ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/8 ojú ìwé 5-12
  • Ìpìlẹ̀ Ẹfolúṣọ̀n Kò Ha Kúnjú Òṣùwọ̀n Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpìlẹ̀ Ẹfolúṣọ̀n Kò Ha Kúnjú Òṣùwọ̀n Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdíjúpọ̀ Tí Kò Ṣeé Dín Kù —Ìdènà Gbígba Ẹfolúṣọ̀n Gbọ́ Ni Bí?
  • Ìdíjúpọ̀ Tí Kò Ṣeé Dín Kù ti Ìdìpọ̀ Ẹ̀jẹ̀
  • “Ohun Akójìnnìjìnnì-Báni Kan àti Ìdákẹ́jẹ́ẹ́ Pátápátá”
  • Àwọn Ìṣòro Lórí Bí Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀
  • Èé Ṣe Tí Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Fi Gbà Á Gbọ́?
  • Báwo Ni Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ẹfolúṣọ̀n Ń Jẹ́jọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Bá Bíbélì Mu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Jí!—1997
g97 5/8 ojú ìwé 5-12

Ìpìlẹ̀ Ẹfolúṣọ̀n Kò Ha Kúnjú Òṣùwọ̀n Bí?

KÍ NI kókó pàtàkì inú àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀? “Ní ti èrò gbogbogbòò, tí ó jẹ́ ti ìwàláàyè, . . . ẹfolúṣọ̀n túmọ̀ sí ìlànà kan, nínú èyí tí ìwàláàyè jẹ yọ láti inú ohun tí kò sí láàyè, tí ó sì dàgbà lẹ́yìn náà, lọ́nà ti ẹ̀dá pátápátá.” Ẹfolúṣọ̀n ti Darwin polongo pé, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìwàláàyè, tàbí ó kéré tán, gbogbo apá fífani-lọ́kànmọ́ra jù lọ nínú rẹ̀ ni ó jẹ yọ láti inú àṣàyàn àdánidá tí ń ṣiṣẹ́ lọ́nà ìyàtọ̀ ségesège.”—Darwin’s Black Box—The Biochemical Challenge to Evolution,a láti ọwọ́ Michael Behe, amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè, ní Yunifásítì Lehigh, Pennsylvania, U.S.A.

Ìdíjúpọ̀ Tí Kò Ṣeé Dín Kù —Ìdènà Gbígba Ẹfolúṣọ̀n Gbọ́ Ni Bí?

Nígbà tí Darwin gbé àbá èrò orí rẹ̀ kalẹ̀, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò ní ìmọ̀ púpọ̀ nípa bí alààyè sẹ́ẹ̀lì ṣe díjú lọ́nà àgbàyanu tó. Ìmọ̀ ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè lọ́nà ti òde òní, tí ó jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa ìwàláàyè ní ìpele molecule, ti ṣí díẹ̀ lára ìlọ́júpọ̀ yẹn payá. Ó tún ti mú àwọn ìbéèrè pàtàkì àti iyè méjì wá sójútáyé nípa àbá èrò orí tí Darwin gbé kalẹ̀.

Molecule ni àwọn ohun tí ó para pọ̀ di sẹ́ẹ̀lì. Àwọn sẹ́ẹ̀lì ní ń para pọ̀ di ohun alààyè. Ọ̀jọ̀gbọ́n Behe jẹ́ onísìn Roman Kátólíìkì, ó sì gba ẹfolúṣọ̀n gbọ́ bí ọ̀nà láti ṣàlàyé ìdàgbàsókè àwọn ohun alààyè tí kì í ṣe ewéko nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Bí ó ti wù kí ó rí, ó mú àwọn iyè méjì pàtàkì wá sójútáyé nípa bóyá ẹfolúṣọ̀n lè ṣàlàyé lórí bí sẹ́ẹ̀lì ṣe wà. Ó sọ nípa àwọn ẹ̀rọ tí a fi molecule ṣe, tí “ń gbé ẹrù gba ‘àwọn ojú ọ̀nà’ tí a fi àwọn molecule míràn ṣe, láti ibì kan lọ sí ibòmíràn nínú sẹ́ẹ̀lì . . . Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀rọ náà, àwọn sẹ́ẹ̀lì ń lọ káàkiri, wọ́n ń ṣẹ̀dà ara wọn, wọ́n ń jẹun. Ní ṣókí, àwọn ẹ̀rọ tí a fi molecule ṣe, tí ó díjú gidigidi, ní ń darí gbogbo ìgbésẹ̀ tí ń lọ nínú sẹ́ẹ̀lì. Nítorí náà, gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìwàláàyè ni a ṣètò láti ṣiṣẹ́ dáradára, ẹ̀rọ ìwàláàyè sì díjú lọ́nà kíkàmàmà.”

Lábẹ́ ipò yí, títí dé àyè wo ni ìgbòkègbodò yí ń ṣẹlẹ̀? Sẹ́ẹ̀lì àfiṣàpẹẹrẹ kan jẹ́ kìkì 0.03 mìlímítà ní ìbú! Nínú àyè kíkéré jọjọ yẹn, àwọn ìgbésẹ̀ lílọ́júpọ̀, tí ó ṣe kókó fún ìwàláàyè ń ṣẹlẹ̀. (Wo àwòrán, ojú ìwé 8 àti 9.) Abájọ tí a fi ń sọ pé: “Kókó pàtàkì jù lọ náà ni pé sẹ́ẹ̀lì—ìpìlẹ̀ ìwàláàyè gan-an—lọ́jú pọ̀ lọ́nà àgbàyanu.”

