Ìròyìn Nípa Sáyẹ́ǹsì—Etí Wo Lo Fi Ń Gbọ́ Ọ?
ÀWỌN àrùn tuntun àti àwọn tàtijọ́ tó tún ń yọjú jẹ́ ìpèníjà fún sáyẹ́ǹsì. Nítorí pé àwọn ènìyàn ń fẹ́ ìwòsàn lọ́nàkọnà, wọ́n ń fiyè sí ìròyìn nípa sáyẹ́ǹsì. Ìbẹ̀rù ikú ń mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa yán hànhàn láti dán egbòogi ajẹ́bíidán tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe wò, lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í ronú nípa àwọn ìyọrísí onígbà pípẹ́.
Nínú ọ̀ràn púpọ̀, sáyẹ́ǹsì ti ran àwọn aláìsàn lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé tó sunwọ̀n. Èyí tó ta yọ ni àwọn ìlànà iṣẹ́ abẹ láìlo ìfàjẹ̀sínilára, tó léwu. Sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ti fún aráyé ní agbára láti ṣe àwọn nǹkan tó kọjá àfinúrò. Àwọn ohun tí ó jẹ́ àròsọ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nígbà kan rí ti di ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé ní báyìí. Síbẹ̀, gbogbo ohun tí sáyẹ́ǹsì ń ṣe kọ́ ló wà fún ire àwọn ẹlòmíràn, tí àwọn àìní ṣíṣe kókó ẹ̀dá ènìyàn ń sún ṣiṣẹ́.
Ta Ní Ń Sọ̀rọ̀?
Ọ̀pọ̀ sáyẹ́ǹsì ni àǹfààní ti ara ń sún ṣiṣẹ́, tí àwùjọ àwọn agbẹnusọ kan sì ń tì lẹ́yìn bí a ti sọ ṣáájú. Nítorí náà, kí o tó dé orí ìpinnu tàbí kí àwọn àwárí tuntun nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mú inú rẹ dùn jù, bi ara rẹ pé, ‘Ta ní ń sọ̀rọ̀ gan-an?’ Kọ́ láti mọ àṣírí tó fara sin náà. Ti pé àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń gbèrú nípasẹ̀ ìmọ̀ọ́mọ̀-rùmọ̀lára-sókè kì í ṣe àṣírí mọ́. Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde kan yóò ṣe ohunkóhun tó bá ṣeé ṣe láti ta àwọn ìwé agbéròyìnjáde wọn. Kódà, àwọn ìwé àtìgbàdégbà díẹ̀ ń fàyè gba ìmọ̀ọ́mọ̀-rùmọ̀lára-sókè dé àyè kan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé sáyẹ́ǹsì àti ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń ní ìbátan àdàlù ìfẹ́ òun ìríra. Ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde lè mú kí sáyẹ́ǹsì lóókọ rere, ṣùgbọ́n lọ́nà mìíràn, “àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sábà máa ń gbìyànjú láti darí ohun tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde lè gbé jáde nípa kíkọ̀ láti bá wọn fọ̀rọ̀ wérọ̀, àyàfi bí wọ́n bá lè ṣàyẹ̀wò, kí wọ́n sì ṣàtúnṣe àpilẹ̀kọ ìròyìn náà ṣáájú kí wọ́n tó tẹ̀ ẹ́ jáde. Nítorí ìbẹ̀rù àyẹ̀wò alátùn-únṣe láti ọwọ́ àwọn tí wọ́n ní ọkàn ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ọ̀ràn náà, àwọn oníròyìn kì í fẹ́ fi àpilẹ̀kọ wọn han àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọ́n máa ń fìdí ìpéye àlàyé wọn múlẹ̀ lọ́dọ̀ wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni Dorothy Nelkin ṣe kọ ọ́ nínú ìwé rẹ̀, Selling Science.
