ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 12/1 ojú ìwé 5-6
  • Ta Ni Ó Ní Ojurere Ọlọrun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Ó Ní Ojurere Ọlọrun?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ọ̀pá-ìdiwọ̀n Giga Jù Ti Ọlọrun
  • A Lè Jere Ojurere Ọlọrun
  • Iru Awọn Eniyan Wo Ni Iwọ ń ṣojurere sí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ṣé Ọlọ́run Ṣojúure Sáwọn Orílẹ̀-èdè Kan Ju Àwọn Míì Lọ ni?
    Jí!—2005
  • Ǹjẹ́ o ‘Ní Ọrọ̀ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run’?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Tálákà?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 12/1 ojú ìwé 5-6

Ta Ni Ó Ní Ojurere Ọlọrun?

GBOGBO wa ni a ń fẹ́ ki awọn alabaakẹgbẹpọ wa fẹran wa. Fun Kristian kan ìfẹ́-ọkàn ti o tubọ lagbara ni lati rí ojurere Ọlọrun. Nipa Jehofa Ọlọrun, a sọ ọ́ ninu Orin Dafidi 84:11 (NW) pe: “Ojurere ati ògo ni oun ń funni. Jehofa fúnraarẹ̀ kì yoo fa ọwọ ohunkohun ti ó dara sẹhin kuro lọdọ awọn ti ń rìn ni airiwisi.” Nigba ìbí Jesu, igbe ayọ awọn angẹli ọrun ṣeleri “alaafia lori ilẹ̀-ayé fun awọn eniyan ti oun ṣojurere si!”—Luku 2:14, Moffatt.

Ṣugbọn ta ni Ọlọrun ń ṣojurere si? Awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun ha jẹ́ ọkan-naa pẹlu ti eniyan bi? Lọna ti ó yéni yekeyeke, wọn kò rí bẹẹ, gẹgẹ bi a ti fihàn ninu ohun ti a jiroro ninu ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti ó ṣiwaju. Dajudaju, niwọn bi a ti gba awọn Kristian nimọran lati “ṣe afarawe Ọlọrun,” ẹnikọọkan wa lè beere pe, Emi ha ń fi ojurere hàn si awọn eniyan ti Ọlọrun ṣojurere si, tabi emi ha ni itẹsi lati tẹle awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n ayé ninu ṣiṣedajọ awọn eniyan? (Efesu 5:1) Lati jere ojurere ati itẹwọgba Jehofa, a nilati lo iṣọra lati rí awọn nǹkan lati oju-iwoye rẹ̀.

Awọn Ọ̀pá-ìdiwọ̀n Giga Jù Ti Ọlọrun

“Ọlọrun kìí ṣe ojuṣaaju eniyan,” ni aposteli Peteru sọ, “ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ede, ẹni ti o bá bẹru rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀.” Siwaju sii, aposteli Paulu jẹrii sii pe Ọlọrun “ ti fi ẹ̀jẹ̀ kan-naa dá gbogbo orilẹ-ede.” (Iṣe 10:34, 35; 17:26) Nitori naa, ó wulẹ bá ọgbọ́n ironu mu lati de ori ipinnu naa pe gbogbo eniyan dọgba niwaju Ọlọrun laika ohun ti àmì animọ ara ìyára wọn jẹ́ sí. Nigba ti ọ̀ràn ti rí bayii, kì yoo ṣanfaani fun Kristian kan lati ṣojurere si ẹnikan laiyẹ kìkì nitori pe onitọhun wá lati inu ayika kan ni pataki tabi nitori ti ó jẹ́ alawọ ara kan pàtó tabi nitori ti ó wá lati inu ẹ̀yà-ìran miiran. Kàkà bẹẹ, oun yoo ṣe daradara lati tẹle Awofiṣapẹẹrẹ rẹ̀, Jesu Kristi, nipa ẹni ti awọn ọ̀tá paapaa gba pe kò fi ojuṣaaju hàn.—Matteu 22:16.