Behe ṣàlàyé pé sẹ́ẹ̀lì lè gbéṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí odindi nǹkan tí ó pé pérépéré nìkan. Nípa bẹ́ẹ̀, kò lè gbéṣẹ́ nígbà tí a bá ń mú un dàgbà nípasẹ̀ àwọn ìyípadà díẹ̀díẹ̀ tí kò yára, tí ẹfolúṣọ̀n sọ. Ó fi pàkúté kan ṣàpẹẹrẹ. Ohun èlò kékeré yìí lè gbéṣẹ́ nígbà tí gbogbo ẹ̀yà ara rẹ̀ bá wà pa pọ̀ nìkan. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan fúnra rẹ̀—àtẹ, irin lílọ́, òòtẹ̀, ìkẹ́ǹkẹ́, ẹ̀mú—kì í ṣe pàkúté, kò sì lè ṣe iṣẹ́ pàkúté. A nílò gbogbo ẹ̀yà ara náà lẹ́ẹ̀kan náà, kí a sì tò wọ́n pọ̀ kí a tó ní pàkúté kan tí ń gbéṣẹ́ ṣe. Lọ́nà kan náà, sẹ́ẹ̀lì kan lè ṣiṣẹ́ bíi sẹ́ẹ̀lì nígbà tí a bá to gbogbo ẹ̀yà rẹ̀ pọ̀. Ó lo àkàwé yìí láti fi ṣàlàyé ohun tí ó pè ní “ìlọ́júpọ̀ tí kò ṣeé dín kù.”b

Èyí gbé ìṣòro pàtàkì kan kalẹ̀ fún àbá èrò orí nípa ìlànà ẹfolúṣọ̀n, tí ó kan bí àwọn ànímọ́ wíwúlò ṣe ń fara hàn, tí a sì ń gbà wọ́n mọ́ra díẹ̀díẹ̀. Darwin mọ̀ pé àbá èrò orí tí òun gbé kalẹ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n tí ń wáyé díẹ̀díẹ̀ nípasẹ̀ àṣàyàn àdánidá dojú kọ ìpèníjà ńlá kan nígbà tí ó sọ pé: “Bí a bá lè fi hàn pé ẹ̀yà ara dídíjú kan wà, tí kò lè ṣeé ṣe kí ó wà nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ìṣàtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tí a ṣe léraléra, àbá èrò orí tí mo gbé kalẹ̀ yóò wó lulẹ̀ pátápátá.”—Origin of Species.

Sẹ́ẹ̀lì dídíjú tí kò ṣeé dín kù náà jẹ́ ìdènà ńlá kan fún gbígba àbá èrò orí tí Darwin gbé kalẹ̀ gbọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹfolúṣọ̀n kò lè ṣàlàyé ìyípadà àwọn nǹkan láti aláìlẹ́mìí sí abẹ̀mí. Lẹ́yìn náà ni ìṣòro nípa sẹ́ẹ̀lì dídíjú kìíní, tí ó gbọ́dọ̀ yọjú lẹ́ẹ̀kan náà gúran bí ìdìpọ̀ odindi kan, tún yọjú. Lọ́nà míràn, sẹ́ẹ̀lì náà (tàbí, pàkúté náà) gbọ́dọ̀ yọjú lójijì, kí ó wà ní títò, kí ó sì máa ṣiṣẹ́ lọ!

Ìdíjúpọ̀ Tí Kò Ṣeé Dín Kù ti Ìdìpọ̀ Ẹ̀jẹ̀

Àpẹẹrẹ ìdíjúpọ̀ tí kò ṣeé dín kù míràn ni ìgbésẹ̀ kan tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa kò kà sí nígbà tí a bá fi nǹkan gé ara wa—ìdìpọ̀ ẹ̀jẹ̀. Bí ó ti sábà máa ń rí, ohun olómi èyíkéyìí yóò ṣàn jáde nínú ohun ìkóǹkansí tí ó bá ń jò nídìí, yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ títí tí ohun ìkóǹkansí náà yóò fi ṣófo. Síbẹ̀, nígbà tí a bá dá ihò sí ara wa tàbí tí a gé awọ ara wa, ẹ̀jẹ̀ yára ń dì, ó sì ń dí ojú ihò tí ì bá ti máa jò dà nù náà. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí àwọn dókítà ti mọ̀, “dídì tí ẹ̀jẹ̀ ń dì jẹ́ ìgbékalẹ̀ dídíjú kan tí ó lọ́ mọ́ra lọ́nà lílọ́júpọ̀, tí ó ní ọ̀pọ̀ ẹ̀ka oní-protein tí ó gbára léra wọn.” Ìwọ̀nyí ní ń sún ohun tí a ń pè ní ìgbésẹ̀ alásokọ́ra ti dídì tí ẹ̀jẹ̀ ń dì pọ̀ ṣiṣẹ́. Ìgbésẹ̀ ìwòsàn ẹlẹgẹ́ yìí “sinmi gidigidi lórí ìbọ́sákòókò àti ìwọ̀n ìyára tí ìyípadà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ náà ṣiṣẹ́ sí.” Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo ẹ̀jẹ̀ ara ẹnì kan lè dì, kí ó sì le gbagidi, tàbí níhà kejì, ó lè jò dà nù títí tí ẹni náà yóò fi kú. Ìbọ́sákòókò àti ìwọ̀n ìyára ni àwọn kókó pàtàkì náà.

