Àwọn Kristẹni àti Ètò Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍŃDÍÀ
KÍ NÍ ń wá sọ́kàn rẹ tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́”? Bóyá èrò nípa Íńdíà àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí wọ́n wà níbẹ̀ tí wọn kò sí ní ẹgbẹ́ kankan—àwọn tí a ta nù—ló ń wá sọ́kàn rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ jẹ́ apá kan ìsìn Híńdù, àwọn alátùn-únṣe ìsìn Híńdù ti jà raburabu láti mú ipa tí ó ti ní lórí àwọn tí wọ́n wà ní ipò rírẹlẹ̀ àti àwọn tí a ta nù nínú ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kúrò. Nípa bẹ́ẹ̀, kí ni ìwọ yóò sọ bí o bá gbọ́ pé wọ́n tilẹ̀ ń ṣe ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni?
Ibi Tí Ó Ṣeé Ṣe Kí Ètò Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Ti Ṣẹ̀ Wá ní Íńdíà
Kì í ṣe Íńdíà nìkan ni ètò pípín àwọn ènìyàn sí ìsọ̀rí ẹlẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ nínú èyí tí àwọn kan ti ń nímọ̀lára ìyọrí-ọlá wà. Gbogbo kọ́ńtínẹ́ǹtì ló ti nírìírí irú ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kan tàbí òmíràn. Ohun tí ó mú kí ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ti Íńdíà yàtọ̀ ni pé, wọ́n mú ìlànà ìtẹnilóríba ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ kan wọnú ìsìn ní ohun tí ó lé ní 3,000 ọdún sẹ́yìn.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè fọwọ́ sọ̀yà pé a mọ ibi tí ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ti ṣẹ̀ wá, àwọn aláṣẹ kan ṣàwárí ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ nígbà ọ̀làjú ayé àtijọ́ ti Àfonífojì Indus ní Pakistan òde òní. Ó jọ pé ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn tọ́ka pé, lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wá láti àríwá ìwọ̀ oòrùn wá fipá gba ibẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ látètèkọ́ṣe, nínú ohun tí a sábà ń pè ní “ìṣíkiri àwọn Aryan.” Nínú ìwé rẹ̀, The Discovery of India, Jawaharlal Nehru pe èyí ní “ìkórajọpọ̀ àti ìsopọ̀ṣọ̀kan àkọ́kọ́ títóbijùlọ ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀,” tí “àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní Íńdíà àti lájorí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Íńdíà” ti wá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìsopọ̀ṣọ̀kan yìí kò mú ìbáradọ́gba ti ẹ̀yà wá.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Àwọn onísìn Híńdù ṣàlàyé nípa ìdí tí ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ (jātis, tí ó túmọ̀ sí, ‘ìbí,’ lólówuuru) ṣe ń gbilẹ̀ sí i nítorí pípín ẹgbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, tàbí àwọn varna, nítorí gbígbé ara wọn níyàwó (èyí tí a ti kà léèwọ̀ nínú àwọn ìwé ìsìn Híńdù nípa dharma). Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó jọ pé àwọn alábàá-èrò-orí òde òní rò pé ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ wá láti inú àwọn àṣà ààtò ìsìn ìdílé yíyàtọ̀síra, ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ nínú ẹ̀yà, àti ìyàtọ̀ iṣẹ́ àti ìmọṣẹ́dunjú. Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé òde òní pẹ̀lú ń siyè méjì bóyá ètò varna rírọrùn náà wulẹ̀ jẹ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ìsìn alábàá-èrò-orí, wọ́n sì ti tẹnu mọ́ ọn pé, ó ṣeé ṣe kí pípín ẹgbẹ́ àwùjọ onísìn Híńdù sí ìpín dídíjú gidigidi tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 3,000 ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ àti àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀ wà ní ìgbà láéláé pàápàá.”
