Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 28. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Ta ni olórí elénìní Jèhófà? (Ìṣípayá 20:2)
2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tí a ń gbà pe orúkọ àtọ̀runwá náà tí a mọ̀ dáradára jù lọ lédè Yorùbá ni “Jèhófà,” èwo ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé ará Hébérù yàn láàyò?
3. Kí ni Íṣímáẹ́lì, ọmọkùnrin tí ó jẹ́ àkọ́bí Ábúráhámù dà, kí ó fi lè máa pèsè oúnjẹ fún ara rẹ̀ nínú aginjù? (Jẹ́nẹ́sísì 21:20)
4. Ìkùnà ọkùnrin wo láti fi ọ̀wọ̀ hàn fún bàbá rẹ̀ ni ó yọrí sí fífi ọmọ rẹ̀ gégùn-ún? (Jẹ́nẹ́sísì 9:22-25)
5. Bí Sólómọ́nì kò ti fẹ́ kí omidan Ṣúlámáítì lọ, àwọn ohun àfiṣọ̀ṣọ́ wo ni ó ṣèlérí láti fún un? (Orin Sólómọ́nì 1:11)
6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò jẹ́ kí Mósè wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà, láti ibo ni ó ti wò ó? (Diutarónómì 3:27)
7. Kí ni wọ́n fi bo inú àti òde áàkì Nóà? (Jẹ́nẹ́sísì 6:14, NW)
8. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe láti “fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa”? (Hébérù 12:1)
9. Ta lo ṣe àjíǹde àkọ́kọ́ tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀? (Àwọn Ọba Kìíní 17:21-23)
10. Ìdí wo ni Jésù sọ pé a kì í ṣeé da wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó àpò awọ? (Máàkù 2:22)
11. Àkọsílẹ̀ ìtàn wo ni a rí nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 6 sí 9? (Jẹ́nẹ́sísì 6:9)
12. Ní àfikún sí wúrà, fàdákà, àti eyín erin, oríṣi ẹran méjì wo ni Sólómọ́nì ń fi ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun rẹ̀ láti Táṣíṣì kó wọ ìlú nínú ìrìn àjò ojú òkun ẹlẹ́ẹ̀kan lọ́dún mẹ́ta-mẹ́ta? (Àwọn Ọba Kìíní 10:22)
13. Kí ló jẹ́ àbáyọrí wíwọ̀ tí Ọba Rèhóbóámù àti Hádórámù, tí ń bójú tó àwọn tí a ń fi ipá mú ṣiṣẹ́, wọ ìpínlẹ̀ àwọn ẹ̀yà ìhà àríwá tí ń kúrò lára wọn? (Kíróníkà Kejì 10:18)
14. Kí ni Ọlọ́run sọ pé ó jẹ́ “àpótí ẹsẹ̀” òun? (Ìṣe 7:49)
15. Ta ló di ọmọ òrukàn nígbà tí ìyá rẹ̀ kú nígbà ìbí rẹ̀, lẹ́yìn tí ó gbọ́ pé ọkọ òun ti kú? (Sámúẹ́lì Kíní 4:19-21)
16. Àwọn tí wọ́n ṣàìní ohun wo ní Ọlọ́run ń mú kí “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi” fún? (Aísáyà 40:29, NW)
17. Kí ni kò gbọ́dọ̀ ní ìwúkàrà tàbí “oyin” nínú tí a bá mú un tọ Ọlọ́run wá? (Léfítíkù 2:11, NW)
18. Kí ni Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé orílẹ̀-èdè kankan kì yóò kọ́ mọ́? (Míkà 4:3)
19. Kí ni Jésù sọ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́? (Jòhánù 17:17)
20. Ta ni bàbá Jónà? (Jónà 1:1)
21. Kí ni Ọba Ahasuwérúsì yọ̀ǹda fún àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ rẹ̀ nígbà àsè fífi Ẹ́sítérì ṣe ayaba? (Ẹ́sítérì 2:18, NW)
22. Kí ni a ń ṣe láti fi hàn pé ẹrú Hébérù kan fínnúfíndọ̀ yàn láti má di òmìnira, àmọ́ láti máa sin ọ̀gá rẹ̀ lọ? (Ẹ́kísódù 21:5, 6)
23. Ibo ni ará Samáríà aládùúgbò rere náà gbé ọkùnrin tí wọ́n ṣá lọ́gbẹ́ náà lọ kí ó lè tọ́jú rẹ̀? (Lúùkù 10:34)
Àwọn Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Sátánì Èṣù
2. Yahweh
3. Tafàtafà
4. Ti Hámù
5. “Ọ̀wọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wúrà” àti “àmì fàdákà”
6. Orí òkè Písígà
7. Ọ̀dà bítúmẹ́nì
8. “Mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn”
9. Èlíjà
10. Awọ náà yóò bẹ́, a óò sì pàdánù ọtí wáìnì àti awọ náà pẹ̀lú
11. Ìtàn Nóà
12. Ìnàkí àti ẹyẹ ológe
13. Wọ́n sọ Hádórámù ní òkúta pa, Rèhóbóámù sì sá lọ
14. Ilẹ̀ ayé
15. Íkábódì
16. Okun alágbára
17. Ọrẹ ẹbọ ọkà
18. Ogun
19. Òtítọ́
20. Ámítáì
21. Ìdáríjì ọba
22. Wọn óò fi òòlu lu etí rẹ̀
23. Ilé èrò