọn bíṣọ́ọ̀bù oníwà-ìbàjẹ́ ṣẹ̀sín pé “ọ̀dàlẹ̀, òpùrọ́, àti alágàbàgebè” ni wọ́n.
Bí Ṣọ́ọ̀ṣì Ṣe Gbógun Ti Òmìnira
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ìjọ ti Róòmù ka ara rẹ̀ sí èyí tí ó ga ju gbogbo ilẹ̀ ọba àti ìjọba lọ. Ogun wá di ohun ìjàjàgbara rẹ̀. Póòpù Innocent Kẹta ṣèlérí gbogbo ọrọ̀ ilẹ̀ Languedoc fún jagunjagun èyíkéyìí tí ó bá lè ṣẹ́gun àwọn ọmọ aládé, kí ó sì pa gbogbo àwọn tí wọn kò bá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìsìn ní àwọn àgbègbè ìhà gúúsù ilẹ̀ Faransé. Ọ̀kan lára àwọn àkókò ìdánilóró àti ìpànìyàn tí ó ní ìtàjẹ̀sílẹ̀ nínú jù lọ nínú ìtàn ilẹ̀ Faransé ló tẹ̀ lé e. A wá mọ̀ ọ́n sí Ogun Ìsìn Albigensian (1209 sí 1229).d
Àwọn akọrinkéwì pè é ní Arúmọjẹ Ogun Ìsìn. Àwọn orin wọn fi ìbínú hàn nípa ọ̀nà rírorò tí ṣọ́ọ̀ṣì gbà hùwà sí àwọn tí kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì àti bí póòpù ṣe ń nawọ́ ìsanpadà ọrọ̀ kan náà fún pípa àwọn ará Faransé tí wọn kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì bí ó ṣe nawọ́ rẹ̀ fún pípa àwọn Mùsùlùmí, tí ó kà sí alátakò ìsìn. Ṣọ́ọ̀ṣì náà kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà Ogun Ìsìn Albigensian àti Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Wọ́n fi ogún àwọn ìdílé dù wọ́n, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ilẹ̀ àti ilé wọn.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn akọrinkéwì náà pé wọ́n jẹ́ aládàámọ̀ ará Cathari ló mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn sá lọ sí àwọn ilẹ̀ tí ìwà jàgídíjàgan náà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Ogun Ìsìn yí sàmì sí òpin ọ̀làjú Occitan, ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀, ewì rẹ̀. Òfin Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ sọ ọ́ di ohun tí kò bófin mu láti kọrin, tàbí láti lá orin akọrinkéwì kan pàápàá. Àmọ́ ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ kò kú. Ní gidi, àwọn orin wọn tí ó lòdì sí àwùjọ àlùfáà múra èrò inú àwọn ènìyàn sílẹ̀ fún ohun tí yóò wá di ìsìn Àlátùn-únṣe. Lótìítọ́, ohun tí a lè rántí nípa àwọn akọrinkéwì ju àwọn orin ìfẹ́ wọn lọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èdè Látìn tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Róòmù, tí wọ́n ń pè ní Roman, ti di èdè àdúgbò méjì ní ilẹ̀ Faransé: Ìhà gúúsù ilẹ̀ Faransé ń sọ langue d’oc (tí a tún mọ̀ sí Occitan, tàbí Provençal), tí ìhà àríwá ilẹ̀ Faransé sì ń sọ langue d’oïl (irú èdè Faransé ìgbà ìjímìjí tí wọ́n ń pè ní èdè Faransé Àtijọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan). Àwọn èdè méjèèjì yàtọ̀ síra nípa ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún bẹ́ẹ̀ ni. Ní gúúsù, wọ́n ń lo oc (láti inú ọ̀rọ̀ Látìn náà, hoc); ní àríwá, wọ́n ń lo oïl (láti inú ọ̀rọ̀ Látìn náà, hoc ille), tí ó wá di oui tí èdè Faransé òde òní ń lò.
b Ìwékíwèé tí a bá fi èdè àdúgbò ìhà àríwá tàbí ti gúúsù kọ ni wọ́n ń pè ní roman. Nítorí pé púpọ̀ lára àwọn ìtàn ìwà ọmọlúwàbí yìí ní í ṣe pẹ̀lú èrò inú ìfẹ́ ìmẹ̀tọ́mẹ̀yẹ, wọ́n wá di ọ̀pá ìdíwọ̀n fún gbogbo ohun tí a bá kà sí ìtàn eré ìfẹ́ tàbí ọ̀rọ̀ eré ìfẹ́.
c Wo Ile-Iṣọ Naa, February 1, 1982, ojú ìwé 27 sí 30, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Printer’s Ornaments/láti ọwọ́ Carol Belanger Grafton/Dover Publications, Inc.
Bibliothèque Nationale, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwòrán kan láti inú ìwé kíká kan ní ọ̀rúndún kejìlá
[Credit Line]
Bibliothèque Nationale, Paris