Fún ìgbà díẹ̀, àwọn tí wọ́n wà nínú àwọn ìsọ̀rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń gbé ara wọn níyàwó, ẹ̀tanú tí wọ́n ti ní sí ara wọn tẹ́lẹ̀ látàrí àwọ̀ ara wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ mọ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni àwọn òfin dan-indan-in tí ń ṣàkóso ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ wá bẹ̀rẹ̀ nínú ìsìn, tí wọ́n kọ sínú ìwé mímọ́ Vedic àti Òfin (tàbí Àkójọ Ìlànà) ti Manu, amòye kan nínú ìsìn Híńdù. Àwọn Brahman fi kọ́ni pé ńṣe ni a bí àwọn tí wọ́n wà ní ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga pẹ̀lú àìlábààwọ́n kan tí ó yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀. Wọ́n gbin èrò ìgbàgbọ́ náà sọ́kàn àwọn Sudra, tàbí àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀ jù lọ, pé iṣẹ́ tí kò ní láárí tí wọ́n ń ṣe jẹ́ ìjìyà tí Ọlọ́run pa láṣẹ nítorí ìwà burúkú tí wọ́n hù nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wá sáyé àti pé ìgbìyànjú èyíkéyìí láti ṣẹ́pá ìpín ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ náà yóò sọ wọ́n di ẹni tí a ta nù. Bí ẹnì kan tí ó wà ní ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga bá gbé Sudra kan níyàwó, tí ó jẹun pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí ó pọnmi níbi tí ó ti pọnmi, tàbí tí ó ń wọ inú tẹ́ńpìlì kan náà pẹ̀lú rẹ̀, ó lè pàdánù àyè rẹ̀ bí ẹni tí ó wà ní ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga.
Bí Ètò Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Ṣe Rí Lóde Òní
Lẹ́yìn gbígba òmìnira ní ọdún 1947, ìjọba ilẹ̀ Íńdíà fọgbọ́n gbé òfin kan kalẹ̀ tí ó sọ ìyàsọ́tọ̀ ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ di ẹ̀ṣẹ̀ ìwà ọ̀daràn. Bí ìjọba ti mọ̀ pé àwọn onísìn Híńdù tí wọ́n jẹ́ ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀ ti wà ní ipò àìláǹfààní fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ó ṣe òfin fífi ipò nínú ètò ìjọba àti ipò tí a ń dìbò yanni sí títí kan àwọn ipò àbójútó ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ fún àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tí a ṣètò àti àwọn ẹ̀yà.a Ọ̀rọ̀ tí a ń lò fún ẹgbẹ́ onísìn Híńdù yìí ni “Dalit,” tí ó túmọ̀ sí “tí a ni lára, tí a tẹ̀ lórí ba.” Ṣùgbọ́n àkọlé ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ kan sọ pé: “Àwọn Kristẹni Tí Wọ́n Jẹ́ Dalit Béèrè fún Ẹ̀tọ́ [ẹ̀tọ́ fún àǹfààní iṣẹ́ àti àǹfààní ẹ̀kọ́ yunifásítì].” Báwo ni èyí ṣe ṣẹlẹ̀?
Àwọn àǹfààní púpọ̀ tí ìjọba fún àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀ nínú ìsìn Híńdù jẹ́ nítorí pé wọ́n ti jìyà àìṣèdájọ́ òdodo nítorí ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́. Nítorí náà, wọ́n ronú pé àwọn ìsìn tí wọn kò tíì lọ́wọ́ nínú ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kò lè retí láti jẹ nínú àwọn àǹfààní wọ̀nyí. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Dalit sọ pé, kì í ṣe àwọn onísìn Híńdù nìkan ni wọ́n ń ya àwọn sọ́tọ̀ nítorí pé àwọn jẹ́ ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀, tàbí ẹni tí a kò gbọ́dọ̀ fara kàn, tí a yí lọ́kàn padà, àmọ́ ‘àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́’ àwọn pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí ha jẹ́ òtítọ́ bí?
Àwọn Míṣọ́nnárì Kirisẹ́ńdọ̀mù àti Ètò Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́
Ọ̀pọ̀ àwọn onísìn Híńdù ni àwọn míṣọ́nnárì Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì láti ilẹ̀ Potogí, ilẹ̀ Faransé, àti Britain yí lọ́kàn padà ní àwọn ìgbà ìgbókèèrè-ṣàkóso. Àwọn ènìyàn láti inú gbogbo ìpele ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ di Kristẹni aláfẹnujẹ́, àwọn oníwàásù kan ń fa ojú àwọn Brahman mọ́ra, àwọn mìíràn ń fa ti Àwọn Ẹni Tí A Kò Gbọ́dọ̀ Fara Kàn mọ́ra. Ìyọrísí wo ni ẹ̀kọ́ àti ìwà àwọn míṣọ́nnárì náà ní lórí ìgbàgbọ́ fífìdímúlẹ̀ tí wọ́n ní nínú ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́?