Ìwádìí lórí ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè ti fi hàn pé dídì tí ẹ̀jẹ̀ ń dì kan ọ̀pọ̀ kókó abájọ, tí kò sí èyí tí ó gbọ́dọ̀ ṣàìsí níbẹ̀, kí ìgbésẹ̀ náà lè kẹ́sẹ járí. Behe béèrè pé: “Ní gbàrà tí ẹ̀jẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í dì, kí ní ń ṣí i lọ́wọ́ láti máa dì nìṣó títí tí gbogbo ẹ̀jẹ̀ náà . . . ì bá fi dì gbagidi?” Ó ṣàlàyé pé, “ṣíṣẹ̀dá ìdìpọ̀ ẹ̀jẹ̀, pípààlà rẹ̀, fífún-un-lókun, àti mímú-un-kúrò” para pọ̀ jẹ́ ìgbékalẹ̀ alásokọ́ra kan nínú ìwàláàyè. Bí apá kankan bá kùnà, nígbà náà, ìgbékalẹ̀ náà kùnà.

Russell Doolittle, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n, tí ó sì jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè ní Yunifásítì California, béèrè pé: “Báwo gan-an ni ìgbésẹ̀ dídíjú, tí ó wà déédéé lọ́nà ẹlẹgẹ́ yìí ṣe jẹ yọ? . . . Ẹ̀dà ọ̀rọ̀ ibẹ̀ ni pé, bí protein kọ̀ọ̀kan bá gbára lé ìsúnṣiṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ òmíràn, báwo ni ìgbékalẹ̀ ìdìpọ̀ ẹ̀jẹ̀ náà ṣe lè wáyé? Báwo ni apá èyíkéyìí ìgbékalẹ̀ náà ṣe lè wúlò tó láìsí àkópọ̀ náà lódindi?” Nípa lílo àwọn àlàyé ẹfolúṣọ̀n, Doolittle gbìyànjú láti ṣàlàyé orírun ìgbésẹ̀ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Behe tọ́ka sí i pé a óò “nílò ìwọ̀n oríire kíkàmàmà kan láti fi àwọn ẹyọ apilẹ̀ àbùdá yíyẹ sí àwọn àyè yíyẹ.” Ó fi hàn pé, àlàyé tí Doolittle ṣe àti èdè rírọrùn tí ó lò fi àwọn ìṣòro kíkàmàmà pa mọ́.

Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀kan lára àwọn àtakò pàtàkì-pàtàkì lòdì sí àgbékalẹ̀ èrò ẹfolúṣọ̀n ni ìdènà tí kò ṣeé gbé dá, ti ìdíjúpọ̀ tí kò ṣeé dín kù. Behe sọ pé: “Mo tẹnu mọ́ ọn pé, àṣàyàn àdánidá, irinṣẹ́ ẹfolúṣọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀, yóò gbéṣẹ́, kìkì níbi tí ohun tí a lè ṣà yàn bá wà—ohun kan tí ó wúlò nísinsìnyí, kì í ṣe lọ́jọ́ iwájú.”

“Ohun Akójìnnìjìnnì-Báni Kan àti Ìdákẹ́jẹ́ẹ́ Pátápátá”

Ọ̀jọ̀gbọ́n Behe sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mélòó kan ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa “àwọn àgbékalẹ̀ èrò oníṣirò fún ẹfolúṣọ̀n tàbí àwọn ọ̀nà ìṣe oníṣirò tuntun láti ṣàfiwéra ìtòtẹ̀léra àkójọ èrò, kí wọ́n sì túmọ̀ wọn.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Ìṣirò náà gbà pé ẹfolúṣọ̀n gidi jẹ́ ìgbésẹ̀ gátagàta, tí a ṣe díẹ̀díẹ̀; kò ṣàfihàn rẹ̀, kò sì lè ṣe bẹ́ẹ̀.” (Ìkọ̀wé wínníwínní àpólà ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́yìn jẹ́ tiwa.) Ó sọ ṣáájú pé: “Bí o bá ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé tí a gbé karí sáyẹ́ǹsì, tí a kọ lórí ẹfolúṣọ̀n, tí o sì kó àwárí rẹ lé orí ọ̀ràn bí àwọn ẹ̀rọ tí a fi molecule ṣe—ìpìlẹ̀ ìwàláàyè—ṣe rú yọ, ìwọ óò rí ohun akójìnnìjìnnì-báni kan àti ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pátápátá. Dídíjú tí ìpìlẹ̀ ìwàláàyè díjú ti sọ ìgbìyànjú sáyẹ́ǹsì láti ṣàlàyé rẹ̀ di aláìlágbára; àwọn ẹ̀rọ tí a fi molecule ṣe ti gbé ìdènà kan tí kò tí ì ṣeé gbé dá dí ọ̀nà láti tẹ́wọ́ gba èrò orí Darwin.”

Èyí mú ọ̀wọ́ àwọn ìbéèrè kan wá sójútáyé fún àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn láti gbé yẹ̀ wò: “Báwo ni ìlànà photosynthesis ṣe ń ṣiṣẹ́? Báwo ni ìṣàtúntò inú molecule ṣe ń bẹ̀rẹ̀? Báwo ni ìṣèmújáde èròjà cholesterol ṣe ń bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ohun alààyè? Báwo ni agbára ìríran ṣe ń kan èròjà retinal? Báwo ni ipa tí àmì isọfúnni phosphoprotein ń gbà ṣe ń wáyé?”c Behe fi kún un pé: “Òtítọ́ náà pé a kò tilẹ̀ mẹ́nu ba èyíkéyìí lára àwọn ìṣòro wọ̀nyí, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé a ń yanjú wọn, jẹ́ ìtọ́kasí lílágbára kan pé èrò orí Darwin jẹ́ ìpìlẹ̀ kan tí kò ká ojú ìwọ̀n fún lílóye orírun àwọn ìgbékalẹ̀ dídíjú ti ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè.”