Ó wá tọ́ka sí àwọn àpẹẹrẹ láti fẹ̀rí ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn pé: “Àwọn ìròyìn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde nípa àwọn àṣeyọrí tuntun ti sáyẹ́ǹsì máa ń ru ìrètí àwọn ènìyàn tí ń wá nǹkan lọ́nàkọnà sókè. . . . Àwọn aláìsàn ń mú àwọn ẹ̀dà [ìwé ìròyìn tó gbajúmọ̀] tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà wọn, wọ́n sì ń béèrè fún ìtọ́jú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé.” Àpẹẹrẹ kan wà, tí Dorothy Nelkin fà yọ, nípa oníròyìn kan tó béèrè lọ́wọ́ alága Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ìlera àti Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé “bóyá ó rò pé àwọn adáhunṣe lè ṣèwòsàn lọ́nà gbígbéṣẹ́ ní Áfíríkà.” Ó dáhùn pé “ó ṣeé ṣe kí” wọ́n “lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ rere tí wọ́n ní láàárín àwọn ènìyàn.” Àmọ́ kí ni àkọlé ìròyìn lọ́jọ́ kejì? Ó kà pé: “Ògbógi Kan Nínú Àjọ U.N. Ń Fẹ́ Adáhunṣe Púpọ̀ Sí I”!
Nelkin wí pé, ó bani nínú jẹ́ pé, ó jọ pé àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ń ní ìtẹ̀sí lóde òní láti gbára lé àwọn ìwé agbéròyìnjáde àti àwọn ìwé ìròyìn láti sọ fún wọn nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ní lọ́wọ́lọ́wọ́. Ní ti àwọn mìíràn, tí wọn kò lọ́kàn ìfẹ́ sí i tàbí tí wọn kò lè kàwé tó bẹ́ẹ̀, tẹlifíṣọ̀n ti di orísun ìsọfúnni wọn ní pàtàkì.
Pípa Èrò Wíwàdéédéé Mọ́ Nípa Sáyẹ́ǹsì
Láìka àwọn àṣeyọrí tó ṣe aráyé láǹfààní tí sáyẹ́ǹsì ti ṣe sí, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ẹ̀dá ènìyàn lásán ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Wọn kò ju ẹni tí a ń dẹ wò tí ó sì ń hùwà ìbàjẹ́ lọ. Gbogbo ìgbà kọ́ ni ète wọn ń wúni lórí. Lóòótọ́, sáyẹ́ǹsì ní àyè tó tọ́ sí i láwùjọ, ṣùgbọ́n kì í ṣe iná atọ́nà tó dájú pátápátá nínú ayé kan tó túbọ̀ ń wọ òkùnkùn.
Ìwé ìròyìn náà, Speculations in Science and Technology, sọ pé: “Ìtàn sáyẹ́ǹsì fi hàn pé bó ti wù kí àwọn aṣíwájú sáyẹ́ǹsì lọ́lá tó . . . lójú, wọ́n lè ṣàṣìṣe.” Ní gidi, ti àwọn kan burú ju ṣíṣàṣìṣe lásán lọ.
Nítorí àwọn ìdí tí a mẹ́nu kàn nínú àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí, kò ní bọ́gbọ́n mu fún àwọn Kristẹni láti kó ara wọn wọnú àríyànjiyàn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tàbí láti ṣagbátẹrù àwọn àbá èrò orí sáyẹ́ǹsì tí a kò fẹ̀rí wọn múlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìbẹ̀rù ìbátan àárín iná mànàmáná àti mágínẹ́ẹ̀tì lè wọ àwọn kan lẹ́wù. Pẹ̀lú èrò rere, wọ́n lè wá bẹ̀rẹ̀ sí rọ àwọn ẹlòmíràn láti kó àwọn ohun ìdáná tí ìgbì mànàmáná rẹ̀ kéré gan-an, àwọn kúbùsù abánáṣiṣẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ń lò dà nù. Ó dájú pé olúkúlùkù ló lómìnira láti ṣe yíyàn, láìsí àríwísí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí àwọn tó ṣe yíyàn tó yàtọ̀ retí láti rí irú òmìnira yíyàn kan náà. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti yẹra fún títan ìmọ̀ọ́mọ̀-rùmọ̀lára-sókè kálẹ̀. A kò ì fẹ̀rí hàn síbẹ̀ pé àwọn ìkéde kan tí kò wọ́pọ̀ jẹ́ òtítọ́ tàbí pé wọn kì í ṣe òtítọ́. Bí àwọn kan lára àwọn ìkéde náà bá wá já sí aláìlẹ́sẹ̀-nílẹ̀ tàbí irọ́, nígbà náà, àwọn tí ń ṣagbátẹrù irú ìkéde bẹ́ẹ̀ kò ní wulẹ̀ dà bí òmùgọ̀ lásán, ṣùgbọ́n wọ́n yóò ti ṣèpalára fún àwọn ẹlòmíràn láìmọ̀ọ́mọ̀.