Òǹkọ̀wé Nirad Chaudhuri sọ nípa àwọn ará Britain tí wọ́n wà ní Íńdíà pé, “àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n jẹ́ Íńdíà kò lè jókòó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Yúróòpù” nínú ṣọ́ọ̀ṣì. “Ìsìn Kristẹni kò fi èrò ìyọrí-ọlá ti ẹ̀yà tí a gbé ìṣàkóso Britain kà ní Íńdíà pa mọ́.” Ní fífi irú ẹ̀mí ìrònú tí ó jẹ èyí hàn, ní 1894, míṣọ́nnárì kan sọ fún Àjọ Abójútó Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì ní Ilẹ̀ Òkèèrè ní United States pé, yíyí tí a ń yí àwọn tí wọ́n jẹ́ ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀ lọ́kàn padà “ń mú kí a kó tajátẹran jọ sínú Ìjọ.”
Ní kedere, níní tí àwọn míṣọ́nnárì ìgbàanì nímọ̀lára ìyọrí-ọlá ní ti ẹ̀yà àti ìsopọ̀ṣọ̀kan èrò àwọn Brahman pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ló fa kí ọ̀pọ̀ àwọn tí a pè ní Kristẹni máa ṣe ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láìfibò ní Íńdíà.
Ètò Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Nínú Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Lónìí
Nígbà tí Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti Kátólíìkì náà, George Zur, ń sọ̀rọ̀ níbi Àpérò Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì ní Íńdíà ní 1991, ó wí pé: “Kì í ṣe àwọn onísìn Híńdù ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga nìkan ní ń bá àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tí a ṣètò, tí a yí lọ́kàn padà, lò bí ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀, àwọn Kristẹni ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga pẹ̀lú ń bá wọn lò lọ́nà bẹ́ẹ̀. . . . Wọ́n ya àwọn ibì kan sọ́tọ̀ fún wọn nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò àti itẹ́ ìsìnkú. A kò fojú dídára wo gbígbéyàwó láti inú ẹgbẹ́ náà . . . Ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ wọ́pọ̀ láàárín àwùjọ àlùfáà.”
Bíṣọ́ọ̀bù M. Azariah, ti Ṣọ́ọ̀ṣì Gúúsù Íńdíà, tí ó jẹ́ ará Ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì Oníṣọ̀kan, sọ nínú ìwé rẹ̀, The Un-Christian Side of the Indian Church, pé: “Àwọn Kristẹni Ìsọ̀rí Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ (Dalit) Tí A Ṣètò ni àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ń tipa báyìí yà sọ́tọ̀ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì oríṣiríṣi, èyí kì í sì í ṣe nítorí pé wọn kò yọrí ọlá àmọ́ nítorí pé a bí wọn sínú ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀, kódà bí wọ́n bá jẹ́ ìran kejì, ìkẹta, tàbí ìkẹrin ti Kristẹni. Àwọn Kristẹni ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga tí wọn kò tó nǹkan nínú Ìjọ ń hùwà ẹ̀tanú kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ wọn lọ, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran, ìgbàgbọ́ àti ìṣe Kristẹni kò sì nípa lórí wọn.”
Ìwádìí kan tí ìjọba ṣe nípa ìṣòro tí àwùjọ àwọn tí nǹkan kò ṣẹnuure fún ń ní ní Íńdíà, tí a mọ̀ sí Àjọ Mandal, ṣàwárí pé, ńṣe ni wọ́n pín àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni ní Kerala “sí onírúurú àwùjọ ẹ̀yà látàrí ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tí wọ́n ti wá. . . . Kódà, lẹ́yìn tí a bá ti yí wọn lọ́kàn padà, àwọn tí a yí lọ́kàn padà, tí wọ́n jẹ́ ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀ ni wọ́n ń bá a lọ láti hùwà sí bí Harijab . . . Àwọn ará Síríà àti àwọn Pulaya tí wọ́n jẹ́ ará Ìjọ kan náà pẹ̀lú wọn ń ṣe àwọn ààtò ìsìn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ilé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
Ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde Indian Express ní August 1996, sọ nípa àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Dalit pé: “Ní Tamil Nadu, àwọn ibùgbé wọn yàtọ̀ sí èyí tí àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga wà. Ní Kerala, wọ́n jẹ́ lébìrà aláìnílẹ̀ ní gbogbogbòò, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún àwọn Kristẹni ará Síríà àti àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga mìíràn tí wọ́n jẹ́ onílẹ̀. Kò sí ọ̀ràn àjọjẹ tàbí gbígbé ara ẹni níyàwó láàárín àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Dalit àti àwọn ti Síríà. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀, àwọn Dalit máa ń jọ́sìn nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tiwọn, tí a ń pè ní ‘ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Pulaya’ tàbí ‘ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Paraya.’” Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn orúkọ àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀. Ohun tí “paraya” jẹ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ni “pariah.”