Bí àbá èrò orí Darwin kò bá lè ṣàlàyé ìpìlẹ̀ dídíjú oní-molecule ti àwọn sẹ́ẹ̀lì, báwo ni yóò ṣe jẹ́ àlàyé tí ń tẹ́ni lọ́rùn lórí bí àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ irú ọ̀wọ́ tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yìí ṣe wáyé? Ó ṣe tán, ẹfolúṣọ̀n kò tilẹ̀ lè mú irú ìdílé ohun alààyè tuntun jáde nípa dídí àlàfo àárín irú ìdílé kan àti òmíràn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:11, 21, 24.

Àwọn Ìṣòro Lórí Bí Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Bí ó ti wù kí àbá èrò orí tí Darwin gbé kalẹ̀ bọ́gbọ́n mu tó lójú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan, wọ́n ní láti kojú ìbéèrè náà níkẹyìn pé, Ká tilẹ̀ ní a gbà pé oríṣiríṣi àwọn ohun alààyè rú jáde nípa àṣàyàn àdánidá, báwo ni ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀? Lọ́nà míràn, ìṣòro náà kì í ṣe ti bí alágbára jù lọ náà ṣe là á já, bí kò ṣe ti ibi tí alágbára jù lọ náà ti wá, àti èyí tó kọ́kọ́ wà! Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Darwin sọ nípa bí ojú ṣe jẹ yọ ṣe fi hàn, kò sí ohun tó gbún un nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Bí iṣan ara kan ṣe ń mọ ìmọ́lẹ̀ lára kò kàn wá lọ́nà kan náà tí bí ìwàláàyè fúnra rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ kò gbà gbún wa.”

Òǹkọ̀wé sáyẹ́ǹsì náà, Philippe Chambon, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé, kọ̀wé pé: “Darwin fúnra rẹ̀ ṣe kàyéfì lórí bí ìṣẹ̀dá àdánidá ṣe ṣàṣàyàn àwọn ìrísí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọrí bọ̀ kí wọ́n tó gbéṣẹ́ lọ́nà pípé. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun àràmàǹdà inú ẹfolúṣọ̀n kò lópin. Ó sì yẹ kí àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè lóde òní fìrẹ̀lẹ̀ gbà, pẹ̀lú Ọ̀jọ̀gbọ́n Jean Génermont ti Yunifásítì Ìhà Gúúsù Paris ni Orsay, pé, ‘àgbélẹ̀rọ àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n kò lè ṣàlàyé orírun àwọn ohun dídíjú ní pàtó.’”

Lójú àìṣeéṣe rẹpẹtẹ fún ẹfolúṣọ̀n láti ṣàmújáde ìwàláàyè lónírúurú àti lọ́nà dídíjú bẹ́ẹ̀, ó ha ṣòro fún ọ láti gbà gbọ́ pé gbogbo nǹkan yọ jáde ní ìhà títọ́ nípa èèṣì lásán bí? O ha ṣe kàyéfì lórí bí àwọn ẹ̀dá èyíkéyìí ṣe lè la ogun ìlàájá alágbára jù lọ náà já nígbà tí ojú wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jáde bí? Tàbí nígbà tí a gbà pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ ìka nínú ara tí kò ì di ti ènìyàn tán? O ha ṣe kàyéfì bí àwọn sẹ́ẹ̀lì ṣe là á já bí wọ́n bá wà ní ipò àìpé àti àìkúnjú-ìwọ̀n bí?

Robert Naeye, tí ó ń kọ̀wé fún ìwé ìròyìn Astronomy, tí ó sì tún jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n, kọ̀wé pé, ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìyọrísí “ìtòtẹ̀léra gígùn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ [tí] ó ṣeé ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́, tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́nà títọ́ gẹ́lẹ́ láti mú kí a wà, bíi pé a ti jẹ tẹ́tẹ́ oríire aláàádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là nígbà àádọ́ta ọ̀kẹ́ léraléra.” Ó ṣeé ṣe kí a lè lo ọ̀nà ìrònú kan náà yẹn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun alààyè tí ń bẹ lónìí. Ohun tí ó lè ṣàìjẹ́ òtítọ́ pátápátá gbáà ni. Síbẹ̀, a retí pé kí a gbà gbọ́ pé, nípa èèṣì, ẹfolúṣọ̀n pẹ̀lú ṣe ìmújáde akọ kan àti abo kan ní àkókò kan náà, kí irú ọ̀wọ́ tuntun náà lè máa wà nìṣó. Èyí tí kò tún lè jẹ́ òtítọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ ni pé, a tún ní láti gbà gbọ́ pé akọ àti abo náà kò wulẹ̀ yọ jáde lásán lẹ́ẹ̀kan náà, ṣùgbọ́n pé wọ́n yọ jáde ní ibì kan náà! Bí kò bá sí ìbápàdé lọ́nà báyìí, kò ní sí ìmúrújáde kankan!

Dájúdájú, ẹni tí ń gbà gbọ́ pé lótìítọ́ ni ìwàláàyè wà ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ oríṣiríṣi tí ó kún rẹ́rẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèṣì tí ó kẹ́sẹ járí, wulẹ̀ ń mú kí ohun tí ó ṣeé gbà gbọ́ ré kọjá ààlà ni.

