ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 12/1 ojú ìwé 3-5
  • Iru Awọn Eniyan Wo Ni Iwọ ń ṣojurere sí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iru Awọn Eniyan Wo Ni Iwọ ń ṣojurere sí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ọ̀pá-ìdiwọ̀n Idiyele Ti Ó Wọ́pọ̀
  • Iwọnyi Ha Jẹ́ Awọn Ọ̀pá-ìdiwọ̀n Yíyèkooro Bi?
  • Ta Ni Ó Ní Ojurere Ọlọrun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ojú Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ẹ̀kọ́ Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ṣó Dájú Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ẹnì Kan Á Dáa Tó Bá Kàwé Dáadáa Tó Sì Lówó Rẹpẹtẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́—Lò Ó Láti Yin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 12/1 ojú ìwé 3-5

Iru Awọn Eniyan Wo Ni Iwọ ń ṣojurere sí?

“A ŃWÁ IYAWO. Ó nilati mọ́ra ki ó sì jẹ́ ọ̀pẹ́lẹ́ngẹ́, akẹkọọgboye tabi ó sàn ju ki ó jẹ́ ẹni ti ó ti gboye akọkọ jade. Ó gbọdọ wá lati inu idile olówó pẹlu awọn ohun-ìní. Ó tẹ́ wa lọ́rùn ki ó wá lati inu ẹgbẹ́-agbo kan-naa bii tiwa.”

BI IPOLOWO ti ó jẹmọ́ ọ̀ràn igbeyawo ti iwọ lè ri ninu iwe-irohin kan ni India ṣe kà niyẹn. Boya ó lè ṣeeṣe, ki iwọ rí ohun kan ti ó jọ bẹẹ ni ọpọ awọn apá ibomiran lori ilẹ̀-ayé. Ni India ìfitónilétí naa ni a sábà maa ń gbé jade lati ọwọ́ awọn òbí ọkọlọ́la kan. Idahunpada lè ní ninu aworan ọmọbinrin kan ti ó wọ aṣọ sari pupa-yòò kan ti ó sì wọ ailonka awọn ohun ìṣẹ̀ṣọ́ oniwura. Bi idile ọmọkunrin naa bá fọwọsi i, ìdúnàádúrà pẹlu èrò lati gbeyawo yoo bẹrẹ.

Awọn Ọ̀pá-ìdiwọ̀n Idiyele Ti Ó Wọ́pọ̀

Ni India ibeere fun iyawo kan ti ó mọ́ra jẹ́ ohun kan ti ó wọ́pọ̀ gan-an. Eyi jẹ́ nitori igbagbọ fifẹsẹmulẹ kan pe awọn ti a fẹnu lasan pe ni ẹgbẹ́-agbo rirẹlẹ ninu ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà Hindu jẹ́ adúláwọ̀. Ni ẹnu aipẹ yii, itolẹsẹẹsẹ kan lori tẹlifiṣọn ni India sọ ìtàn awọn ọmọbinrin meji kan, ọ̀kan mọ́ra ekeji sì dúdú. Ọmọbinrin ti ó mọ́ra naa jẹ́ òkú òǹrorò ati alaimọwaahu; ọmọbinrin dúdú naa jẹ́ oninuure ati oniwapẹlẹ. Iyipada onídán kan ṣẹlẹ, ọmọbinrin ti ó mọ́ra naa sì di dúdú gẹgẹ bi ijiya kan, nigba ti ọmọbinrin dúdú naa di ẹni ti ó mọ́ra gẹgẹ bi ẹ̀san rere kan. Dajudaju ẹkọ ti ìtàn naa fi kọni ni pe nigba ti rere lékè ní asẹhinwa-asẹhinbọ, mímọ́ra jẹ́ ẹ̀san rere kan ti a ń fẹ́.

Iru awọn imọlara ti ẹ̀yà ìran bẹẹ sábà maa ń rinlẹ ju bi ẹnikan ti lè loye lọ. Fun apẹẹrẹ, ara Asia kan lè ṣebẹwo si ilẹ Iwọ-oorun kan ki ó sì ráhùn pe a kò bá oun lò lọna ti ó dara nitori àwọ̀ ara oun tabi ojú oun ti ó ṣe fíntínfíntín. Iru awọn ìwà bẹẹ dà á laamu, ó sì nimọlara pe a kò fi ẹ̀tọ́ bá oun lò. Ṣugbọn nigba ti o bá pada si ilẹ̀ ibilẹ rẹ̀, oun lè hùwà si awọn eniyan ti wọn wá lati inu awujọ ẹ̀yà miiran ni ọ̀nà kan-naa gẹ́lẹ́. Kódà lonii àwọ̀ ara ati ipilẹ ẹ̀yà-ìran ń kó ipa pataki kan lori bi ọpọlọpọ eniyan ṣe ń fojudiwọn iniyelori ẹlomiran.