Ìdí fún Ìmòyemèrò
Báwo ni ó ṣe yẹ kí Kristẹni kan hùwà padà sí àwọn ìròyìn nípa sáyẹ́ǹsì tí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde mọ̀ọ́mọ̀ fi ń rùmọ̀lára sókè? Lákọ̀ọ́kọ́, ṣàyẹ̀wò ète náà. Ète wo la fi gbé àpilẹ̀kọ tàbí kókó ìròyìn náà jáde? Lọ́nà kejì, ka gbogbo àpilẹ̀kọ náà. Àkọlé ìròyìn arùmọ̀lára-sókè náà lè ṣàìbá ohun tí àpilẹ̀kọ náà ń sọ gan-an mu. Ẹ̀kẹ́ta, tó sì ṣe pàtàkì jù, ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ àṣeyọrí tí àwọn tó kọ ọ́ ní. Ṣé wọ́n máa ń sọ òtítọ́? Ǹjẹ́ wọ́n ní àṣírí kan tó fara sin?—Róòmù 3:4.
A lè sọ pé bí àwọn ènìyàn kan bá ní iyè méjì nípa àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, àwọn fúnra wọn ló ni ẹ̀bi náà. Ìfùsì àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gẹ́gẹ́ bí olùwá-òdodo láìfìsíbìkan ti lábàwọ́n gan-an. Sáyẹ́ǹsì ti ṣí ọ̀nà tí ń rùmọ̀lára sókè sílẹ̀ ní ti ìmọ̀ nípa ayé wa àti àgbáálá ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ayé tuntun kan tó sàn jù, tí a gbé karí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ń fa ìbẹ̀rù àti àníyàn dípò ìrètí.
Àwọn ògbógi kan ń ṣèkìlọ̀ bíbanilẹ́rù nípa àwọn àjálù ọjọ́ iwájú. Onímọ̀ físíìsì, ará ilẹ̀ Britain, tó gba Ẹ̀bùn Àlàáfíà Nobel náà, Joseph Rotblat, sọ ìdààmú ọkàn rẹ̀ jáde báyìí pé: “Ohun tí ń dà mí láàmú ni pé àwọn àwárí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mìíràn lè yọrí sí àwọn ọ̀nà mìíràn láti fi ṣèparun lọ́pọ̀ yanturu, bóyá, tí yóò tilẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó ju àwọn ohun ìjà átọ́míìkì lọ. Yíyí apilẹ̀ àbùdá padà jẹ́ àgbègbè kan tí èyí ti ṣeé ṣe, nítorí àwọn ìdàgbàsókè bíbanilẹ́rù wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Ben Selinger láti Yunifásítì Àpapọ̀ Ilẹ̀ Australia sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí ó lè rí tẹ́lẹ̀ pé: “Nínú èrò tèmi, ó ṣeé ṣe kí ìṣòro tó kàn wá láti àgbègbè yíyí apilẹ̀ àbùdá padà, ṣùgbọ́n n kò mọ ohun náà, bí yóò ṣe jẹ́, àti ìgbà tí yóò jẹ́.”
Ní ìhà kejì, Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, jẹ́ “ìmọ́lẹ̀” tó dájú, tó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ‘sí òpópónà wa’ lọ sínú ọjọ́ iwájú alálàáfíà, ìlera, àti ìṣọ̀kan àgbáyé, lórí ilẹ̀ ayé kan tí a fọ̀ mọ́ tónítóní lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run.—Sáàmù 119:105; Ìṣípayá 11:18; 21:1-4.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
“Ìjẹgàba Ìtàn Àròsọ Náà”
Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ti ṣe iyèméjì gidigidi nípa bí àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n tí Charles Darwin gbé kalẹ̀ ṣe lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó. Ní pàtàkì, àwọn onímọ̀ nípa molecule nínú ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè ti ṣe bẹ́ẹ̀.