Ìhùwàpadà sí Àìtẹ́nilọ́rùn
Ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ àwọn ọ̀gbẹ̀rì alákitiyan ọ̀ràn ìṣèlú, bí FACE (Àpérò Lòdì Sí Kíkó Àwọn Kristẹni Nífà), ń wá kí ìjọba ṣe àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Dalit láǹfààní. Lájorí àníyàn náà jẹ́ fífi ohun ìní ran àwọn Kristẹni tí a yí lọ́kàn padà lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn ń ṣàníyàn nípa bí a ṣe ń ṣe sí wọn nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Nínú lẹ́tà kan tí wọ́n kọ sí Póòpù John Paul Kejì, nǹkan bí 120 ènìyàn tí wọ́n fọwọ́ sí i sọ pé, “nítorí kí àwọn lè dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́” ni àwọn ṣe “fayọ̀ gba ìsìn Kristẹni” àmọ́ pé wọn kò jẹ́ kí àwọn wọ ṣọ́ọ̀ṣì tí ó wà ní abúlé tàbí láti lọ́wọ́ nínú àwọn ètò ìsìn. A fipá mú wọn láti kọ́ àwọn ilé tí àwọn Kristẹni ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò gíga—tàbí àlùfáà àdúgbò kankan—kò tẹ ibẹ̀ rí sí ẹ̀gbẹ́ òpópó kan ṣoṣo! Obìnrin kan tí ó jẹ́ mẹ́ńbà Kátólíìkì, tí ìdààmú bá òun pẹ̀lú, sọ pé: “Ó dájú pé ó ṣe pàtàkì sí mi pé kí ọmọkùnrin mi kàwé ní kọ́lẹ́ẹ̀jì tí ó ní ọ̀pá ìdíwọ̀n tí ó jíire. Ṣùgbọ́n ó tilẹ̀ ṣe pàtàkì jù pé kí a mọ̀ ọ́n bí ẹni tí ó bá àwọn arákùnrin rẹ̀ [tí wọ́n jẹ́ Kátólíìkì] dọ́gba.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń gbìyànjú láti mú ipò àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Dalit sunwọ̀n sí i, ọ̀pọ̀ ni kì í ní sùúrù. Àwọn ẹgbẹ́ bí Vishwa Hindu Parishad (Ẹgbẹ́ Híńdù Àgbáyé) ń gbìyànjú láti dá àwọn tí a sọ di Kristẹni padà sínú ẹgbẹ́ àwùjọ onísìn Híńdù. Ìwé agbéròyìnjáde Indian Express ròyìn ètò ìsìn kan tí 10,000 ènìyàn lọ, níbi tí èyí tí ó lé ní 600 irú àwọn ìdílé “Kristẹni” bẹ́ẹ̀ ti padà sínú ìsìn Híńdù.
Ọ̀nà ti Kristẹni Tòótọ́ Náà
Ká ní àwọn míṣọ́nnárì àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí a gbé kalẹ̀ ti fi ẹ̀kọ́ ti Kristi tí a gbé karí ìfẹ́ kọ́ni ni, ì bá tí sí “Àwọn Kristẹni Tí Wọ́n Jẹ́ Brahman,” ì bá tí sí “Àwọn Kristẹni Tí Wọ́n Jẹ́ Dalit,” bẹ́ẹ̀ ni ì bá tí sí “Àwọn Kristẹni Tí Wọ́n Jẹ́ Paraya.” (Mátíù 22:37-40) Ì bá tí sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn Dalit, bẹ́ẹ̀ ni ì bá tí sí ìyàsọ́tọ̀ níbi oúnjẹ. Kí ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tí ń sọni di òmìnira yìí tí ó borí ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́?
“Nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run . . . , tí kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò tàbí kí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”—Diutarónómì 10:17.
“Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, àti pé kí ìpínyà má ṣe sí láàárín yín, ṣùgbọ́n kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.”—1 Kọ́ríńtì 1:10.
“Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.