“Owó sì ni idahun ohun gbogbo,” ni Ọba Solomoni ti igbaani kọwe. (Oniwasu 10:19) Ẹ wo bi iyẹn ti jẹ́ otitọ tó! Ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì pẹlu ń nipa lori oju ti a fi ń wo awọn eniyan. Orisun ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì naa ni a kìí sábà gbé ibeere dide si. Ọkunrin kan ha ti di ọlọ́rọ̀ nitori iṣẹ́ aṣekara tabi iṣeto didara tabi nipa abosi bi? Eyiini kò jẹ́ nǹkankan. Ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì, boya a rí i lọna rere tabi bẹẹkọ, ń sún ọpọlọpọ eniyan lati wá ojurere ọlọ́rọ̀ naa.

Ẹkọ-iwe giga pẹlu ni a ti gbé gẹ̀gẹ̀ ninu ayé onidiije yii. Gbàrà ti a bá ti bí ọmọ kan, awọn òbí ni a ń rọ̀ lati tu owó rẹpẹtẹ jọ fun ẹkọ-iwe. Nigba ti o bá maa fi pe ọmọ ọdun meji tabi mẹta, wọn a maa ṣaniyan nipa mímú un wọ ile-ẹkọ awọn ògo-wẹẹrẹ tabi jẹ́lé-ó-sinmi ti o yẹ gẹgẹ bi igbesẹ akọkọ loju ọ̀nà irin-ajo gigun si gbigboye-ẹkọ yunifasiti. Ó dabi ẹni pe awọn kan ronu pe iwe-ẹri onipo-iyi kan ń mú ẹ̀tọ́ lati gba ọ̀wọ̀ ati ojurere lati ọ̀dọ̀ awọn ẹlomiran dání pẹlu rẹ̀.

Bẹẹni, àwọ̀ ara, ẹkọ-iwe, owó, ipilẹ ẹ̀yà-ìran—iwọnyi ti di ọ̀pá-ìdiwọ̀n nipa eyi ti ọpọlọpọ eniyan fi ń sọ èrò wọn nipa ẹlomiran tabi, ti wọn kúkú fi ń ṣe idajọ ẹlomiran laiwadii. Awọn wọnyi ni kókó ti ń pinnu ẹni ti wọn ń ṣojurere sí ati ẹni ti wọn kò ṣe bẹẹ sí. Iwọ ń kọ́? Ta ni iwọ ń ṣojurere sí? Iwọ ha ka ẹnikan ti ó ni owó, ti ó mọ́ra, tabi ní ẹkọ-iwe giga gẹgẹ bi ẹni ti ó tubọ yẹ fun ọ̀wọ̀ ati ojurere bi? Bi ó bá rí bẹẹ, iwọ nilati gbé ipilẹ fun awọn imọlara rẹ yẹwo gidigidi.

Iwọnyi Ha Jẹ́ Awọn Ọ̀pá-ìdiwọ̀n Yíyèkooro Bi?

Iwe naa Hindu World ṣakiyesi pe: “Eyikeyii ninu ẹgbẹ́-agbo rirẹlẹ ti ó bá pa ọ̀kan ninu ẹgbẹ́-agbo ti ó lọ́lá julọ ni a lè daloro titi dé oju iku ki a sì gbé ẹsẹ lé ohun-ìní rẹ̀, ọkàn rẹ̀ ni a sì fiya jẹ titilọ gbére. Ọ̀kan ninu ẹgbẹ́-agbo ti ó lọ́lá julọ kan ti ó bá pa ẹnikẹni ni a wulẹ lè bu owó itanran fun ki a ma sì fiya ikú jẹ ẹ́ lae.” Bi o tilẹ jẹ́ pe iwe naa sọrọ nipa ìgbà atijọ, ki ni nipa tonii? Ẹtanu ti ẹ̀yà-ìran ati pakanleke laaarin ẹ̀yà ti mú ki àgbàrá-ẹ̀jẹ̀ ṣàn kódà ni ọrundun lọna ogun yii. Eyi ni a kò sì fimọ si India nikan. Ikoriira ati iwa-ipa ń baa lọ nipasẹ eto kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ni South Africa, ẹtanu ti ẹ̀yà-ìran ni United States, ẹtanu nitori ifẹ orilẹ-ede ẹni ni Baltics—itolẹsẹẹsẹ naa lọ rẹrẹ—imọlara ẹmi ilọlaju abinibi sì ni okunfa gbogbo rẹ̀. Dajudaju, iru ṣiṣe ojurere si ẹnikan ju ẹlomiran lọ bẹẹ nitori ẹ̀yà-ìran tabi ìlú ibilẹ kò tíì mú awọn eso rere, alalaafia jade.