Ọ̀rọ̀ naa “oju larí” ni a maa ń lò nigba miiran lati ṣapejuwe ohun kan ti kò jinlẹ tabi ṣe pataki. Ohun ti àwọ̀ ara jẹ́ gan-an niyẹn; ojú larí lasan ni. Àwọ̀ ara ẹnikan kò fi ìwà rẹ̀ tabi awọn animọ rẹ̀ hàn ni ọ̀nà eyikeyii. Nigba ti ó bá kan yíyan awọn eniyan ti a o bá kẹgbẹpọ, ti a o bá jẹun, tabi ti a o bá gbọwọ́, dajudaju a kò gbọdọ wo àwọ̀ ara ni pataki. Ranti pe, omidan naa ti ó ru kíkọ orin ewì didara julọ ati eléré-ìfẹ́ soke sọ nipa araarẹ̀ pe: “Emi dú, ṣugbọn mo ní ẹwà, . . . mo dú, nitori pe oorun ti boju wò mi.” (Orin Solomoni 1:5, 6) Kìí ṣe ẹ̀yà-ìran tabi àwọ̀ ni ó jẹ́ ipilẹ titọ fun fifi ojurere hàn. Ohun ti ó tubọ ṣe pataki ni pe boya ẹnikan bẹru Ọlọrun ti ó sì ń ṣe awọn iṣẹ́ òdodo.

Bawo ni Ọlọrun ṣe nimọlara nipa níní ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì? Ninu gbogbo awọn ti Ọlọrun nifẹẹ ti ó sì ṣojurere si, Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ni ẹni akọkọ. Sibẹ, nigba ti ó wà ni ayé, Jesu “kò ní ibi ti yoo gbé fi ori rẹ̀ lé.” (Matteu 8:20) Oun kò ni awọn ilẹ, ilé, pápá, igi-eleso, tabi ẹranko. Sibẹ, Jehofa bu ọlá fun un ó sì gbé e ga sí ipo kan ti ó ju ti gbogbo ẹnikẹni miiran lọ ni agbaye afi ti Ọlọrun fúnraarẹ̀.—Filippi 2:9.

Jesu Kristi rí ojurere Ọlọrun nitori pe oun lọ́rọ̀ kìí ṣe niti dukia ti ara ṣugbọn niti awọn iṣẹ́ rere. (Fiwe 1 Timoteu 6:17, 18.) Ó gba awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nimọran pe: “Ẹ maṣe to iṣura jọ fun araayin ni ayé, nibi ti kokoro ati ìpáàrà íbàájẹ́, ati nibi ti awọn olè írunlẹ̀ ti wọn sìí jale: ṣugbọn ẹ to iṣura jọ fun araayin ni ọrun, nibi ti kokoro ati ìpáàrà kò lè ba a jẹ́, ati nibi ti awọn olè kò lè runlẹ ki wọn sì jale.” (Matteu 6:19, 20) Nipa bayii, dipo fifi ojurere hàn si kìkì awọn ti wọn ní ọrọ̀ niti awọn dukia ti ayé, awọn Kristian kì yoo fi iyatọ hàn lori ipilẹ awọn ohun-ìní ti ayé. Wọn yoo ṣe àwárí awọn wọnni ti wọn lọ́rọ̀ sipa ti Ọlọrun laika boya wọn lọ́rọ̀ tabi talika lọna ti ayé sí. Maṣe gbagbe lae pe “Ọlọrun . . . yan awọn talaka ayé yii ṣe ọlọ́rọ̀ ni igbagbọ, ati ajogun ijọba naa.” (Jakọbu 2:5) Bi iwọ bá di oju-iwoye Ọlọrun mú, iwọ kì yoo kó sọwọ aṣa ti ó gbilẹ ti ṣiṣojurere si tabi gbigbiyanju lati jere ojurere awọn ọlọ́rọ̀ nipa ti ara lae.

Nipa ti ẹkọ-iwe, Bibeli fihàn ni kedere pe Ọlọrun rọ̀ wá lati wá ìmọ̀ ati ọgbọ́n ati pe Jesu Kristi ni olukọni ti ó ga julọ ti ó tii rin lori ilẹ̀-ayé rí. (Owe 4:7; Matteu 7:29; Johannu 7:46) Ṣugbọn kìí ṣe ọgbọ́n tabi ẹkọ-iwe ti aye ni ó ń rí ojurere Ọlọrun. Ni odikeji eyi, Paulu sọ fun wa pe “kìí ṣe ọpọ awọn ọlọgbọn eniyan nipa ti ara, . . . ni a pè: Ṣugbọn Ọlọrun ti yan awọn ohun were ayé lati fi daamu awọn ọlọgbọn.”—1 Korinti 1:26, 27.