Bíbélì fi kọ́ni pé Ọlọ́run dá gbogbo ìran aráyé láti inú ọkùnrin kan. Ó tún sọ pé gbogbo àtọmọdọ́mọ ọkùnrin kan yẹn gbọ́dọ̀ ‘máa wá Ọlọ́run, kí wọ́n sì rí i, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.’—Ìṣe 17:26, 27.
Nígbà tí ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí wọ inú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, òǹkọ̀wé náà, Jákọ́bù, lábẹ́ agbára ìmísí, dẹ́bi fún un ní tààràtà. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ní ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láàárín ara yín, ẹ sì ti di onídàájọ́ tí ń ṣe àwọn ìpinnu burúkú, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” (Jákọ́bù 2:1-4) Ẹ̀kọ́ Kristẹni tòótọ́ kò gba irú ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ èyíkéyìí láyè.
Ó Yẹ Kí A Máa Ronú Bí Pé A Wà Nínú Ayé Tuntun
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fẹ́ láti yí àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti ìwà wọn àtijọ́ tí wọ́n ti kọ́ láti inú àwọn onírúurú ìsìn padà. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ti yọ ìmọ̀lára ìyọrí-ọlá tàbí àìyọrí-ọlá kúrò nínú ọkàn àti èrò inú wọn, yálà ìwọ̀nyí ta gbòǹgbò láti inú ìjagunmólú àwọn agbókèèrè-ṣàkóso, ẹ̀yà, ìyàtọ̀ ẹ̀yà, tàbí ètò kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́. (Róòmù 12:1, 2) Ohun tí Bíbélì pè ní “ilẹ̀ ayé tuntun,” nínú èyí tí “òdodo yóò sì máa gbé” yé wọn yékéyéké. Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà ológo tí ìyẹn jẹ́ fún ògìdìgbó àwọn ènìyàn tí ń jìyà ní ilẹ̀ ayé!—2 Pétérù 3:13.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tí a ṣètò” jẹ́ ọ̀rọ̀ àfàṣẹsí tí ó wà fún àwọn ẹgbẹ́ tí ipò wọn rẹlẹ̀ láàárín àwọn onísìn Híńdù, tàbí àwọn tí a ta nù, Àwọn Ẹni Tí A Kò Gbọ́dọ̀ Fara Kàn, tí wọ́n ti jìyà ìfiǹkanduni ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìṣúnná owó.
b Ọ̀rọ̀ kan tí M. K. Gandhi ṣẹ̀dá fún àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀. Ó túmọ̀ sí “Àwọn Ènìyàn Hari,” ọ̀kan lára àwọn orúkọ tí ọlọ́run kékeré náà, Vishnu, ń jẹ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]
“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Báwo Ló Ṣe Ń Rí Lára?
Òtítọ́ ni, báwo ló ṣe ń rí lára bí àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni bá hùwà síni bí pé a jẹ́ ẹni tí a ta nù? Kristẹni kan, tí a yí àwọn baba ńlá rẹ̀ lọ́kàn padà láti inú ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀ kan nínú ìsìn Híńdù, tí a mọ̀ sí Cheramar tàbí Pulaya, sọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kerala tí wọ́n bí i sí ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn pé:
Wọ́n pè mí sí ibi ìgbéyàwó kan tí ó jẹ́ pé púpọ̀ lára àwọn tí wọ́n pè ló jẹ́ mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí wọ́n rí mi níbi àpèjẹ náà, ó fa àìfararọ dé àyè kan, àwọn tí wọ́n sì wá láti Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Síríà sọ pé àwọn kò ní dúró níbi àpèjẹ náà àyàfi bí mo bá fi ibẹ̀ sílẹ̀, nítorí pé àwọn kò lè bá “pulaya” kan jẹun pọ̀. Nígbà tí bàbá ìyàwó kọ̀ jálẹ̀ láti gbà pẹ̀lú ohun tí wọ́n béèrè pé kí ó ṣe, gbogbo wọn lápapọ̀ fi ibi àpèjẹ náà sílẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, àwọn ènìyàn gbé oúnjẹ káàkiri. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé oúnjẹ sórí àwọn tábìlì kọ̀ láti palẹ̀ ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tí mo fi jẹun mọ́, wọ́n sì kọ̀ láti palẹ̀ orí tábìlì mi mọ́.
[Àwòrán]
Ṣọ́ọ̀ṣì kan ní Gúúsù Íńdíà, níbi tí kìkì àwọn ìsọ̀rí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ onípò rírẹlẹ̀ ti ń pàdé