Ki ni nipa ti ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì? Laiṣe àníàní, ọpọlọpọ di ọlọ́rọ̀ nipasẹ iṣẹ́ aṣekara alailabosi. Bi o ti wu ki o ri, ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì tabua ni a ti tùjọ pelemọ lati ọwọ́ awọn ọdaran amòòkùnjalè, awọn onifayawọ, awọn olugbẹhin-ọgba-ṣowo oogun, awọn oluṣowo ohun ìjà ogun laibofinmu, ati awọn miiran. Nitootọ, awọn kan lara awọn wọnyi ń ṣe itọrẹ aanu tabi ṣe itilẹhin fun awọn iwewee lati ran awọn talika lọwọ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn ìwà ọdaran wọn ti mú ijiya ati òṣì ti kò ṣee fẹnusọ bá awọn ojiya ipalara wọn. Kódà awọn ti iwa-aitọ wọn tilẹ kere ni ifiwera paapaa, iru bi awọn wọnni ti ń gba abẹtẹlẹ tabi lọwọ ninu iṣowo màgòmágó, ti ṣokunfa ijakulẹ, iṣeleṣe, ati ikú nigba ti awọn eso amujade wọn tabi iṣẹ́ wọn bá kuna tabi ṣàìgbéṣẹ́. Dajudaju, níní ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì niti araarẹ̀ kìí ṣe ipilẹ fun idajọ bibarade.

Ki ni, nigba naa, nipa ẹkọ-iwe? Ǹjẹ́ itolẹsẹẹsẹ awọn oyè-ẹ̀kọ́ ti ó lọ jantirẹrẹ ati orukọ oyè lẹhin orukọ ẹnikan ha mu un daniloju pe oun jẹ alailabosi ati olotiitọ bi? Eyi ha tumọsi pe a nilati fi ojurere hàn sí i bi? A gbà bẹẹ, ẹkọ-iwe lè mu ki ìmọ̀ ẹnikan tubọ gbooro si, ọpọlọpọ ti ó sì ti lo ẹkọ-iwe wọn lati fi ṣe awọn ẹlomiran lanfaani yẹ fun ọlá ati ọ̀wọ̀. Ṣugbọn ìtàn kún fọ́fọ́ fun awọn apẹẹrẹ ìkóninífà ati inilara awọn gbáàtúù lati ọwọ́ ẹgbẹ́ awọn ọmọwe. Sì ṣakiyesi ohun ti ń ṣẹlẹ ninu awọn kọlẹẹji tabi yunifasiti lonii. Awọn ọgbà ikawe ni a ti kó awọn iṣoro ilokulo oogun ati awọn àrùn ti iṣekuṣe ṣokunfa rẹ̀ bá, ọpọlọpọ awọn akẹkọọ ni wọn sì forukọ silẹ kìkì nitori ilepa owó, agbara, ati òkìkí. Ẹkọ-iwe ẹnikan nikanṣoṣo kò ṣeegbarale gẹgẹ bi àmì itọka iru ẹni ti ó jẹ́ niti gidi.

Bẹẹkọ, àwọ̀ ara, ẹkọ-iwe, owó, ipilẹ ẹ̀yà-ìran, tabi iru awọn kókó abájọ miiran bẹẹ kìí ṣe ipilẹ ti ó yekooro lori eyi ti a lè gbà ṣedajọ iniyelori ẹlomiran. Awọn Kristian kò gbọdọ jẹ́ ki ọwọ́ wọn dí pẹlu awọn ọ̀ràn wọnyi ninu isapa wọn lati jere ojurere awọn ẹlomiran. Ki ni, nigba naa, ni ẹnikan gbọdọ jẹ́ ki o jẹ oun lọ́kàn? Awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n wo ni ẹnikan nilati tẹle?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́