Èé Ṣe Tí Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Fi Gbà Á Gbọ́?

Èé ṣe tí ẹfolúṣọ̀n fi lókìkí, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tẹ́wọ́ gbà á bí àlàyé kan ṣoṣo tí ó wà fún ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé? Ìdí kan ni pé, òun ni èrò gbogbogbòò tí a fi ń kọ́ni ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ àti yunifásítì, sísọ iyè méjì kankan jáde yóò sì mú ìyọrísí búburú bá ọ. Behe sọ pé: “Láti inú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn, ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ń kọ́ láti fi ojú ìwòye ẹfolúṣọ̀n wo àgbáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kọ́ nípa bí ẹfolúṣọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀ ṣe lè ṣèmújáde àwọn ìgbékalẹ̀ ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè tí ó lọ́jú pọ̀ gidigidi tí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ń ṣàpèjúwe.” Ó fi kún un pé: “Bí a bá fẹ́ láti lóye àṣeyọrí èrò orí Darwin gẹ́gẹ́ bí èrò gbogbogbòò àti ìkùnà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nínú ìgbìyànjú láti ṣàlàyé ìpìlẹ̀ àwọn sẹ́ẹ̀lì ní ìpele ti molecule, a ní láti ṣàtúpalẹ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi ń kọ́ àwọn tí ń tiraka láti di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.”

“Bí a bá wádìí lẹ́nu gbogbo onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lágbàáyé, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn yóò sọ pé àwọn gbà pé èrò orí tí Darwin gbé kalẹ̀ jẹ́ òtítọ́. Ṣùgbọ́n bíi ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbé ọ̀pọ̀ jù lọ èrò wọn karí ohun tí àwọn ẹlòmíràn sọ. . . . Bákan náà, lọ́nà tí ó sì bani nínú jẹ́, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti sábà máa ń rọ́ àwọn àríwísí tì sápá kan nítorí ìbẹ̀rù fífún àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá ní kókó àgbọ́kànlé. Ó jẹ́ òdì ọ̀rọ̀ pé, nítorí kí a lè dáàbò bo sáyẹ́ǹsì, a ti pa àríwísí tààràtà lọ́nà ti sáyẹ́ǹsì lòdì sí àṣàyàn àdánidá tì sápá kan.”d

Yíyàn tó gbéṣẹ́, tó sì ṣeé gbára lé wo ló wà yàtọ̀ sí àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀? Àpilẹ̀kọ wa tó kẹ́yìn nínú ọ̀wọ́ yìí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ń tọ́ka sí i láti ìhín lọ gẹ́gẹ́ bíi Darwin’s Black Box.

b “Ìlọ́júpọ̀ tí kò ṣeé dín kù” ṣàpèjúwe “ìgbékalẹ̀ kan tí ó ní àwọn apá mélòó kan tí a tò pọ̀ dáradára, tí ó jùmọ̀ bára mu, tí ń kópa nínú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ pàtó kan, nínú èyí tí ó jẹ́ pé, bí a bá yọ apá èyíkéyìí kan kúrò, ìgbékalẹ̀ náà kì yóò gbéṣẹ́ mọ́.” (Darwin’s Black Box) Nípa bẹ́ẹ̀, ìpele kíkéré jù lọ tí ìgbékalẹ̀ kan ti lè gbéṣẹ́ nìyí.

c Ìlànà photosynthesis ni ọ̀nà tí àwọn sẹ́ẹ̀lì ewéko gbà ń lo ìmọ́lẹ̀ àti chlorophyll láti ṣẹ̀dá àwọn èròjà carbohydrate láti inú afẹ́fẹ́ carbon dioxide àti omi. Àwọn kan pè é ní ìyípadà kẹ́míkà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìṣẹ̀dá. Ìṣèmújáde kẹ́míkà nínú ohun alààyè ni ìlànà tí àwọn alààyè sẹ́ẹ̀lì fi ń ṣèmújáde àwọn èròjà oníkẹ́míkà dídíjú. Ìgbékalẹ̀ agbára ìríran dídíjú ní èròjà retinal nínú. Apá kan nínú àwọn ọ̀nà ìṣiṣẹ́ sẹ́ẹ̀lì ni ipa tí àmì isọfúnni phosphoprotein ń gbà.

d Èrò orí ìṣẹ̀dá wé mọ́ ìgbàgbọ́ pé a ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé ní àwọn ọjọ́ oníwákàtí 24 mẹ́fà, tàbí nínú àwọn ọ̀ràn kan, pé a ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé ní kìkì nǹkan bí ẹgbàarùn-ún ọdún sẹ́yìn. Nígbà tí ó jẹ́ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá, wọn kì í ṣe elérò orí ìṣẹ̀dá. Wọ́n gbà gbọ́ pé àkọsílẹ̀ ìròyìn inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì nínú Bíbélì fàyè gbà á pé ilẹ̀ ayé ti lè wà fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọdún.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Bí a bá lè fi hàn pé ẹ̀yà ara dídíjú kan wà, tí kò lè ṣeé ṣe kí ó wà nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ìṣàtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tí a ṣe léraléra, àbá èrò orí tí mo gbé kalẹ̀ yóò wó lulẹ̀ pátápátá.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

“Ìmọ̀ ẹ̀rọ títayọlọ́lá jù lọ, tí ó sì díjú pọ̀ lọ́nà tí ń ṣeni ní kàyéfì” ni ó wà nínú sẹ́ẹ̀lì.—Evolution: A Theory in Crisis