Nínú ìwé rẹ̀, Evolution: A Theory in Crisis, Michael Denton, olùwádìí nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè, kọ̀wé pé: “Gbígbé ipò àbá èrò orí Darwin ga sí àyè ìlànà òtítọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ fúnra rẹ̀ ti yọrí sí sísọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ àti ìtakora tí Darwin torí rẹ̀ ṣe làálàá tó bẹ́ẹ̀ nínú ìwé Origin di ohun tí kò ṣeé rí rárá. Ó ṣe kedere pé a kò jíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì bí àìsí àwọn ìsopọ̀ tàbí ìṣòro èrò nípa irú ìwàláàyè àárín ọ̀kan sí èkejì, a sì ti fi ìṣẹ̀dá ìmárabápòmu tó díjú jù pàápàá sílẹ̀ fún àṣàyàn àdánidá láìsí ìwọ̀n iyèméjì tó kéré jù pàápàá.”
Ó ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ìjẹgàba ìtàn àròsọ náà ti ṣẹ̀dá ìtànjẹ tó gbilẹ̀ náà pé dájúdájú, a ti fẹ̀rí ìjótìítọ́ àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n múlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn . . . Èyí jẹ́ irọ́ pátápátá.”—Ojú ìwé 77.
“Bí a bá lè fi hàn pé ẹ̀yà ara dídíjú kan wà, tí kò lè ṣeé ṣe kí ó wà nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ìṣàtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tí a ṣe léraléra, àbá èrò orí tí mo gbé kalẹ̀ yóò wó lulẹ̀ pátápátá.”—Origin of Species, Charles Darwin, ojú ìwé 154.
“Bí iye àwọn ìgbékalẹ̀ ohun alààyè dídíjú, tí kò ṣeé fọ́ sí wẹ́wẹ́, tí kò sì ṣeé ṣàlàyé, ti ń pọ̀ sí i,a ìdánilójú tí a ní pé a ti dojú ọ̀pá ìdíwọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀ láti fi mọ̀ bí ó bá kùnà dé ń pọ̀ sí i dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibi tí sáyẹ́ǹsì fàyè gbà.” (Darwin’s Black Box—The Biochemical Challenge to Evolution, Michael J. Behe, ojú ìwé 39 àti 40) Ká sọ ọ́ lọ́nà mìíràn, àwọn àwárí lọ́ọ́lọ́ọ́ ní ẹ̀ka ìmọ̀ nípa molecule nínú ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè ti dá iyèméjì sílẹ̀ nípa àbá èrò orí Darwin.
“Àbájáde àwọn ìsapá tí a tò jọ pelemọ láti ṣèwádìí nípa sẹ́ẹ̀lì—láti wádìí ìwàláàyè ní ìpele ti molecule—jẹ́ ẹ̀rí kedere, tí ń wọni lára pé ó jẹ́ ‘ìgbékalẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe!’ Àbájáde náà kò rúni lójú rárá, ó sì ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ tí a fi gbọ́dọ̀ kà á sí ọ̀kan lára àwọn àṣeyọrí títóbijùlọ tí sáyẹ́ǹsì tí ì ṣe. Àwárí náà bá àwọn àwárí tí Newton àti Einstein, Lavoisier àti Schrödinger, Pasteur, àti Darwin ṣe dọ́gba. Àkíyèsí pé ìwàláàyè wá nípa ìgbékalẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe ọlọ́gbọ́n ṣe pàtàkì lọ́nà kan náà tí àkíyèsí pé ilẹ̀ ayé ń yí oòrùn po fi ṣe pàtàkì.”—Darwin’s Black Box, ojú ìwé 232 àti 233.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àyẹ̀wò kíkún lórí ẹfolúṣọ̀n àti ìmọ̀ nípa molecule nínú ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè, wo Jí!, May 8, 1997, ojú ìwé 3 sí 17, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Kristẹni ń fi ọgbọ́n yẹra fún àríyànjiyàn lórí bóyá ó ṣeé ṣe kí àwọn ohun alààyè máa gbé orí pílánẹ́ẹ̀tì mìíràn tàbí àwọn ipa tí a rò pé ìbátan àárín iná mànàmáná àti mágínẹ́ẹ̀tì ń ní
[Àwọn Credit Line]
Fọ́tò NASA /JPL
Fọ́tò NASA/JPL