Omi àti Ìlera Rẹ
“ÌWÉ ìròyìn Health tọ́ka pé: “O kò lè fi bí òùngbẹ ṣe ń gbẹ ọ́ tó pinnu ìwọ̀n omi tí ara rẹ nílò.” Síbẹ̀, mímu omi púpọ̀ ṣe pàtàkì fún wíwà ní ipò ti ara àti ìmọ̀lára tí ó wà déédéé, kódà fún ìrísí wa pẹ̀lú. Ara wa ń pàdánù omi léraléra nínú ìlàágùn, omijé, àti ìtọ̀, bákan náà, nínú èémí. Omi tí a ń pàdánù yìí nílò àfidípò. Báwo ni èyí tí a nílò ṣe pọ̀ tó? Ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ dámọ̀ràn mímu, ó kéré tán, ife omi mẹ́jọ—lítà méjì—lójoojúmọ́.
Èé ṣe? Omi ṣe pàtàkì fún gbígbé àwọn èròjà aṣaralóore kiri nínú ara wa àti fún gbígbé ìdọ̀tí jáde. Ó wúlò fún ṣíṣàkóso ìdíwọ̀n ooru ara wa àti yíyí àwọn oríkèé ara wa. Ìwé ìròyìn Health sọ pé: “Kódà, bí ó bá ku ìwọ̀n kékeré kí ó tó, ó lè mú kí o káàárẹ̀ . . . tàbí kí o ṣàìsàn. Ìpàdánù omi ara ni okùnfà wíwọ́pọ̀ jù lọ tí a maa ń gbójú fò tí ń fa àárẹ̀.” Ìwé ìròyìn náà dámọ̀ràn pé: “Má ṣe jẹ́ kí jíjẹ́ tí kọfí àti tíì, ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí ó ní kaféènì nínú, àti ọtí líle, jẹ́ ohun olómi tàn ọ́ jẹ; ní gidi, wọ́n ń dá kún ìpàdánù omi ara ni.” Kaféènì àti ọtí líle ń jẹ́ kí ìtọ̀ pọ̀, kí ara sì pàdánù omi.
Ní àfikún, “awọ ara rẹ nílò omi kí ó lè ṣe jọ́mújọ́mú, kí ó sì rọ̀.” Láti ṣàrànṣe nínú èyí, a tún lè lo àwọn ìpara tí ń fún awọ ara lómi. Ṣùgbọ́n wọn kì í gbé omi wá sí awọ ara. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi ìpele ìdáàbòbò kan sí i, tí yóò ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí omi tí ó ti wà nínú awọ ara wà níbẹ̀. Mímú kí omi yìí wà níbẹ̀ túbọ̀ ń ṣe pàtàkì sí i bí àgbà ṣe ń dé, níwọ̀n bí awọ ara ti máa ń pàdánù díẹ̀ lára agbára rẹ̀ láti gba omi dúró bí àgbà ṣe ń dé.
Ó bani nínú jẹ́ pé ní ibi púpọ̀ lágbàáyé, ìsapá púpọ̀ jọjọ ni a nílò láti rí omi mímọ́tónítóní, tí ó pọ̀ tó. Ṣùgbọ́n ìsapá kì í ṣe asán. Lọ́nàkọnà, máa mu omi púpọ̀, sì ṣàmúlò àǹfààní ọ̀nà rírọrùn yìí tí yóò mú kí ara rẹ máa yá gágá!