Ọlọrun ṣojurere si awọn wọnni ti wọn kawe daradara, kìí ṣe ninu awọn ẹ̀kọ́ ti ayé ti a ń kọ ni awọn ile-ẹkọ giga, ṣugbọn ninu “èdè mimọ gaara” ti otitọ gẹgẹ bi a ṣe rí i ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. (Sefaniah 3:9, NW) Dajudaju, Jehofa funraarẹ ń kọ́ awọn eniyan rẹ̀ lonii nipasẹ itolẹsẹẹsẹ ẹkọ-iwe kan ti ó ti nasẹ dé ipẹkun ayé. Gẹgẹ bi wolii Isaiah sì ti sọtẹlẹ, awọn eniyan ni gbogbo orilẹ-ede ń dahunpada nipa sisọ pe: “Ẹ jẹ ki a lọ si oke Oluwa, si ile Ọlọrun Jakobu; Oun ó sì kọ́ wa ni ọ̀nà rẹ̀, awa ó sì maa rin ni ipa rẹ̀.” Nitori naa, dipo fifi ògo fun ẹkọ-iwe ti ayé, awọn Kristian yoo ṣawari awọn wọnni ti wọn fihàn nipa ọ̀rọ̀ ati iṣe wọn pe wọn jẹ́ “awọn wọnni ti Jehofa kọ́” niti tootọ. Nipa ṣiṣe bẹẹ, wọn yoo gbadun ‘ọpọ alaafia’ ti Jehofa ń funni.—Isaiah 2:3; 54:13, NW.

A Lè Jere Ojurere Ọlọrun

Bẹẹni, awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun fun ṣiṣojurere si awọn ẹlomiran yatọ patapata si ti eniyan. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awa gbọdọ saakun lati jẹ ki ọ̀nà rẹ̀ dari wa bi awa bá fẹ́ jere ojurere ni oju rẹ̀. Eyi tumọsi pe awa gbọdọ kọ́ lati fi oju-iwoye Ọlọrun rí awọn ẹlomiran kìí sii ṣe nipasẹ ọ̀pá-ìdiwọ̀n eniyan, ti a ti fi imọtara-ẹni-nikan ati ẹtanu nipa le lori. Bawo ni a ṣe lè ṣe iyẹn?

Jehofa Ọlọrun a maa ṣayẹwo ọkan-aya ẹnikan a sì maa ṣojurere si awọn wọnni ti wọn fi awọn animọ bii ifẹ, iwarere, inurere, ati ipamọra hàn. Awa naa gbọdọ ṣe bakan naa. (1 Samueli 16:7; Galatia 5:22, 23) Awa nilati wo ohun ti ẹnikan jẹ́ ninu lọ́hùn-ún, titi dé iwọn ààyè ti awa eniyan lè ṣe, kìí sii ṣe àwọ̀ ara rẹ̀ tabi ipilẹ ẹ̀yà-ìran rẹ̀. Dipo ṣiṣawari awọn eniyan ti wọn lọ́rọ̀ nipa awọn ohun-ìní ti ara, awa yoo ṣe daradara lati ni oju-iwoye Ọlọrun nipa ọrọ̀ lọ́kàn ki a sì lakaka lati ‘jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu awọn iṣẹ rere, ọ̀làwọ́, ki a sì muratan lati ṣajọpin.’ (1 Timoteu 6:18, NW) Lati jere ojurere Ọlọrun, awa nilati maa baa lọ lati maa wá ìmọ̀ pipeye nipa Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, nipa didi ẹni ti o mọ èdè mimọ gaara ti otitọ daradara. (Johannu 17:3, 17) Ni ṣiṣe bẹẹ, awa pẹlu yoo wà lara awọn wọnni ti Ọlọrun ń ṣojurere si.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́