Àwọn ìsọfúnni tí ó wà nínú ásíìdì DNA sẹ́ẹ̀lì náà, “bí a bá kọ wọ́n jáde, yóò kún ẹgbẹ̀rún ìwé tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní 600 ojú ewé.”—National Geographic

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

“Ìṣirò náà gbà pé ẹfolúṣọ̀n gidi jẹ́ ìgbésẹ̀ gátagàta, tí a ṣe díẹ̀díẹ̀; kò ṣàfihàn rẹ̀, kò sì lè ṣe bẹ́ẹ̀.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

“Ó jẹ́ òdì ọ̀rọ̀ pé, nítorí kí a lè dáàbò bo sáyẹ́ǹsì, a ti pa àríwísí tààràtà lọ́nà ti sáyẹ́ǹsì lòdì sí àṣàyàn àdánidá tì sápá kan.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

Molecule àti Sẹ́ẹ̀lì

Ìmọ̀ ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè—“ẹ̀kọ́ nípa ìpìlẹ̀ ìwàláàyè fúnra rẹ̀: àwọn molecule tí ó para pọ̀ di sẹ́ẹ̀lì àti iṣan ara, tí ń ṣokùnfà ìyípadà oníkẹ́míkà ti bí oúnjẹ ṣe ń dà, ìlànà photosynthesis, ìdènà àrùn, àti púpọ̀ sí i.”—Darwin’s Black Box.

Molecule—“ìpín kékeré jù lọ tí a lè pín ohun kan tàbí èròjà kan sí láìsí pé a yí àwọn ànímọ́ oníkẹ́míkà àti ìrísí rẹ̀ pa dà; àgbájọ àwọn átọ̀mù jíjọra tàbí yíyàtọ̀síra tí ipá oníkẹ́míkà so pọ̀.”—The American Heritage Dictionary of the English Language.

Sẹ́ẹ̀lì—ẹ̀ka ṣíṣekókó jù lọ fún gbogbo ohun alààyè. “Sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbékalẹ̀ tí a ṣètò lọ́nà gígalọ́lá, tí ń pinnu ìrísí àti ìṣiṣẹ́ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.” Sẹ́ẹ̀lì mélòó ló para pọ̀ di àgbàlagbà ẹ̀dá ènìyàn kan? Ọgọ́rùn-ún tírílíọ̀nù (100,000,000,000,000)! A ní nǹkan bí 155,000 sẹ́ẹ̀lì ní gbogbo ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà kan níbùú lóròó awọ ara wa, ọpọlọ ẹ̀dá ènìyàn sì ní iye iṣan ọpọlọ tí ó wà láàárín bílíọ̀nù 10 sí 100. “Sẹ́ẹ̀lì ni kókó ìpìlẹ̀ fún ìmọ̀ nípa ìwàláàyè nítorí pé, ní ìpele yìí ni ìwọ̀n ìpíndọ́gba omi, iyọ̀, àwọn molecule tí kò ṣeé fojú lásán rí, àti àwọn awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ti ń para pọ̀ di ìwàláàyè ní ti gidi.”—Biology.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

“Ìdíjúpọ̀ Aláìlẹ́gbẹ́” ti Sẹ́ẹ̀lì

“Láti lóye ohun tí ìwàláàyè jẹ́ ní ti gidi, gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ nípa molecule nínú ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè ti fi hàn, a ní láti sọ sẹ́ẹ̀lì kan di ńlá ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún mílíọ̀nù, títí yóò fi fẹ̀ ní ogún kìlómítà láti ìkángun kan dé èkejì, tí yóò sì dà bí ọkọ̀ òfuurufú kíkàmàmà kan, tí ó tóbi tó láti bo ìlú ńlá kan bíi London tàbí New York. Ohun tí a óò rí nígbà náà yóò jẹ́ ohun kan tí ìdíjúpọ̀ rẹ̀ jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, tí ó sì ní ìwéwèé tí ó ṣeé mú bá oríṣiríṣi ipò mu. A óò rí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ihò lára sẹ́ẹ̀lì náà, bíi fèrèsé ara ọkọ̀ òfuurufú ńlá kan, tí ń ṣí, tí sì ń pa dé láti fàyè gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ nǹkan láti wọlé àti láti jáde. Bí a bá lè wọnú ọ̀kan lára àwọn fèrèsé wọ̀nyí, a óò bá ara wa ní ibi ìmọ̀ ẹ̀rọ gígalọ́lá jù lọ àti ìdíjúpọ̀ yíyanilẹ́nu kan. A óò rí àìlópin àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ àti ọ̀pá ìpínǹkankiri tí a ṣètò lọ́nà gíga, tí wọ́n pẹ̀ka síhà gbogbo, láti eteetí sẹ́ẹ̀lì náà, tí àwọn kan lọ sí ibi àpapọ̀ àkójọ ìrántí tí ó wà nínú nucleus, tí àwọn mìíràn sì lọ sí àwọn ibi ìtoǹkanjọ àti àwọn ibi ìyíǹkanpadà. Nucleus náà fúnra rẹ̀ yóò jẹ́ iyàrá ńlá rìbìtì kan tí ó fẹ̀ ju kìlómítà kan lọ, tí ó dà bí ilé olórùlé rìbìtì kan, nínú èyí tí a óò ti rí àwọn ìkájọ àsokọ́ra molecule ásíìdì DNA, tí ó gùn ní ọ̀pọ̀ máìlì, tí a dì pọ̀ nigínnigín lọ́nà ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ elétò. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ohun tí a ti ṣe parí àti àwọn èròjà tí a óò fi ṣe nǹkan mìíràn yóò máa gba inú àwọn onírúurú ọ̀pá ìgbéǹkankiri tí a ṣètò jọ lọ́nà gígalọ́lá lọ sí àwọn ibi ìtoǹkanjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó wà ní ìhà òde sẹ́ẹ̀lì náà, wọn yóò sì máa pa dà bọ̀ láti ibẹ̀.

“Ìwọ̀n ìdarí tí ń ṣiṣẹ́ nínú ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ nǹkan ń gbà rìn lọ rìn bọ̀ nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ipa ọ̀nà tí ó jọ pé kò lópin náà, lọ́nà ìbáramu pípé, yóò yani lẹ́nu. A óò rí onírúurú ẹ̀rọ tí ó dà bíi róbọ́ọ̀tì láyìíká wa, níbi yòó wù kí a yíjú sí. A óò ṣàkíyèsí pé àwọn apá gbígbéṣẹ́ tí ó rọrùn jù lọ lára sẹ́ẹ̀lì, àwọn protein molecule, jẹ́ àwọn ẹyọ ẹ̀rọ ìpele molecule dídíjú, tí ń ṣeni ní kàyéfì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún átọ̀mù tí a tò ní ìrísí alálàfo nǹkan olóríṣi igun ìwọ̀n mẹ́ta, tí a tò jọ lọ́nà gígalọ́lá. Èyí tí yóò túbọ̀ yà wá lẹ́nu sí i ni bí a ṣe ń wo àwọn ìgbòkègbodò eléte tí àwọn ẹ̀rọ ìpele molecule ajẹ́bíidán wọ̀nyí ń ṣe, ní pàtàkì, nígbà tí a bá mọ̀ pé, láìka gbogbo ìmọ̀ físíìsì àti kẹ́mísìrì tí a ní sí, ṣíṣàgbékalẹ̀ irú ẹ̀rọ molecule bẹ́ẹ̀—ìyẹn ni, ẹyọ protein molecule gbígbéṣẹ́ kan ṣoṣo—yóò ré kọjá agbára wa ní lọ́ọ́lọ́ọ́ pátápátá, ó sì ṣeé ṣe kí a má lè ṣe é títí di, ó yá jù lọ, ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tí ń bọ̀. Síbẹ̀, ìwàláàyè sẹ́ẹ̀lì gbára lé àwọn àkópọ̀ ìgbòkègbodò ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó dájú pé ó pé ẹgbẹẹgbàárùn-ún, bóyá tí ó tilẹ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún onírúurú protein molecule.”—Evolution: A Theory in Crisis.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]

Òtítọ́ àti Àròsọ

“Fún ẹnì kan tí ó rò pé òun lómìnira láti ṣèwádìí lórí okùnfà onílàákàyè, ìparí èrò tó ṣe tààrà náà ni pé, ọ̀pọ̀ ìgbékalẹ̀ ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè ni a mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Kì í ṣe àwọn òfin àdánidá, tàbí èèṣì, tàbí àìgbọ́dọ̀máṣe ló ṣe wọ́n; kàkà bẹ́ẹ̀, a wéwèé wọn ni. . . . Ní ìpele ìpìlẹ̀ rẹ̀, nínú àwọn ẹ̀yà rẹ̀ tí ó ṣe kókó jù lọ, ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìyọrísí ìgbòkègbodò onílàákàyè.”—Darwin’s Black Box.

“Kò lè sí iyè méjì pé, lẹ́yìn ọ̀rúndún kan tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ohun alààyè ti fi ṣe ìsapá tí ó gba ìnáwónára gidigidi, wọ́n ti kùnà láti fìdí [àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀] múlẹ̀ ní èrò ìtumọ̀ gúnmọ́ èyíkéyìí. Ó ṣì jẹ́ òtítọ́ pé ẹ̀dá kò tí ì ṣí àwọn ohun alààyè tí wọ́n bára tan tímọ́tímọ́ tó irú èyí tí a nílò fún àbá èrò orí Darwin payá, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò tí ì mú kí èrò náà, pé ìwàláàyè bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ èèṣì, ṣeé gbà gbọ́.”—Evolution: A Theory in Crisis.

“Ipa tí àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n ń ní lórí àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ míràn tí kò bá ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè tan jẹ́ àpẹẹrẹ wíwọnilọ́kàn jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn nípa bí èrò orí gíga kan, tí a kò lè fi dánra wò, tí kò sì ní ẹ̀rí sáyẹ́ǹsì ní ti gidi, ṣe lè nípa lórí ọ̀nà ìrònú odindi àwùjọ ènìyàn, kí ó sì darí ojú ìwòye ìran ènìyàn kan.”—Evolution: A Theory in Crisis.

“Sáyẹ́ǹsì àtijọ́ èyíkéyìí . . . tí o yọ ṣíṣeéṣe àpilẹ̀ṣe tàbí ìṣẹ̀dá tí a gbé kalẹ̀ ṣáájú sọ nù, kò jẹ́ ìwákiri òtítọ́ mọ́, ó sì di ìránṣẹ́ (tàbí ẹrú) ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èrò orí tí ń dá ìṣòro sílẹ̀ kan, ìyẹn ni, àìnígbàgbọ́ nínú ohun tí ó bá ju ẹ̀dá lọ.”—Origins Research.

“Ó jẹ́ àròsọ kan . . . pé Charles Darwin yanjú ìṣòro orírun ìdíjúpọ̀ ohun alààyè. Ó jẹ́ àròsọ kan pé a ní òye tí ó pọ̀ tó, tàbí tí ó tilẹ̀ mọ níwọ̀nba tó nípa orírun ìwàláàyè, tàbí pé àwọn àlàyé títọ́ ń tọ́ka sí àwọn okùnfà tí a pè ní ti àdánidá. Ní tòótọ́, àwọn àròsọ àìnígbàgbọ́ nínú ohun tí ó bá ju ẹ̀dá lọ wọ̀nyí àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ ní ipò kan tí ó dájú. Ènìyàn kò jẹ́ bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n níṣojú àwọn tí wọ́n ka ara wọn sí ẹni tí ó lajú. Ṣùgbọ́n ẹnì kan kò gbọ́dọ̀ gbà wọ́n láìṣe lámèyítọ́ wọn.”—Origins Research.

“Bó bá ku àwọn araawọn, ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé sáyẹ́ǹsì kò lè ṣàlàyé orírun ìwàláàyè. . . . Darwin kò fìgbà kankan ronú kan ìdíjúpọ̀ kíkọyọyọ tí ó wà ní ìpele ìpìlẹ̀ jù lọ nínú ìwàláàyè pàápàá.”—Darwin’s Black Box.

“A kò gbé ẹfolúṣọ̀n ìpele molecule karí ọlá àṣẹ sáyẹ́ǹsì. . . . Ọ̀pọ̀ ìkéde ló wà pé irú ẹfolúṣọ̀n bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí èyí tí ó ní ìtìlẹ́yìn àṣedánrawò tàbí ìṣirò tí ó tan mọ́ ọn. Níwọ̀n bí kò ti sí ẹni tí ó mọ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n ìpele molecule nípasẹ̀ ìrírí tààràtà, tí kò sì sí ọlá àṣẹ kankan tí a lè gbé àwọn ìsọjáde nípa ìmọ̀ náà kà, a lè sọ ní tòótọ́ pé . . . ìkéde ẹfolúṣọ̀n ìpele molecule ti Darwin jẹ́ ìfúnnu lásán.”—Darwin’s Black Box.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

Ẹfolúṣọ̀n “Eré Kan Tí A Gbé Karí Èèṣì”

Dájúdájú, àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n jẹ́ àlá atatẹ́tẹ́ kan. Èé ṣe? Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe wí, ó ń ṣàṣeyọrí nìṣó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àìṣeéṣe tí ó dojú kọ pọ̀ rẹpẹtẹ.

Robert Naeye kọ̀wé pé: “Nítorí pé ẹfolúṣọ̀n jẹ́ eré àṣedárayá tí a gbé karí èèṣì nípìlẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó jọ pé kò já mọ́ nǹkan tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ti lè ṣẹlẹ̀ lọ́nà yíyàtọ̀ kan, kí ó sì ti fòpin sí ìgbésẹ̀ ẹfolúṣọ̀n wa kí ẹ̀dá ènìyàn tó yọ jáde.” Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, a retí pé kí a gbà gbọ́ pé gbogbo èèṣì náà ló kẹ́sẹ járí, ní ìgbà àràádọ́ta ọ̀kẹ́. Naeye gbà pé: “Ọ̀wọ́ àwọn ìṣòro gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ tí ìgbésẹ̀ ẹfolúṣọ̀n bá pàdé mú un ṣe kedere pé yíyọríjáde ìwàláàyè onílàákàyè ṣòro púpọ̀ gan-an ju bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ronú rẹ̀ nígbà kan rí lọ. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ìdènà púpọ̀ sí i ṣì wà tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tilẹ̀ tí ì bá pàdé síbẹ̀.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Àwòrán Sẹ́ẹ̀lì kan tí A Mú Rọrùn

Àwọn ribosome

Àwọn ohun tí a ń ṣe protein lórí wọn

Cytoplasm

Àgbègbè tí ó wà láàárín nucleus àti awọ sẹ́ẹ̀lì

Endoplasmic reticulum

Àwọn abala awọ tí ń gba protein tí àwọn ribosome tí ó so pọ̀ mọ́ wọn ń ṣe mọ́ra, tàbí tí ń gbé wọn kiri

Nucleus

Òun ni ìkóríta ìṣàkóso tí ń darí àwọn ìgbòkègbodò inú sẹ́ẹ̀lì

Nucleolus

Ibi tí a ti ń ṣe àwọn ribosome

Àwọn chromosome

Ásíìdì DNA, ìṣètò apilẹ̀ àbùdá gíga jù lọ ti sẹ́ẹ̀lì náà, wà nínú wọn

Vacuole

Ó ń gba omi, iyọ̀, protein, àti carbohydrate pa mọ́

Lysosome

Ó ń fi àwọn enzyme pa mọ́ fún ìṣètò oúnjẹ dídà

Ẹran ara Golgi

Ìdìpọ̀ àwọn àpò awọ tí a ń di protein tí sẹ́ẹ̀lì náà bá ṣe sí, tí ó sì ń pín in kiri

Awọ sẹ́ẹ̀lì

Awọ tí ń ṣàkóso ohun tí ń wọ inú sẹ́ẹ̀lì tàbí tí ń ti inú sẹ́ẹ̀lì jáde

Centriole

Ó ṣe pàtàkì fún ṣíṣe ẹ̀dà sẹ́ẹ̀lì

Mitochondrion

Ibùdó tí a ti ń ṣe molecule ATP, àwọn molecule tí ń fún sẹ́ẹ̀lì lágbára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ náà kì í ṣe pàkúté —wọ́n gbọ́dọ̀ pé láti gbéṣẹ́ bíi pàkúté

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́